ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 7/15 ojú ìwé 23-27
  • Kíkó “Awọn Ohun Fifanilọkanmọra” Jọpọ̀ ni Poland

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kíkó “Awọn Ohun Fifanilọkanmọra” Jọpọ̀ ni Poland
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Awọn Aṣaaju-ọna Ṣí Ọ̀nà Silẹ
  • Ọrọ Ti O Gbodekan
  • Didena Ẹmi Ayé
  • Ọ̀daràn Paraku Yipada
  • A Dán Igbagbọ ati Ifarada Wò
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 7/15 ojú ìwé 23-27

Kíkó “Awọn Ohun Fifanilọkanmọra” Jọpọ̀ ni Poland

POLAND ni a sọ pe o jẹ́ orilẹ-ede onisin Katoliki. Gẹgẹ bi akọsilẹ iṣiro ti a faṣẹ si ti sọ, ipin 93 ninu ọgọrun-un awọn ti ń gbé ibẹ jẹ ti Ṣọọṣi Katoliki. Awọn iyipada oṣelu ati ti ẹgbẹ-oun-ọgba tí ń ṣẹlẹ nibẹ lẹnu aipẹ yii, bi o ti wu ki o ri, ti ní ipa pipẹtẹrí kan lori awọn eniyan naa ati lori igbesi-aye isin wọn. Awọn iwadii fihàn pe kìkì nǹkan bii ipin 50 ninu ọgọrun-un awọn wọnni ti a fi ibeere wadii ọ̀rọ̀ wo lẹnu wọn ka araawọn si ẹni ti ń ṣe isin Katoliki.

Ni May 1989, Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni a damọ lọna ofin gẹgẹ bi eto-ajọ isin kan ni Poland. Lati ìgbà naa, iye ti o tó 11,000 awọn ẹni titun ti darapọ mọ́ òtú wọn gẹgẹ bi akede ihinrere Ijọba naa. Nisinsinyi iye awọn akede Ijọba ti o ju 106,000 lọ ni wọn ń darapọ mọ ijọ ti o lé ni 1,300, ti awọn eniyan 200,422 sì wá sibi ti a ti ṣe Iṣe-iranti ikú Kristi. Nipa bayii, akojọpọ ‘awọn ohun fifanilọkanmọra ti awọn orilẹ-ede’ ti a sọtẹlẹ naa ń ṣẹlẹ ni Poland. (Haggai 2:7) Lẹnu aipẹ yii, awọn apejọpọ agbaye ti Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti o di àkọlé iwaju iwe irohin ni a ṣe ni Poland. Ṣugbọn wiwo awọn ilu keekeeke ni orilẹ-ede naa yoo fi bi iṣẹ ikojọpọ naa ti ń tẹsiwaju hàn ni pataki ni ilẹ yẹn.

Awọn Aṣaaju-ọna Ṣí Ọ̀nà Silẹ

Sztum jẹ ilu kan ti o wà lẹbaa ọgangan ibi ti Odo Vistula ti wọnu Òkun Baltic ti o ní nǹkan bii 10,000 awọn ara-ilu. Ilu-nla yii ni a ti kà sí ipinlẹ ti o ṣoro bi o ba kan ọ̀ràn iṣẹ iwaasu. Ni 1987 kìkì awọn akede mẹjọ péré ni wọn wà ni agbegbe naa. Bi o ti wu ki o ri, awọn nǹkan bẹrẹ sii yipada nigba ti awọn aṣaaju-ọna, tabi awọn olupokiki Ijọba alakooko-kikun, dé. Ni ipade karun-un, ti wọn ṣe ninu ile eré sinima kan, 100 awọn olufifẹhan ni wọn wá sibẹ! Ijọ kan ni a dá silẹ lẹhin ọdun meji ti isapa alaapọn. Nisinsinyi awọn 90 akede ti ní Gbọngan Ijọba tiwọn funraawọn, 150 awọn eniyan sì ń wá si awọn ipade wọn deedee.

Gẹgẹ bi a ti reti, inunibini ru dide laipẹ lati inu Ṣọọṣi Katoliki. Obinrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé kan ti wọn kà sí “ògbóǹtagí” sọ awọn ọ̀rọ̀ atẹ́nilógo nipa Awọn Ẹlẹ́rìí naa, ni fifẹsun kikọni ni awọn ẹ̀kọ́ èké kàn wọn. Ṣugbọn gẹgẹ bi o ti sábà maa ń ṣẹlẹ, ibi yii pada sori wọn. Awiye rẹ̀ wulẹ mú ki awọn eniyan fẹ́ lati wadii otitọ ni. Ọpọlọpọ ninu wọn ti kẹkọọ otitọ wọn sì jẹ́ aṣaaju-ọna deedee nisinsinyi! Wọn wi pe: ‘Nigba ti a ń kẹkọọ otitọ, a ronu pe gbogbo eniyan ti ń fẹ́ lati di Ẹlẹ́rìí nilati dabi olukọ rẹ̀, eyi ti o tumọsi didi aṣaaju-ọna kan.’ Nitori naa ẹmi aṣaaju-ọna gbilẹ ninu gbogbo ijọ naa.

Gẹgẹ bi iyọrisi rẹ̀, ohun ti o tó 180 ikẹkọọ Bibeli inu ile ni a ń dari ni agbegbe naa. Nipasẹ iwe naa Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye, a tilẹ ti kọ́ awọn kan lati kawe. Ni akoko kan naa, wọn ti kẹkọọ otitọ. Ikẹkọọ Bibeli deedee oniṣẹẹju mẹwaa ni a ń dari pẹlu awujọ awọn ẹlẹwọn adugbo nigba ti wọn ba jade wá lati sọ oju popo di mimọ tonitoni. Ọ̀kan lara wọn gbèjà Ẹlẹ́rìí kan nigba ti obinrin kan ti ń kọja lọ bẹrẹ sii sọrọ èébú sí i. Ó sare tọ arabinrin naa lọ, ó gba iwe Walaaye Titilae lọwọ rẹ̀, ó nà án soke, ó sì beere lọwọ obinrin ẹlẹ́rẹ̀kẹ́ èébú naa pe: “Ṣe iwọ kò lè kawe ni? Ki ni wọn kọ sihin-in? Iwọ le walaaye titilae ninu paradise lori ilẹ-aye! Iwọ ha tíì gbọ́ iru ohun kan bẹẹ rí bi? Èétirí ná ti iwọ fi ń tabuku Ọlọrun ati awọn olujọsin rẹ̀?”

Ọrọ Ti O Gbodekan

Kruszwica, olu-ilu Poland lilokiki ní igbakanri, jẹ́ odi agbara Katoliki. Àní ni aarin ọdun 1990 paapaa, kìkì iwọnba Awọn Ẹlẹ́rìí diẹ ni wọn wà laaarin awọn 9,300 olùgbé rẹ̀. Ṣugbọn ibukun jingbinni Jehofa wà lori isapa awọn olupokiki Ijọba naa.

Ni ṣiṣakiyesi agabagebe awọn aṣaaju tẹmi wọn, pupọ pupọ awọn eniyan sii—ni pataki awọn ọ̀dọ́—yijusi Awọn Ẹlẹ́rìí fun idahun. Laaarin akoko kukuru, 20 ikẹkọọ Bibeli inu ile ni a bẹrẹ. Alufaa ṣọọṣi naa sọ awọn ọ̀rọ̀ iwaasu rírorò melookan nipa Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, ṣugbọn eyi kò kó irẹwẹsi ba awọn eniyan olotiitọ-ọkan lati maṣe wá si awọn ipade. Awọn Ẹlẹ́rìí naa di kókó ijumọsọrọpọ pataki ninu awọn ṣọọbu ati gareeji ọkọ̀ ati ninu ṣọọṣi paapaa. Ni oṣu mẹfa lẹhin naa, awujọ ikẹkọọ Bibeli ńlá meji ni a dá silẹ. Kruszwica ní ijọ ti ń gbéṣẹ́ṣe ti o ni iye ti o tó 35 awọn olujọsin Jehofa ninu nisinsinyi. Wọn ń dari 75 ikẹkọọ Bibeli inu ile wọn sì mú ọwọ́ wọn dí ninu mimu “awọn ohun fifanilọkanmọra” tí isin èké dè nigbekun nigbakanri wọle nisinsinyi.

Laaarin awọn wọnyi ni Bogdan wà mẹmba idile Katoliki paraku kan ti o jẹ ẹni ọdun 23. Ó sọyeranti pe: “Mo maa ń mu ọti, mu siga, mo sì maa ń gbé igbesi-aye oniwa palapala. A mọ̀ mí sí ẹhanna ati adárúgúdùsílẹ̀, kò sì jọbi ẹni pe ẹnikẹni bikita. Bi o ti wu ki o ri, nigba ti mo bẹrẹ sii kẹkọọ Bibeli, ìya mi halẹ̀ lati gbé majele jẹ funraarẹ. Bi emi kò ti lè faragba ikimọlẹ naa, mo já gbogbo ifarakanra pẹlu Awọn Ẹlẹ́rìí. Lẹhin naa, pẹlu iranlọwọ awọn aṣaaju-ọna akanṣe, ó ṣeeṣe fun mi lati jàbọ́ lominira kuro lọwọ gbogbo awọn aṣa buburu. Bi mo ti di ẹni ti a baptisi ni Apejọpọ Agbegbe ‘Awọn Olùfẹ́ Ominira’ ti ọdun 1991, mo ti yan iṣẹ-ojiṣẹ alakooko kikun gẹgẹ bii gongo mi ninu igbesi-aye mo sì ti ń ṣe aṣaaju-ọna oluranlọwọ lati ìgbà naa wá.”

Sławomir ẹni ọdun 21 ni ìbẹ́mìílò ati Ijọsin Satani ti gbámú, eyi ó kọ̀ silẹ gbàrà ti o rí i pe Bibeli dẹbi fun iru awọn aṣa bẹẹ. “Ṣugbọn Satani ń baa lọ laidawọduro,” ni ó sọ. “Ni òru ọjọ kan ẹ̀rọ orin aláwo bẹrẹ sii kọrin laiṣi i silẹ, mo sì gbọ́ ohùn orin Satani, bi o tilẹ jẹ pe mo ti kó gbogbo ohun ti ó tanmọ ijọsin Eṣu jade kuro ninu ile. Mo gbadura si Jehofa, o si ràn mi lọwọ lati pada jere iwadeedee nipa tẹmi. Oniṣegun ọpọlọ kan ti mo maa ń lọ bá nipa ìrọni awọn obi mi ṣakiyesi imusunwọn sii patapata ninu ipo mi ó sì pari èrò pe araami yá. Ó kọ: ‘A mu un larada nipasẹ Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa’ sara iwe isọfunni mi.”

Didena Ẹmi Ayé

Ni guusu iwọ-oorun Kruszwica ni Środa Śląska wà. “Awọn ohun fifanilọkanmọra” tún ń fi araawọn hàn ninu ilu kekere yii ti o ní 9,000 awọn eniyan ninu. Ni ọdun mẹrin sẹhin, kìkì ọ̀kan lara awọn arabinrin wa nipa tẹmi ni o ń gbé nibẹ̀. Bi o ti wu ki o ri, nisinsinyi, iye awọn akede Ijọba ti goke de 47. Ọpọlọpọ ninu awọn ti o jẹ Ẹlẹ́rìí ni a ti fẹ̀ẹ̀kanrí gbámú ninu awọn idẹkun ìbẹ́mìílò, ìfara-ẹni-jìn-fún-òògùn, ati iwapalapala. Wọn nimọlara pe eyi ní ọ̀nà gbigbooro julọ jẹ́ nitori àfo tẹmi ti ó wà ninu ṣọọṣi naa ti ó wulẹ lè dẹbi fun awọn eniyan nipa tẹmi nikan, kì í ṣe ki o ràn wọn lọwọ. Awọn Ẹlẹ́rìí ń pese itura alaafia gidi fun awọn eniyan naa.

Awọn ọ̀dọ́ ninu ijọ ti fi ile-ẹkọ ṣe ipinlẹ àdáni wọn fun iṣẹ iwaasu. “Awọn ọmọ ile-ẹkọ ẹlẹgbẹ mi maa ń saba sọ fun mi pe: ‘Iwọ ń fi ìgbà èwe rẹ tàfàlà,’” ni Kasia ẹni ọdun 18 rohin. “Ṣugbọn mo ti yẹra fun ọpọlọpọ ijangbọn, igbesi-aye mi sì ti di eyi ti o nitumọ. Mo ń dari awọn ikẹkọọ Bibeli melookan ni ile-ẹkọ emi kò sì ṣainaani yala iṣẹ àṣetiléwá tabi ikẹkọọ ara-ẹni mi. Awọn ọmọbinrin ti wọn sọ pe mo ‘ń fi ìgbà èwe mi tàfàlà’ ti di ìyá ṣaaju akoko yii, ni wíwọ̀jà pẹlu awọn ẹrù iṣoro.”

Awọn itẹjade Watch Tower ti di eyi ti o gbajúmọ̀ gidigidi ni awọn ile-ẹkọ adugbo. Fun apẹẹrẹ, olukọ èdè Polish kan sọ fun awọn akẹkọọ rẹ̀ lati tẹle èdè ti o ṣe kedere ti iwe irohin wa Ji! gẹgẹ bi awokọṣe ninu kíkọ àròkọ wọn. Ewa aṣaaju-ọna oluranlọwọ rí iwe pẹlẹbẹ naa School and Jehovah’s Witnesses gẹgẹ bi eyi ti o wulo gan-an. “Mo mọriri itẹjade yii gan-an. Awọn olukọ mi mọ̀ ọ́n daradara. Emi kò tíì ni iṣoro eyikeyii ninu rírí iyọnda gbà kuro ni kilaasi ki ń ba lè lọ si awọn apejọpọ ńlá.” Iru ẹmi ironu rere kan bẹẹ ní apá ìhà awọn ọ̀dọ́ eniyan ń mú ọkan-aya Jehofa yọ̀.—Owe 27:11.

Ọ̀daràn Paraku Yipada

Si apá ila-oorun Środa Śląska ni Strzelce Opolskie, nibi ti ọgbà ẹ̀wọ̀n meji wà. Ọ̀kan jẹ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n ti o ni idaabobo ti o peléke ju fun awọn arufin ti o ti gíràn-án. Awọn Ẹlẹ́rìí ń ṣe ibẹwo deedee sinu awọn ọgbà eto-idasilẹ ijiya ẹṣẹ meji yii lati mú otitọ lọ fun awọn ẹlẹwọn, ọpọlọpọ ninu awọn ti wọn tún wà ni igbekun Babiloni Ńlá, ilẹ-ọba isin èké agbaye.—Ìfihàn 18:1-5.

Awọn Ẹlẹ́rìí naa bá awọn ẹnikọọkan ti wọn jẹ́ alajọgbe inu ẹ̀wọ̀n ati awujọ kekere ti awọn ẹlẹwọn kẹkọọ Bibeli, diẹ ninu awọn tí a ti baptisi. Bi o tilẹ jẹ pe wọn gbọdọ lo akoko ifisẹwọn wọn pé, wọn ń waasu ihinrere fun awọn alájọgbé inu ẹ̀wọ̀n miiran lọna gbigbeṣẹ. Ẹlẹwọn kan tí ń murasilẹ fun iribọmi ṣe iru iyipada ti o pẹtẹrí bẹẹ debi pe awọn alaṣẹ ọgbà ẹwọn yọnda fun un lati lọ si ile lẹẹkan lọ́sẹ̀. Awọn miiran ti kọwe si awọn idile wọn ni sisọ ipinnu wọn jade lati fi ọgbà ẹ̀wọ̀n silẹ, kì í ṣe gẹgẹ bi ọdaran, ṣugbọn gẹgẹ bi Ẹlẹ́rìí Jehofa.

Ọ̀gá patapata fun ọ̀kan ninu awọn ọgbà ẹ̀wọ̀n naa ṣe aroye pe awọn alufaa Katoliki sábà maa ń wá ṣugbọn wọn kò ṣaṣepari ohunkohun. O beere lọwọ Awọn Ẹlẹ́rìí naa pe: “Ki ni ó jẹ ki o ṣeeṣe fun yin lati yí ki ẹ sì mú awọn eniyan wọnyi pada si ipo ti o dara?” Lẹta kan lati ọdọ ẹlẹwọn kan si idile rẹ̀ dahun: “Nihin-in ninu ọgbà ẹ̀wọ̀n, Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti sọ fun mi nipa ileri agbayanu ti Ọlọrun nipa iṣakoso titun, Ijọba Jehofa, ti yoo ṣakoso lori ilẹ̀-ayé laipẹ. Nihin-in mo ti ní akoko lati ṣayẹwo ọ̀nà igbesi-aye mi iṣaaju ninu imọlẹ Bibeli. Bi mo ti dé awọn ipari èrò bibani ninujẹ, ìfẹ́-ọkàn lati di eniyan ominira ati lati ri araami ni ọmọ-abẹ Ijọba Ọlọrun ti gbá mi mú. Lonii mo jẹ Ẹlẹ́rìí Jehofa ti a ti ṣe iribọmi fun.”

Ni inu ọgbà ẹ̀wọ̀n keji, ọpọlọpọ ni wọn ń lo akoko ọlọdun 25 fun iṣikapaniyan. Ikẹkọọ Bibeli deedee kan ni a ń dari pẹlu awọn ọkunrin 12. Ọ̀kan lara wọn ya igbesi-aye rẹ̀ si mimọ fun Jehofa a sì ṣe iribọmi fun un, awọn ti o sì ṣẹku ń wéwèé lati gbé awọn igbesẹ wọnyi. Ni mimọriri awọn iyọrisi ọ̀nà ìgbàkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tí Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lò, ọ̀gá patapata fun ọgbà ẹ̀wọ̀n naa sọ pe: “Kì í ṣe awọn ọ̀daràn 12 ni mo ni. Mo ni 600. Ẹ jọwọ bá mi tún wọn yí pada si ipo ti o dara. Emi yoo pese gbogbo ohun ti ẹ nilo fun yin, ṣugbọn ẹ jọwọ ẹ ṣe itolẹsẹẹsẹ naa. Ẹ bojuto wọn!”

Ohun ti awọn arakunrin naa ṣe gan-an niyẹn. Wọn ṣe igbekalẹ itolẹsẹẹsẹ Bibeli kan ti ó dalori ète igbesi-aye, ireti fun ọjọ-ọla, ati ijẹpataki fifi awọn aṣa jatijati silẹ. Wọn tun sọ awọn iriri ẹlẹwọn tẹlẹri kan ti ó di ọ̀kan lara Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti a sì yàn án ní alagba ijọ kan. Awọn Ẹlẹ́rìí naa funni ni awọn kókó itẹnumọ lati inu ìtàn igbesi-aye olè ají-diamondi kan ati aloogun nilokulo ti wọn ti kẹkọọ otitọ.a Awọn 20 ẹlẹwọn ti wọn wá ri itolẹsẹẹsẹ naa bi eyi ti o gbadunmọni julọ wọn sì beere ọpọlọpọ ibeere, awọn kan tilẹ beere fun ikẹkọọ Bibeli.

A Dán Igbagbọ ati Ifarada Wò

Lubaczów jẹ ilu kekere kan lẹbaa ibode Ukraine ti o ni 12,000 eniyan ninu. Iṣẹ ajihinrere nibẹ ni a tubọ járamọ́ ni 1988 nigba ti awọn aṣaaju-ọna ṣí wá lati ran awọn akede 12 adugbo lọwọ. Nisinsinyi 72 awọn akede Ijọba agbekankanṣiṣẹ ni wọn wà, ti 150 awọn eniyan sì wá sí ayẹyẹ Iṣe-iranti ti 1991 ninu Gbọngan Ijọba titun ti wọn ṣẹṣẹ kọ́.

Ni June 1991, Pope John Paul II ṣebẹwo si Lubaczów. Ṣugbọn iyẹn kò ṣe ohunkohun lati pagi ti ojulowo igbagbọ laaarin awọn eniyan naa. Ọpọlọpọ ninu wọn ni iyemeji ati awọn ibeere nipa ète igbesi-aye ati ireti fun ọjọ-ọla ń yọ lẹnu. Nigba ti wọn kò lè ri idahun ti ń tẹnilọrun gbà lọdọ awọn awujọ alufaa, wọn yiju si Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Bi o tilẹ jẹ pe awọn eniyan naa lè kọ́kọ́ ni irora ẹ̀rí-ọkàn fun kíkọ ẹ̀hìn wọn si isin wọn, otitọ Bibeli ti wọn kọ́ ràn wọn lọwọ lati rí i pe awọn ti ṣe ipinnu ti o tọna.

Eyi ti o jẹ apẹẹrẹ pataki ni iriri Honorata, ti o jẹ́ aṣaaju-ọna deedee kan nisinsinyi. Ni nǹkan bi ọdun kan sẹhin, ó beere ohun ti orukọ Ọlọrun jẹ lọwọ alufaa ni ibi ijẹwọ ẹṣẹ. “Ifẹ ni Ọlọrun—iyẹn ni orukọ rẹ̀ ti ó rẹwà julọ,” ni alufaa naa dahun. Lẹhin ti o pẹ́ diẹ, ó fikun un pe: “Iwọ dabi garawa omi mimọgaara bii kristali kan ninu eyi ti ẹnikan kán ẹ̀kán aró sí. Ipa ti ó ní kò ṣee yipada.” Ó tipa bayii rí idahun rẹ̀. “Mo pinnu nigba naa pe emi yoo di ọ̀kan lara Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa,” ni Honorata sọ. “Iyẹn pẹlu kò ṣee yipada.”

Ó fẹrẹẹ jẹ́ gbogbo ẹni ti ó kẹkọọ otitọ ni Lubaczów ni o nilati farada àtakò lilagbara, ti ó jẹ́ agbawèrèmẹ́sìn paapaa. Ṣugbọn iyẹn kò fà wọn sẹhin kuro ninu titẹwọgba otitọ Bibeli ati mímú iduro wọn fun Jehofa.

Elżbieta rohin pe: “Lakọọkọ wọ́n lù mi ni ile. Lẹhin naa idile mi rọ́ wọnu Gbọngan Ijọba. . . . Wọn mú mi lọ si ile wọn sì bẹrẹ sii ‘ṣe idajọ’ pẹlu igi oníkókó. Wọn lù mi wọn sì gbá mi lati ori dé àtàǹpàkò ẹsẹ kìkì nitori pe mo ń kẹgbẹpọ pẹlu Awọn Ẹlẹ́rìí. A lù mi bii kíkú bii yíyè debi pe mo nilo itọju iwosan kanjukanju a sì gbé mi lọ si ile iwosan. Jehofa ràn mi lọwọ, araami sì kọ́fẹ pada. Idile mi kọ̀ mi sílẹ̀. Nigba ti mo sọ eyi fun alufaa, o foju tẹmbẹlu mi, ni wiwi pe: ‘Ṣe nitori iwọnba ìgbátí diẹ ni o wá fẹjọsun fun?’”

Arabinrin miiran sọyeranti pe: “Lọdọọdun ni mo sábà maa ń lọ si Częstochowa lati rákòrò niwaju Ọ̀wọ́ Agbelebuu, eyi ti mo kà sí ojuṣe kan fun gbogbo Katoliki olotiitọ-ọkan. Mo ṣì ní awọn àpá ni awọn eékún mi.” Ni ẹni ọdun 18 ó kẹkọọ otitọ ó sì sọ fun alufaa ati idile rẹ̀ pe oun kò ni pada si ṣọọṣi mọ. Oun ni a lù lọna ti o lekoko—“ó buru debi pe mo ni ìkọlù ọpọlọ,” ni ó rohin. “Ṣugbọn ni ile iwosan mo kọ́fẹ pada lọna ti o tó lati lọ si Apejọpọ Agbegbe ‘Awọn Olùfẹ́ Ominira.’ Mo búsẹ́kún fun ayọ nigba ti mo rí iṣọkan tootọ ati ifẹ laaarin awọn eniyan laisi ẹmi ìgbawèrèmẹ́sìn—awọn ohun ti emi kò tíì rí rí ni Częstochowa. Mo ti layọ tó pe mo ti niriiri iwarere-iṣeun Jehofa ti mo sì ti kẹkọọ lati gbẹkẹle e.” Jehofa ń fun awọn wọnni ti wọn kó awọn ẹrù-ìnira wọn sara rẹ̀ lokun ó sì ń dì wọn mu.—Orin Dafidi 55:22.

Ọpọlọpọ awọn igbekun Babiloni Nla ni wọn ń kọbiara si ìpè naa lati “jade kuro ninu rẹ̀” nisinsinyi ni orilẹ-ede Katoliki yii, àní gẹgẹ bi wọn ti ń ṣe ni awọn ibomiran paapaa. Bi o bá jẹ́ ifẹ-inu Jehofa, awọn eniyan rẹ̀ alaibẹru yoo maa baa lọ lati kó pupọ sii “awọn ohun fifanilọkanmọra” ti wọn fọ́nkáàkiri jakejado Poland jọpọ sibẹ. Dajudaju, pupọ sii ṣì maa dahunpada sibẹ si ìpè naa pe: “Maa bọ. Ati ẹni ti o ń gbọ́ ki o wi pe, Maa bọ. Ati ẹni ti ongbẹ ń gbẹ ki o wá. Ẹnikẹni ti o bá sì fẹ́, ki o gba omi ìyè naa lọ́fẹ̀ẹ́.”—Ìfihàn 18:4; 22:17.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo Ji! ti February 8, 1985, oju-iwe 18 si 21, ati May 22, 1988, oju-iwe 21 si 23.

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 24]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Sztum

Poznan

Kruszwica

POLAND

Warsaw

Środa Śląska

Częstochowa

Strzelce Opolskie

Lubaczów

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Wiwaasu ihin-iṣẹ Ijọba naa ni Kruszwica, Poland

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́