Igbesẹ Kan Lori Ọ̀nà Àtipadà
‘ÓBÁ wọn sọrọ pẹlu awọn àkàwé.’ Bayii ni Bibeli ṣe nasẹ awọn àkàwé manigbagbe mẹta Jesu nipa aanu—agutan kan ti o sọnù, owó drachma kan ti ó sọnù, ati ọmọ oninaakuna naa.—Luku 15:3-32.
Awọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ meji ninu Ilé-Ìṣọ́nà ti April 15, 1991, ṣe ifọsiwẹwẹ awọn àkàwé wọnni ti o sì ran ọpọlọpọ òǹkàwé lọwọ lati ri bi a ṣe lè fi aanu hàn lonii. Olori ọgangan afiyesi wa ni a dari rẹ̀ si awọn oluṣọ-agutan tẹmi ti wọn ń lo idanuṣe lati kàn si awọn ti a ti yọlẹgbẹ ṣugbọn ti wọn yoo dahunpada si ibẹwo oninurere. Ki ni o ti jẹ abajade awọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ wọnyi ati ọ̀nà igbase nǹkan titun naa?
Kete lẹhin ti a ti tẹ iwe irohin naa jade, ọkunrin kan ni ipinlẹ Washington, U.S.A., kọwe pe: “Ọpọ yanturu ẹ̀rí inurere onifẹẹ ti Jehofa dé sinu apoti ìgbàwé mi lonii. Mo jokoo nihin-in pẹlu omije ni oju mi ati ayọ ninu ọkan-aya mi lori ipese naa ati iṣatunṣe tí Ọga Ogo pese. Kìkì Ọlọrun ododo nikan ni o lè pese iranlọwọ fun awọn ẹni-bi-agutan ti wọn ti sọnu. . . . Bẹẹni, a ti yọ mi lẹgbẹ ṣugbọn mo wà ni oju-ọna si ìgbàpadà.” A gbà á pada ni October.
Ṣugbọn ki ni nipa awọn ibẹwo ti awọn alagba ijọ meji ṣe? Kristian iyawo kan kọwe pe: “Awọn ọ̀rọ̀ kò lè sọ bi imọlara mi ṣe rí jade. A ti yọ ọkọ mi lẹgbẹ fun ohun ti o tó ọdun 13. Awọn alagba ṣebẹwo sọdọ rẹ̀, gẹgẹ bi a ti damọran rẹ̀ ninu ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ naa. Ni alẹ́ àná fun ìgbà akọkọ lati ọpọlọpọ ọdun, ó lọ si ọ̀kan lara awọn ipade. Oun nisinsinyi ń gbiyanju lati yí igbesi-aye rẹ̀ pada ati lati ṣe ipadabọsipo.”
Bi awọn alaboojuto arinrin-ajo ti ń lọ lati ijọ dé ijọ, wọn ń rí awọn abajade naa. Alaboojuto ayika kan kọwe laipẹ yii pe:
“Nigba ti a tẹ Ilé-Ìṣọ́nà April 15, 1991, jade, ọpọlọpọ ṣekayeefi nipa ohun ti idahunpada naa yoo jẹ́ fun awọn alagba ti wọn ń ṣe ikesini. Idahun naa ti ṣe kedere.
“Ni ayika wa, awọn ijọ mẹrin ti mo bẹ̀wò ti niriiri ìpadà awọn eniyan mẹsan-an ọ̀tọ̀tọ̀ sinu awọn Gbọngan Ijọba. Bi o tilẹ jẹ pe ẹnikanṣoṣo ni a ti gbà pada, awọn mẹjọ yooku ń tẹsiwaju daradara. Awọn alagba ati awọn ijọ layọ lati ri awọn eso isapa wọn ati ọgbọ́n ti o wà ninu fifi itọsọna iṣakoso Ọlọrun silo.
“Awa layọ ninu iṣeto rere, alaaanu yii. Bi arabinrin kan ti a gbà pada ti sọ, ‘Emi kò ni igboya lati pada funraaami, niwọn bi mo ti nimọlara idalẹbi niwaju Jehofa. Ṣugbọn nigba ti awọn alagba kàn sí mi, iṣiri naa ni mo nilo lati pada.’ Itara-ọkan rẹ̀ ti fun ijọ naa niṣiiri lọna giga.”
Àní bi ọpọlọpọ ti a bẹ̀wò kò bá dahunpada paapaa. Ohun rere ni a ti ṣaṣepari rẹ̀ nipasẹ idanuṣe alaaanu yii. Nigba naa, bẹrẹ ni September awọn alagba ninu ijọ kọọkan yoo ṣatunyẹwo orukọ awọn ẹni ti ó wà ni ipinlẹ iṣẹ wọn ti a ti yọlẹgbẹ ti wọn yoo sì ṣeto lati ṣebẹwo sọdọ gbogbo awọn ti wọn nimọlara pe wọn yoo dahunpada si aanu ti a nawọ rẹ̀ jade.