“Ẹ Yipada Si Ọdọ Mi, Emi Ó Sì Yipada Si Ọdọ Yin”
IDILE naa ń gbadun ijade didunmọni kan lọ sinu igbó. Nigba naa ni Peter ti o kereju, pada sẹhin, ni lile ọ̀kẹ́rẹ́ kan lọ si isalẹ oke kekere kan. Lojiji, ikuuku bo oju ọ̀run, ti òjò si bẹrẹ sii rọ̀. Lakọọkọ ọ̀wara ojo kekere kan ni, ṣugbọn ni kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ o wa di òjò nla kan. Idile naa kó awọn ẹrù wọn jọ ni kiakia wọn si sá lọ si inu ọkọ wọn. Gbogbo wọn si ń ṣe kayeefi ibi ti Peter wà.
Lakooko yii, Peter ń gbiyanju lati pada si ọdọ idile naa. O ṣoro lati ri iwaju, oju ọ̀nà ori oke naa si ń yọ̀ ninu òjò. Lairotẹlẹ, o dabi ẹni pe ilẹ yẹ̀ kuro labẹ ẹsẹ rẹ̀ ti o si ṣubu sinu kòtò jijin, fifarasin kan. O gbiyanju lati pọ́nkè jade, ṣugbọn awọn ẹgbẹẹgbẹ rẹ̀ ti ń yọ̀ jù.
Omi òjò ṣàn wa lati ori oke naa o si ń gbá ẹrẹ̀ kun inu kòtò naa. Peter wa ninu ewu rírì niti gidi. Ṣugbọn nigba naa ni baba rẹ̀ ri i ti o si fà á jade pẹlu okùn kan. Lẹhin naa, Peter ni a bawi kikankikan fun rírìn régberègbe kaakiri. Sibẹ, bi a ti yi i mọ́ aṣọ blanket ni ọwọ iya rẹ̀, ibawi rọrun gan-an lati gbà.
Iriri yii ṣapejuwe daradara ohun ti o ṣẹlẹ si awọn kan ti wọn ti wà laaarin awọn eniyan Ọlọrun tẹlẹ. Wọn ti ṣubú sinu kòtò jijin eto awọn nǹkan isinsinyi wọn si ń fi igbekuta gbiyanju lati rápálá jade ki wọn si pada si ibi-aabo eto-ajọ Jehofa. Ẹ wo bi o ti dùnmọ́ni tó lati mọ pe Jehofa jẹ alaaanu ti o si ṣetan lati ‘sọ okùn sisalẹ’ ki o si ràn wọ́n lọwọ pada si ibi aabo!
Awọn Ibalo Alaaanu Jehofa
Lẹhin lọhun-un ni ọjọ awọn ọmọ Israeli, ni opin kíkọ́ tẹmpili, Solomoni gba adura iyasimimọ ninu eyi ti o ti bẹ Jehofa lati tẹtisi awọn ẹ̀bẹ̀ ti a bá dari siha tẹmpili naa. Oun nigba naa wi pe: “Bi wọn [awọn ọmọ Israeli] ba ṣẹ̀ si ọ, nitori kò si eniyan kan ti kì í ṣẹ̀, bi iwọ ba si binu si wọn, ti o si fi wọn le ọwọ́ ọ̀tá, . . . bi wọn ba ro inu wọn wò ni ilẹ nibi ti a gbé kó wọn ni ìgbèkùn lọ, ti wọn ba si ronupiwada, ti wọn ba si bẹ̀ ọ́ ni ilẹ awọn ti o kó wọn ni ìgbèkùn lọ, . . . nigba naa ni ki iwọ ki o gbọ́ adura wọn ati ẹ̀bẹ̀ wọn ni ọ̀run ibugbe rẹ, ki o si mu ọ̀ràn wọn duro.”—1 Awọn Ọba 8:46-49.
Ẹbẹ Solomoni ni a muṣẹ ni ọpọ ìgbà ninu itan Israeli. Lati ìgbà dé ìgbà, awọn eniyan Ọlọrun yí sẹ́gbẹ̀ẹ́kan ti wọn si kọ̀ ọ́ silẹ. Nigba naa ni wọn mọ aṣiṣe wọn wọn si pada, ni wiwa a. Jehofa si dariji wọn. (Deuteronomi 4:31; Isaiah 44:21, 22; 2 Korinti 1:3; Jakọbu 5:11) Nipasẹ Malaki, Jehofa ṣakopọ ẹgbẹrun ọdun ibalo pẹlu awọn eniyan Rẹ̀ nigba ti Ó sọ pe: “Lati ọjọ awọn baba yin wá ni ẹyin tilẹ ti yapa kuro ni ilana mi, ti ẹ kò si pa wọn mọ. Ẹ yipada si ọdọ mi, Emi ó si yipada si ọdọ yin.”—Malaki 3:7.
Awọn Ìdí fun Ìkọ̀sẹ̀
Gẹgẹ bi o ti ri pẹlu awọn ọmọ Israeli, ọpọ awọn eniyan Ọlọrun lonii ni wọn yipada ti wọn si ya araawọn sọtọ kuro ninu eto-ajọ Jehofa. Eeṣe? Awọn kan ń sáré lé ohun kan ti o farahan bi eyi ti kò le panilara lakọọkọ lẹhin, bii Peter tí ń lé ọ̀kẹ́rẹ́. Ohun ti o ṣẹlẹ si Ada niyii. O rohin pe: “O ti jẹ́ aṣa fun gbogbo awa ti a jẹ alajọṣiṣẹ lati lọ papọ fun ounjẹ ọ̀sán ni awọn ile ounjẹ ti o sunmọtosi ni ọwọ́ ọ̀sán. Nitori naa nigba ti wọn késí mi lati gba ife kọfi kan ni opin ọjọ naa, kì í ṣe ohun ti o ṣoro lati tẹwọgba. Mo ronu pe emi kò lo akoko ti mo nilati lo fun awọn ipade tabi fun iwaasu. N kò mọ̀ pe eyi le jẹ́ ikuna kan si ati pa ilana ti o wa ni 1 Korinti 15:33 mọ́.
“Laipẹ, mo ń lọ bá wọn gẹṣin ni awọn ọjọ Saturday. Mo si tun ń lọ si sinima ati ibi ere ìtàgé pẹlu wọn. Iyẹn jalẹ si pipadanu awọn ipade diẹ. Ni paripari rẹ̀, emi kò lọ si ipade kankan tabi ṣajọpin ninu iṣẹ iwaasu mọ. Nigba ti mo mọ ohun ti o ń ṣẹlẹ, emi kò darapọ mọ́ eto-ajọ naa mọ́.”
Ninu awọn ọ̀ràn miiran idi naa le jẹ́ ẹṣẹ wiwuwo kan ti o farasin ti ń mu ki ẹni naa nimọlara aitootun lati sin Jehofa. (Orin Dafidi 32:3-5) Tabi ẹnikan le kọsẹ lori ohun kan ti Kristian ẹlẹgbẹ rẹ̀ kan sọ tabi ṣe, ni ṣiṣailoye, gẹgẹ bi Solomoni ti sọ, pe “kò si eniyan kan ti kì í ṣẹ̀.”—1 Awọn Ọba 8:46; Jakọbu 3:2.
Sibẹ awọn miiran ń rẹwẹsi nigba ti wọn ba gba ibawi. (Heberu 12:7, 11) Òòfà fun gbigbe igbesi-aye onifẹẹ ọrọ̀ alumọọni ti sún ọpọlọpọ lati dawọ ṣiṣiṣẹsin Ọlọrun duro. Lọpọ ìgbà, ninu iwakiri fun aṣeyọri ti ayé, wọn ti ri araawọn bọ inu iṣẹ ounjẹ oojọ patapata debi pe kò tii si aaye ninu igbesi-aye wọn fun iṣẹ isin Ọlọrun. (Matteu 13:4-9; 1 Timoteu 6:9, 10) Ǹjẹ́ ipo iru awọn ẹni bẹẹ ha jẹ eyi ti kò ṣee mú sunwọn sii bi?
Iwọ Yoo Ha Dahunpada si Ikesini Jehofa Bi?
Ni akoko kan Jesu sọ ohun kan ti o ṣoro lati loye, a si mu awọn kan kọsẹ. Akọsilẹ naa wi pe: “Ọpọ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pada sẹhin, wọn kò si ba a rìn mọ.” Ṣugbọn kì í ṣe gbogbo wọn ni a mú kọsẹ. Akọsilẹ Bibeli naa ń baa lọ pe: “Jesu wi fun awọn mejila pe, Ẹyin pẹlu ń fẹẹ lọ bi? Nigba naa ni Simoni Peteru dá a lohun wi pe, Oluwa, ọdọ ta ni awa o lọ? iwọ ni o ní ọ̀rọ̀ ìyè ainipẹkun.” (Johannu 6:66-68) Awọn aposteli Jesu fi ọgbọ́n woye pe fifi Jesu silẹ lè mu jamba wá.
Awọn kan ti wọn ṣubú lẹhin-ọ-rẹhin dori ipari ero ti o jọra. Wọn mọ lẹkun-un-rẹrẹ pe fifi eto-ajọ Ọlọrun silẹ jẹ́ igbesẹ onijamba kan lati gbé ati pe kiki ọdọ Jehofa ati Kristi nikan ni wọn ti le ri ọ̀rọ̀ ti ń sinni lọ si iye. Niwọn ti wọn ba ti dori iru ìmọ̀ lẹkun-un-rẹrẹ bẹẹ, wọn gbọdọ tun mọ lẹkun-un-rẹrẹ pe kò tii pẹ jù lae lati ṣatungbeyẹwo, tọrọ idariji lọwọ Jehofa, ki wọn si pada wa si ọdọ rẹ̀. Jehofa funraarẹ ni o ṣe ikesini naa pe: “Ẹ yipada si ọdọ mi, Emi ó si yipada si ọdọ yin.”—Malaki 3:7.
Niti gidi, nibo ni Kristian oloootọ-inu kan ti le ri ayọ bi kì í ba ṣe ninu ṣiṣiṣẹsin Jehofa? Bi ẹnikan ba sú lọ lẹhin ti o ti di apakan eto-ajọ Ọlọrun fun ìgbà diẹ, ki ni o duro de e lẹhin òde? Yoo tete mọ lẹkun-un-rẹrẹ pe oun nisinsinyi ti di apakan ayé ti o tubọ ń di oniwa-ipa sii. Oun yoo rii pé oun ti kó wọnú eto awọn nǹkan ti o kún fun agabagebe, irọ́, jibiti, ati iwapalapala, ayé kan ti ó lewu ti kò sì gbadunmọni bii kòtò ẹlẹ́rẹ̀ ti ó wu iwalaaye Peter ọdọ léwu. Nigba ti o ro inu rẹ̀ wò ti o si mọ lẹkun-un-rẹrẹ pe iwalaaye ayeraye oun wa ninu ewu, o gbọdọ tètè wá iranlọwọ lati yọ araarẹ kuro ninu ipo naa. Sibẹ, pipada le ṣairọrun.
Iwọ ha jẹ́ ẹnikan tí o ti gbiyanju lati yipada si ọdọ Jehofa ṣugbọn ti o ri i bi ohun ti o ṣoro bi? Nigba naa mọ̀ pe iwọ nilo iranlọwọ. Sì gbagbọ pe awọn arakunrin ati arabinrin rẹ ninu eto-ajọ Ọlọrun wà ní imuratan lati pese iranlọwọ fun ọ. Ṣugbọn iwọ nilati sapa lati fi ọkan-ifẹ rẹ fun Jehofa hàn. Akoko niyii lati ‘ro inu rẹ wò’ ki o si ‘yipada si ọdọ Jehofa niti gidi.’—1 Awọn Ọba 8:47.
A Ran an Lọwọ Lati Yipada
Ada ṣalaye ohun ti o ran an lọwọ lati yipada si ọdọ Jehofa: “Ni akoko ti o tọna gan-an, arabinrin naa ti o ti dari ikẹkọọ pẹlu mi késí mi lati wá si apejọ ayika kan pẹlu rẹ̀. Iwa rẹ̀ fanimọra! Oun kò si ṣaata mi rara! O fi ifẹ pupọ tobẹẹ hàn. O ti kọja ọdun kan ti mo ti lọ si ipade gbẹhin, ṣugbọn mo ti ń ṣaṣaro nipa ìjófìfo ayé ati lori otitọ naa pe, kiki ibanujẹ, ijakulẹ, ati iwapalapala ni ohun ti o wa lẹhin ifanimọra ṣakala naa. Nitori naa mo pinnu lati lọ sí apejọ naa. Nigba ti mo dé gbọngan iworan tí a ti ṣe é, mo lọ si ila ijokoo ti o kẹhin mo si fi araami pamọ si igun ṣíṣókùnkùn kan. N kò fẹ ki awọn ara ri mi ki wọn si beere awọn ibeere.
“Bi o ti wu ki o ri, itolẹsẹẹsẹ naa funni ni awọn imọran ti mo nilo gan-an. Nigba ti o pari, mo pinnu kì í ṣe kiki lati yipada sọdọ awọn eniyan Jehofa nikan ni ṣugbọn lati ya araami sọtọ fun un pẹlu gbogbo ọkan-aya mi. Awọn ara gbà mi pẹlu ọyaya ‘onínàákúnàá’ naa si pada wa.” (Luku 15:11-24) Gbogbo iyẹn ṣẹlẹ ni awọn akoko ti o ti kọja, Ada nisinsinyi si ti wà ninu iṣẹ isin alakooko kikun fun eyi ti o ju ọdun 25 lọ.
Ọ̀ràn ẹlomiran ti o ṣákolọ ní abajade alayọ kan ti o jọra. Awọn alagba kan fun José nimọran ti o tubọ ṣagbeyọ ironu tiwọn funraawọn ju ti awọn ilana Bibeli lọ. José, ẹni ti a mú rẹwẹsi ti o si kun fun ifibinuhan, lẹhin-ọ-rẹhin ṣubù sinu aiṣedeedee. Fun ọdun mẹjọ a ya a sọtọ kuro lọdọ awọn eniyan Ọlọrun, ni aarin akoko yẹn oun gbé alaigbagbọ kan niyawo ti o si di baba fun awọn ọmọ, ọkan ninu wọn ti oun fayegba kí á baptisi ninu Ṣọọṣi Katoliki.
Nikẹhin, a ràn án lọwọ nigba ti alaboojuto ayika ṣe awọn ibẹwo oluṣọ agutan sọdọ rẹ̀ ti o si rọ awọn alagba lati ṣe bakan naa. A mu un padabọsipo o si layọ lati ri ti aya rẹ̀ ni ifẹ-ọkan ninu otitọ. José ni lọwọlọwọ ń sin gẹgẹ bi alagba ninu ijọ. Bi awọn iriri meji wọnyi ti fihàn, Jehofa kii fa ọwọ ibukun sẹhin kuro lọdọ awọn ti wọn bá dahunpada si ikesini rẹ̀ onifẹẹ lati yipada.
Bi o ti wu ki o ri, lati le gbadun iru awọn ibukun bẹẹ, ẹnikan nilati kọ́kọ́ mọriri iranlọwọ ti a pese ki o si dahunpada si i. Ni awọn ijọ ti o pọju awọn ara ranti awọn ti wọn ti di alaiṣiṣẹmọ wọn si ń bẹ̀ wọn wo lati igba de igba, ni gbigbiyanju lati ràn wọ́n lọwọ. Didahunpada si iru iranlọwọ bẹẹ fi imọriri hàn fun aanu Jehofa.—Jakọbu 5:19, 20.
Ni otitọ, akoko niyii lati dahunpada si ikesini Jehofa pe: “Ẹ yipada si ọdọ mi.” (Malaki 3:7; Isaiah 1:18) Maṣe duro pẹ mọ. Awọn iṣẹlẹ aye ń tẹsiwaju pẹlu iyarakankan ti o pẹtẹrí. Ibi ti o dara julọ lati wà lakooko oníjì ti o wà niwaju ni inu eto-ajọ Jehofa, ni ipamọ labẹ idaabobo rẹ̀. Kiki awọn ti wọn sadi Jehofa ni wọn ni ireti aduroṣinṣin ti wiwa labẹ ipamọ kuro lọwọ irunu rẹ̀ ni ọjọ ibinu nla rẹ̀.—Sefaniah 2:2, 3.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
Iwọ yoo ha dahunpada si ikesini Jehofa pe, “Ẹ yipada si ọdọ mi” bi?