ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 11/15 ojú ìwé 24-25
  • Fífòye Yéni ni Namibia

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Fífòye Yéni ni Namibia
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Dide Góńgó Aṣeyọri Giga Kan
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 11/15 ojú ìwé 24-25

Fífòye Yéni ni Namibia

NÍ ÈDÈ meloo ni iwọ ti gbọ gbólóhùn-ọ̀rọ̀ naa “Kò yé mi”? “Hi nokuzuva,” ni obinrin ọmọ Herero naa, ninu aṣọ ibilẹ rẹ̀ gígùn ati gèlè ti o rí ṣóńṣó bí ìwo sọ. “Nghi udite ko,” ni ọmọbinrin ọmọ Kwanyama naa dahunpada, pẹlu ẹ̀rín músẹ́. “Kandi uvite ko,” ni ọmọ ìletò Ndonga naa fèsì, ni gígún èjìká rẹ̀. “Kapi na kuzuvha,” ni darandaran ọmọ Kwangali kan ṣalaye.

Gbogbo awọn wọnyi lẹnikọọkan ń sọ pe, “Kò yé mi.” Ẹ wo bi eyi ti ṣapejuwe rẹ̀ tó pe awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni Namibia dojukọ iṣoro ńláǹlà nipa èdè nigba ti wọn ba ń gbiyanju lati de ọ̀dọ̀ awọn 1,370,000 olugbe ninu agbegbe ipinlẹ gbigbooro yii ti o tó nǹkan bii 318,000 ibùsọ̀ níbùú-lóòró!

Abájọ! Kìí ṣe kiki awọn ọmọ Herero ati Nama nikan ṣugbọn awọn ọmọ Ovambo, Kavango, Tswana, Caprivian, Himba, Bushman, ati awọn ọmọ Damara ti Namibia pẹlu ni wọn ní awọn èdè tiwọn pẹlu. Ni iyatọ ifiwera, kìkìdá awọn iwe lori Bibeli ni èdè Gẹẹsi ati Afrikaans ni awọn Ẹlẹ́rìí ní lọwọ. Ó ṣe kedere pe, ki pupọ eniyan sii to le loye otitọ, iṣẹ ṣiṣe itumọ iwe lati èdè kan si ìkejì ṣekoko. Eyi bẹrẹ lọna kan ti o kere gan-an ni ọpọ ọdun sẹhin ni Windhoek, olu-ilu ohun ti a mọ̀ nigba naa si South-West Africa.

“Ni Windhoek, atako lilekoko dojukọ iṣẹ wa lati ọ̀dọ̀ ṣọọsi ati awọn ọlọpaa,” ni Dick Waldron ranti. Papọ pẹlu aya rẹ̀, Coralie, ó wá si orilẹ-ede yii ni 1953 gẹgẹ bi akẹkọọyege ti Watchtower Bible School of Gilead. “A kò fi ààyè gbà wá lati kọja si agbegbe ti awọn aláwọ̀ dudu ń gbe, a sì maa ń halẹ mọ wa nigba ti a ba ń bá awọn aláwọ̀ dudu sọrọ. Nigba ti o yá a rí ibikan ti a ti fi wa silẹ jẹ́jẹ́—isalẹ odò gbígbẹ ti Odò Gammans! Eyi wà ni kete lẹhin ilu. Ni fifarasin sabẹ igbo igi acacia, a ṣe awọn ikẹkọọ Bibeli.”

Nibẹ pẹlu ni a ti kọkọ tumọ awọn itẹjade Watch Tower si awọn èdè adugbo. Wọn ni ninu awọn ìwé-àṣàrò-kúkúrú diẹ ni èdè Kwanyama ati iwe pẹlẹbẹ naa “Ihinrere Ijọba Yi” ni èdè Nama. Arakunrin Waldron ranti iriri alarinrin kan ni isopọ pẹlu iwe pẹlẹbẹ yii, ti olufifẹhan kan ń bá wọn ṣe itumọ rẹ̀. Wọn kò rí ọ̀rọ̀ èdè Nama ti o ṣe deedee pẹlu gbólóhùn-ọ̀rọ̀ naa, “Adamu jẹ ọkunrin pipe kan.” Nitori naa ọkunrin olufifẹhan naa sọ pe: “Sáà ti kọ ọ́ pe Adamu rí bíi eso peach ti o ti pọ́n. Awọn ara Nama yoo loye rẹ̀ pe oun jẹ ẹni pipe.” Eyi, nigba naa, ni bi a ṣe bẹrẹsii fi oye Iwe Mimọ yé ọpọlọpọ laaarin awọn ọmọ ìbílẹ̀ Namibia.—Fiwe Danieli 11:33.

Dide Góńgó Aṣeyọri Giga Kan

A dé góńgó aṣeyọri giga kan ni ibẹrẹ awọn ọdun 1970 nigba ti a tumọ iwe naa Otitọ ti Nsinni Lọ si Iye Aiyeraiye si èdè Ndonga ati Kwanyama. Iwọnyi ni awọn èdè pataki meji ti awọn ọmọ Namibia ti wọn kún Ovamboland fọ́fọ́ ń sọ, ni nǹkan bi ibusọ 450 si ìhà ariwa Windhoek. Ilé aṣaaju-ọna kan ni a dá silẹ lẹhin naa ni Ondangwa, àdádó kan ni Ovamboland. Lati ran awọn olufifẹhan ni agbegbe yii lọwọ lati janfaani lati inu ijiroro Bibeli ọsọọsẹ ti a gbekari Ilé-ìṣọ́nà, awọn aṣaaju-ọna akanṣe ti wọn ń ṣiṣẹsin ni Ovamboland ni a yan iṣẹ fun lati tumọ akopọ ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ fun ikẹkọọ ni èdè Gẹẹsi si èdè Ndonga ati Kwanyama.

“Ọ́fíìsì” fun ṣiṣe itumọ iwe naa jẹ́ ibi igun kan ti a fi ikele ké sọtọ kuro lara iyara ìgbọ́kọ̀sí kan nibi ti a ti ń mu awọn ẹ̀dà Ilé-Ìṣọ́nà ti a ti tumọ jade lori ògbólógbòó ẹ̀rọ ti a fi ń ṣe ẹ̀dà iwe. Kò rọrun lati pọkanpọ sori iṣẹ ti ń munilómi yii, niti pe ipo nǹkan kò bá ti ode-oni mu ti idiwọn itutu oju ọjọ nigba otutu si jẹ laaarin iwọn 100 si 110 lori iwọn Fahrenheit. Bi o tilẹ ri bẹẹ, nihin-in yii ni a ti tumọ awọn iwe pẹlẹbẹ titun ati iwe naa Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye.

Bi a ti ń da awọn ijọ silẹ ni Ovamboland ati awọn ibomiran ni Namibia, idahunpada naa jẹ iru eyi ti a fi nilo awọn ile ti o tubọ tobi ti o si dara sii. Ni afikun, ibi kan ti o tubọ bọ́ si aarin-gbungbun sii ni a ń fẹ ti a o fi le bojuto awọn aini ni awọn agbegbe yooku ni orilẹ-ede naa. Laaarin ìgbà yii, iwa ẹ̀tanú lodisi iṣẹ iwaasu Ijọba ti lọsilẹ. Nitori naa iyọnda ni a gbà lati bẹrẹsii kọle sori ilẹ ńla kan ti ọ̀kan lara awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni Windhoek fi ṣe itọrẹ. Laipẹ, eyi ti o ju 40 awọn oṣiṣẹ oluyọnda ara-ẹni ni a wá ibugbe fun lori ilẹ̀ ikọle naa, ati ni December 1990 a pari awọn ọ́fíìsì fun ṣiṣe itumọ iwe naa.

Nisinsinyi, ninu awọn ọ́fíìsì ati iyàrá ti wọn tunilara ninu ile ìgbàlódé yii, iṣẹ fifi òye yé ọpọlọpọ ń baa lọ láìsọsẹ̀. Iwe titun ni a ń tumọ leralera si èdè Herero ati Kwangali. Niti èdè Ndonga ati Kwanyama, itẹjade ẹlẹẹkan loṣu ti ẹda-itumọ Ilé-ìṣọ́nà ní àpapọ̀-èdè meji ni o ti ń jade ni aláwọ̀ meremere nisinsinyi. Ó ni gbogbo awọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ fun ikẹkọọ ati awọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ yooku ninu. Eyi, niti tootọ, jìnnà gidigidi si ti ibẹrẹ kekere naa ni ìsàlẹ̀ odò gbígbẹ ni ọpọ ọdun sẹhin.

“Kò yé mi” ni a kìí sábà gbọ́ mọ́. Kakabẹẹ, eyi ti o ju 600 awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni Namibia kun fun ọpẹ́ lọpọlọpọ si Baba wọn ọrun, ti wọn si le sọ nisinsinyi pe: “Ìfihàn ọ̀rọ̀ rẹ funni ni imọlẹ; o si fi òye fun awọn òpè.”—Orin Dafidi 119:130.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Pipokiki ihinrere naa laaarin awọn ọmọ Herero

Titumọ awọn itẹjade Kristian fun anfaani awọn ọmọ Namibia

Awọn ọ́fíìsì ti a ti ń ṣe itumọ iwe ni Namibia

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́