Awọn Olupokiki Ijọba Rohin
Ihinrere Lati Ìhà Ila-oorun Europe
ỌPỌLỌPỌ awọn ohun ti ń runisoke ni ń ṣẹlẹ ninu pápá ti iṣakoso Ọlọrun ni Ìhà Ila-oorun Europe. Eyi ti o tayọ ni apejọpọ jakejado awọn orilẹ-ede ni Zagreb, August 16-18, 1991, nigba ti 7,300 Awọn Ẹlẹ́rìí fun awọn ará wọn lati orilẹ-ede 15 ni itẹwọgba atọkanwa. Lapapọ, 14,684 ni iye awọn ti ó wá. Ó jẹ agbayanu ìfihàn ifẹ ati iṣọkan ni orilẹ-ede kan ti rukerudo ti mì tìtì!
Awọn Ẹlẹ́rìí ni Ìhà Ila-oorun Europe ni ọwọ́ wọn dí ninu sisọ fun awọn ẹlomiran nipa ihinrere Ijọba Jehofa, eyi ti wọn mọ daju pe ó jẹ́ ireti kanṣoṣo fun alaafia tootọ. Ni awọn apa kan ó jẹ́ ipenija fun wọn lati di iduro aidasi tọtuntosi wọn mu. Sibẹ, awọn eniyan sábà maa ń fetisilẹ, Awọn Ẹlẹ́rìí naa sì rohin ọpọlọpọ iriri rere.
Ni ilu kan ọdọmọbinrin ẹni ọdun 16 kan gbọ́ ihinrere lọdọ Ẹlẹ́rìí Jehofa kanṣoṣo ti ó wà ni ilu naa. Ikẹkọọ Bibeli deedee kan ni a bẹrẹ, imọriri rẹ̀ fun otitọ sì ga soke. Bi o ti ni ifẹ-ọkan giga lati sọ fun awọn ẹlomiran nipa awọn ohun agbayanu ti o ti kẹkọọ rẹ̀, ó gbiyanju lati bá awọn ọmọ ile-ẹkọ ẹlẹgbẹ rẹ̀ sọrọ ṣugbọn ó bá àtakò ati ifiniṣẹlẹya pade. Ọmọ ile-ẹkọ ẹlẹgbẹ rẹ̀ kan ni pataki takò ó ṣugbọn a yà á lẹnu a sì wú u lori nipasẹ suuru rẹ̀, nitori pe ọdọ akẹkọọ Bibeli naa kò di onibiinu loju gbogbo awọn ìwọ̀sí naa. Nigba ti o yá, a fun ọdọmọbinrin yii ni ijẹrii ti o tubọ ṣe kúnnákúnná sii, ó sì wá mọ daju pe iṣarasihuwa oun kò tọ̀nà. Ikẹkọọ Bibeli ni a bẹrẹ pẹlu rẹ̀, ati lẹhin naa akẹkọọ Bibeli akọkọ ati ẹnikeji rẹ̀ titun gbiyanju lati ṣajọpin ayọ wọn pẹlu awọn ẹlomiran, laika atako lati ọdọ awọn obi wọn ati olukọ wọn, ati awọn ọmọ ile-ẹkọ ẹlẹgbẹ wọn sí.
Gẹgẹ bi iyọrisi ijẹrii wọn, ọmọ ile-ẹkọ ẹlẹgbẹ wọn miiran tẹwọgba otitọ. Nisinsinyi awọn mẹtẹẹta ni wọn wà ninu yàrá ikawe, awọn mẹtẹẹta sì jẹ́ apẹẹrẹ rere ti imuratan lati ran awọn ẹlomiran lọwọ ati lati fi ifẹ hàn laaarin araawọn. Ọdọmọbinrin miiran darapọ mọ wọn lẹhin naa.
Nisinsinyi awọn mẹrin ni wọn wà lori ijokoo gbọọrọ ninu ọgbà ile-ẹkọ nibi ti wọn ti ń jiroro Bibeli papọ. Ati si iyalẹnu ọpọlọpọ, iye wọn pọ sii. Ọdọmọbinrin miiran lati inu kilaasi naa, ti iwa rere wọn mú ní ìtara-ọkàn, pinnu lati darapọ mọ wọn ninu ikẹkọọ Bibeli. Awọn maraarun ń baa lọ lati késí awọn miiran, awọn akẹkọọ ati olukọ, lati ṣe bakan naa. Sibẹ, awọn ọdọmọbinrin naa ń baa lọ lati niriiri ikimọlẹ ńlá lati ọdọ awọn obi wọn. Awọn obi naa gbiyanju lati fipa mú awọn ọdọmọbinrin naa lati dawọ ikẹkọọ Bibeli wọn duro nipa fifa iwe ikẹkọọ wọn ya ati biba wọn lò lọna ti kò dara.
Ki ni iyọrisi ijẹrii yii tí ọ̀dọ́ olufifẹhan kan wulẹ bẹrẹ? Ọkan lara awọn ọdọmọbinrin naa ṣe iribọmi ni apejọpọ agbegbe ni 1990, ati awọn mẹrin yooku ni apejọ ayika ni ìgbà iruwe 1991. Eyi jẹ idi fun ayọ ńlá! Lonii, gbogbo awọn ọdọmọbinrin maraarun ń ṣiṣẹsin gẹgẹ bi aṣaaju-ọna deedee! Ninu ilu ti eyi ti ṣẹlẹ, awọn akede 11 ni wọn wà nibẹ nisinsinyi, 8 ninu wọn wà ninu iṣẹ-isin aṣaaju-ọna.
Jehofa ń ti Awọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ ni Ìhà Ila-oorun Europe lẹhin ó sì ń bukun wọn. Lọna ti o ṣe kedere ṣiṣeeṣe fun ibisi ńlá wà laaarin awọn alailabosi ọkàn ní apá ibi yii ninu ayé.