ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 6/1 ojú ìwé 31
  • Ibeere Lati Ọwọ Awọn Onkawe

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ibeere Lati Ọwọ Awọn Onkawe
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Má Ṣe Bẹ̀rù Àwọn Ẹranko Abàmì Náà
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2019
  • Bíbá Ẹranko Rírorò Méjì Wọ̀jà
    Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
  • Pípa Bábílónì Ńlá Run
    Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 6/1 ojú ìwé 31

Ibeere Lati Ọwọ Awọn Onkawe

Njẹ Bibeli ṣetilẹhin fun wíwà awọn “unicorn” (ẹranko inu ìtàn àròsọ ti o dabi ẹṣin pẹlu iwo kanṣoṣo ni iwaju ori rẹ̀), ti a menukan ninu awọn ẹ̀dà itẹjade miiran bi?

Ẹ̀dà itumọ ti King James, Douay, ati awọn ẹ̀dà itumọ miiran, mẹnukan awọn unicorn. Ṣugbọn eyi kò ri bẹẹ pẹlu awọn ẹ̀dà itumọ ti ode-oni ti wọn tumọ ede Heberu naa lọna ṣiṣe rẹgi.—Orin Dafidi 22:21; 29:6; 92:10 (21:22; 28:6; 91:11, Douay).

La awọn ọrundun kọja ọpọ awọn ìtàn arosọ ni o ti gbèrú nipa ẹranko kan ti o ni ara ati ori ẹṣin ṣugbọn ti o ni ẹsẹ̀ agbọnrin ati ìrù kinniun. Boya kiki ẹ̀yà ara ti o dayatọ julọ lara ẹ̀dá inu ìtàn àròfọ̀ yii ni ìwo lílọ́ kanṣoṣo ti o wà ni iwaju ori rẹ̀.a

“Awọn eniyan fi ìgbà kan gbà pe ìwo unicorn ní oògùn aporó nínú, ati laarin awọn Sanmani Agbedemeji, awọn iyẹfun ti a tànmọ́ ọ̀n pe a ṣe lati ara iru awọn ìwo bẹẹ ni a ń tà ni iye owo gọbọi. Ọpọjulọ awọn opitan ni wọn gbagbọ pe ère unicorn ni a gbéyọ lati ara àgbọ́sọ lati inu ìtàn awọn ara Europe nipa àgbáǹréré.” (The World Book Encyclopedia) Awọn ohun iranti kan bayii ti awọn ara Asiria ati Babiloni fi awọn ẹranko oniwo kan hàn. Iwọnyi ni a ti wa dá mọ̀ si awọn akọ agbọnrin, ewurẹ ìgbẹ́, abo maluu, ati akọ maluu ti a yaworan rẹ̀ lati ẹ̀gbẹ́ kan, ìrí kan ti kò fi awọn ìwo mejeeji hàn.

Eyi fa ifẹ awọn akẹkọọ Bibeli mọra diẹ nitori pe ni ìgbà mẹsan-an ni Iwe Mimọ tọka si ẹranko kan pẹlu ede isọrọ Heberu naa reʼemʹ. (Numeri 23:22; 24:8; Deuteronomi 33:17; Jobu 39:9, 10; Orin Dafidi 22:21; 29:6; 92:10; Isaiah 34:7) Awọn olùtumọ̀ ti fi ìgbà pipẹ ṣaini idaniloju niti ẹranko wo ni a nilọkan. Ẹ̀dà Septuagint ti Griki tumọ reʼemʹ pẹlu òye ti ‘ìwo kanṣoṣo,’ tabi unicorn. Ẹ̀dà ti Latin Vulgate saba maa ń tumọ rẹ̀ si “àgbáǹréré.” Awọn ẹ̀dà itumọ miiran lo ‘ẹhanna akọ maluu,’ ‘ẹranko ẹhanna,’ tabi ‘ẹfọ̀n.’ Robert Young wulẹ yá ede Heberu naa lò ti o sì pa lẹ́tà rẹ̀ dà si ti Gẹẹsi gẹgẹ bii “Reem,” ni pataki julọ o fi onkawe silẹ sinu okunkun.

Àmọ́ ṣa o, awọn ọmọwe ode-oni, ti mu pupọ ìdíjúlùpọ̀ kuro lori ọrọ naa reʼemʹ. Awọn onṣewe atumọ ọrọ Ludwig Koehler ati Walter Baumgartner fihan pe o tumọ si “awọn ẹhanna akọ maluu” ti o ni orukọ imọ ijinlẹ naa Bos primigenius. Eyi jẹ “ìsọ̀rí ẹ̀yà kan ninu iran awọn ẹranko oniwo nla pẹlu pátákò lẹsẹ.” Iwe gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica ṣalaye pe:

“Awọn apá àyọkà ọlọ́rọ̀-ewì kan bayii ninu Majẹmu Laelae tọka si ẹranko alagbara oníwo gàgàrà kan ti a pe ni reʼemʹ. Ọrọ yii ni a tumọsi ‘unicorn’ tabi ‘àgbáǹréré’ ninu ọpọlọpọ ẹ̀dà itumọ, ṣugbọn pupọ awọn itumọ Bibeli ti ode-oni yàn lati lo ‘ẹhanna akọ maalu ìgbẹ́’ (aurochs), eyi ti o jẹ itumọ titọna fun ọrọ Heberu naa reʼemʹ.”

Niwọn bi o ti jẹ pe ninu ede Gẹẹsi ti lọọlọọ “akọ maluu” ni òye itumọ akọ maluu ti a tẹ̀lọ́dàá, ẹ̀dà itumọ ti New World Translation of the Holy Scriptures tumọ reʼemʹ lọna ti o ṣọ̀kandélẹ̀ ati lọna titọ si “ẹhanna akọ maluu.” O dabi pe aurochs (ẹhanna akọ maluu) ti di eyi ti o ti parẹ tan nigba ti o fi di ọrundun 17, ṣugbọn awọn onimọ ijinlẹ ti fa ọrọ yọ jade pe o yatọ patapata si unicorn ti inu ìtàn àròsọ. Aurochs ti atijọ ni ara ti o tó nǹkan bii ẹsẹ bata mẹfa, o si gùn ni ẹṣẹ bata mẹwaa ni ìbú. O lè wọ̀n to 2,000 iwọ̀n pound, ọkọọkan awọn ìwo rẹ̀ si lè to 30 ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn.

Eyi dajudaju wà ni ibaamu pẹlu bi Bibeli ti mẹnukan ọrọ naa reʼemʹ, tabi ẹhanna akọ maluu. A mọ̀ ọ́n fun agbara ati itẹsi ihuwa alaiṣee ṣakoso rẹ̀ (Jobu 39:10, 11, NW) ati pẹlu ìyárakánkán rẹ̀. (Numeri 23:22; 24:8) Dajudaju o ni ìwo meji, kì í ṣe ẹyọkan gẹgẹ bii ti unicorn inu itan àròfọ̀. Mose tọka si awọn ìwo rẹ̀ nigba ti o ń ṣakawe ẹ̀yà alagbara meji ti yoo jẹyọ lati ọdọ awọn ọmọkunrin Josẹfu mejeeji.—Deuteronomi 33:17.

Nitori naa Bibeli kò ṣetilẹhin fun erongba nipa awọn unicorn bi o ti ṣe gbajumọ ninu itan àròfọ̀. O yaworan pipeye ṣaa, bi o tilẹ jẹ pe o mọ niwọnba, nipa aurochs, tabi ẹhanna akọ maluu titobi gàgàrà ati amuni-kun-fun ibẹru, ti ó wà ni awọn ìgbà ti a kọ Bibeli ati titi di awọn ìgbà ti kò tíì pẹ pupọ sẹhin yii.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ọjọgbọn Paul Haupt ṣalaye pe: ‘Ninu àkójọ awọn ohun ìṣẹ̀m̀báyé ti sanmani agbedemeji awọn ìwo ẹranko bii àgbáǹréré tabi ehin gigun ti ẹran omi narwhal (ti a tun ń pè ni ẹja unicorn tabi ẹja àbùùbùtán ti unicorn) ni a kàsí awọn ìwo unicorn.’

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 31]

Iwe Treasury of Fantastic and Mythological Creatures: 1,087 Renderings from Historic Sources, lati ọwọ Richard Huber/Dover Publications, Inc.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́