Eyi Kò Ṣeeṣe!
“ÓRỌRÙN fun ibakasiẹ lati wọ oju abẹ́rẹ́, ju fun ọlọ́rọ̀ lati wọ ijọba Ọlọrun lọ.” (Matteu 19:24) Jesu Kristi sọ eyi lati kọ́ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lẹkọọ kan. Ọdọmọkunrin ọlọ́rọ̀ kan ti o jẹ́ oluṣakoso ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ ikesini kan lati wá di ọmọlẹhin Jesu ki o si ṣajọpin lara ọpọlọpọ awọn anfaani agbayanu nipa tẹmi silẹ ni. Ọkunrin naa yàn lati rọ̀ mọ́ awọn ọrọ̀ rẹ̀ ti o pọ̀ ju ki o tẹle Messia naa.
Kìí ṣe pe Jesu ń sọ wi pe o jẹ ohun ti kò ṣeeṣe patapata fun ọlọ́rọ̀ kan lati jere ìyè ainipẹkun ninu iṣeto ti Ijọba naa, nitori pe awọn kan ti wọn jẹ ọlọ́là di ọmọlẹhin rẹ̀. (Matteu 27:57; Luku 19:2, 9) Bi o ti wu ki o ri, eyi kò ṣeeṣe fun ọlọ́rọ̀ eyikeyii kan ti o ni ifẹ giga fun awọn ọrọ̀ rẹ̀ ju fun awọn ohun tẹmi lọ. Kiki nipa jíjẹ́ ki awọn aini rẹ̀ nipa tẹmi jẹ ẹ́ lọ́kàn ati wiwa iranlọwọ atọrunwa ni iru ẹni bẹẹ fi le gba igbala ti Ọlọrun fifunni.—Matteu 5:3; 19:16-26.
Apejuwe ibakasiẹ ati oju abẹ́rẹ́ kìí ṣe eyi ti a o gbà bi iṣẹlẹ gidi. Jesu ń lo àkàwé àsọdùn lati fi tẹnumọ iṣoro ti o dojukọ awọn ọlọ́là eniyan ti ń gbiyanju lati tẹ́ Ọlọrun lọ́rùn nigba ti wọn ń gbiyanju lẹsẹkan naa lati maa bá ọ̀nà ìgbé igbesi-aye ọlọ́rọ̀, onifẹẹ ọrọ̀-alumọọni kan niṣoo. —1 Timoteu 6:17-19.
Awọn kan sọ pe oju abẹ́rẹ́ naa ni ẹnu ibode kekere kan lara ogiri ilu-nla kan inu eyi ti ibakasiẹ kan lè gbà kọja pẹlu ìnira bi a bá sọ ẹrù rẹ̀ kalẹ. Ṣugbọn ọ̀rọ̀ Griki naa rha·phisʹ, ti a tumọ si “abẹ́rẹ́” ni Matteu 19:24 ati Marku 10:25, wá lati inu ọ̀rọ̀-ìṣe kan ti o tumọ si “rán.” Ni Luku 18:25 èdè-ọ̀rọ̀ naa be·loʹne tọkasi abẹ́rẹ́ ìránṣọ kan, ati nibẹ yẹn New World Translation kà pe: “Ó rọrun, niti tootọ, fun ibakasiẹ lati gba ojú abẹ́rẹ́ ìránṣọ kọja jù fun ọkunrin ọlọ́rọ̀ kan lati wọ inu ijọba Ọlọrun.” Oniruuru awọn ọla-aṣẹ ti ọ̀nà ìgbà lo ọ̀rọ̀ yii lẹhin. W. E. Vine sọ pe: “Ero ti siso ‘ojú abẹ́rẹ́’ pọ̀ mọ́ awọn ibode keekeeke dabi eyi ti o jẹ ti ode-oni; a kò rí ẹ̀rí pe o wà ni atijọ.”—An Expository Dictionary of New Testament Words.
Ibakasiẹ ńlá kan ti ń gbiyanju lati gba ojú abẹ́rẹ́ ìránṣọ bíńtín kan “fi animọ ti àsọdùn awọn ará Ila-oorun hàn,” ni iwe ìwádìí kan sọ. Ati nipa ti awọn kan ti wọn lọ́gbọ́n tobẹẹ gẹẹ ti o fi dabi pe wọn ṣe ohun ti ko ṣeeṣe, iwe The Babylonian Talmud sọ pe: “Wọn fa erin kan gba ojú abẹ́rẹ́ kan.” Jesu lo iru àsọdùn ati iyatọ ifiwera ṣiṣekedere kan-naa lati fi tẹnumọ aileṣeeṣe. Kò ṣeeṣe fun ibakasiẹ kan, tabi erin kan, lati gba ojú abẹ́rẹ́ ìránsọ. Bi o ti wu ki o ri, pẹlu iranlọwọ atọrunwa, ọkunrin ọlọ́rọ̀ kan le pa oju-iwoye onifẹẹ ọrọ-alumọọni rẹ̀ tì ki o si fi tootọtootọ wá ìyè ayeraye. Bẹẹ pẹlu ni gbogbo awọn ti wọn bá ni ifẹ atọkanwa lati kẹkọọ ati lati ṣe ifẹ-inu Ọlọrun Ọga-ogo Julọ naa, Jehofa.