Awọn Irisi-Iran Lati Ilẹ Ileri
Gerasa—Ibi Ti Awọn Ju ati Griki Ti Pade
APOSTELI Paulu kọwe pe laaarin awọn iru-ọmọ Abrahamu tootọ, “kò lè si Ju tabi Griki.” (Galatia 3:26-29) Bẹẹni, ìtàn nipa orilẹ-ede tabi àṣà iṣẹdalẹ kò jámọ́ nǹkankan niti bi ọ̀ràn itẹwọgba Ọlọrun ti rí.
Iru awọn ọrọ wọnni lè jọ bi ohun yiyẹ fun awọn Kristian ti wọn tukaakiri awọn ẹkun ipinlẹ Romu, iru bii ẹkun ipinlẹ Galatia, nibi ti apapọ awọn Ju, Griki, Romu, ati awọn eniyan adugbo wà. Ṣugbọn ki ni nipa ti awọn apakan Israeli fúnraarẹ̀, iru bii Gileadi?
Ẹkùn yẹn wà ni ila-oorun Jordani, laaarin Òkun Iyọ̀ (Òkú) ati Òkun Galili. Ni ọwọ́ aarin gbungbun ilẹ ọlọraa títẹ́ pẹrẹsẹ yii, ni Odo Jabboku ti ṣàn wálẹ̀ sinu Jordani. Fọto ti o wà loke yii fi apá fifanimọra diẹ hàn lara awọn àwókù Gerasa, ti a ń pe ni Jerash bayii, ti o wà nitosi Jabboku apa-oke.
Ipa-ọna èrò ọjà ariwa si guusu igbaani ti a ń pe ni “opopona ọba” la Gileadi kọja. Ni fifi Harani silẹ, Jakọbu ati idile rẹ̀ lọna ṣiṣe kedere gba ọ̀nà yii kọja lọ si Jabboku. Ó jijakadi pẹlu angẹli kan ti o sì ṣalabaapade Esau nitosi ibi ti a o kọ Gerasa si. (Genesisi 31:17-25, 45-47; 32:22-30; 33:1-17) Ni akoko kan lẹhin naa, awọn ọmọ Israeli rin lati guusu lọ si apa oke opopona ọba nigba ti wọn dorikọ Ilẹ Ileri naa. Ẹ̀yà meji ati aabọ fidikalẹ si ariwa ati guusu Jabboku ni ọ̀nà èrò ọja naa.—Numeri 20:17; Deuteronomi 2:26, 27.
Ǹjẹ́ awọn Griki nipin-in ninu agbegbe yii, bi o bá sì rí bẹẹ bawo ni? Bẹẹni, wọn ṣe bẹẹ nigba ti Alẹkisanda Ńlá ṣẹgun ẹkùn naa. Gẹgẹ bi ìtàn atọwọdọwọ ti sọ, ó tẹ Gerasa dó fun awọn jagunjagun rẹ̀ ti wọn ti pẹ́ lẹ́nuuṣẹ́. Kẹrẹkẹrẹ, agbara idari Griki di eyi ti o fidimulẹ daradara. Mẹwaa lara awọn ilu-nla atokeere ṣakoso ni ila-oorun Jordani, ati Okun Galili dá àjọ alajọṣepọ ti a mọ si Dekapoli silẹ. Iwọ lè ti ṣakiyesi orukọ yẹn ninu Bibeli, ti o rohin pe “ọpọlọpọ eniyan si tọ̀ ọ́ [Jesu] lẹhin lati Galili, ati Dekapoli, ati Jerusalemu, ati lati Judea wá, ati lati oke odo Jordani.” Gerasa jẹ́ ọ̀kan lara awọn ilu-nla Dekapoli.—Matteu 4:25.
‘Ó jẹ́ apakan lara iwewee Alẹkisanda lati foju awọn eniyan Griki mọ gbogbo awọn apa ilẹ-ọba naa. Syria Apa-isalẹ [ti o ní Dekapoli ninu], ni pataki, gẹgẹ bi ọ̀kan lara awọn ibudo ṣiṣe pataki gidi, gba iye awọn Hellene pupọ gan-an. Titi di oni yii kò si apakan lara ila-oorun ayé ti o lè fi ọpọ àwókù ilẹ̀ Griki ti o jẹ́ agbafiyesi bẹẹ hàn gẹgẹ bi orilẹ-ede ila-oorun Jordani naa. Awọn ilu-nla Griki lorefee, fi igbekalẹ awọn eto-apilẹṣe ati awọn àṣà hàn—awọn tẹmpili ragaji fun awọn ọlọrun akọ ati abo Griki, awọn gbọngan idaraya, ibi ìlúwẹ̀ẹ́ gbogbogboo, ayẹyẹ ọdọọdun ti awọn eré idaraya, ati ninu ọpọlọpọ ọ̀ràn awọn ile-ẹkọ ọgbọ́n imọ-ọran ati awọn ile-ẹkọ giga.’—Hellenism, lati ọwọ Norman Bentwich.
Bi iwọ ba ṣebẹwo sibi àwókù Gerasa, iwọ yoo ri ẹ̀rí ti ó pọ̀ tó fun iyẹn. Nitosi ọ̀nà abawọle ti iha guusu, ni ibi ipade ijiroro birikiti, tabi ọja gbogbogboo wà, eyi ti a lè rí ninu aworan. Ó ṣeeṣe ki ibi ìlúwẹ̀ẹ́ naa, awọn tẹmpili, awọn gbọngan iṣere, ati awọn ile gbogbogboo mú ọ ṣe kayeefi, ti a so pupọ ninu wọn mọra nipasẹ awọn opopona ti a fi okuta tẹ́ ti a sì to ọwọ̀n si lọ́tun-ún lósì. Lẹhin ode ilu-nla naa, iwọ lè ri awọn okuta ibusọ tabi ohun ami akiyesi loju ọ̀nà igbaani ti o so Gerasa pọ mọ awọn ilu-nla Dekapolis miiran ati ebute Mediterranean.
Kódà lẹhin ti Romu ti gba Gerasa ni 63 B.C.E., animọ pataki ti o jẹ́ ti awọn Hellene ń baa niṣo. Iwọ lè finuro bi animọ pataki naa ṣe lè nipa lori awọn Ju ti wọn ń gbé ni Gerasa ati ẹkùn naa. Iwe naa Hellenism ṣalaye pe: “Ni kẹrẹkẹrẹ ṣugbọn lọna didaju awọn Ju bẹrẹsi gba èrò isin awọn eniyan ti o wà yi wọn ká sinu, ati lati wo Iwe Mimọ labẹ agbara idari iru awọn èrò bẹẹ.”
Nigba ti o ṣeeṣe ki Jesu ma ti waasu ni ilu-nla naa, oun wọ igberiko Gerasa, ti o ti lè nasẹ̀ dé Òkun Galili. Oun lé ẹmi eṣu jade kuro lara ọkunrin kan ni igberiko yẹn, ti o sì jẹ́ ki wọn wọ inu agbo ẹlẹdẹ. (Marku 5:1-17) Ó ṣeeṣe, ki awọn ọmọ-ẹhin rẹ akọkọ waasu fun awọn Ju ni awọn ila-nla Dekapolis, ati lẹhin 36 C.E., Ihinrere naa ni a ti lè ṣajọpin rẹ̀ pẹlu awọn Griki ni Gerasa. Boya ẹnikan ti ń tẹwọgba isin Kristian ti jẹ́ olusọ isin Ju dàṣà loju mejeeji, Ju ti a sọ di Hellene, tabi Griki, oun lè ṣe itẹwọgba fun Ọlọrun tootọ naa gẹgẹ bi apakan iru-ọmọ tẹmi ti Abrahamu.
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 24]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Dion
Gerasa (Jarash)
Philadelphia (Rabbah)
King’s Road
Salt Sea
Jerusalem
Jordan
Jabbok
Pella
Scythopolis (Beth-shean)
Gadara
Sea of Galilee
[Credit Line]
A gbekari aworan ilẹ ti gbogbo ẹ̀tọ́ rẹ̀ jẹ́ ti Pictorial Archive (Near Eastern History) Est. ati Survey of Israel.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Aworan oke yii wa ni ìwọ̀n titobi ninu 1992 Calendar of Jehovah’s Witnesses.
[Credit Line]
Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 25]
Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.