ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 2/1 ojú ìwé 7-8
  • Wọn Yí Ọ̀nà Igbesi-aye Wọn Pada

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wọn Yí Ọ̀nà Igbesi-aye Wọn Pada
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ipilẹ fun Iyipada Naa
  • Awọn Miiran Ń Fẹ Lati Kẹkọọ Bibeli
  • Otitọ Bibeli Ń Yí Igbesi-aye Pada
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Bọ́ Lọ́wọ́ Lílo Oògùn Olóró?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní
  • Báwo Ni Mi Ò Ṣe Ní Kó Sọ́wọ́ Àwọn Tó Ń Fipá Báni Lò Pọ̀?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 2/1 ojú ìwé 7-8

Awọn Olupokiki Ijọba Rohin

Wọn Yí Ọ̀nà Igbesi-aye Wọn Pada

KÒ SI iyemeji pe o ti rí wọn ti wọn ń ba awọn ẹlomiran sọrọ ni opopona, ti wọn ń ṣe ikesini lati ile de ile, tabi ti wọn ń lọ si awọn ipade Kristian ninu Gbọngan Ijọba wọn. A ń sọrọ nipa awọn èwe Ẹlẹ́rìí Jehofa amura letoleto wọnni. Iwọ lè ti pari èrò si pe wọn jẹ́ Ẹlẹ́rìí nitori pe awọn òbí wọn kọ́ wọn lati jẹ́ bẹẹ, bi ọ̀ràn sì ti ri fun ọpọlọpọ ninu wọn niyẹn. Ni ọwọ keji ẹ̀wẹ̀, awọn kan wà ninu awọn ọ̀dọ́ eniyan wọnyi ti ipò àtìlẹ̀wá wọn yatọ gan-an ti awọn ọ̀nà igbesi-aye wọn tẹlẹri sì jẹ eyi ti o yatọ patapata si igbesi-aye ti wọn ń gbe nisinsinyi. Niti tootọ, awọn wọnni ti a fihàn ni oju-ewe ti o tẹle e yii ń kẹgbẹpọ tẹlẹri pẹlu awọn awujọ ninu eyi ti iwa-ipa ati ilokulo oogun ti jẹ́ iṣẹlẹ ojoojumọ. Ki ni o mú wọn lati yí igbesi-aye wọn pada patapata bẹẹ? Jẹ ki a bẹ ilu kan wò ni Norway ki a sì kàn sí diẹ ninu awọn ọ̀dọ́ eniyan ti wọn ti ṣe iru awọn iyipada bẹẹ.

Ipilẹ fun Iyipada Naa

Nigba ti awọn Ẹlẹ́rìí meji pade Annette ninu iṣẹ-ile-de-ile, oun jẹ ọmọ ọdun 19. “A ti maa ń figba gbogbo sọ fun mi lati maṣe bá awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa sọrọ páàpáà, ṣugbọn mo ń haragaga mo sì késí wọn wa sinu ile,” ni oun ranti. Oun ti jẹ aloogun lati ìgbà ti o ti wà ni ọmọ ọdun 11 ti o sì ti lọwọ ninu oniruuru ìfọ́lé ati ọkọ̀ jíjí.

Ihinrere Ijọba naa fà á mọra. A fun un ni iṣiri ni pataki julọ nipa ireti ajinde, niwọn bi oun ti padanu ìyá rẹ̀ nigba ti o ṣì wà ni ọmọ ọdun marun-un. Nitori naa o tẹwọgba ikẹkọọ Bibeli lọfẹẹ o sì bẹrẹ sii wá sí awọn ipade ni Gbọngan Ijọba. O sọ fun ọrẹkunrin rẹ̀ ati awọn miiran ohun ti oun ń kẹkọọ. Ki ni iṣarasihuwa naa? Wọn kò fẹ ohunkohun ṣe pẹlu rẹ̀ wọn si fi ẹsun kan Annette fun jijẹ ẹni ti a ti ra níyè. Bi o tilẹ ri bẹẹ, diẹ ninu awọn ti wọn gbe atako dide lẹhin naa bẹrẹ sii kẹkọọ Bibeli.

Gẹgẹ bi apẹẹrẹ, wo Espen, ọdọmọkunrin kan ẹni 20 ọdun. O gbọ nipa ihinrere Ijọba naa lati ẹnu ọrẹkunrin Annette ó sì fẹ ikẹkọọ Bibeli kan loju ẹsẹ. Bi o ti wu ki o ri, o ń duro lati ṣẹwọn oṣu mẹrin, niwọn bi o ti lọwọ ninu fayawọ oogun ati, gẹgẹ bii Annette, ninu oniruuru ifipajale. Oun jẹ ẹni ti o tun ń lo tábà, marijuana, ati awọn oogun miiran. Nisinsinyi, ki ni ó lè mú ki ẹnikan ti o ti lọwọ ninu iru awọn nǹkan bẹẹ fẹ́ lati bẹrẹ kikẹkọọ Bibeli? Espen bẹrẹ sii mọ òfo ati aisi ète ninu ọ̀nà igbesi-aye rẹ̀. O ṣalaye pe: “Awọn ileri Bibeli nipa ọjọ-ọla kan ti o fun mi ni ète ninu igbesi-aye fà mi mọra. Nitori naa mo bẹrẹ sii kẹkọọ ki ń baa lè ṣèwádìí bi a bá ti sọ otitọ fun mi.”

Awọn Miiran Ń Fẹ Lati Kẹkọọ Bibeli

Ni akoko yii, ọdọmọkunrin kan lati inu agbo awọn ọ̀dọ́ eniyan kan-naa gbọ́ nipa ihinrere naa, oun naa sì bẹrẹ sii kẹkọọ ó sì ń wa si awọn ipade pẹlu. Tẹle e, ikẹkọọ kan ni a bẹrẹ pẹlu omiran ninu awọn èwe wọnyi, ó sì bẹrẹ sii wá sí awọn ipade. Laipẹ laijinna, ọdọmọkunrin miiran tun darapọ mọ awọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ni kikẹkọọ Bibeli ati nini itẹsiwaju nipa tẹmi. Sibẹ naa èwe miiran ninu awujọ kan-naa ni a fà lọ́kàn mọra nipa awọn iyipada ṣíṣepàtó ti awọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ń ṣe, ati laaarin ìgbà kukuru, o fẹ́ lati kẹkọọ Bibeli.

Gilbert, ọ̀dọ́ olórin kan lati inu awujọ kan-naa, ti bẹrẹ sii kẹkọọ Bibeli nisinsinyi. Awọn òbí rẹ̀ mejeeji ni àrùn jẹjẹrẹ ti pa, nitori naa oun ni a tù ninu nipa ireti ajinde ti Bibeli. (Johannu 5:28, 29) Oun tun ń lo marijuana pẹlu o sì ń gbe igbesi-aye idibajẹ, o sì ni ilepa-aṣeyọri lati di olórin rock olokiki. Bi o ti wu ki o ri, bi akoko ti ń lọ o ni itẹsiwaju ti o dara nipa tẹmi o sì pinnu laipẹ lati di Ẹlẹ́rìí kan fun Jehofa. Lakootan, aburo Espen ọkunrin bẹrẹ sii ṣayẹwo Bibeli o sì ń kẹgbẹpọ pẹlu awọn Ẹlẹ́rìí.

Otitọ Bibeli Ń Yí Igbesi-aye Pada

Iyipada nla ṣẹlẹ ninu awọn ọ̀dọ́ eniyan wọnyi ti wọn ti figbakan ri jẹ ẹni ti ń mura lọna aibikita, pẹlu irun jákujàku lori, ti wọn si ń lọwọ ninu oogun, olè jíjà, ati awọn iwa-ọdaran miiran. Annette jẹ́ akede Ijọba rere o sì ṣiṣẹsin gẹgẹ bi aṣaaju-ọna fun nǹkan bi ọdun kan. Espen ati Gilbert ti ṣiṣẹsin gẹgẹ bi aṣaaju-ọna oluranlọwọ, wọn sì tun jẹ iranṣẹ iṣẹ-ojiṣẹ. Awọn mejeeji ti ṣegbeyawo ninu ijọ Kristian. Mẹrin sii ninu awujọ isaaju naa jẹ́ akede Ijọba onitara pẹlu!

Ki ni nipa ti ẹwọn olóṣu mẹrin ti Espen nilati lọ? Nitori awọn iyipada ti o ṣe ninu igbesi-aye rẹ̀, ifisẹwọn rẹ̀ ni a yipada si 80 wakati ti iṣẹ́ adugbo. Pẹlu ifọwọsi ọlọpaa ati ti awọn miiran, o lo awọn wakati wọnyi ni ṣiṣiṣẹ ni Gbọngan Ijọba Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti adugbo. Awọn ọlọpaa naa ni inu wọn dun pupọpupọ si iṣeto yii.

Bẹẹni, ọpọlọpọ awọn ọ̀dọ́ eniyan miiran kaakiri agbaye ni ipó àtilẹ̀wá tí ó jẹ́ ti oniwa-ọdaran. Ṣugbọn otitọ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ti fun wọn ni idahun si awọn ibeere ti o ṣekoko ati ireti ti o daju fun ọjọ-ọla. Bi o ba ri bẹẹ, wọn kìí tun ṣe oniwa-ọdaran tabi ajoogunyo mọ́, bẹẹ ni wọn kìí sìí lọ kaakiri pẹlu imura lọna ṣakala kan. Lẹhin yiyi ọ̀nà igbesi-aye wọn pada, wọn dabi awọn eniyan ti a mẹnukan loke yii gan-an—wọn jẹ ọ̀dọ́, wọn mura letoleto, wọn si jẹ akikanju Ẹlẹ́rìí fun Jehofa. Wọn fẹ lati sọ awọn ojutuu Bibeli wiwapẹtiti si awọn iṣoro tí ọpọlọpọ awọn ọ̀dọ́ eniyan ni lonii di mímọ̀ fun awọn ẹlomiran.—Wo 1 Korinti 6:9-11.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Espen, Annette, ati Gilbert

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́