Wiwaasu ní Maputo Olú-Ìlú Fifanimọra Ti Mozambique!
Ni 1991, Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni a kàsí labẹ ofin ni Mozambique. Lati igba naa wá iwaasu ihinrere Ijọba Ọlọrun ti ń ni itẹsiwaju pipabambari ni orilẹ-ede ilẹ olóoru yii ti o wà ni etikun gúúsù ila-oorun Africa. Irohin ti o tẹ̀lé e yii ni o sọ nipa bi Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti ń ba iṣẹ idanilẹkọọ Bibeli wọn lọ ni Mozambique, ni pataki ni ayika Maputo, ti i ṣe olú-ìlú rẹ̀.
BÍ OMI Òkun India lílọ́wọ́ọ́wọ́ ti ń nipa le ayika rẹ̀ lori, Mozambique ń gbadun ipo ojú-ọjọ́ atunilara. Awọn bèbè okun ti o kun fun awọn igi ọpẹ ti o rẹwà lọna kikọyọyọ ati awọn òkìtì iyùn pọ̀ yamùrá ni ẹgbẹ̀ẹ̀gbẹ́ etikun naa. Ìyawọlẹ̀-omi-okun nla kan pẹlu awọn omi ti a ṣijibo tẹ́rẹrẹ gba gúúsù orilẹ-ede naa kọja—ibi àyè ti o bojumu fun Maputo, olú-ìlú rẹ̀
Ẹwà ati iparọrọ ilẹ yii, bi o ti wu ki o ri, funni ni ero ti ó gbòdì nipa iwa-ipa inu itan rẹ̀. Fun ọpọ ọrundun o ti jijakadi labẹ ijẹgabalenilori lati ilẹ okeere, lakọọkọ labẹ awọn Arabu ati lẹhin naa awọn ará Portugal. Awọn ti igbẹhin yii wá pẹlu ẹkunrẹrẹ ibukun Ṣọọṣi Katoliki lati ja ilẹ naa lólè awọn ohun iṣura rẹ̀—ehín erin, góòlù, ati awọn ẹrú. Nigbẹhin-gbẹhin, lẹhin ọpọ ọrundun itẹniloriba awọn atokeere ṣakoso, irukerudo abẹle kikoro kan bú jade ti o jalẹ si gbigba ominira ni 1975. Lọna ti o banininujẹ, iyipada naa kò mu ki igbesi-aye tubọ jẹ́ alailewu, bi o ti jẹ pe orilẹ-ede naa ti kówọnú yọ́yọ́ ogun abẹle, eyi ti o yọrisi ọpọ ìjìyà fun awọn eniyan, ni pataki fun awọn alaimọwọmẹsẹ olugbe igberiko.
Maputo, Olú-ìlú Naa
Ni ẹwadun ti o kọja, ẹgbẹẹgbẹrun awọn eniyan ilẹ Mozambique ni wọn ti fẹsẹ̀fẹ́ẹ lọ si awọn ibi ti o láàbò diẹ ninu awọn ilu ati awọn ilu-nla. Eyi ni ó rọrun lati kiyesi julọ ni pataki ni Maputo, nibi ti àdàlù awọn ọna ikọle atijọ ti awọn ará Portugal ati ti Africa rirẹwa ti bù ayika apafiyesi kún ilu-nla naa. Ni rinrin irin gbẹ̀fẹ́ la awọn opopona gbóóró naa, ti o ni igi lẹgbẹẹgbẹ ni Maputo kọjá lonii, ohun akọkọ ti iwọ yoo ṣakiyesi ni ogunlọgọ awọn eniyan ti wọn ń sa kòókòó-jàn-àn-jàn-án kiri ninu iṣẹ-aje wọn ojoojumọ. Ṣugbọn iyatọ kan wà. “Laika ìhágádígádí ati ìnira igbesi-aye ojoojumọ si, awọn eniyan naa maa ń wà ni imuratan nigba gbogbo lati jẹ ẹni bi ọrẹ,” ni Rodrigo, ojihin-iṣẹ-Ọlọrun kan ni Maputo ṣakiyesi. “Agbara káká ni iwọ yoo fi ri awọn eniyan oniwa ìpáǹle!” Bẹẹni, awọn eniyan Mozambique ni a mọ́ bi onifẹẹ atinuwa ati ẹni bi ọrẹ.
Dajudaju, bi o ti ri pẹlu ibi ti ó pọ̀ julọ ni Africa, ibi ti o dara julọ lati ṣalabaapade awọn eniyan ni ní awọn ọja adugbo. Lati debẹ iwọ lè wọ ọkọ Chapa 100, orukọ adugbo fun ọpọ awọn ọkọ ọlọ́pọ́n ti a ń lò fun èto-irinna gbogbogboo. Bi o ti saba maa ń rí, pupọ julọ awọn eniyan dabi ẹni ti ń rọ̀ mọ́ ode ọkọ naa ju awọn ti wọn wà ninu lọ. Boya o sanju lati fẹsẹ rin.
Awọn eniyan Mozambique jẹ awọn ti òwò ti di apakan araawọn. Oluṣebẹwo kan si Maputo laisi aniani ni yoo ṣakiyesi iye eniyan ti wọn ni iṣẹ adani nipa gbigbe ìsọ̀ kekere kan ró si iwaju ile ati ni awọn igun opopona. Iwọ yoo ha fẹ́ lati ra eso tutu, ewebẹ, ewé egboogi, tabi awọn èròjà atasánsán bi? Eyi ti o pọ̀ tó lati kárí ẹnikọọkan wà. Kí ni nipa awọn ààyè adiẹ, awọn eso kajú, tabi awọn esusu ti o lè fi kọ ile rẹ? Kò si ohunkohun ti o fun wọn ni wahala pupọ ju, ohun gbogbo ni a sì ń ṣe pẹlu ẹmi ibanidọrẹẹ. Awọn iṣẹ bii dídán awọn bata tabi fifọ awọn ọkọ̀ ni wọn wà larọọwọto pẹlu. Ni lilo ìyọ̀ṣó onirin gbigbona kan ati awọn abala ike fẹlẹfẹlẹ kan, ọdọmọkunrin kekere kan paapaa yoo ṣe ike si awọn iwe akọsilẹ rẹ ṣiṣeyebiye.
Niti gidi, kì í ṣe gbogbo òwò ṣíṣe ni opopona ni a gba laaye labẹ ofin. Wọn ń ṣe é ṣa o. Awọn akiri-ọjà alaibofinmu wọnyi ni a ń pe ni dumba nenge, eyi ti o tumọsi “gbarale ẹsẹ rẹ.” Laisi iyemeji eyi jẹ nitori pe nigba ti awọn alaṣẹ ba wa si itosi lati ṣayẹwo, ẹsẹ fífẹ́rẹ̀ nilẹ ni o ṣe pataki si jijẹ ki òwò wọn ti o wa labẹ ewu laaja.
Bi a o bá fi òórùn ti a ń gbọ́ pinnu, awa gbọdọ ti maa sunmọ ọja ẹja! Ni ọjọrọ ọjọ kọọkan, ni awọn bèbè okun ni Costa do Sol, igbokegbodo oníwótòwótò kan maa ń yi awọn ọkọ̀ ipẹja ká bi wọn ṣe ń kó awọn ẹja ti wọn pa ni ọjọ naa silẹ. Ni afikun si awọn ẹja ni oniruuru irisi ati ìtóbi, ni awọn alakan wà, akọ edé, ati, dajudaju, awọn edé tí ó gbajúmọ̀ ní Mozambique. Bi o ti wu ki o ri, iwọ lè lọkan ifẹ ninu iru iṣẹ ẹja pipa miiran ti o ń lọ lọwọ ninu ati ni ayika Maputo.
“Awọn Apẹja Eniyan”
Lati igba ti a ti ri ikasi gba labẹ ofin ni Mozambique, Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti ń ri idahunpada rere gbà lati ọdọ awọn ara ilu. Ọkunrin kan sọ imọriri rẹ jade nipa sisọ pe: “Ni London mo ti ri ọpọ lara yin ni awọn opopona. Ni tootọ, nibikibi ti mo ti dé, mo ti ri Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Nisinsinyi o mu mi nimọlara rere lati ri yin nihin-in pẹlu.”
Bi titẹwọgba awọn Bibeli ati awọn iwe nla ti a gbekari Bibeli ni èdè awọn ará Portugal ati Tsonga, awọn èdè ibilẹ, ba jẹ ohun ifitọka eyikeyii, nigba naa awọn wọnyi jẹ awọn eniyan ti wọn ni itẹsi ọkan nipa tẹmi niti gidi. Paula, ojihin-iṣẹ-Ọlọrun miiran kan, rohin pe ni owurọ Saturday ti ko buru pupọ ju kan, o jẹ ohun ti o ṣeeṣe daradara lati fi eyi ti o ju 50 iwe-irohin sode ni awọn ibi ọja kólọ-ń-lẹ̀ kódówó, tabi ọja gbogbogboo. Iwe naa Questions Young People Ask—Answers That Work ń jásí ọkan ti o gbajumọ lọna ti o lékenkà. Ọpọ awọn ọ̀dọ́ eniyan ni a ti tanù tabi sọ di alailobii nipasẹ ogun, ti o si dabi ẹni pe wọn mọriri iniyelori ati itọsọna ti iwe yii ń pese.
Ni iru ọ̀nà àṣà Africa ti a kò ṣedilọwọ fun kan, awujọ awọn eniyan ti o fi ọkàn-ìfẹ́ hàn yoo korajọpọ yika ojihin-iṣẹ-Ọlọrun naa lati gbọ́ ohun ti a ń sọ. Iru ikorajọpọ ojú pópó bẹẹ sábà maa ń yọrisi ijiroro Iwe Mimọ gbigbeṣẹ. Arabinrin kan sọyeranti iriri arumọlarasoke kan.
“Nigba ti mo ń ṣiṣẹ ijẹrii ojú pópó ni akoko kan, ẹ̀rù bà mi nigba ti ọkọ̀ ologun kan tẹ ìjánu mọto lojiji ó sì duro lẹgbẹẹ mi. Sọja kan ti o jẹ́ ọ̀dọ́ kigbe pe awọn ti o duro nitosi pé: ‘Éè, ẹyin ti ẹ wà nibẹ yẹn, ẹ sọ fun ọmọbinrin yẹn pe ki ó wá níbí.’ Nigba ti mo dé ọdọ rẹ̀, oju rẹ̀ mú ẹ̀rín wa bi o ti wi pe: ‘Eniyan rere ni yin. Awa layọ lati ri yin nihin-in. Mo gbagbọ pe o ní iwe ti ó sọrọ nipa awọn ọ̀dọ́ eniyan. Emi yoo fẹ́ ọ̀kan pẹlu.’ Mo dahun pe emi kò ni ọ̀kankan lọwọ, ṣugbọn mo mú un dá a loju pe ni gbàrà ti wọn bá ti wà lọwọ, emi yoo mú ọ̀kan wá si ile rẹ̀.”
Jíjá Iwe Si Ibi Ìkẹ́rùsí
Lati koju ibeere fun iwe ikẹkọọ ti ń pọ̀ sii, ẹ̀ka ọfiisi Watch Tower Society ni South Africa ń já iwe ikẹkọọ si ibi ìkẹ́rùsí ti o wà ni Maputo ni ọsẹ meji-meji. Manuel, ojihin-iṣẹ-Ọlọrun kan ń ṣabojuto ibi ìkẹ́rùsí naa oun ni o sì ni ẹrù-iṣẹ́ fun ṣiṣeto ipinkiri awọn iwe ikẹkọọ naa.
Ni òwúrọ̀ ọjọ kan, ọkunrin atójúúbọ́ kan kùgììrì wọle ó sì beere ohun ti a ń lo ibi yii fun. Manuel dahun pe eyi jẹ ibi ìkẹ́rùsí fun iwe ikẹkọọ Bibeli. Ọkunrin naa rin jade, ṣugbọn laaarin iṣẹju kan ó pada dé.
“Ó sọ pe iwe Bibeli niwọnyi, abi bẹẹkọ?” ni ó beere.
Manuel fesipada pe, “Bẹẹ gan-an ni.”
Ọkunrin naa beere pe, “Eto-ajọ wo ni eyi wà fun?”
Manuel fesipada pe, “Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa,” ó sì fikun un pe “awa maa ń pese awọn iwe ikẹkọọ yii fun awọn ijọ adugbo wa.”
Ọkunrin naa tújúká, “Áà Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa! Ohun pupọ ni mo nifẹẹ si nipa ẹyin eniyan wọnyi. Ṣugbọn sá, ohun kan wà ti emi kò nifẹẹ si nipa yin.”
“Ó dara, ki ni ohun ti o nifẹẹ si nipa wa?” ni Manuel fi ọgbọn beere.
“Mo nifẹẹ si awọn iwe adanilẹkọọ ti ń fanilọkanmọra ti ẹ ń mu jade,” ni ọkunrin naa ṣalaye. “Ohun ti emi kò nifẹẹ si ni pe emi kò lè ni eyi ti ó to ninu wọn lọwọ. Ó kò lè gbagbọ bi ebi iru iwe ikẹkọọ yin yii ti ń pa wa tó ni Maputo.” Lẹhin naa ni o fa akọsilẹ itolẹsẹẹsẹ awọn itẹjade lati ọwọ́ Watch Tower Society yọ, ti o ni ninu awọn itẹjade iwe irohin Ilé-Ìṣọ́nà ati Ji! ti oun ti tàsé.
“Mo maa ń mú akọsilẹ yii kiri nibikibi ti mo bá wà,” ni ó sọ fun Manuel. “Nigbakigba ti mo bá pade Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, mo maa ń gbiyanju lati gba awọn itẹjade eyikeyii ti wọn bá ni. Bi iwọ bá lè ràn mi lọwọ lati rí awọn ti mo tò sinu akọsilẹ mi, mo muratan lati san owo gọbọi.”
Ijiroro tẹle e. Manuel wa mọ pe ọkunrin naa kọkọ salabaapade Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni awọn sáà ọdun 1950 nigba ti o ka iwe naa Creation. Ṣugbọn niwọn bi a ti fofinde iṣẹ Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa labẹ ijọba awọn ará Portugal, itẹsiwaju diẹ ni o ṣeeṣe.
Nigba ti o ṣe ibẹwo si ọfiisi ọkunrin naa lẹhin naa, Manuel ṣakiyesi pe gbogbo awọn itẹjade Watch Tower ti ó ní ni o pọ́n sinu ọ̀rá ti o sì tò nigínnigín. Ó ṣeeṣe fun Manuel lati pese awọn itẹjade ti ọkunrin naa ń fẹ lati mu ki iwe gbigba rẹ̀ pe perepere, oun sì ṣeto lati maa dari ikẹkọọ Bibeli pẹlu ọkunrin naa ati idile rẹ̀.
Gbogbo ifunrugbin ati ibomirin nipa tẹmi yii bẹrẹ sii so eso bi Ọlọrun ti ń jẹ́ ki “ibisi wá.” Ẹ̀rí ti o daju wà pe ikore awọn ọlọkan títọ́ yoo nilati so eso yanturu ni Mozambique!—1 Korinti 3:6; Johannu 4:36.
Ilọsiwaju Niti Iṣakoso Ọlọrun Laika Awọn Idigbolu Sí
Lonii, iye ti o ju 50 ijọ ni ó wà ni ilu Maputo ati ayika rẹ̀. Bi o ti wu ki o ri, kò sí ẹyọ Gbọngan Ijọba kanṣoṣo ti o jẹ́ ti Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nibẹ. Eeṣe ti o fi rí bẹẹ? Nitori ipo ọrọ-aje ti kò barade ni, awọn ijọ naa kò tíì lè kọ́ nǹkankan ani bi o tilẹ jẹ pe awọn kan ti ni ilẹ fun ọpọlọpọ ọdun.a
Sibẹ, iru awọn idigbolu bẹẹ kò dí itẹsiwaju lọwọ. Ni lọwọlọwọ iye ti o ju 5,000 ikẹkọọ Bibeli inu ile ni a ń dari ni apa iwọ-oorun Mozambique. Ibeere fun ikẹkọọ ga tobẹẹ gẹẹ ti o fi jẹ pe awọn ohun akọkọmuṣe kan ni a gbọdọ fi lelẹ. Bi ẹnikan bá beere fun ikẹkọọ, o sábà maa ń jẹ́ lori gbigba pe oun yoo kọkọ lọ si gbogbo ipade ti ijọ.
Ijọ kan ti o wà ni adugbo alailowo lọwọ kan laipẹ yii ni iye eniyan ti o jẹ́ 189 ni ipade ọjọ Sunday ani bi o tilẹ jẹ pe kìkì akede ihinrere 71 ni wọn. Awujọ titobi yii padepọ ni ibi gbalasa ni agbala ile kan. Agbegbe naa ni a pamọ kuro lọwọ afiyesi gbogbogboo nipasẹ ọgbà ti a fi paanu ati esùsú ṣe. Ṣaaju ipade kọọkan, agbegbe naa ni a ń gbá mọ́ tonitoni, apa pupọ julọ awujọ naa ti o ni ninu awọn agbaagba, a maa jokoo sori ẹní ti a fi esùsú ṣe ti a tẹ́ sori ilẹ. Ẹ sì wo bi wọn ti fetisilẹ yekeyeke si itolẹsẹẹsẹ naa tó! Niwọn bi ọpọ julọ awọn ẹni titun kò ti ni ẹ̀dà Ilé-Ìṣọ́nà lọwọ lati maa bá ikẹkọọ naa lọ, wọn kẹkọọ lati fetisilẹ kínníkínní nigba kíkà awọn ipinrọ, ti ọwọ́ pupọ yoo sì nà soke ni idahunpada si awọn ibeere ti oludari ikẹkọọ beere.
Ijọ miiran ti o ni awọn akede 59 ní iye ti o ju 140 lọ ti wọn maa ń wá deedee. Wọn sábà maa ń pade lori ilẹ titẹju kan ni gbangba. Ṣugbọn nigba òjò, ijọ naa yoo fúnpọ̀ sinu yàrá meji ti o wà ninu ile àdáni kan. Awọn ti o lé silẹ ninu awujọ naa yoo bẹrẹ sii kún inu ọ̀dẹ̀dẹ̀, ile ìdáná, ati ọ̀dẹ̀dẹ̀-pẹ̀tẹ́ẹ̀sì. Lẹẹkan sii, ẹnikan kò lè ṣaikiyesi imọriri ati ifetisilẹ yekeyeke naa bi olukuluku, ti o ní ọpọlọpọ ọ̀dọ́ ninu, ti ń fọkan bá itolẹsẹẹsẹ naa lọ.
Kò si ibi ti idagbasoke ọjọ iwaju ni Mozambique ti hàn kedere ju ni awọn apejọpọ lọ. Laipẹ yii apejọ ayika kan ni a ṣe ni gbọngan eré kan ti eniyan ati maluu ti maa ń jà ni aarin ilu naa ni atijọ. Iwọ ha lè woye iyalẹnu naa ni iha ọdọ iye akede ti o fẹrẹẹ tó 3,000 nigba ti iye ti o ju 10,000 pesẹ si ijokoo naa?
“Ikore Pọ̀”
Awọn iriri wọnyi fihàn ni kedere pe iṣẹ pupọ sii ni o ṣì wà lati ṣe ni Mozambique. Awọn ijọ kan ṣẹṣẹ ni ibẹwo alaboojuto arinrin-ajo wọn akọkọ tí ẹ̀ka ọfiisi rán jade ni. Wọn ń ri itilẹhin ti wọn nilo julọ gba lati ràn wọn lọwọ lati mú ilana iṣe nǹkan yiyẹ ti eto-ajọ naa ṣiṣẹ.
Gidigidi ni awọn ijọ tun mọriri dide awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun lati Gileadi laipẹ yii. Francisco, alagba kan ni Maputo sọ pe: “Eyi jẹ́ igbesẹ titobi kan fun itẹsiwaju fun wa. A ni itara. A ni ifẹ. Sibẹ, a kò ní isọfunni kíkún ti o dé kẹhin nipa awọn ọ̀ràn eto-ajọ naa. Ohun ti a nilo niti gidi ni ẹnikan ti o ní iriri ti o wá ni taarata lati kọ́ wa nipa bi o ṣe yẹ ki a ṣe awọn nǹkan. Nisinsinyi, a layọ gidigidi lati ni awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun pẹlu wa.”
Awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun naa, ni ìhà ọ̀dọ̀ wọn, layọ lati ṣiṣẹsin awọn arakunrin wọn. Hans, ẹni ti a rán si Mozambique laipẹ yii lẹhin ṣiṣiṣẹsin fun 20 ọdun ni Brazil, ko gbogbo rẹ̀ pọ ni ọ̀nà yii: “Ṣiṣiṣẹ ninu pápá awọn ará Mozambique jẹ anfaani giga kan! A ronu pe a wà ni bebe ibisi pupọ nihin-in. Iṣẹ pupọ ni o wà lati ṣe. A lè lo 10 si 20 ojihin-iṣẹ-Ọlọrun miiran ni Maputo nikanṣoṣo.”
Ibisi iṣakoso Ọlọrun ni Mozambique rán wa leti ọrọ kanjukanju Jesu pe: “Ikore pọ̀, ṣugbọn awọn alagbaṣe kò tó nǹkan; nitori naa ẹ gbadura si Oluwa ikore ki o lè rán awọn alagbaṣe sinu ikore rẹ̀.” (Matteu 9:37, 38) Gbogbo idi ni o wà lati gbagbọ pe Jehofa yoo dahun ẹbẹ kanjukanju yẹn nitori awọn iranṣẹ rẹ̀ ni Mozambique.
Ẹgbẹẹgbẹrun Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lo ọdun 12 tabi ju bẹẹ lọ ni ọgbà àhámọ́ ti o wà ni ariwa iwọ-oorun Mozambique. Nigba ti awọn kan lara wọn pada si Maputo laipẹ yii, kìkì ohun ti wọn ni nikaawọ wọn ni ìró-aṣọ kan lati ró mọ ibadi wọn. Ohun ti wọn ni ní yanturu ni igbagbọ! Awọn ọrẹ ọlọlawọ ti ounjẹ ati aṣọ lati ọdọ Awọn Ẹlẹ́rìí ẹlẹgbẹ wọn ni awọn ilẹ ti o wà nitosi ràn wọn lọwọ lati ni ibẹrẹ rere kan ninu igbesi-aye
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bi ọkunrin kan bá ṣeeṣi rìnnàkore lati ri iṣẹ nibẹ, owo rẹ̀ ní ipindọgba jẹ́ $20 si $30 loṣu.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Awọn ijọ ń gbadun ọpọ awọn eniyan ti wọn jade fun ijẹrii Kristian ni awọn òwúrọ̀ Saturday
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Jaimito ọmọ ọdun 5 niyii. A bii sinu ọgbà àhámọ́. Lonii, awọn obi Jaimito layọ lati tun pada wà ní Maputo. Ni ọsọọsẹ Francisco, baba Jaimito, ń kó idile naa jọ papọ fun ikẹkọọ Bibeli. Awọn obi mejeeji ń lo ọpọlọpọ akoko ni títọ́ awọn ọmọ wọn lati jẹ́ olukọ ti o gbéṣẹ́ ninu iṣẹ-isin pápá. Jaimito ń gbadun fifi awọn iwe ikẹkọọ sode ni ọja titobi julọ naa
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Otitọ naa pe awọn ijọ kò ni Gbọngan Ijọba ní ikaawọ wọn kò dá itẹsiwaju wọn duro. Ninu ọ̀ràn ti o pọ julọ, iye ti o ju ilọpo meji awọn akede ń wá si awọn ipade