Biṣọọbu Àgbà Kò Lè Koju Iṣoro!
NI ỌDUN ti o kọja, apapọ igbimọ ṣọọṣi kan (igbimọ giga julọ ti awọn olóyè cardinal) ni a ṣeto lati jiroro awọn kókó ọ̀ràn kan ti o kan Ṣọọṣi Katoliki gbọ̀ngbọ̀n. Ọ̀kan lara awọn wọnyi, gẹgẹ bi iwe irohin Il Sabato ṣe sọ, ni “bibẹru ti awọn ẹya-isin kò bẹru atako.” Bi o ti wu ki o ri, iwe irohin naa sọ pe: “Kò yẹ ki o jẹ iṣoro kankan fun awọn alufaa àgbà naa lati dori ifohunṣọkan lori kókó yii. Gbogbo wọn fohunṣọkan pe aini wà fun iwadii jijinlẹ sii nipa ohun yiyanilẹnu ti awọn ajọ igbokegbodo isin titun ati aini naa lati dí itankalẹ wọn lọwọ, bi o bá ti lè ṣeeṣe tó.”
Bi o ti wu ki o ri, ó ṣe kedere pe, “bibẹru ti awọn ẹya-isin kò bẹru atako” ki i wulẹ ṣe iṣoro ni Italy nikan. Il Sabato rohin pe: “Nigba ti ó ń ṣebẹwo si Vatican laipẹ yii, Biṣọọbu àgbà Kirill ará Smolensk [ọkan lara awọn ilu-nla Russia ti o lọjọ lori julọ] . . . beere lọwọ pope fun itilẹhin gbogbo ṣọọṣi wọn lagbaaye fun kikoju iṣoro ìpọ̀yamùrá Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ati awọn ẹgbẹ́ ti o farajọ wọn ni Soviet Union.”
Ni ọrundun kìn-ín-ní, awọn aṣaaju isin ti o ti fidimulẹ ni iru aroye kan-naa nigba ti Isin Kristian di eyi ti a tankalẹ nipasẹ awọn alatilẹhin rẹ̀ lọna aibẹru atako. Ni akoko iṣẹlẹ kan awọn Ju ti wọn kun fun irunu ṣaroye fun awọn alakooso ilu naa pe: “Awọn wọnyi ti o ti yí ayé po wá si ihin yii pẹlu”! (Iṣe 17:6) Nigba yẹn lọhun-un, awọn aṣaaju isin gbiyanju karakara lati dá itankalẹ isin Kristian duro, ṣugbọn wọn kùnà. Lonii pẹlu, isapa eyikeyii lati dá itankalẹ ẹ̀kọ́ isin Kristian tootọ duro ni yoo forile iparun. Ọlọrun fúnraarẹ̀ ṣeleri pe: “Kò sí ohun ìja ti a ṣe si ọ ti yoo lè ṣe nǹkan; ati gbogbo ahọ́n ti o dide si ọ ni idajọ ni iwọ óò dá ni ẹbi. Eyi ni ogún awọn iranṣẹ Oluwa [“Jehofa,” NW], lati ọdọ mi ni ododo wọn ti wá.”—Isaiah 54:17.