ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 10/1 ojú ìwé 24-25
  • Títàn Bii Awọn Afúnni ní Ìmọ́lẹ̀ Ninu Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Títàn Bii Awọn Afúnni ní Ìmọ́lẹ̀ Ninu Ayé
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Ile-ẹkọ Aṣaaju-ọna níCentral African Republic
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 10/1 ojú ìwé 24-25

Títàn Bii Awọn Afúnni ní Ìmọ́lẹ̀ Ninu Ayé

NINU ayé kan ti o ti dibajẹ fun ìwà-wíwọ́ ati ìwà-àyídáyidà, awọn Kristian tootọ jakejado ilẹ̀-ayé nilati jẹ́ orisun imọlẹ. Wọn nilati jẹ́ afúnni ní ìmọ́lẹ̀ ninu ayé ṣiṣokunkun kan. (Filippi 2:15) Ẹgbẹẹgbẹrun ń muratan lati ṣe eyi gẹgẹ bi awọn aṣaaju-ọna, tabi awọn oniwaasu alakoko kikun. Iye pupọ ninu wọn ti lo ọpọlọpọ ọdun ninu iṣẹ-isin yii ti a si ti san èrè fun wọn nipa rírí oniruuru awọn eniyan ti wọn ń ṣe iyipada ninu igbesi-aye wọn lati di ojulowo ọmọ-ẹhin Jesu Kristi.—Matteu 28:19.

Lati fun awọn aṣaaju-ọna wọnyii niṣiiri lati maa baa niṣo ninu iṣẹ-isin mimọ yii ati lati sunwọn sii ninu òye ikọnilẹkọọ wọn, Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti ṣeto Ile-ẹkọ Iṣẹ-isin Aṣaaju-ọna. Ó jẹ́ idanilẹkọọ ọlọjọ mẹwaa ti a gbekari Bibeli ti a wéwèé lati fi ran awọn aṣaaju-ọna lọwọ ni awọn apá ìhà mẹta: rinrin pẹlu Jehofa gẹgẹ bi ọmọlẹhin Jesu Kristi; pipọ ninu ifẹ fun ẹgbẹ́ awọn ará; títàn bii awọn afúnni ní ìmọ́lẹ̀ ninu ayé.

Ile-ẹkọ Aṣaaju-ọna níCentral African Republic

Ni Bangui, olu-ilu Central African Republic, awọn akẹkọọ 48 ati awọn oludanilẹkọọ 2 wá papọ ni August 1991. Awọn akẹkọọ naa wá lati gba awọn itọni ati imọran gbigbeṣẹ fun iṣẹ wọn. Kí ni o munilayọ tobẹẹ nipa kilaasi Bangui?

Fun ohun kan, 21 lara awọn akẹkọọ naa ṣì jẹ́ awọn ti ń lọ si ile-ẹkọ ayé sibẹ. Nigba ti wọn wà ni ile-ẹkọ, wọn wá ààyè fun iṣẹ-isin aṣaaju-ọna deedee. Wọn ń lo awọn oṣu isinmi wọn, awọn ipari ọsẹ ti ọwọ́ dilẹ, ati awọn irọlẹ lati waasu ati lati kọ́ni.

Awọn ọ̀dọ́ wọnyii ti rí ijẹpataki ṣiṣiṣẹsin Ẹlẹdaa wọn nisinsinyi. (Oniwasu 12:1; fiwe 1 Korinti 7:29.) Ohun agbafiyesi kan ni pe 12 ninu wọn ní awọn obi alaigbagbọ. Ni ile awọn nikan ni o wà ninu otitọ. Awọn ọdọmọkunrin meji, tẹgbọntaburo, ni baba wọn fi ipa lé kuro ni ile nitori igbagbọ wọn. Tọkọtaya ọ̀dọ̀ kan ninu ijọ naa gba awọn ọdọmọkunrin mejeeji yii laaye lati gbé pẹlu wọn.

Ọ̀ràn ti Michée ati Sulamithe Kaleb yatọ. Awọn mejeeji jẹ́ aṣaaju-ọna ti wọn si tun ń lọ si ile-ẹkọ, ṣugbọn awọn obi wọn jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jehofa. Niti tootọ, baba wọn jẹ́ akẹkọọ kan ninu kilaasi kan-naa!

Awọn ijọ ni Bangui ṣalabapin ninu ile-ẹkọ naa pẹlu, kìkì ni ọ̀nà kan ti o yatọ. Wọn pese awọn ohun koṣeemani ti ara, iru bii ounjẹ. Owó, adìyẹ, ṣuga, irẹsi, ati gbágùúdá ni a fi tọrọ lati bọ́ awọn akẹkọọ naa.

Awọn àwùjọ asoúnjẹ ni awọn ijọ ti wọn wà nitosi ṣeto lati se awọn ounjẹ rirọrun ṣugbọn ti wọn jẹ́ aladun. Central African Republic ni a mọ daradara fun ngunza, ounjẹ kan ti gbogbo eniyan kúndùn. Awọn eroja rẹ̀ ń kọ? Ewé gbágùúdá, epo pupa, alubọsa, ọpọ aàyú, ọpọlọpọ òroro ẹ̀pà, ati suuru lati jẹ́ ki o jinna daradara. Awujọ kọọkan ní ọ̀nà akanṣe tirẹ̀ fun sísè é. Ó jẹ́ aṣeyọri ńláǹlà; kò sí ẹni ti kò lè ṣàìjẹ ẹ́.

Lẹhin ode Bangui kilaasi meji miiran ni a ṣe, ọ̀kan ni Bouar ati ọ̀kan ni Bambari, ni mímú iye awọn akẹkọọ naa jẹ́ 68. Laaarin ọdun meji ti o ti kọja, Central African Republic ti rí idagbasoke ninu iye awọn aṣaaju-ọna. Ni January 1992 awọn aṣaaju-ọna deedee 149 ati awọn aṣaaju-ọna akanṣe 17 pẹlu awọn aṣaaju-ọna oluranlọwọ 78 ni wọn wà. Eyi ti yọrisi igbokegbodo pupọ sii ni gbogbo orilẹ-ede naa pẹlu gongo titun ninu iye awọn akede, wakati, ipadabẹwo, ati awọn ikẹkọọ Bibeli. Nigba ti ọpọ awọn oṣiṣẹ bá ti wà, ikore naa yoo pọ̀ sii.—Isaiah 60:21, 22; Matteu 9:37, 38.

Ọpẹ́ wa lọ sọdọ Jehofa Ọlọrun fun awọn ipese wọnyi ati si eto-ajọ rẹ̀ ori ilẹ̀-ayé fun ṣiṣeto awọn kilaasi wọnyi. Wọn ran awọn akẹkọọ ati awọn oludanilẹkọọ lọwọ bakan-naa lati tàn bii afúnni ní ìmọ́lẹ̀ ninu ayé ṣiṣokunkun yii.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Awọn akẹkọọ 21 ti Ile-ẹkọ Aṣaaju-ọna ti wọn ṣì wà ni ilẹ-ẹkọ giga

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Awọn ọdọmọkunrin meji wọnyi nilati fi ile silẹ nitori otitọ

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́