A Kì Yoo Já Ọ Kulẹ̀
Ó GBA tọkọtaya kan ni ilẹ̀ Philippines ni ọjọ meji lati de ibẹ̀. Wọn rin ìrìn 40 ibusọ, ni gbigbe awọn ọmọ meji kọja gba inu igbo ti kokoro mùjẹ̀mùjẹ̀ ti kunfọfọ ati ori awọn odò ti òjò nipaṣẹ ìjì lile ti mu ki o kun dẹmudẹmu. Ṣugbọn wọn pinnu lati maṣe tàsé rẹ̀.
Awọn obinrin meji ni ilẹ̀ Zaire rin ìrìn ti o ju 300 ibusọ lọ, ni lilo ọjo 14 loju ọ̀nà, lati lè wà nibẹ. Bakan naa ni ilẹ̀ Zaire, ọkunrin kan, ẹni 70 ọdun, dé ibẹ nipa gigun kẹkẹ rẹ̀ fun 160 ibusọ. Ọna jíjìn naa ati inira rẹ̀ kò kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá a. Ohun ṣiṣe pataki naa ni lati maṣe tàsé rẹ̀.
Nibo ni gbogbo wọn ń lọ? Si ọ̀kan lara apejọpọ nla tí Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ṣeto fun ni orilẹ-ede wọn ni. Bi o sì ti wu ki ìrìn àjò naa nira tó, gbogbo wọn nimọlara pe isapa wọn yẹ fun un.
Iwọ ha ti ṣe awọn iwewee lati tun wà ni Apejọpọ Agbegbe ti “Awọn Olùtan Imọlẹ” ni ọdun 1992 bi? O ṣeeṣe pe o kò nilati ṣe tó bi awọn oluṣotitọ wọnyi ti ṣe lati lè wà nibẹ. Bi ó bá tilẹ ni ọ lara diẹ paapaa, a rọ̀ ọ́ lati maṣe tàsé rẹ̀.
A ti ṣeto awọn itolẹṣẹẹsẹ titayọ ti o si gbeṣẹ gidigidi. Bi iwọ bá gbadun ibakẹgbẹ Kristian ti o si nifẹẹ ninu kikẹkọọ bi o ṣe lè ṣawari alaafia tootọ, ohun ti ọjọ ọla ní ní ipamọ, tabi ọna ti o darajulọ lati ṣe ifẹ-inu Ọlọrun, awa lè mú un dá ọ loju pe a ki yoo já ọ kulẹ̀. Ẹlẹ́rìí eyikeyii laduugbo rẹ̀ yoo sọ fun ọ nibo ni ati nigba wo ni a o ṣe apejọpọ ti o sunmọ tosi rẹ julọ.