ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 6/15 ojú ìwé 28-30
  • Diocletian Gbejako Isin Kristian

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Diocletian Gbejako Isin Kristian
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Isin Abọriṣa Ni Ilodisi Isin Kristian
  • Awọn Aṣẹ Ofin
  • Isin Kristian Ọrundun Kẹrin
  • Bí Kristẹndọm Ṣe Di apakan Ayé Yii
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Kò Sí Èrò Nípa Jíjuwọ́sílẹ̀!
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ìsìn Kristian Ìjímìjí àti Orílẹ̀-èdè
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Bí Bíbélì Ṣe Tẹ̀ Wá Lọ́wọ́
    Jí!—2007
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 6/15 ojú ìwé 28-30

Diocletian Gbejako Isin Kristian

NI IBI ajọdun Terminus ọlọrun Romu ni February 23, 303 C.E., ti a ṣe ni Nicomedia ni Asia Kekere, olu-ilu titun ti ilẹ-ọba naa, awọn ọkunrin figagbága pẹlu ẹnikinni keji lati fi ẹmi ifọkansin orilẹ-ede ẹni hàn. Ṣugbọn awujọ Kristian ti o pọ ni a lè kiyesi pé wọn kò sí nibẹ.

Lati ibi ti wọn ti lè ríran rí ọ̀kánkán daadaa ni ààfin wọn, Olu-ọba Diocletian ati Galerius Caesar ọmọ-abẹ rẹ̀ wo ibi ipade Kristian adugbo. Nipa àmì kan ti ó fifun wọn, awọn ọmọ-ogun ati awọn ijoye oṣiṣẹ ijọba fipá wọle sinu ile awọn Kristian, wọn piyẹ́ rẹ̀, wọn sì jó awọn ẹ̀dà Bibeli ti wọn rí. Nikẹhin, wọn ba ile naa jẹ́ kanlẹ.

Bayii ni sáà inunibini ti ó tàbàwọ́n bá iṣakoso Diocletian ṣe bẹrẹ. Awọn opitan sami sii gẹgẹ bi “inunibini titobi ti o kẹhin,” “inunibini oniwa-ipa julọ,” koda “kò kéré si pipa orukọ Kristian run yán-án-yán-án.” Wiwo ipilẹ awọn iṣẹlẹ amunijigiri wọnyi jásí eyi ti ń funni ni isọfunni julọ.

Isin Abọriṣa Ni Ilodisi Isin Kristian

Diocletian, ti a bí ni Dalmatia, ẹkùn ibi ti ó di Yugoslavia, di ẹni ti o yọri ọla lati inu ẹgbẹ́ ọmọ ogun Romu. Bi a ti kan sárá sii gẹgẹ bi olu-ọba ni 284 C.E., ó di olokiki fun atunṣe oṣelu nigba ti o fidii tetraki, agbajọpọ ipo aṣaaju mẹrin lelẹ, lati ṣolori ilẹ-ọba naa. Diocletian yan Maximian, ọmọ-ogun atijọ ẹlẹgbẹ rẹ̀ kan, lati ṣiṣẹsin lẹgbẹẹ rẹ̀ gẹgẹ bi olu-ọba keji, Augustus keji, pẹlu ẹrù-iṣẹ́ akanṣe ni apá ìhà iwọ-oorun ilẹ-ọba naa. Ati Diocletian ati Maximian ní Caesar ọmọ-abẹ kan ti wọn yọnda awọn ẹ̀tọ́ ìgorí àlééfà fun. Constantius Chlorus ṣiṣẹsin gẹgẹ bi Caesar fun Maximian, nigba ti Galerius lati Thrace di agbara mú labẹ Diocletian.

Galerius Caesar, bii ti Diocletian, jẹ olujọsin paraku fun awọn ọlọrun oriṣa. Bi o ti ni ifẹ alagbara lati gbapò olu-ọba naa, Galerius díbọ́n pe oun bẹru itanjẹ ninu ẹgbẹ́ ọmọ ogun naa. Ó koriira agbara idari tí ń pọ sii ti awọn ọmọ-ogun ti wọn sọ pe awọn jẹ Kristian. Ni oju-iwoye olu-ọba naa, kíkọ̀ wọn lati kopa ninu ijọsin oloriṣa ṣe deedee pẹlu ipenija fun ọla-aṣẹ rẹ̀. Nitori naa Galerius rọ Diocletian lati gbé awọn igbesẹ lati pa isin Kristian run patapata. Nikẹhin, ni ìgbà otutu 302/303 C.E., olu-ọba naa juwọsilẹ fun imọlara aṣodi si Kristian ti Caesar ó sì gbà lati mú awọn ẹnikọọkan wọnyi kuro ninu ẹgbẹ́ ọmọ ogun ati ibugbe ọba-alaṣẹ naa. Ṣugbọn Diocletian wọ́gi lé itajẹsilẹ, ni bibẹru pe awọn ajẹriiku fun ipa-ọna Kristian yoo ru awọn miiran dide si iṣayagbangba pofin-nija ti a fipinnu ṣe.

Sibẹ, láláì nitẹẹlọrun pẹlu ọ̀nà igbabojuto iṣoro yii, Diocletian fikunlukun pẹlu awọn ọgagun ati ijoye oṣiṣẹ ologun, titikan Hierocles, gomina Bithynia. Griki paraku yii ti igbesẹ oniwa-ipa lodisi awọn Kristian lẹhin. Itilẹhin ti Diocletian fun awọn ọlọrun ibilẹ Romu jalẹ si iforigbari pẹlu isin Kristian. Abajade rẹ̀, gẹgẹ bi iwe naa Diocletian and the Roman Recovery, lati ọwọ Stephen Williams ti wi jẹ́, “ogun àjàkú akátá laaarin awọn ọlọrun Romu ati ọlọrun awọn Kristian.”

Awọn Aṣẹ Ofin

Lati maa bá igbetaasi inunibini rẹ̀ lọ, Diocletian kede awọn aṣẹ ofin mẹrin ti o tẹlera. Ni ọjọ ti ó tẹle igbejakoni naa ni Nicomedia, ó paṣẹ pe ki wọn pa gbogbo ibi ipade ati ohun ìní Kristian run ó sì paṣẹ pe ki wọn kó gbogbo awọn iwe mimọ kalẹ ki a sì jó wọn. Awọn Kristian ti wọn wà ni ipo ijoye oṣiṣẹ Ijọba ni ki a rọ̀ wálẹ̀.

Nigba ti iná meji sọ jade ninu aafin olu-ọba naa gan-an, ẹ̀bi rẹ̀ subu sori awọn Kristian ti a gbà síṣẹ́ nibẹ. Eyi ru aṣẹ ofin keji dide, eyi ti o paṣẹ ifaṣẹ-ọba-mu ati ifisẹwọn gbogbo awọn biṣọọbu, alufaa, ati awọn diakoni. Ni pipaṣẹ idaloro bi o bá pọndandan, aṣẹ ofin kẹta gbidanwo lati jẹ ki awọn ọkunrin wọnyi pẹhinda, ni bibeere pe ki wọn rubọ si awọn ọlọrun Romu. Aṣẹ kẹrin lọ siwaju ó sì sọ ọ́ di ẹṣẹ tí ijiya iku tọ́sí fun ẹnikẹni lati jẹwọ isin Kristian.

Ìgbì ìroròmọ́ni ti o yọrisi mú ẹgbẹ́ kan ti a sọ lorukọ traditores (ti o tumọsi, “awọn wọnni ti wọn juwọsilẹ”) jade, awọn ọ̀dàlẹ̀ si Ọlọrun ati Kristi ti wọn gbidanwo lati daabobo iwalaaye wọn nipasẹ fifi awọn ẹ̀dà Iwe Mimọ wọn kalẹ. Gẹgẹ bi opitan Will Durant ti wi, “ẹgbẹẹgbẹrun awọn Kristian kó ọrọ wọn jẹ . . . Ṣugbọn ọpọ julọ ninu awọn ti a ṣe inunibini si duro gbọnyingbọnyin; tí riri tabi gbigbọ irohin nipa iṣotitọ onigboya labẹ idaloro sì fun igbagbọ awọn ti ń ṣiyemeji lókun ti ó sì jere awọn mẹmba titun fun awọn ijọ ti a ń dọdẹ naa.” Awọn Kristian ni Frigia, Kappadokia, Mesopotamia, Fenike, Egipti, ati ọpọ julọ awọn apa Ilẹ-ọba Romu miiran jiya iku ajẹriiku.

Opitan ṣọọṣi Eusebius ara Kesarea ṣiro pe ẹgbẹẹgbẹrun awọn Kristian parẹ́ ni akoko inunibini naa. Ni ọwọ́ keji ẹ̀wẹ̀, Edward Gibbon, onṣewe The Decline and Fall of the Roman Empire, fi idaloju sọ iye kan ti o kere si ẹgbẹrun meji. “Gibbon gbe pupọ ninu awọn ìtàn wọnyi yẹwo pẹlu ẹmi tabi-tabi diẹ, bi o ti jẹ pe wọn ń wa lati awọn orisun ti o jẹ́ ti Kristian eyi ti a ti fèrúyípo lọna ti o ga ti o sì tẹ̀ siha fifogo fun awọn ajẹriiku ati fun mimu ìwà awọn oluṣotitọ sàn sii,” ni onkọwe kan ṣalaye. “Kò si iyemeji,” ni ó ń baa lọ, “pe asọdun ń bẹ lẹnu awọn onkọwe ti wọn fi tirọruntirọrun yí iwọnba iku diẹ si ‘ògìdìgbó’, ti wọn kò fi iyatọ saaarin iku ajẹriiku ti a kò beere fun ati awọn wọnni ti ń jẹ jade lati inu ìmọ̀ọ́mọ̀ munibinu; ti wọn sì ń sọ bi awọn ẹranko ẹhanna ninu awọn ile iṣere ti fi ibinu fa gbogbo awọn ọdaran miiran ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ ṣugbọn ti a dá wọn duro nipasẹ ‘agbara ti o ju ti ẹ̀dá lọ kan’ lati maṣe fọwọ kan awọn Kristian. Ṣugbọn, bi a ba tilẹ faaye silẹ fun ọgbọ́n ìtànjẹ, ohun ti o kù banilẹru tó.” Laisi aniani inunibini ti o rorò julọ wáyé ṣáá ni pẹlu awọn ìsokọ́, ìsunni níná, ati ìnani bi ẹni maa kú, ati awọn ẹ̀mú gẹgẹ bi idaloro.

Awọn alaṣẹ kan di oju-iwoye naa mú pe Galerius, dipo Diocletian, ni ẹni ti o súnná sí inunibini naa. “Kì í ṣe laisi ijẹpataki iwarere jijinlẹ kan,” ni Ọjọgbọn William Bright sọ ninu The Age of the Fathers, “pé isapa onipo ajulọ ti agbara ayé oloriṣa lati fẹsẹ tẹ igbesi-aye Ijọba ti kì í ṣe ti ayé yii mọlẹ nilati jẹ́ orukọ Diocletian, dipo ti olùsúnná sí rẹ̀ tootọ Galerius.” Sibẹ, laaarin awọn tetraki paapaa, Diocletian ní iṣakoso onipo ajulọ níkàáwọ́, gẹgẹ bi onkọwe Stephen Williams ti fi itẹnumọ kede pe: “Kò si iyemeji pe Diocletian ní iṣakoso gbogbo aṣẹ pataki julọ ninu Ilẹ-ọba naa titi di 304 níkàáwọ́, ó sì ni ẹrù-iṣẹ́ pataki julọ fun inunibini naa titi di ọjọ yẹn.” Diocletian dubulẹ aisan ó sì kọ iṣakoso rẹ̀ silẹ lẹhin-ọ-rẹhin ni 305 C.E. Fun nǹkan bii ọdun mẹfa lẹhinwa ìgbà naa, inunibini ti ń baa lọ naa fi ikoriira rírorò tí Galerius ni fun ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu Kristian hàn.

Isin Kristian Ọrundun Kẹrin

Awọn iṣẹlẹ adẹ́rùbani wọnyi ní ibẹrẹ ọrundun kẹrin fi ẹ̀rí ijotiitọ ohun ti a ti sọ ṣaaju nipasẹ awọn aposteli Paulu ati Peteru, ati awọn onkọwe yooku ti a misi hàn. “Ọkunrin alailofin” ti a sọ asọtẹlẹ rẹ̀ naa, ẹgbẹ́ awujọ alufaa ti ń ṣakoso ti awọn Kristian aláfẹnujẹ́, ni o ti fẹsẹmulẹ ṣaaju akoko yii, gẹgẹ bi awọn aṣẹ ofin Diocletian, ekeji ni pataki, ti jẹrii sii. (2 Tessalonika 2:3, 4; Iṣe 20:29, 30; 2 Peteru 2:12) Nigba ti o fi maa di ọrundun kẹrin, awọn aṣa ipẹhinda ti wà ni ibi pupọ ṣaaju akoko yii. Kì í ṣe diẹ ninu awọn ti wọn jẹwọ jíjẹ́ Kristian ni wọn jẹ́ mẹmba ẹgbẹ́ ọmọ ogun Romu. Kò ha si awọn Kristian eyikeyii nigba naa lọ́hùn-ún ti wọn jẹ́ oluṣotitọ si “apẹẹrẹ awọn ọrọ ti o yè kooro” ti wọn gbà lati ọdọ awọn aposteli ni bi?—2 Timoteu 1:13.

Eusebius darukọ diẹ ninu awọn ojiya ipalara inunibini naa, ó tilẹ ṣapejuwe kúnnákúnná nipa idaloro, ijiya, ati iku ajẹriiku ti o pàpà yọrisi fun wọn. Yala gbogbo awọn ajẹriiku wọnyi kú bi olupawatitọmọ si otitọ ti a ṣipaya ti o wà larọọwọto nigba naa, awa kò lè mọ̀ nisinsinyi. Kò si iyemeji pe awọn kan ti fi awọn ikilọ Jesu lati yẹra fun ìtòrò pinpin mọ ẹ̀ya isin, iwa palapala, ati iru ijuwọsilẹ fohunṣọkan eyikeyii sọkan. (Ifihan 2:15, 16, 20-23; 3:1-3) Lọna ti o han gbangba, awọn oluṣotitọ diẹ ti wọn là á já farasin kuro ninu oju-iwoye ìtàn. (Matteu 13:24-30) Nitootọ, awọn igbesẹ lati fún ijọsin Kristian pa ṣaṣeyọri gan-an debi pe ọwọ̀n iranti Spain kan ti akoko naa kokiki Diocletian fun ‘pípa ti ó pa igbagbọ asan nipa Kristi rẹ́.’ Bi o tilẹ ri bẹẹ, awọn isapa lati gbámú ki wọn sì pa awọn ẹ̀dà Iwe Mimọ run, ìhà pataki ninu igbejako Diocletian lori isin Kristian, kuna lati nu Ọrọ Ọlọrun nù kuro patapata.—1 Peteru 1:25.

Niwọn bi kò ti ṣaṣeyọri ninu pipa isin Kristian run patapata, Satan Eṣu, oluṣakoso ayé, ń ba ọgbọn arekereke rẹ̀ niṣo nipasẹ Olu-ọba Constantine, ẹni ti o ṣakoso lati 306 si 337 C.E. (Johannu 12:31; 16:11; Efesu 6:11, akiyesi ẹsẹ iwe) Constantine Abọriṣa kò bá awọn Kristian jà. Kaka bẹẹ, o tọ́ loju rẹ̀ lati da awọn igbagbọ aboriṣa pọ mọ Kristian sinu isin Ijọba titun kan.

Ikilọ wo ni ó wà nibẹ fun gbogbo wa! Nigba ti a bá dojukọ inunibini rírorò, ifẹ wa fun Jehofa yoo ràn wá lọwọ lati yẹra fun ijuwọsilẹ nititori itura alaafia ara-ìyára onigba kukuru eyikeyii. (1 Peteru 5:9) Bakan naa, awa ki yoo yọnda fun akoko alalaafia lati tán okun Kristian wa. (Heberu 2:1; 3:12, 13) Rirọ timọtimọ mọ awọn ilana Bibeli yoo pa wa mọ ni aduroṣinṣin ti Jehofa, Ọlọrun naa ti o lè dá awọn eniyan rẹ̀ nide.—Orin Dafidi 18:25, 48.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 28]

Musei Capitolini, Roma

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́