ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 11/15 ojú ìwé 31
  • Ìrísí Lè Tannijẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìrísí Lè Tannijẹ
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 11/15 ojú ìwé 31

Ìrísí Lè Tannijẹ

“KÒ SÍ ìrísí ti o ṣee gbẹkẹle,” ni òṣèré ori ìtàgé ara Ireland naa Richard Sheridan sọ. Eyi jẹ otitọ nipa awọn igi ati awọn eniyan pẹlu.

Ni ọjọ kan ni iha opin oṣu March ni ọdun 33 C.E., Jesu Kristi ri igi ọpọtọ kan bi oun ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ti ń rìn lọ lati Betani si Jerusalemu. Ewe igi naa ti bò daradara, ṣugbọn ayẹwo fínnífínní fihàn pe kò ni eso eyikeyii. Nitori naa Jesu sọ fun un pe: “Ki ẹnikẹni ma jẹ eso lori rẹ mọ́ titi lae.”—Marku 11:12-14.

Eeṣe ti Jesu fifi igi naa bú niwọn bi, gẹgẹ bi Marku ti ṣalaye “akoko eso ọpọtọ kò tii tó”? (Marku 11:13) O dara, nigba ti igi ọpọtọ kan bá ti ruwe, o sábà maa ń so eso ọpọtọ àkọ́so. Kìí sábà ṣẹlẹ pe ki igi ọpọtọ kan léwé ni akoko yẹn ninu ọdun. Ṣugbọn niwọn bi o ti léwé, Jesu fi ẹ̀tọ́ reti lati ri eso ọpọtọ lori rẹ̀. (Wo aworan ti o wà loke.) Otitọ naa pe igi naa ni kìkì ewe fihàn pe kò ni méso wá. Ìrísí rẹ̀ tannijẹ. Niwọn bi a ti maa ń sanwó orí fun awọn igi eleso, igi alaileso kan jẹ ẹrù-ìnira niti iṣuna-owo ti o sì yẹ fun gige lulẹ̀.

Jesu lo igi alaileso yẹn lati ṣapejuwe ẹ̀kọ́ pataki kan nipa igbagbọ. Ni ọjọ ti o tẹle e, o ya awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lẹnu lati rii pe igi naa ti rọ. Jesu ṣalaye pe: “Ẹ ni igbagbọ si Ọlọrun. . . . Ohunkohun ti ẹyin ba tọrọ nigba ti ẹ ba ń gbadura, ẹ gbagbọ pe ẹ ti rí wọn gbà ná, yoo si ri bẹẹ fun yin.” (Marku 11:22-24) Ni afikun si ṣiṣapejuwe idi fun gbigbadura ninu igbagbọ, igi ọpọtọ ti o rọ naa fihàn lọna aṣeefojuri kedere ohun ti yoo ṣẹlẹ si orilẹ-ede kan ti kò ni igbagbọ.

Ni oṣù diẹ ṣaaju ìgbà naa Jesu ti fi orilẹ-ede awọn Ju we igi ọpọtọ kan ti o ti jẹ alaileso fun ọdun mẹta ti a o si gé e lulẹ bi o bá ń baa lọ lati jẹ alaileso. (Luku 13:6-9) Nipa fifi igi ọpọtọ naa bú ní ọjọ mẹrin pere ṣaaju ìgbà iku rẹ̀, Jesu fihàn bi orilẹ-ede awọn Ju ko ti ṣe mu eso ti o yẹ si ironupiwada jade ati nipa bẹẹ wọn wà ni ìlà fun iparun. Bi o tilẹ jẹ pe orilẹ-ede yẹn—bii igi ọpọtọ naa—farahan lode ara bii eyi ti ara rẹ̀ dá ṣáṣá, akiyesi kínníkínní fihàn pe wọn kò ni igbagbọ eyi ti o yọrisi kíkọ̀ ti wọn kọ Messia naa.—Luku 3:8, 9.

Ninu Iwaasu rẹ̀ lori Oke, Jesu kilọ lodisi “awọn èké wolii” ti o si wi pe: “Eso wọn ni ẹyin o fi mọ̀ wọn. Eniyan a maa ka eso ajara lori ẹ̀gún ọ̀gàn, tabi eso ọpọtọ lara ẹ̀wọ̀n? Gẹgẹ bẹẹ gbogbo igi rere nii so eso rere; ṣugbọn igi buburu nii so eso buburu. Igi rere kò le so eso buburu, bẹẹ ni igi buburu kò si le so eso rere. Gbogbo igi ti ko ba so eso rere, a ke e lulẹ̀, a sì wọ́ ọ sọ sinu iná. Nitori naa nipa eso wọn ni ẹyin o fi mọ̀ wọn.” (Matteu 7:15-20) Awọn ọ̀rọ̀ Jesu wọnyi ati akọsilẹ iṣẹlẹ ti igi ọpọtọ ti a fi bú naa fihàn kedere pe a nilati wà lojufo nipa tẹmi, nitori ìrísí ti isin le tannijẹ pẹlu.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́