ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 1/1 ojú ìwé 9-18
  • Yíyọ̀ Ninu Atobilọla Ẹlẹdaa Wa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Yíyọ̀ Ninu Atobilọla Ẹlẹdaa Wa
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ‘Ṣíṣe É Kánkán’
  • Bibojuto Igbooro Siwaju Sii
  • Billion kan Wakati!
  • Itolẹsẹẹsẹ Ilé-kíkọ́ Bíbùáyà Kan
  • Àwọn Ilé Tá À Ń Kọ́ Ń Bọlá fún Jèhófà
    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
  • Ìbísí Bíbùáyà Mú Kí Ìmúgbòòrò Ojú Ẹsẹ̀ Pọn Dandan
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 1/1 ojú ìwé 9-18

Yíyọ̀ Ninu Atobilọla Ẹlẹdaa Wa

“Jẹ ki Israeli ki ó yọ̀ si ẹni ti ó dá a; jẹ ki awọn ọmọ Sioni ki ó kún fun ayọ sí Ọba wọn.”—ORIN DAFIDI 149:2.

1. Laika igbe “ominira nigbẹhin-gbẹhin” si, ki ni ipo iran eniyan niti gidi?

AYÉ ode-oni ni “ipọnju” ń yọ lẹnu. Iyẹn     ni ọ̀rọ̀ ti Jesu lò ninu asọtẹlẹ rẹ̀ ti     ó niiṣe pẹlu “opin eto-igbekalẹ awọn nǹkan,” sanmani alájàálù ti ó bẹrẹ pẹlu ogun agbaye kìn-ín-ní ni 1914. (Matteu 24:3-8, NW) Ọpọ awọn oṣelu rí kìkì ìdágùdẹ̀ fun ọjọ-ọla. Laika igbe “ominira nigbẹhin-gbẹhin” ni iha Ila-oorun Europe si, ààrẹ orilẹ-ede kan ni apa ibẹ yẹn nigbakan ri ṣakopọ ipo naa nigba ti o sọ pe: “Àkúnya iye eniyan ati iyọrisi-iṣẹ ile-eweko, awọn ihò ninu ìbòrí ozone ati àrùn AIDS, fifi ìlò ohun ìjà alagbara atọmik halẹmọni ati ààlà ti ń gbooro sii lọna amunijigiri laaarin ariwa ọlọ́rọ̀ ati guusu abòṣì, ewu ìyàn, ìmújoro awọn ohun ti ń gbé iwalaaye ró, ati orisun awọn alumọọni inu planẹti, igbooro awujọ awọn eniyan ti o jẹ pe awọn ohun ti a ń gbé jade lori tẹlifiṣọn ti a ṣonigbọwọ fun ni ń pinnu èrò ati iṣarasihuwa wọn ati ihalẹmọni ogun ẹkun-ayika ti ń pọ̀ sii—gbogbo iwọnyi, papọ pẹlu ẹgbẹẹgbẹrun awọn kókó abajọ miiran, ṣoju fun ihalẹmọni gbogbogboo ti o dojukọ araye.” Kò sí agbara eniyan eyikeyii ti ó lè mu ihalẹmọni ajalu-ibi tí kò lẹ́rọ̀ yii kuro.—Jeremiah 10:23.

2. Ta ni ó ni ojutuu pipẹtiti si awọn iṣoro araye, igbesẹ wo ni oun sì ti gbé ná?

2 Bi o ti wu ki o ri, a lè layọ, pe Atobilọla Ẹlẹdaa wa ni ojutuu ti ó wà pẹtiti. Ninu asọtẹlẹ Jesu “opin eto-igbekalẹ awọn nǹkan” ni a sopọ mọ́ “wiwanihin-in” rẹ̀ alaiṣeefojuri. (Matteu 24:3, 37-39, NW) Lati ṣẹ̀dá “awọn ọrun titun,” naa Jehofa gbé Jesu ka ori ìtẹ̀ rẹ̀ gẹgẹ bi Messia Ọba, ẹ̀rí alasọtẹlẹ fihàn pe iṣẹlẹ ọlọ́rọ̀ ìtàn yii ṣẹlẹ ninu awọn ọrun ni ọdun 1914.a (2 Peteru 3:13) Gẹgẹ bi alabaaṣakoso pẹlu Jehofa Oluwa Ọba-alaṣẹ Agbaye, Jesu ni a yàn nisinsinyi lati ṣedajọ awọn orilẹ-ede ati lati ya awọn eniyan ọlọkantutu, ẹni-bi-agutan lori ilẹ̀-ayé kuro lara awọn ẹni-bi-ewurẹ olórí kunkun. “Awọn ewurẹ” alaiwa-bi-Ọlọrun ni a sami sí fun “ikekuro ainipẹkun” ati “awọn agutan” fun ìyè ayeraye ninu ilẹ-ọba ori ilẹ̀-ayé ti Ijọba naa.—Matteu 25:31-34, 46, NW.

3. Idi wo ni awọn Kristian tootọ ni fun yíyọ̀?

3 Aṣẹku Israeli tẹmi lori ilẹ̀-ayé, tí awọn ogunlọgọ nla ti awọn agutan onigbọran wọnyi ti darapọ mọ́ nisinsinyi, ní gbogbo idi lati maa layọ ninu Jehofa, Ọba ayeraye, bi oun ti ń mú awọn ète rẹ̀ titobilọla wá si ipari nipasẹ Ijọba Ọmọkunrin rẹ̀. Wọn lè sọ pe: “Emi o yọ̀ gidigidi ninu Oluwa, ọkàn mi yoo yọ̀ ninu Ọlọrun mi; nitori ó ti fi agbádá wọ̀ mi . . . Gẹgẹ bi ilẹ ti i mu èéhù rẹ̀ jade, ati bi ọgbà ti i mú ohun ti a gbìn sinu rẹ̀ hù soke; bẹẹ ni Oluwa Jehofa yoo mú ododo ati iyin hù soke niwaju gbogbo orilẹ-ede.” (Isaiah 61:10, 11) ‘Híhù soke’ yii ni a rí daju ninu araadọta-ọkẹ ti a ń kójọ nisinsinyi lati inu awọn orilẹ-ede wá lati kọrin iyin Jehofa.

‘Ṣíṣe É Kánkán’

4, 5. (a) Bawo ni a ṣe sọ asọtẹlẹ ìkórèwọlé awọn eniyan Ọlọrun? (b) Ibisi titayọ wo ni a rí ninu ọdun iṣẹ-isin 1992?

4 Ìkórèwọlé naa ń yára kánkán bi opin eto-igbekalẹ Satani ti ń sunmọ etile. Atobilọla Ẹlẹdaa wa polongo pe: “Ati awọn eniyan rẹ, gbogbo wọn óò jẹ́ olododo . . . ẹ̀ka gbígbìn mi, iṣẹ́ ọwọ́ mi, ki a baa lè yin mi logo. Ẹni kekere kan ni yoo di ẹgbẹrun, ati kekere kan di alagbara orilẹ-ede: emi Oluwa yoo ṣe é kánkán ni akoko rẹ̀.” (Isaiah 60:21, 22) Ṣiṣe é kánkán yii ni a fihàn lọna ti ó yanilẹnu ninu Irohin Ọdun Iṣẹ-isin 1992 ti Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa Kárí-ayé, ti a tẹjade ni oju-iwe 12 si 15 ninu iwe-irohin yii.

5 Ohun ti ó tayọ ninu irohin yii ni gongo titun ti 4,472,787 awọn olupokiki Ijọba, ibisi 193,967—ipin 4.5 ninu ọgọrun-un ju ti ọdun ti ó kọja lọ. Gongo 301,002 ti a baptisi ni ọdun 1992 tun fi otitọ naa hàn pẹlu pe ogunlọgọ eniyan ń tẹwọgba otitọ Bibeli. Bawo ni a ṣe layọ tó pe ni “ọjọ okunkun ati okudu” yii, “eniyan ńlá ati alagbara” wà awọn ẹni ti, bi ọ̀wọ́ awọn eéṣú, ń mú ki ẹ̀rí Ijọba naa gbooro “dé opin ilẹ̀-ayé”! (Joeli 2:2, 25; Iṣe 1:8) Lati Alaska oníyìnyín—nibi ti ọkọ̀ ofuurufu Watch Tower Society ti ṣe ibẹwo ti ó ju 50 lọ si awọn ipinlẹ oníyìnyín dídì—si aṣálẹ̀ gbígbẹ́ táutáu ti Mali ati Burkina Faso ati awọn erekuṣu gátagàta ti Micronesia, awọn iranṣẹ Jehofa ń tàn gẹgẹ bi ‘ìmọ́lẹ̀ awọn keferi, ki igbala [rẹ̀] lè wà titi dé opin ayé.’—Isaiah 49:6.

6, 7. Iyipada ipo ti a kò reti wo ni a ṣẹlẹrii rẹ̀ ni awọn ọdun lọ́ọ́lọ́ọ́, bawo sì ni awọn iranṣẹ Jehofa ti ṣe huwa pada si i?

6 Jehofa ti dabi odi-agbara ati ilé-ìṣọ́ alagbara kan ni didaabobo ati gbigbe ẹmi awọn eniyan rẹ̀ ro. Ni ọpọlọpọ ibi lori ilẹ̀-ayé, awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti nilati farada ikimọlẹ ati inunibini oníkà fun ọpọ ẹwadun. (Orin Dafidi 37:39, 40; 61:3, 4) Ṣugbọn ni lọ́ọ́lọ́ọ́ yii, ńṣe ni ó dabii iṣẹ-iyanu, awọn ikalọwọko ati idena ni a ti mú kuro ni awọn ilẹ bii 21, ti o fi jẹ pe nisinsinyi awọn eniyan Ọlọrun lè polongo ni fàlàlà pe Atobilọla Ẹlẹdaa wa ti fi Kristi sori oyè gẹgẹ bi Ọba lori ilẹ̀-ayé.—Orin Dafidi 2:6-12.

7 Awọn eniyan Jehofa ha ń lo ominira wọn titun lọna rere bi? Ninu itolẹsẹẹsẹ isọfunni ṣakiyesi awọn ibisi fun Bulgaria, Romania, ati Soviet Union tẹlẹri ni iha Ila-oorun Europe ati fun Angola, Benin, ati Mozambique ni Africa. Ni Zaire, pẹlu, igbooro siwaju sii naa kọyọyọ. Pẹlu ayọ ninu ọkan-aya wọn, awọn ará wa ti a fun lominira dahun ìpè naa pe: “Ẹ fi ọpẹ́ fun Oluwa: nitori ti o ṣeun . . . , fun oun nikan ti ń ṣe iṣẹ́ iyanu-nla: nitori ti aanu rẹ̀ duro laelae.” (Orin Dafidi 136:1, 4) Idupẹ yii ni a ń sọ jade nipa iṣẹ-isin onitara ninu kíkó awọn eniyan miiran ti wọn jẹ́ ẹni-bi-agutan jọ siha Ijọba naa.

8. Bawo ni awọn oluyin Jehofa titun ṣe “ń fò bi awọsanma” ni iha Ila-oorun Europe? ni Africa?

8 Nigba ẹ̀rùn awọn ara Europe ti o kọja, apejọpọ awọn eniyan Jehofa ti a ṣe ni awọn ilẹ Kọmunisti tẹlẹri ti ni iye awọn olupesẹ ti ó gadabu. Eyi ti ó tilẹ yanilẹnu ju paapaa ni iye awọn ẹni ti a baptisi, gẹgẹ bi itolẹsẹẹsẹ isọfunni ti o tẹle e ṣe fihàn. Bakan naa, ni Togo, Africa, ifofinde naa ni a mú kuro ni December 10, 1991. Ni awọn oṣu ti ó tẹle e apejọpọ ti orilẹ-ede kan ni a ṣe. Ni ifiwera pẹlu ipindọgba oṣooṣu ti 6,443 awọn akede ni pápá, iye awọn tí ó pesẹ sibẹ roke dé 25,467, pẹlu 556 ti a baptisi—ipin 8.6 ninu ọgọrun-un iye awọn akede. Gẹgẹ bi Isaiah 60:8 ṣe fihàn, awọn olùyin Jehofa titun “ń fò bi awọsanma, ati bi awọn ẹyẹle si ojule wọn” ninu ijọ awọn eniyan Jehofa.

9. Awọn ipese wo ni a ti ṣe ki awọn Kristian ni awọn orilẹ-ede ti ó ṣẹṣẹ lominira lè ‘jẹun ki wọn sì yó’?

9 Ebi fun ounjẹ tẹmi ni iha Ila-oorun Europe ati Africa ni a mú dinku pẹlu. Awọn ile-iṣẹ Watch Tower Society ni Germany, Italy, ati South Africa ti fi ọpọlọpọ ọkọ̀-ẹrù ti ó kún fọ́fọ́ fun iwe-ikẹkọọ ranṣẹ tẹleratẹlera, ni ọpọlọpọ èdè, si awọn orilẹ-ede ti ń kú lọ fun ebi nipa tẹmi. Laipẹ yii, ọpọ ninu awọn Ẹlẹ́rìí naa nilati fi awọn iwe-irohin àjákù ṣọwọ si ẹnikinni keji, ṣugbọn nisinsinyi wọn ń gba ọpọ yanturu ounjẹ tẹmi. Wọn yọ̀ lati nipin-in ninu imuṣẹ asọtẹlẹ naa pe: “Eyin ó sì jẹun ni ọpọlọpọ, ẹ ó sì yó, ẹ ó sì yin orukọ Oluwa Ọlọrun yin, ẹni ti ó fi iyanu bá yin lò; oju kì ó sì ti awọn eniyan mi lae.”—Joeli 2:26.

Bibojuto Igbooro Siwaju Sii

10. Ni oju-iwoye iye awọn eniyan ti ó pọ sii ti ń wá si Iṣe-iranti, ikesini wo ni a nawọ rẹ̀ si awọn olufifẹhan?

10 Iyalẹnu nitootọ ni iye awọn olupesẹ kaakiri agbaye sibi Iṣe-iranti ikú Jesu jẹ́, 11,431,171, ibisi 781,013, tabi ipin 7.3 ninu ọgọrun-un ju ti ọdun ti o kọja lọ. Ẹ kaabọ, gbogbo ẹyin ti ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ dé! Yoo ti jẹ agbayanu tó bi gbogbo iru awọn olufifẹhan titun bẹẹ bá gbadun anfaani ikẹkọọ Bibeli inu ile kan pẹlu ọ̀kan lara awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa! (Wo Isaiah 48:17.) Irohin Ọdun Iṣẹ-isin fihàn pe 4,278,127, ninu awọn ikẹkọọ wọnyi ni a ń dari loṣooṣu, ibisi didara ti ipin 8.4 ninu ọgọrun-un. Bi o ti wu ki o ri, ọpọlọpọ ṣì lè mú araawọn wà larọọwọto fun iṣẹ-isin yii. Inu awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa dùn lati késí awọn olufifẹhan ni deedee lati dari ikẹkọọ Bibeli inu ile kan lọfẹẹ, ni titipa bayii ran awọn wọnyi lọwọ lati fi ẹsẹ wọn mulẹ gbọnyin loju ọ̀nà ti ó lọ si ìyè ainipẹkun. (Johannu 3:16, 36) Eeṣe ti o kò beere fun iru ikẹkọọ bẹẹ? Sì ranti, ikini kaabọ ọlọyaya wà ní sẹpẹ́ fun ọ nigba gbogbo ni Gbọngan Ijọba!—Orin Dafidi 122:1; Romu 15:7.

11, 12. (a) Awọn iṣoro wo ni wọn ń dojukọ ni awọn ilẹ melookan? (b) Ni ọ̀nà wo ni “idọgba” gbà ń ṣẹlẹ laaarin awọn ilẹ ti ó lọ́rọ̀ ati awọn ilẹ ti ó tòṣì?

11 Awọn ijọ wọnni ti wọn ní Gbọngan Ijọba didara ni a ń bukun ni jingbinni. Ipo naa yatọ ni awọn ilẹ nibi ti awọn Ẹlẹ́rìí aduroṣinṣin ti farada ọpọlọpọ ọdun labẹ ifofinde, ni pipadepọ ni bookẹlẹ ninu awujọ keekeeke. Ni ọpọlọpọ iru awọn ibi bẹẹ, wọn lominira nisinsinyi ṣugbọn wọn ní awọn Gbọngan Ijọba ti kò pọ̀. Ni orilẹ-ede Africa kan, fun apẹẹrẹ, kìkì Gbọngan Ijọba mẹta péré ni o wà fun ìlò awọn ijọ 93. Nitori naa awọn ipade ni a sábà maa ń ṣe lori ààyè ilẹ̀ títẹ́jú gbalasa fífẹ̀ kan. Ijọ kan ti ó ní eniyan 150 lè ni tó eniyan 450 ti ń wá si awọn ipade wọnyi deedee.

12 Ni iha Ila-oorun Europe ó sábà maa ń lekoko lati ra dúkìá tabi lati kọle, ṣugbọn itẹsiwaju diẹ ni a ti ṣe. Iyasimimọ ile-lilo ẹka titun kan ti o dara ni a ṣeto fun November 28, 1992, ni Poland. Awọn itilẹhin ọlọ́làwọ́ fun iṣẹ́ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kaakiri agbaye ni a ń lò lati ṣeranwọ lati kọ́ awọn gbọngan ati awọn ilé-lílò miiran. Nipa bayii, “ìdọ́gba” ṣẹlẹ niti pe iwa-ọlawọ awọn ará ti wọn ṣetilẹhin lati inu “ọpọlọpọ ìní” ti ara wọn ṣeranlọwọ ni pipese fun aini tẹmi awọn ijọ ni awọn ilẹ ti kò laasiki.—2 Korinti 8:13, 14.

Billion kan Wakati!

13. Wakati meloo ni a lò ninu wiwaasu ati kíkọ́ni ni ọdun 1992, isapa awọn wo ni a sì gbeyọ ninu iye yii?

13 Ki ni iwọ yoo ṣe pẹlu billion kan wakati? Gbogbo awọn ti wọn jere ìyè ainipẹkun yoo lè lo awọn wakati pupọ yẹn, ati pupọ sii paapaa, ninu iṣẹ-isin amesojade, ti ń tẹnilọrun si Jehofa. Ṣugbọn ronu nipa kíkó ọpọ wakati yẹn jọ sinu ọdun kan! Iyẹn ni ohun ti awọn eniyan Jehofa ṣaṣepari rẹ̀ ni ọdun 1992. Nipa ṣiṣe aropọ irohin gbogbo awọn akede Ijọba lẹnikọọkan, a rí gongo titun ti 1,024,910,434 wakati ti a lò ni ọ̀nà ti ó dara julọ ti a lè gbà lo wakati—yiyin Atobilọla Ẹlẹdaa wa, ‘ni kíkọni ni gbangba ati lati ile de ile.’ (Iṣe 20:20) Ni ipindọgba, 4,289,737 awọn Ẹlẹ́rìí ni wọn ń rohin loṣooṣu. Wọn wá lati inu oniruuru ipo igbesi-aye. Akoko ti awọn kan lè fi ṣetilẹhin fun iṣẹ́ Ijọba naa mọniwọn. Iwọnyi ní awọn olori idile ninu, ti wọn gbọdọ pese fun agbo-ile wọn; awọn arugbo; ati ọpọlọpọ ti wọn ni iṣoro ilera; titikan awọn ọmọde ti wọn ṣì wà ni ile-ẹkọ paapaa. Sibẹ, irohin ti ẹnikọọkan ṣe jẹ́ ìfihàn ifẹ fun Jehofa ti a kà si iyebiye.—Fiwe Luku 21:2-4.

14. Bawo ni awọn ọ̀dọ́ eniyan ṣe ‘ń ranti Atobilọla Ẹlẹdaa wọn’?

14 Iran kan ti o jẹ́ ti awọn ọ̀dọ́ eniyan ń dagba ninu iṣẹ-isin Jehofa, o si jẹ́ ohun ayọ pe ọpọ julọ ninu awọn wọnyi ń ṣe ifisilo ọ̀rọ̀ Solomoni ni Oniwasu 12:1 pe: “Ranti Ẹlẹdaa rẹ nisinsinyi ni ọjọ èwe rẹ.” Wọn ń lo araawọn lati bojuto iṣẹ́ ile-ẹkọ wọn, ti a sì tun ń dá wọn lẹkọọ ninu awọn ọ̀ràn tẹmi nipasẹ awọn òbí olufọkansin. Ó ti jẹ́ ohun ayọ lati rí ọpọ awọn ọdọlangba alaito-ọmọ-ogun-ọdun ti wọn dide duro ni awọn apejọpọ ẹnu aipẹ yii, ti wọn jọ̀wọ́ araawọn fun iribọmi. Ó jẹ́ ohun ayọ bakan naa pẹlu lati mọ̀ pe, nipa kíkọ́ òwò tabi iṣẹ-ọwọ kan, ọpọlọpọ ń ṣe imurasilẹ ti ó lọgbọn-ninu fun ṣiṣe aṣaaju-ọna nigba ti wọn bá pari ile-ẹkọ wọn. Nipa bayii, wọn yoo lè ṣetilẹhin fun araawọn, gẹgẹ bi aposteli Paulu ti ṣe lati ìgbà de ìgbà nipa pipa àgọ́.—Iṣe 18:1-4.

15, 16. Bawo ni awọn aṣaaju-ọna ati awọn iranṣẹ alakooko kikun miiran ṣe ń ṣetilẹhin fun ilọsiwaju iṣẹ́ Ijọba naa, ibukun wo si ni diẹ ninu wọn ti gbadun?

15 Wo iru agbayanu itilẹhin ti awọn aṣaaju-ọna ati awọn iranṣẹ alakooko kikun miiran ń ṣe fun ilọsiwaju iṣẹ́ Ijọba naa! Iye awọn aṣaaju-ọna lọ soke de gongo 931,521 ni ọdun ti o kọja yii. Bi awọn wọnyi ti ń waasu lati ile de ile ti wọn sì ń ṣe awọn ikẹkọọ Bibeli ninu ile awọn eniyan, wọn di ọ̀jáfáfá ninu sisọ ọ̀rọ̀ jade lori Iwe Mimọ. Siwaju sii, ọpọlọpọ ti tóótun lati lọ si Ile-ẹkọ Iṣẹ-isin Aṣaaju-ọna ọlọsẹ meji, eyi ti ń ràn wọn lọwọ lati mú agbara ati ayọ ti ó tubọ pọ̀ sii dagba ninu ṣiṣe iṣẹ́ Ọlọrun.

16 Ọkọọkan ninu awọn aṣaaju-ọna aduroṣinṣin wọnyi lè jọ́hẹn si ọ̀rọ̀ ti ó wà ni Isaiah 50:4 pe: “Oluwa Jehofa ti fi ahọ́n akẹkọọ fun mi, ki emi ki o lè mọ bi a tii sọrọ ni akoko fun aláàárẹ̀.” Ọpọ yanturu eniyan lẹnikọọkan ni ń bẹ lonii ti ayé oniwa-palapala ti ó wà yí wọn ká ti sú ṣugbọn ti wọn ń rí itura lati inu ọ̀rọ̀ ti awọn aṣaaju-ọna oluṣotitọ wa ń sọ.—Fiwe Owe 15:23; Esekieli 9:4.

Itolẹsẹẹsẹ Ilé-kíkọ́ Bíbùáyà Kan

17. Ni afikun si ikọle tẹmi, ikọle nipa ti ara wo ni a ti ṣẹlẹrii rẹ̀ ni awọn ọdun lọ́ọ́lọ́ọ́ yii?

17 Aasiki nipa tẹmi kari-aye ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ṣokunfa idagbasoke nipa ohun ti ara pẹlu. Imugbooro awọn ilé-lílò fun iwe-titẹ, awọn ọfiisi, awọn ile Beteli ati kíkọ́ awọn Gbọngan Ijọba ati Gbọngan Apejọ di eyi ti o pọndandan. Nitori naa awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni a beere pe ki wọn di kọ́lékọ́lé ni ọ̀nà ti ara kan. Iru ikọle kan-naa ṣẹlẹ ni ọjọ Ọba Solomoni. Solomoni kọ́ tẹmpili fun ijọsin Jehofa ni ibamu pẹlu “apẹẹrẹ . . . eyi ti ó ní ní inu rẹ̀ pẹlu rẹ̀,” lẹhin ti Jehofa ti pese eyi fun baba rẹ̀, Ọba Dafidi. (1 Kronika 28:11, 12) Nipa bẹẹ, kìí ṣe kìkì pe Solomoni gbé awọn olugbọ rẹ̀ ró pẹlu awọn ọ̀rọ̀ ọgbọn oniyebiye nikan ni ṣugbọn ó tun dari ilé-kíkọ́ nipa ti ara kan ti ó pẹtẹri eyi ti ayé kan kò tíì kọ́ ri.—1 Ọba 6:1; 9:15, 17-19.

18, 19. (a) Awọn idawọle ikọle ti ń tẹsiwaju kánkán wo ni a ń ṣe nipasẹ eto-ajọ Jehofa? (b) Bawo ni a ṣe fi ẹmi Jehofa hàn nipa ikọle nipa ti ara ati nipa tẹmi?

18 Lonii, awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kò kọle nipasẹ awọn aworan ile kíkọ́ ti a mísí latọrunwa, ṣugbọn wọn ní ẹmi Ọlọrun. Gẹgẹ bi o ṣe rí ni ọjọ Israeli, eyi sún wọn lati kọle ni ọ̀nà ti ó ya awọn eniyan ayé lẹnu. (Sekariah 4:6) Akoko kuru. Awọn Gbọngan Ijọba ati awọn ile miiran ni a nilo laisi ijafara. Ni awọn orilẹ-ede melookan awọn Gbọngan Ijọba ti a tètè ń kọ́ jẹ eyi ti o wọ́pọ̀. Ni ọdun mẹwaa ti ó kọja, fun apẹẹrẹ, Canada rohin kíkọ́ 306 gbọngan, ọkọọkan ní ohun ti o dín si ọjọ meji. Nitori gbigbooro sii ti iṣẹ́ Jehofa ń gbooro ni kanmọkanmọ kaakiri agbaye, aropọ 43 ilé-ẹ̀ka titun tabi imugboorosii ẹka ni a ń kọ́ lọwọlọwọ tabi ti a ń wewee rẹ̀. Siwaju sii, ilé gbígbé alájà 30, pẹlu ààyè ibugbe fun nǹkan bi ẹgbẹrun kan awọn oluyọnda ara-ẹni ni Beteli, ni a ti fẹrẹẹ pari ni Brooklyn. Bakan naa ni Ipinlẹ New York, ni Patterson, ikọle ẹ̀ka ikọnilẹkọọ Bibeli, idawọle titobi julọ ti Watch Tower Society tíì koju rẹ̀ rí, ń tẹsiwaju kíkankíkan rekọja iwewee ti a ṣe fun un.

19 Awọn idawọle wọnyi ń tẹsiwaju lọna gbigbeṣẹ pẹlu ijojulowo iṣẹ́ ti ó ya awọn ile-iṣẹ ikọle ti ayé ti ó nimọ lẹnu. Eeṣe? Nitori itilẹhin pipẹtẹri tí awọn Ẹlẹ́rìí oluṣeyasimimọ ti Jehofa ṣe. Ẹmi rẹ̀ ń sún wọn kìí ṣe kìkì lati pese itilẹhin nipa ti ara nikan ni ṣugbọn lati funni ni akoko ati agbara wọn latọkanwa pẹlu. Awọn agbegbe ilẹ ikọle kúnfọ́fọ́ fun awọn oṣiṣẹ ti wọn mọṣẹ ti wọn sì jẹ́ olufọkansin. Kò sí ìdaṣẹ́sílẹ̀ awọn oṣiṣẹ, kò sì sí ifakokoṣofo lẹnu iṣẹ́. Ẹmi Jehofa ń pese isunniṣe, gan-an gẹgẹ bi o ṣe sún awọn olukọ àgọ́-ìsìn ni ìgbà Mose ati awọn wọnni ti wọn kọ́ tẹmpili ni awọn ọjọ Solomoni. Ipo tẹmi ni animọ titayọ ti a beere fun lati ọwọ́ awọn oṣiṣẹ wọnyi.—Fiwe Eksodu 35:30-35; 36:1-3; 39:42, 43; 1 Ọba 6:11-14.

20. (a) Dé ìwọ̀n ààyè wo ni a o ṣì nilati waasu ihinrere naa? (b) Ifojusọna alabukun wo ni ó ń duro de awọn eniyan Jehofa?

20 Solomoni ń bá itolẹsẹẹsẹ ilé-kíkọ́ rẹ̀ niṣo lẹhin pipari tẹmpili naa. (2 Kronika 8:1-6) Ìwọ̀n ààyè ti ẹ̀rí ode-oni yoo gbooro dé naa—pẹlu aini ti ń baa rìn fun kíkọ́ awọn gbọngan ati awọn ilé lílò miiran—awa kò mọ̀. Bi o ti wu ki o ri, a mọ̀, pe nigba ti ihinrere Ijọba yii bá ti di eyi ti a waasu rẹ̀ dé ìwọ̀n ti Jehofa palaṣẹ, ìgbà naa ni opin, “ipọnju nla,” yoo dé. (Matteu 24:14, 21) Ninu ayé kan ti awọn oniwọra eniyan kò bajẹ mọ́, iṣeto “awọn ọrun titun ati ayé titun” ti Jehofa yoo wá mú ibukun alaiṣeefẹnusọ wá fun iran eniyan nigba naa. Ǹjẹ́ ki awa nigba naa ‘ki ó yọ̀, ki inu wa ki ó sì dùn titilae ninu ohun ti Ọlọrun dá,’ ni fifi gbogbo iyin fun Atobilọla Ẹlẹdaa wa!—Isaiah 65:17-19, 21, 25.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo iwe “Let Your Kingdom Come,” ti a tẹjade lati ọwọ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., oju-iwe 105 si 116, 186 si 189.

Iwọ Ha Lè Ṣalaye Bi?

◻ Awọn idi wo ni a ní fun yíyọ̀ ninu Atobilọla Ẹlẹdaa wa?

◻ Awọn ilọsoke wo ni a rohin ni ọdun iṣẹ-isin 1992?

◻ Ni awọn orilẹ-ede ti a ti fofinde wiwaasu tẹlẹrii, ibukun jigbinni wo ni a rohin rẹ̀?

◻ Bawo ni awọn èwe ati aṣaaju-ọna ṣe ń ṣetilẹhin fun ibisi ninu eto-ajọ Jehofa?

◻ Bawo ni ọwọ́ awọn eniyan Jehofa ṣe ń dí ninu awọn iṣẹ́ ikọle nipa ti ara ati nipa ti ẹmi?

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 17]

Ni ọdun ti ó kọja ohun ti ó ju billion kan wakati ni a lò ninu iṣẹ́ iwaasu ati kíkọ́ni naa

[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 12-15]

ÌRÒYÌN ỌDÚN IṢẸ́ ÌSÌN 1992 TI ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ JEHOFA KÁRÍ AYÉ

(Wo àdìpọ̀)

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Ọgọrọọrun lọna ẹgbẹẹgbẹrun awọn olùnàgà fun anfaani iribọmi lọdun ti ó kọja fi ibukun Jehofa lori iṣẹ́ wiwaasu ati kíkọ́ni naa hàn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Iye awọn ọ̀dọ́ ti ó pọ ‘ń ranti Atobilọla Ẹlẹdaa wọn’

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́