ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 7/1 ojú ìwé 21-23
  • Mo Dahunpada ni Akoko Ìkórè

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Mo Dahunpada ni Akoko Ìkórè
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Igbeyawo ati Irinkerindo
  • Titẹwọgba Otitọ
  • Kíkórè Ni Cape Palmas
  • Lọ Si Lower Buchanan
  • Awọn Anfaani ati Awọn Èrè Siwaju Sii
  • Kò Rọrùn Láti Tọ́ Ọmọ Mẹ́jọ Ní Ọ̀nà Jèhófà, Àmọ́ Ó Máyọ̀ Wá
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, Ìdílé Wa Ṣọ̀kan!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Jèhófà Jẹ́ Ọlọ́run Olóore Sí Mi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ohun Tí Ó Lé Ní 50 Ọdún ‘Ríré Kọjá Wá’
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 7/1 ojú ìwé 21-23

Mo Dahunpada ni Akoko Ìkórè

GẸGẸ BI WINIFRED REMMIE TI SỌ Ọ́

“ÌKÓRÈ pọ̀, ṣugbọn awọn alagbaṣe kò tó nǹkan.” Awọn ọrọ wọnyi lati ẹnu Jesu Oluwa wa ní imọlara jijinlẹ fun awọn eniyan tí àárẹ̀ mú ti wọn sì tukaakiri bii awọn agutan ti kò ni oluṣọ ti sún un lati sọ. Mo ti niriiri iru imọlara kan naa yii, ati fun 40 ọdun ti o ti kọja sẹhin, mo ti ń fi ìgbà gbogbo gbiyanju lati dahunpada lọna rere si ìkésíni Ọga naa lati ṣiṣẹ ninu ìkórè.—Matteu 9:36, 37.

A bí mi ni Iwọ-oorun Africa sinu idile ọlọmọ meje, ti gbogbo wa jẹ obinrin. Awọn obi wa jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́, sibẹ wọn kò gba gbẹ̀rẹ́; wọn si tun jẹ́ ẹlẹmii isin gan-an pẹlu. Lilọ si ṣọọṣi ati ile-ẹkọ ọjọ Isinmi lọsọọsẹ jẹ́ ohun ti a kò lè fi bánidọ́rẹ̀ẹ́. Fun mi eyi kì í ṣe iṣoro kan nitori pe mo nifẹẹ si awọn nǹkan tẹmi. Ni tootọ, ni ẹni ọdun 12, a yàn mi lati dari kilaasi ile-ẹkọ ọjọ Isinmi.

Igbeyawo ati Irinkerindo

Ni 1941, ní ẹni ọdun 23, mo ṣegbeyawo pẹlu Lichfield Remmie, olupa-akọsilẹ owo mọ́ ni ile-iṣẹ ijọba. Niti ohun ìní, ọlọ́rọ̀ ni a jẹ́, ṣugbọn ifẹ fun irinkerindo ati ifẹ-ọkan lati kó ọrọ̀ nipa ti ara jọ mú ki a lọ si Liberia ni 1944. Akoko iyipada ninu igbesi-aye ọkọ mi, ati nikẹhin temi, dé ni 1950 nigba ti ó pade Hoyle Ervin, ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ti Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Lẹhin ikẹkọọ ọsẹ mẹta péré, ọkọ mi bẹrẹ sii nipin-in ninu iṣẹ iwaasu naa.

Inu mi bajẹ nigba ti ọkọ mi ṣíwọ́ lilọ si ṣọọṣi. Ó ṣetan, oun jẹ́ Protẹstant aduroṣinṣin kan ti o tilẹ maa ń gba aawẹ ni akoko Lẹ́ǹtì. Ìgbà akọkọ ti mo rí i ti o ń jade lọ lati lọ waasu, pẹlu àpò ni ọwọ rẹ̀, mo kun fun ìrunú. “Ki ni ó rọ́ lù ọ́?” ni mo fi dandangbọn beere. “Gbajumọ ọkunrin bi tirẹ ń jade lọ lati waasu pẹlu awọn omugọ eniyan wọnyi!” Ni akoko ọrọ ibinu yii ó parọ́rọ́ ó sì ṣe pẹlẹ.

Ni ọjọ keji, Arakunrin Ervin ṣe ikesini si ile wa lati kẹkọọ pẹlu Lichfield. Gẹgẹ bii ti ọpọ ìgbà, mo takété nigba ikẹkọọ naa. Boya eyi ni idi rẹ̀ ti Arakunrin Ervin fi beere lọwọ mi boya alaimọwe ni mi. Ki ni mo gbọ́ yii? Eemi, ni alaimọwe? Iru ẹgbin wo ni eyi jẹ́! Emi yoo fihan an bi mo ṣe mọwe tó! Emi yoo tú aṣiri isin èké yii!

Titẹwọgba Otitọ

Kò pẹ́ lẹhin eyi, ni mo ṣakiyesi iwe naa “Jẹki Ọlọrun Jẹ Olõtọ” lori tabili inu pálọ̀. ‘Iru àkọlé apanilẹrin-in wo ni eyi,’ ni mo ronu. ‘Ọlọrun ti fi ìgbà gbogbo jẹ́ oloootọ, ko ha ṣe bẹẹ bi?’ Bi mo ti ń ka iwe naa gààràgà, kiakia ni mo tun ri ohun miiran ti o fa aroye. Ó ní eniyan kò ní ọkàn kan, pe o jẹ́ ọkàn kan! Ani awọn aja ati ologbo pẹlu jẹ́ ọkàn! Eyi mu mi binu niti gidi. ‘Iru ẹkọ òṣì wo niyii!’ ni mo ronu.

Nigba ti ọkọ mi wọle dé, mo fi ibinu kò ó lójú. “Awọn atannijẹ wọnyi sọ pe eniyan kò ni ọkàn kan. Wolii èké ni wọn!” Ọkọ mi kò bá mi jà; kaka bẹẹ, ó fi pẹlẹpẹlẹ dahunpada: “Winnie, gbogbo rẹ̀ wà ninu Bibeli.” Lẹhin naa, nigba ti Arakunrin Ervin fi suuru fihan mi lati inu Bibeli temi pe ọkàn ni wá ati pe ọkàn wa jẹ́ eyi ti ń kú, a mu mi gbọnriri pẹlu iyalẹnu. (Esekieli 18:4) Ohun ti o fami mọra ni pataki ni ọrọ iwe mimọ ni Genesisi 2:7, ti o sọ pe: “Eniyan [Adamu] sì di alààyè ọkàn.”

Bawo ni mo ti ṣìnà tó! Mo ni imọlara pe awọn alufaa ti tú mi jẹ emi kò sì tun pada tẹ ṣọọṣi mọ. Dipo eyiini, mo bẹrẹ sii lọ si awọn ipade Kristian ti Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Bawo ni o ti fanilọkanmọra tó lati ri ifẹ ti o wa laaarin wọn! Eyi nilati jẹ́ isin tootọ naa.

Kíkórè Ni Cape Palmas

Ni nǹkan bii oṣu mẹta lẹhin akoko naa, ọkọ mi ni anfaani lati jí owo bàǹtàbanta kuro ni ile-isẹ rẹ̀—ṣugbọn kò ṣe bẹẹ. Awọn ẹlẹgbẹ rẹ̀ fi ṣe ẹlẹya pe: “Remmie, òṣì ni yoo ta ọ pa.”

Bi o ti wu ki o ri, nitori ailabosi rẹ̀, wọn gbe e ga lẹnuuṣẹ wọn sì ran an lọ si Cape Palmas lati ṣí ile-iṣẹ titun kan sibẹ. A fi itara waasu ati lẹhin oṣu meji péré, a ti ni awujọ kekere ti ó ni ifẹ-ọkan mimuna ninu ihin-iṣẹ Bibeli. Lẹhin naa, nigba ti Lichfield rinrin-ajo lọ si olu-ilu naa, Monrovia, lati gba awọn ipese kan fun ile-iṣẹ titun naa, a baptisi rẹ̀. Ó tun beere iranlọwọ lati ọdọ Society lati bojuto awọn ti wọn wà ni Cape Palmas awọn ti wọn ń fi ifẹ hàn ninu otitọ.

Society dahunpada nipa rírán Arakunrin ati Arabinrin Faust wá si Cape Palmas. Arabinrin Faust jẹ́ iranlọwọ ṣiṣeyebiye fun mi, ati ni December 1951, mo fi ẹ̀rí iyasimimọ mi hàn si Jehofa nipa ṣiṣe iribọmi. Nisinsinyi ju ti igbakigba ri lọ, mo pinnu lati ‘kó eso jọ fun ìyè ainipẹkun.’ (Johannu 4:35, 36) Ni April 1952, mo bẹrẹ iṣẹ-ojiṣẹ alakooko-kikun gẹgẹ bi aṣaaju-ọna.

Isapa mi ni Jehofa bukun lẹsẹkẹsẹ; laaarin ọdun kan péré, mo ran awọn eniyan marun-un lọwọ lati ṣeyasimimọ ati iribọmi. Ọ̀kan ninu wọn, Louissa Macintosh, jẹ́ mọlẹbi W. V. S. Tubman, ẹni ti o jẹ ààrẹ Liberia ní ìgbà naa. A baptisi rẹ̀ ó sì wọnu iṣẹ-ojiṣẹ alakooko-kikun ó sì ń baa lọ ni jíjẹ́ oloootọ si Ọlọrun titi di ìgbà iku rẹ̀ ni 1984. Ni awọn ìgbà melookan ó jẹrii fun ààrẹ naa.

Lọ Si Lower Buchanan

Ni 1957, nigba ibẹwo alaboojuto agbegbe, ọkọ mi ati emi ni a késí lati di aṣaaju-ọna akanṣe. Lẹhin ijiroro taduratadura, a tẹwọgba iṣẹ ayanfunni naa. Lichfield nilo awọn oṣu diẹ lati kógbá iṣẹ amuṣe rẹ̀ kuro nilẹ ni Cape Palmas, nitori naa mo ṣiwaju rẹ̀ lọ si Lower Buchanan, ipinlẹ ti a kò tii ṣiṣẹ nibẹ rí rárá, lati bẹrẹ iṣẹ naa nibẹ.

Ni dídé ti mo dé sibẹ, idile Maclean gba mi sile. Ni ọjọ keji, gẹgẹ bi o ti jẹ́ àṣà ibẹ, a mú mi lọ sọdọ igbakeji baalẹ ẹ̀yà Pele. Baalẹ naa ati idile rẹ̀ fi ifẹ tẹwọgba mi, mo sì jẹrii fun awujọ awọn eniyan kekere kan ni ile rẹ̀. Iye ti kò din si mẹfa ninu awọn eniyan ti mo bá sọrọ ni ọjọ yẹn, ti o ni ninu igbakeji baalẹ naa ati iyawo rẹ̀, ni wọn di Ẹlẹ́rìí nikẹhin.

Laipẹ mo rii ti mo ń dari ikẹkọọ Ilé-Ìṣọ́nà kan pẹlu iye eniyan ti o ju 20 lọ ti wọn wá. Mo nilati gbẹkẹle Jehofa gidi gan-an, o sì fun mi ni okun ati agbara ti mo nilo lati tọju awọn agutan rẹ̀. Nigba ti ó bá rẹ̀ mi tabi ti mo nimọlara aidoju iwọn, emi yoo níran awọn olùṣòtítọ́ ìgbàanì ni pataki awọn obinrin bii Debora, ati Hulda, ti wọn jẹ́ alaibẹru ninu mimu awọn aṣẹ Jehofa ṣẹ.—Onidajọ 4:4-7, 14-16; 2 Ọba 22:14-20.

Ni March 1958, lẹhin kìkì oṣu mẹta péré ni Lower Buchanan, mo gba lẹta kan ti ń fi isọfunni tó mi leti nipa ibẹwo alaboojuto ayika, John Charuk. Mo háyà gbọngan isalẹ ile kan ti yoo lè gba awujọ titobi. Lẹhin naa mo rinrin-ajo lọ si Upper Buchanan lati pade Arakunrin Charuk, ṣugbọn kò wá. Lẹhin diduro di ọwọ́ alẹ́, pẹlu àárẹ̀ mo pada si Lower Buchanan.

Ni ọwọ́ ọ̀gànjọ́ òru, mo gbúròó kíkàn ilẹkun. Ni ṣíṣí i, mo rí kì í ṣe kìkì alaboojuto ayika naa nikan ṣugbọn ọkọ mi pẹlu, ẹni ti dídé rẹ̀ ti o mú iyalẹnu lọwọ ṣe kongẹ lọna didara pẹlu ti Arakunrin Charuk. Bawo ni wọn ṣe wá mi rí? Wọn ti pade ọdẹ kan lọwọ ẹni ti wọn ti beere boya ó mọ obinrin kan ti ń waasu fun awọn eniyan nipa Jehofa. “Bẹẹni,” ni ó dahunpada, o sì dari wọn si ibi ti mo wà. Bawo ni mo ti ni imọlara ayọ tó pe ni kìkì oṣu mẹta péré ni Lower Buchanan ìmọ́lẹ̀ mi ti ń tàn yanranyanran tobẹẹ!—Matteu 5:14-16.

A gbadun gongo 40 iye awọn eniyan ti wọn wá nigba ibẹwo Arakunrin Charuk. Laipẹ ijọ fifẹsẹmulẹ kan ni a dasilẹ, o sì ṣeeṣe fun wa lati kọ́ Gbọngan Ijọba rirẹwa kan. Bi o ti wu ki o ri, igbesi-aye ki i dominira patapata kuro lọwọ iṣoro. Fun apẹẹrẹ, ni 1963 inunibini isin bẹsilẹ ni ilu Kolahun, a sì fi aṣẹ ọba mu ọkọ mi a sì sọ ọ́ sẹ́wọ̀n. Wọn lù ú ni ilukulu debi pe oun ni a nilati gbà si ile iwosan.

Kò pẹ́ sí ìgbà ti wọn ni ki o maa relé lati ile iwosan, ni ọdun yẹn kan naa, a ni apejọpọ kan ni Gbarnga. Ni ọjọ ti o kẹhin, awọn ṣọja yi awujọ olupesẹ ká, wọn sì paṣẹ fun wa lati bẹ́rí fun asia. Nigba ti a kò ṣe bẹẹ, awọn ṣọja naa fi ipá mú wa lati káwọ́ wa soke ki a sì kọju si oorun ni taarata. Wọn lu awọn kan lara wa pẹlu idi ibọn wọn. Gẹgẹ bi iranlọwọ lati pa iwatitọ mi si Ọlọrun mọ́, mo kọ orin Ijọba naa “Ẹ Maṣe Bẹru Wọn!” sinu. Lẹhin eyi awọn ṣọja naa ju wá sinu ẹ̀wọ̀n ẹlẹgbin kan. Ọjọ mẹta lẹhin naa awọn ajeji ni a dasilẹ, Lichfield ati emi ni a sì lelọkuro si Sierra Leone. Awọn Ẹlẹ́rìí adugbo ni a sì dasilẹ ni ọjọ keji.

Awọn Anfaani ati Awọn Èrè Siwaju Sii

A yàn wá lati ṣiṣẹ pẹlu Ijọ Bo, ni guusu Sierra Leone, a ṣiṣẹsin nibẹ fun ọdun mẹjọ ṣaaju ki a tó ṣíwa nípò lọ si Njala. Nigba ti a wà ni Njala a yan ọkọ mi lati ṣiṣẹsin gẹgẹ bi adelé alaboojuto ayika, mo sì ni anfaani ti titẹle e bi o ti ń lọwọ ninu iṣẹ-isin yii. Lẹhin naa ni awọn sáà ọdun 1970, a tun pinṣẹyan fun wa pada si Ijọ East Freetown.

Mo ti nírìírí èrè ti riri pupọ ninu awọn wọnni ti mo kọ́ lẹkọọ Bibeli ti wọn finnufindọ tẹwọgba ijọsin tootọ. Mo ni iye ti o lé ni 60 ọmọ ati ọmọ-ọmọ nipa tẹmi gẹgẹ bi “iwe ìyìn.” (2 Korinti 3:1) Awọn kan nilati ṣeyipada lilagbara, gẹgẹ bi Victoria Dyke, ẹni ti o jẹ́ wolii obinrin fun ẹgbẹ isin Aladuura ti ṣe. Lẹhin ṣiṣe igbeyẹwo 1 Johannu 5:21, oun lẹhin-ọ-rẹhin kó awọn ohun agbara-awo ati awọn ohun akunlẹbọ rẹ̀ danu. Ó fi ẹ̀rí iyasimimọ rẹ̀ hàn nipasẹ iribọmi, o sì di aṣaaju-ọna akanṣe lẹhin-ọ-rẹhin, ni ríran pupọ ninu awọn mọlẹbi rẹ̀ lọwọ lati tẹwọgba otitọ.

Ni April 1985, mo padanu ọkọ mi ninu iku, ní kìkì iwọnba oṣu diẹ ki ayẹyẹ igbeyawo wa pé ọdun 44. Ṣugbọn a kò fi mi silẹ ni emi nikan. Mo ti ń baa lọ lati ṣiṣẹsin Oluranlọwọ mi, Jehofa, gẹgẹ bi ojiṣẹ alakooko kikun. Mo sì ni imọlara ìdè akanṣe kan pẹlu awọn wọnni ti mo ti ranlọwọ lati mọ̀ ọ́n. Wọn jẹ́ idile ni ero itumọ pataki. Mo nifẹẹ wọn awọn pẹlu si nifẹẹ mi. Nigba ti mo bá ń ṣaisan, wọn a maa sare wá lati bojuto mi, niti tootọ, emi pẹlu ran wọn lọwọ.

Kò sí iyemeji nipa rẹ̀, bi mo bá tun nilati tún-un-ṣe lẹẹkan sii, emi yoo fi tayọtayọ mu dòjé mi, emi yoo sì darapọ ninu iṣẹ ìkórè naa gẹgẹ bi alajumọṣiṣẹpọ pẹlu Jehofa.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Winifred Remmie lonii

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́