Dídé Ọ̀dọ̀ “Gbogbo Eniyan” ní Belgium
APOSTELI Paulu rán awọn Kristian ẹni-ami-ororo ẹlẹgbẹ rẹ̀ leti nipa ifẹ-inu Ọlọrun pe “ki gbogbo eniyan ní igbala ki wọn si wá sinu ìmọ̀ otitọ.” Fun idi yii wọn nilati gbadura pe ki a fun wọn ní ‘igbesi-aye idakẹjẹẹ ati ti pẹlẹ’ ki wọn baa lè polongo ihinrere Ijọba naa fun gbogbo eniyan ti wọn ní etí ìgbọ́.—1 Timoteu 2:1-4.
Lonii, mímú ihinrere naa tọ “gbogbo eniyan” lọ ní akanṣe itumọ fun awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Belgium. Lati ipari Ogun Àgbáyé II, orilẹ-ede kekere yii, eyi ti o lè kun inu ààyè-ilẹ̀ Adagun Tanganyika tabi idaji Adagun Michigan lọna ti o ṣe rẹ́gí, ti la awọn iyipada ṣiṣara-ọtọ kọja ninu igbekalẹ rẹ̀ niti ẹya-ede ati àṣà-ìṣẹ̀dálẹ̀. Ni afikun si awọn ẹgbẹ́ awujọ atayebaye mẹta rẹ̀—ti awọn Fleming (Dutch), Faranse, ati German—nisinsinyi oniruuru awujọ èdè ati àṣà-ìṣẹ̀dálẹ̀ ni ń bẹ ní Belgium. Awọn eniyan ilẹ̀ Arab, Turkey, India, China, Philippine, Africa, ati America wà, ki a wulẹ mẹnukan diẹ. A fojudiwọn rẹ̀ pe 1 ninu 10 awọn eniyan ní Belgium jẹ ẹni ti o ti ilẹ̀-òkèèrè wá.
Nipa bayii, awọn Ẹlẹ́rìí ní Belgium, gẹgẹ bii awọn Kristian ẹlẹgbẹ wọn kárí-ayé, ni ipenija mímú ihinrere naa dé ọ̀dọ̀ “gbogbo eniyan” dojukọ. Bawo ni o ṣe ri lati waasu laaarin iru oriṣiriṣi awọn eniyan orilẹ-ede kan bẹẹ? Bawo ni ẹnikan yoo ṣe ba ẹni ti o ní àṣà-ìṣẹ̀dálẹ̀ ati ipilẹ isin kan ti o yatọ patapata sọrọ? Ki sì ni idahunpada wọn si ihin-iṣẹ Bibeli?
Idanuṣe Mu Awọn Iyọrisi Wá
Biba “gbogbo eniyan” sọrọ nipa ihinrere Ijọba naa jẹ iriri alayọ ati arunilọkansoke kan. Ni awọn opopona ti o kún fun igbokegbodo, ni awọn ibi ọjà, ninu ohun irinna gbogbo eniyan, lati ilé de ilé, awọn eniyan lati inu gbogbo kọntinẹnti ni a lè rí. Pẹlu idanuṣe diẹ, akede Ijọba kan lè fi tirọruntirọrun bẹrẹ ijumọsọrọpọ kan, lọpọ ìgbà eyi sì ń jalẹ si awọn iyọrisi atẹ́nilọ́rùn.
Ni ibùdókọ̀ bọọsi kan, Ẹlẹ́rìí kan wulẹ fi ẹ̀rín-músẹ́ ọlọyaya bẹrẹ ijumọsọrọpọ pẹlu iyaafin ọmọ ilẹ Africa kan. Iyaafin naa laipẹ fi idunnu rẹ̀ hàn nigba ti o gbọ́ nipa Ijọba Ọlọrun, ti o si fẹ́ lati mọ̀ sii nipa Bibeli. O gba awọn iwe-irohin Ilé-Ìṣọ́nà ati Ji! o si fun Ẹlẹ́rìí naa ní adirẹsi rẹ̀. Nigba ti o sọ pe oun yoo ṣebẹwọ sọdọ rẹ̀ laipẹ, iyaafin naa kọ̀. “Rara! Rara! Jẹ ki a ṣe adehun pato kan ki n baa lè wà nílé nigba ti o ba wá.”
Ni ọjọ mẹta lẹhin naa, nigba ti Ẹlẹ́rìí naa yoo ṣe ikesini, o ri pe oun ti sọ adirẹsi iyaafin naa nù. Ṣugbọn ní riranti orukọ opopona naa, o lọ́ ó sì beere ní gbogbo ile lati rii bi oun ba lè rí orukọ ọmọ ilẹ̀ Africa kan. O dé opin adugbo naa lairi ohun ti o ń wá. Ẹ wo iru ijakulẹ nla kan ti eyi jẹ́! Bi o ti ń muratan lati lọ, lojiji, bi ẹni pe o ṣẹ́yọ, lori iduro niwaju rẹ̀ gan-an ní iyaafin naa ti o ń wá wà, o sì jẹ́ akoko naa gan-an ti wọn ti fohunṣọkan lé lori fun ibẹwo naa! Ikẹkọọ Bibeli inu ilé kan ni a bẹrẹ.
Ki ni nipa ti oriṣiriṣi awọn àṣà-ìṣẹ̀dálẹ̀, igbagbọ, ati àṣà-àtọwọ́dọ́wọ́? Fun apẹẹrẹ, ki ni nipa igbagbọ awọn onisin Hindu? O dara, aṣaaju-ọna kan ranti ohun ti o ti kà ninu iwe naa Reasoning From the Scriptures. O sọ pe: “Dipo gbigbiyanju lati jiroro ìlọ́júpọ̀ ọgbọn-imọ-ọran isin Hindu, gbé awọn otitọ ti ń tẹnilọrun ti a ri ninu Iwe Mimọ kalẹ. . . . Awọn otitọ ṣiṣe kedere ninu Ọ̀rọ̀ rẹ̀ yoo de inu ọkan-aya awọn wọnni ti ebi ń pa ti oungbẹ si ń gbẹ fun ododo.”
Iyẹn gan-an ni ohun ti aṣaaju-ọna naa ṣe nigba ti o pade Kashi, obinrin kan lati India ti o tẹwọgba ikẹkọọ Bibeli kan. Kashi tẹsiwaju laisọsẹ, laipẹ o ti ń ba gbogbo awọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọrọ nipa ohun ti o ń kẹkọọ. Ni ọjọ kan aṣaaju-ọna naa pade aya aṣoju ijọba nílẹ̀ òkèèrè kan, ẹni ti o beere pe: “Iwọ ha ni ẹni naa ti o kọ́ Kashi ní Bibeli bi?” Bawo ni ẹnu ti ya aṣaaju-ọna naa tó nigba ti iyaafin naa wi pe: “Ẹ wo iru olukọ kan ti oun jẹ́! O ti ṣeeṣe fun un lati yi mi lọkan pada lori ọpọlọpọ awọn kókó. Rò ó wò na, oun, ti o jẹ́ onisin Hindu, ń kọ́ emi ti mo jẹ́ onisin Katoliki, ní Bibeli!”
Nigba ti iwọ bá bá awọn ọmọ ilẹ̀ Philippine pade, lẹsẹkẹsẹ iwọ yoo mọ̀ pe eyi ti o pọ julọ ninu wọn fẹran Bibeli. Wọn jẹ́ ọlọyaya ati onifẹẹ àlejò-ṣíṣe, ti o si rọrun gidigidi lati bẹrẹ ijumọsọrọpọ pẹlu wọn. Iyaafin ọmọ ilẹ̀ Philippine kan yara muratan lati gba awọn iwe-irohin meji, ṣugbọn bi oun ti jẹ Katoliki kan, o kó wọn danu. Ni awọn ọsẹ melookan lẹhin naa oun tún gba iwe-irohin meji, eyi ti o fi silẹ sinu àpò ìfàlọ́wọ́ rẹ̀. Ni òru ọjọ kan o ní ifẹ-ọkan naa lati kàwé. Lẹhin wiwa ayika kiri fun ohun kan ti o fa ọkan-ifẹ mọra, o ri awọn iwe-irohin naa. Pẹlu ìlọ́tìkọ̀, o bẹrẹ sii kà á, ti ọkan-ifẹ rẹ̀ si pọ sii. Kete lẹhin naa, Ẹlẹ́rìí kan ṣe ikesini si ilé rẹ̀, iyaafin naa sì beere ọpọ ibeere. Eyi ni ìgbà akọkọ ti oun yoo figbakanri fi awọn ẹkọ-igbagbọ Katoliki rẹ wera pẹlu ohun ti Bibeli sọ. Igbekalẹ lilọgbọn-ninu, ti o si ba Iwe Mimọ mu naa mu ki o dá a loju pe oun nigbẹhin-gbẹhin ti ri otitọ.
“Fún Ounjẹ Rẹ”
Ọpọ ninu awọn olugbe lati ilẹ̀-òkèèrè wà ní Belgium fun awọn idi ti ó jẹmọ́ iṣẹ́-òwò tabi lati ṣiṣẹ ní ọ̀kan ninu awọn 150 ọfiisi aṣoju ijọba nílẹ̀ òkèèrè tabi ní Ajọ Ẹgbẹ́ ti Europe. Eyi ti o pọ julọ ninu wọn ń duro fun kiki ọdun diẹ. Jijẹẹrii fun ati kikẹkọọ Bibeli pẹlu wọn lè dabi alaileso lakọọkọ. Ṣugbọn Bibeli ran wa leti pe: “Fún ounjẹ rẹ si oju omi; nitori ti iwọ o ri i lẹhin ọjọ pupọ.” (Oniwasu 11:1) Lọpọ ìgbà awọn iyọrisi rẹ ma ń jẹ atẹ́nilọ́rùn lọna yiyanilẹnu.
Bi ọ̀ràn naa ti ri niyi pẹlu obinrin ọmọ ilẹ̀ America kan ti o ń gba awọn iwe-irohin deedee lati ọwọ́ Ẹlẹ́rìí kan. Bi akoko ti ń lọ Ẹlẹ́rìí naa tọkasi anfaani kikẹkọọ Bibeli deedee, o sì fi imuratan rẹ̀ hàn lati kẹkọọ pẹlu rẹ̀. Obinrin naa tẹwọgba ifilọni naa o sì tẹsiwaju lọna yiyarakankan. Laipẹ o ri iyatọ naa laaarin isin tootọ ati èké. Nitori naa ó mu gbogbo awọn ère isin kuro ninu ilé rẹ̀. Lẹhin naa ni akoko tó fun un lati pada si United States. Iyẹn ha tumọsi opin itẹsiwaju tẹmi rẹ̀ bi? Ronuwoye idunnu ati iyalẹnu Ẹlẹ́rìí naa nigba ti o gba ikesini lori tẹlifoonu lati ọ̀dọ̀ Ẹlẹ́rìí kan ni United States ti ń sọ fun un pe iyaafin naa ti ń ba ikẹkọọ rẹ̀ lọ, ó ti ya igbesi-aye rẹ̀ si mimọ fun Jehofa Ọlọrun, ti a si ti baptisi rẹ̀! Niti tootọ, o ti ń ṣiṣẹsin gẹgẹ bi ojiṣẹ aṣaaju-ọna oluranlọwọ ni bayii ná.
Ohun kan-naa ni o jẹ́ otitọ nipa Kashi, obinrin ọmọ ilẹ̀ India kan, ati iyaafin ọmọ ilẹ̀ Philippine ti a mẹnukan ní ibẹrẹ. Nigba ti Kashi pada si India, oun ati ọkọ rẹ bẹrẹ ikẹkọọ Bibeli wọn. Nigbẹhin-gbẹhin awọn mejeeji ya araawọn si mimọ fun Jehofa ti wọn si ṣajọpin ninu iṣẹ́ iwaasu naa. Niwọn bi wọn ti ń gbe ní agbegbe kan nibi ti kò ti sí awọn Ẹlẹ́rìí miiran, wọn yọọda ilé wọn fun Ikẹkọọ Iwe Ijọ. Kashi ṣiṣẹsin gẹgẹ bi aṣaaju-ọna oluranlọwọ kan dé ibi ti ilera rẹ̀ yọọda mọ, o si ti ń dari awọn ikẹkọọ Bibeli inu ilé mẹfa, ti o ní ninu aropọ awọn eniyan 31. Bakan naa, bi akoko ti ń lọ obinrin ọmọ ilẹ̀ Philippine naa ṣílọ si United States, o tẹsiwaju dori iyasimimọ ati baptism, o si di aṣaaju-ọna deedee. Iru awọn iyọrisi alayọ bẹẹ wà lara ọpọ awọn nǹkan ti awọn akede Ijọba ní Belgium ń gbadun bi wọn ti ń baa lọ lati waasu fun awọn eniyan ninu ipinlẹ wọn.
Ipenija Awọn Èdè
Ki a baa lè ṣaṣepari iṣẹ aigbọdọmaṣe ti wiwaasu fun “gbogbo eniyan,” ẹka ọfiisi ni lati ní iwe-ikẹkọọ Bibeli ni eyi ti o ju ọgọrun-un èdè lọ́wọ́. Awọn ijọ Belgium wà nisinsinyi ní èdè mẹwaa. Ninu awọn ijọ 341 ti o wà, 61 jẹ́ ní èdè ajeji, ati ninu 26,000 awọn akede Ijọba, 5,000 jẹ awọn ọmọ orilẹ-ede ajeji. Ijọ kan ní ninu awọn ọkunrin ati obinrin lati inu awọn orilẹ-ede 25 ti o yatọsira. Ronuwoye àwọ̀ ati oniruuru ninu awọn ipade wọn! Sibẹ ifẹ ati iṣọkan laaarin awọn arakunrin naa jẹ ẹ̀rí lilagbara kan nipa sisọni di ọmọ-ẹhin ti isin Kristian tootọ.—Johannu 13:34, 35.
Niwọn bi o ti jẹ́ pe ọpọlọpọ awọn olugbe ni o wà ní Belgium ti wọn nilati gbọ ihinrere naa ní awọn èdè ajeji, awọn akede melookan ti tẹwọgba ipenija ti kíkọ́ awọn èdè ṣiṣoro, iru bii Turkish, Arabic, ati Chinese. Isapa wọn ni a ti san èrè fun ní yanturu.
Awọn wọnni ti wọn ṣiṣẹ laaarin awọn eniyan Arab rii pe wọn lè sunnasi ifẹ-ọkan ninu Bibeli lọpọ ìgbà nipa titẹnumọ awọn iniyelori gbigbeṣẹ rẹ̀. Akede Ijọba kan ní ijiroro arufẹsoke pẹlu ọjọgbọn Arab kan, lẹhin naa fun ọdun mẹta lẹhin eyi kò ṣeeṣe fun un lati ri ọjọgbọn naa mọ́. Bi a kò ti tete mú un rẹwẹsi, akede naa pinnu lati fi iwe pélébé kan pẹlu awọn ibeere Bibeli melookan silẹ fun ọjọgbọn naa. Eyi ru ifẹ itọpinpin rẹ̀ soke tobẹẹ ti o fi muratan lati fi ọkàn rere ṣayẹwo Bibeli. Oun ní ohun ti ó ri yalẹnu tobẹẹ debi pe oun ati aya rẹ̀, ti awọn mejeeji jẹ́ Musulumi, ya awọn irọlẹ kan pato sọtọ lati ka Bibeli papọ.
Awọn wọnni ti wọn ń gbiyanju lati ran awọn eniyan ọmọ ilẹ̀ China lọ́wọ́ ninu awọn ilu-nla pataki naa ní awọn ohun idiwọ miiran lati bori ni afikun si idiwọ ti èdè. Eyi ti o pọ julọ ninu awọn ọmọ ilẹ̀ China kò ní igbagbọ ninu Ọlọrun gẹgẹ bi Ẹlẹ́dàá tabi ninu Bibeli gẹgẹ bi Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Sibẹ, wọn ń tọpinpin wọn sì fẹ́ lati mọ ohun ti gbogbo rẹ̀ jẹ́ gan-an. Wọn jẹ́ olufi titaratitara kàwé pẹlu. Kìí ṣe ohun ara-ọtọ fun wọn lati pari kika iwe-ikẹkọọ Bibeli eyikeyii ti a ba fi silẹ fun wọn, tabi koda pupọ ninu Bibeli, ni kiki ọjọ diẹ. Bi ọkan-aya wọn ba tọ́, awọn ni agbara Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ń sún.
Iyaafin ọmọ ilẹ̀ China kan ni o ṣoro fun gidigidi lati tẹwọgba ero-ọkan naa nipa Ẹlẹ́dàá kan. Ṣugbọn nigba ikẹkọọ keji, omijé wá si ojú rẹ̀ nigba ti o wi pe: “Nisinsinyi emi niti gidi gbagbọ ninu Jehofa Ọlọrun, nitori pe bi a bá kọ Bibeli fun sáà ti o ju 1,600 ọdun lati ọwọ́ awọn eniyan ti o ju 40 sibẹ ti wọn sì wà ní ibaramuṣọkan patapata pẹlu ẹṣin-ọrọ kan, nigba naa o nilati jẹ pe Jehofa Ọlọrun ń dari kikọ rẹ̀. Iyẹn lọgbọn-ninu gan-an ni!”
Iyaafin ọmọ ilẹ̀ China miiran ni Ẹlẹ́rìí kan bá sọrọ ninu bọọsi oju-irin “Ṣe Kristian ni ọ?” ni o beere lọwọ Ẹlẹ́rìí naa. O sọ lẹhin naa pe oun ni a jakulẹ gidigidi lati ri ọpọ itakora laaarin awọn wọnni ti wọn jẹwọ pe Kristian ni awọn. Ẹlẹ́rìí naa faramọ ohun ti o sọ ṣugbọn o ṣalaye pe Bibeli kò tako araarẹ. Kete lẹhin naa iyaafin naa nilati fi bọọsi oju-irin naa silẹ. O fun Ẹlẹ́rìí naa ni adirẹsi rẹ̀, nigba ti o sì ṣebẹwo sọdọ rẹ̀, iyaafin naa polongo pe: “Ka ni mo ti mọ̀ ni, emi ìbá ti wọ bọọsi oju-irin naa ní ọdun kan sẹhin!” Nigba ti a beere ohun ti o ní lọ́kàn, iyaafin naa ṣalaye pe: “Iyẹn ni ìgbà akọkọ ti mo wọ bọọsi oju-irin lọ si yunifasiti. Iwọ ha lè ronuwoye rẹ̀ bi? Mo fi ọdun kan ṣòfò!” Inu rẹ̀ dùn gan-an pe o ṣeeṣe lati kẹkọọ Bibeli àní fun kiki awọn oṣu diẹ ki o tó pada si China.
Awọn iriri bi iru iwọnyi ti kọ́ awọn Ẹlẹ́rìí ni Belgium ní ẹkọ arikọgbọn kan. “Ni kutukutu fún irugbin rẹ, ati ní aṣalẹ maṣe da ọwọ́ rẹ duro,” ni Bibeli wi, “nitori ti iwọ kò mọ eyi ti yoo ṣe rere, yala eyi tabi eyiini, tabi bi awọn mejeeji yoo dara bakan naa.” (Oniwasu 11:6) Awọn isapa ti a lò lati bori awọn ohun idiwọ ti èdè, àṣà-ìṣẹ̀dálẹ̀, ati àṣà-àtọwọ́dọ́wọ́ yẹ daradara fun awọn iyọrisi naa. Awọn idahunpada amọkanyagaga fẹ̀rí hàn, lékè gbogbo rẹ̀, pe Ọlọrun niti tootọ “kìí ṣe ojusaaju eniyan: Ṣugbọn ni gbogbo orilẹ-ede, ẹni ti o ba bẹru rẹ̀, ti o si ń ṣiṣẹ ododo, ẹni itẹwọgba ni lọdọ rẹ̀.”—Iṣe 10:34, 35.