Awọn Ipese Iranlọwọ Fi Ifẹ Kristian Hàn
“ẸFẸ́ awọn ara,” ni aposteli Peteru rọ awọn Kristian ẹlẹgbẹ rẹ̀. (1 Peteru 2:17) Iru ifẹ bẹẹ ti jẹ́ eyi ti o nilati lọ rekọja ààlà ẹya-iran, ẹgbẹ-oun-ọgba, ati orilẹ-ede, ni fífa awọn eniyan mọra ninu ojulowo ẹgbẹ́-ará. Nigba ti aini nipa ti ara dide laaarin awọn Kristian ijimiji, ifẹ sún ọpọlọpọ lati dá ọrẹ jọ fun awọn aposteli fun ipinkiri lọ sọdọ awọn wọnni ti wọn wà ninu aini. Akọsilẹ naa sọ pe “wọn ni ohun gbogbo ṣọkan.”—Iṣe 2:41-45; 4:32.
Iru ifẹ bẹẹ ni a fihàn nigba ti Ẹgbẹ́ Oluṣakoso Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, ni opin ọdun 1991, kesi oniruuru ẹ̀ka Watch Tower Society ni iha Iwọ-oorun Europe lati pese ounjẹ ati aṣọ fun awọn ará wọn ti wọn ṣe alaini ni iha Ila-oorun Europe, eyi ti o ni ninu apa diẹ ninu Soviet Union tẹlẹri. Nihin-in ni a ṣe igbekalẹ ọ̀wọ́ awọn irohin lati diẹ ninu awọn ẹ̀ka ti ọ̀ràn yii kàn.
Sweden
Ni December 5, 1991, lẹta kan ti ń ṣalaye aini naa ni a fi ranṣẹ si gbogbo ijọ 348 ni Sweden. Idahunpada naa jẹ́ kanmọ. Laaarin ọjọ diẹ, ọkọ̀ akẹru akọkọ wà loju ọ̀nà rẹ̀ si St. Petersburg, Russia, eyi ti o kunfọfọ fun tọọnu 15 iyẹfun, òróró-ọ̀rá, awọn ẹran maluu inu agolo, wàrà gbẹrẹfu, ati awọn ohun ti o farajọ ọ. Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa adugbo já ọkọ̀ ẹrù naa wọn si ṣe ipinkiri awọn ìdì 750 naa fun awọn wọnni ti wọn wà ninu aini. Lẹhin naa, ọkọ̀ akérò meji miiran sii gbé ounjẹ lọ si Russia. Lapapọ iye ti o ju 51.5 tọọnu lọ ni a fọkọ̀ kó ranṣẹ lati Sweden.
Imuratan naa lati fi aṣọ ati bata tọrẹ rekọja ifojusọna gbogbo. Àkójọ pelemọ awọn ìdì aṣọ ni a dájọ ní kánmọ́kánmọ́ ninu awọn Gbọngan Ijọba. Ọpọ awọn Kristian fi aṣọ lati inu àkójọ aṣọ tiwọn funraawọn tọrẹ. Awọn miiran ra awọn ohun-eelo titun. Arakunrin kan ra ẹwu imura toke-tilẹ marun-un. Nigba ti olutaja ti ẹnu yà naa mọ nipa ète ti o rà á fun, o fi ẹwu imura toke-tilẹ marun un miiran sii tọrẹ. Arakunrin miiran ra ẹ̀kún apoti ibọsẹ, ibọwọ, ati ìdikù. Nigba ti o ṣalaye ète naa, ontaja naa fun un ni 30 ẹ̀wù toke-tilẹ titun fun iye owo ti o ń ta meji. Olutaja awọn aṣọ iṣere kan fi 100 bata titun ati awọn bata àwọ̀dórúnkún tọrẹ.
Gbogbo awọn ohun-eelo yii ni a wá kó wá si ẹ̀ka fun yíyàsọ́tọ̀, títúndì, ati kíkó sọ́kọ̀. Awọn ohun-eelo aṣọ—eyi ti o kaju ohun ti 40 ọkọ̀ akérò yoo kó—gba ààyè nla ni ẹ̀ka naa! Awọn arakunrin ati arabinrin ṣiṣẹ fun ọpọ ọsẹ ni yíyà wọn sọtọọtọ ní pelemọ fun awọn ọkunrin, obinrin, ati awọn ọmọde wọn si ń dì wọn sinu paali. Awọn ọkọ̀ akérò 15 yiyatọsira ni a lò lati gbe awọn ohun-eelo aṣọ naa lọ si Russia, Ukraine, ati Estonia.
Arakunrin kan ti ó wa ọ̀kan ninu awọn ọkọ̀ akérò Society ni ẹẹmẹẹjọ lọ si Soviet Union tẹlẹri sọ pe: “Igbanilalejo ti awọn ará wa fifun wa ni awọn ibi ti a ń dé si jẹ́ èrè kan ti o ga. Wọn dirọ mọ́ wa wọn sì fẹnu kò wá lẹnu, ati pe laika awọn ohun-ìní wọn ti kò tó nǹkan sí, wọn fun wa ni ẹ̀kọ́ rere kan ninu iwa ọlawọ Kristian.”
Finland
Laika ìfẹ́ri igbokegbodo ọrọ̀-ajé, airiṣẹṣe ti o gbilẹ, ati awọn iṣoro niti ọ̀ràn isunna owó sí, imuratan naa laaarin nǹkan ti o fẹrẹ to 18,000 awọn ará ní Finland ti wọn yoo ran awọn ará wọn ni Soviet Union tẹlẹri lọwọ ti jẹ eyi ti o ga. Wọn fi ohun ti o ju tọọnu 58 ounjẹ ranṣẹ ninu awọn 4,850 paali si St. Petersburg, Estonia, Latvia, Lithuania, ati Kaliningrad. Wọn tilẹ tun fi awọn ohun-eelo aṣọ ti o jẹ 12 igbọnwọ mita kun awọn alafo inu awọn ọkọ̀ akẹ́rù. Nǹkan bii ọkọ̀ ayọkẹlẹ àdáni ati ọkọ̀ akérò àlòkù 25 ni a fi tọrẹ fun lilo ninu iṣẹ Ijọba naa pẹlu.
Diẹ ninu awọn apoti ounjẹ naa dé ijọ kan ti o ní awọn akede 14 ni Slanti ni ayika St. Petersburg. Wọn fi imoore nla hàn ninu lẹta kan. “A ni awọn arabinrin agbalagba mẹwaa ninu ijọ wa. Ọpọ ninu wa ni a ṣaisan gidigidi ti a kò si lè duro lori ila fun awọn wakati lati gba ounjẹ. Bi o ti wu ki o ri, Baba wa ọrun kò fun wa ni idi lati jẹ ẹni ti a kó irẹwẹsi bá ni awọn akoko lilekoko wọnyi ṣugbọn o fi ayọ kún ọkàn wa. A ń dari ikẹkọọ Bibeli inu ile 43.” Nigba ti arabinrin kan ni St. Petersburg ri ìdì ẹrù iranlọwọ rẹ̀ gbà, ori rẹ̀ wú debi pe o sọkun fun wakati meji ki o tó tú u.
Denmark
Ni orilẹ-ede kekere yii ní ẹnu ọ̀nà abawọle Òkun Baltic, nǹkan bii 16,000 awọn Ẹlẹ́rìí fun Jehofa korajọpọ wọn sì fi ọkọ̀ akẹ́rù 19 ti o ni 64 tọọnu ounjẹ ti ń bẹ ninu 4,200 apoti; 4,600 apoti aṣọ ti o niyelori gidi; ati 2,269 bata titun ranṣẹ si Ukraine. Arakunrin kan ni Germany jẹ́ ki ẹ̀ka lo awọn ọkọ̀ akẹ́rù marun-un, eyi ti oun fi tọrẹ lẹhin naa fun awọn ará ni Ukraine. Nigba ti wọn pada si ile, ọ̀kan ninu awọn awakọ naa sọ pe: “A rí pe ohun ti a mú pada wá pọ̀ ju ohun ti a ti mú lọ lọ. Ifẹ ati ẹmi irubọ tí awọn ará wa ni Ukraine fihàn fun igbagbọ wa lokun gidigidi.”
Awọn awakọ nilati ṣọra fun awọn dánàdánà ni oju-ọna ni Soviet Union tẹlẹri. Ni ọjọ diẹ ṣaaju ki ọkọ̀ akẹ́rù ti Denmark tó kọja lọ, ìdigunjalè kan ti ṣẹlẹ ni oju-ọna naa. Awọn ọkọ̀ akẹ́rù marun-un ti wọn ń lọ papọ pẹlu ounjẹ lati ọ̀dọ̀ eto-ajọ ipese iranlọwọ miiran ni awọn ọlọṣa ti daduro ni lilo ọkọ̀ ofuurufu helicopter ati awọn ibọn arọjo-ọta kekere. Wọn gba gbogbo ọkọ̀ akẹ́rú maraarun naa, ni fifi awọn awakọ naa silẹ ni ẹ̀gbẹ́ títì. Laika iru awọn ijamba bẹẹ si, gbogbo awọn ipese lati ẹ̀ka Denmark dé ọ̀dọ̀ awọn ará laisewu. Ni àbọ̀, wọn jẹ ki awakọ kan mú lẹta ti o tẹle e yii lọ sile, eyi ti a kọ lede Gẹẹsi pẹlu iṣoro nla pe: “Ẹyin arakunrin ati arabinrin ni Denmark ọ̀wọ́n: A ti gba ipese iranlọwọ yin. Jehofa yoo san yin ni ẹsan rere.”
Netherlands
Ẹka ti Netherlands fi tọọnu ounjẹ 52 ranṣẹ ninu 2,600 ìdì ẹrù. A já wọn si Ukraine ninu awọn ọ̀wọ́ ọkọ̀ arinrin-ajo meji. Ni ìgbà kọọkan awọn ọkọ̀ akẹ́rù mẹfa naa ni a fi silẹ lẹhin, niwọn bi o ti jẹ́ pe awọn ará ni Germany ti fi tọrẹ fun iṣẹ Ijọba naa ni Ila-oorun. Awọn arakunrin ni Ukraine fi pupọ ninu awọn ounjẹ naa ṣọwọ si Moscow, Siberia, ati awọn ibomiran nibi ti aini ti pọ. Siwaju sii, awọn aṣọ ati bata ti ó gba ààyè 736 igbọnwọ mita ni a fi ṣetilẹhin lati ọ̀dọ̀ awọn ará ni Denmark. A kó wọn wá si Lviv ni Ukraine, pẹlu awọn ọ̀wọ́ ọkọ̀ arinrin-ajo akẹ́rù 11 ti ọkọ̀ ayọkẹlẹ àdáni kan tẹle.
Lẹhin irin fun akoko gigun kan la Germany ati Poland kọja, awọn ọ̀wọ́ ọkọ̀ arinrin-ajo naa kọja lọdọ awọn aṣọbode ilẹ Ukraine pẹlu irọrun, wọn sì dé ikangun Lviv ni agogo 3:00 òru. Awọn awakọ naa rohin pe: “Ki a tó wí, ki a tó fọ̀, awọn 140 ìgìrìpá arakunrin ti péjọ lati já awọn ọkọ̀ ẹrù naa. Ki wọn tó bẹrẹ iṣẹ́ naa, awọn arakunrin onirẹlẹ wọnyi fi igbẹkẹle wọn ninu Jehofa hàn, ni gbigba adura àgbàpọ̀. Nigba ti iṣẹ naa pari, wọn parapọ lẹẹkan sii fun adura ọpẹ si Jehofa. Lẹhin gbigbadun iwa-ọlawọ awọn arakunrin adugbo naa, awọn ti wọn fi diẹ ti wọn ni funni lọna pupọ yanturu, wọn sìn wa de oju tìtì gan-an, nibi ti wọn ti gbadura lẹgbẹẹ títì ki wọn tó fi wá silẹ.
“Nigba irin-ajo gigun pada si ile ninu ọkọ̀, pupọ wà lati pada ronu lé lori—iwa-ọlawọ awọn ará ni Germany ati Poland, ati ti awọn ará wa ni Lviv; igbagbọ lilagbara wọn ati iṣarasihuwa wọn ti o kun fun adura; iwa-ọlawọ wọn ni pipese ile gbigbe ati ounjẹ nigba ti wọn ṣì wa ninu ipo aini funraawọn sibẹ; ifihàn iṣọkan ati isopọ pẹkipẹki wọn; ati ẹmi imoore wọn. Awa tun ronu nipa awọn arakunrin ati arabinrin wa ni ilé lọhun-un, awọn ti wọn ti funni lọna ọlọ́làwọ́ tobẹẹ.”
Switzerland
Ẹ̀ka ti ilẹ Switzerland bẹrẹ irohin rẹ̀ nipa fifa ọ̀rọ̀ yọ lati inu Jakọbu 2:15, 16 pe: “Bi arakunrin tabi arabinrin kan bá wà ni ìhòhò, ti o sì ṣe aini ounjẹ oojọ, ti ẹnikan ninu yin sì wi fun wọn pe, Ẹ maa lọ ni alaafia, ki ara yin ki o maṣe tutu, ki ẹ si yó; ṣugbọn ẹ kò fi nǹkan wọnni ti ara ń fẹ́ fun wọn; èrè ki ni o jẹ́?” Irohin naa si ń baa lọ pe: “Ẹsẹ Iwe Mimọ yii wá si ọkàn nigba ti Ẹgbẹ́ Oluṣakoso Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kesi wa lati pese ohun-eelo iranlọwọ fun awọn ará wa ti wọn ṣalaini.
“Lọgan ọwọ́ gbogbo eniyan dí! Ni kiki ọjọ meji pere, tọọnu ounjẹ 12 ninu 600 ìdì ẹrù ni a fi ranṣẹ si Ukraine pẹlu awọn ọkọ̀ akẹ́rù mẹta lati Germany, eyi ti a fẹ́ lati fi torẹ fun iṣẹ nibẹ. Irohin naa pe gbogbo rẹ̀ ti gunlẹ laisewu mu idunnu nla wá laaarin awọn ará wa nihin-in. Bi akoko ti ń lọ, awọn ijọ ń gba ohun eelo aṣọ, ati laipẹ ẹ̀ka wa ni o kun fọfọ fun awọn paali, apoti ikẹrusi, ati àpò! Awọn wọnni ti a kó aṣọ awọn ọmọde si ninu ní awọn ohun iṣere ọmọde diẹ ninu lati ọ̀dọ̀ awọn ọmọde ni ilẹ Switzerland fun awọn ọ̀rẹ́ ti wọn kò mọ̀ ni Ariwa jijinna. Awọn ọ̀pá ohun mimu chocolate gbọọrọgbọọrọ pupọ ni a fi si aarin awọn aṣọ ti a tò ni ipele naa pẹlu.”
Bawo ni a o ṣe kó gbogbo eyi jíṣẹ́? Irohin naa sọ pe: “Ẹka ti o wà ni France ṣe iranlọwọ fun wa nipa fifun wa ni awọn ọkọ̀ akẹ́rù meji ati awọn awakọ mẹrin. Ni afikun sii, ọkọ̀ akẹ́rù kan lati ẹ̀ka wa ati awọn mẹrin sii ti o jẹ́ ti awọn arakunrin adugbo ni a nilo fun kíkó awọn tọọnu 72 naa lọ si Ukraine.” Awọn ọkọ̀ ti wọn lọ papọ naa, ti o jẹ́ 150 mita ni gigun, gunlẹ ni ibudo ijẹrusi naa ni Lviv laisewu, nibi ti nǹkan bii ọgọrun-un awọn arakunrin adugbo ti duro lati já ẹrù awọn ọkọ̀ akẹ́rù naa. Awọn awakọ naa rohin pe iṣoro èdè kìí ṣe ohun idena rara nitori pe oju wọn fi imọriri jijinlẹ hàn.
Austria
Awọn ará ni Austria fi tọọnu 48.5 ounjẹ, 5,114 paali aṣọ, ati 6,700 bata ranṣẹ si Lviv ati Uzhgorod ni Ukraine. Wọn tun fi tọọnu 7 ounjẹ, 1,418 apoti aṣọ, ati 465 bata ranṣẹ si Belgrade, Mostar, Osijek, Sarajevo, ati Zagreb ni Yugoslavia tẹlẹri. Irohin ẹ̀ka naa sọ pe: “A ni ọkọ̀ akẹ́rù 12 ti a di ẹrù si, ti o ń rinrin-ajo 34,000 kilomita. Pupọ ninu ẹrù kíkó yii ni a ṣe lati ọwọ́ arakunrin kan ati ọmọkunrin rẹ̀ ti wọn ń ṣe òwò ọkọ̀ akẹ́rù.”
Nipa ti awọn aṣọ ti a dájọ, irohin naa ń baa lọ pe: “Awa lo Gbọngan Apejọ kan gẹgẹ bi ibudo ijẹrusi. Pupọ pupọ sii awọn ẹrù ti a di sinu ọkọ̀ akẹ́rù ń wọle, titi ti kò fi si ààyè mọ́. Gẹgẹ bi o ti ri ni ọjọ Mose, awọn eniyan naa ni a nilati dalọwọduro ni mimu wa sii. (Eksodu 36:6) Àní awọn eniyan kan ti wọn kìí ṣe Ẹlẹ́rìí fun Jehofa paapaa ṣetọrẹ owó, ‘nitori pe,’ gẹgẹ bi wọn ti wi, ‘ni ọ̀nà yii awa mọ̀ pe awọn eniyan ti wọn wà ninu aini yoo ri i gbà.’ Awa tun ri ọpọ awọn paali ofifo ti a nilo gidigidi lati ọ̀dọ̀ awọn ile-iṣẹ ayé gbà laisanwo.” Awọn arakunrin ati arabinrin ti wọn ṣe ìyàsọ́tọ̀ọ̀tọ̀ ti wọn si kó ohun gbogbo jọ jẹ lati ọmọ ọdun 9 si 80 lọjọ ori. Wọn tilẹ gbiyanju lati fi táì ọrun ati ṣẹẹti ti o bá toketilẹ aṣọ oyinbo kọọkan mu papọ.
Irohin naa wi pe: “Awọn alaṣẹ ni Austria ati ni ẹhin odi rẹ̀ ti jasi iranlọwọ gidigidi ni mimu ki oniruuru awọn ọkọ̀ ipese iranlọwọ ṣeeṣe ati ni kíkọ awọn iwe ti o ṣe pataki ki a baa lè ṣe gbogbo ipinfunni naa laisi iṣoro ti ó pọ̀.”
Italy
Lati Rome eyi ti o pọ tó tọọnu 188 ounjẹ ni a fi ranṣẹ ninu awọn ọ̀wọ́ ọkọ̀ arinrin-ajo akẹ́rù nla meji sọda si Austria, Czechoslovakia, ati Poland lọ si Soviet Union tẹlẹri. Ọkọọkan ọ̀wọ́ awọn ọkọ̀ arinrin-ajo naa ni awọn awakọ mẹfa, atọkọṣe kan, rìwáyà kan, ògbufọ̀ kan, oluṣekokaari kan, agbọunjẹ kan, dokita kan, aṣaaju ẹgbẹ́ arinrin-ajo ninu ọkọ̀ ayọkẹlẹ jeep kan, ati arakunrin kan pẹlu ile alagbeerin kan ninu.
Ounjẹ naa ni a rà lati ọwọ́ awọn ile-isẹ meje ti ń pese eelo. Ẹka naa rohin pe: “Nigba ti awọn onpese wa gbọ ète igbegbeesẹ naa, awọn diẹ ninu wọn nifẹẹ lati kopa. Ọgọrọọrun melookan ìwọ̀n kilo awọn ounjẹ ti a fi ìyẹ̀fun gbígbẹ́ ṣe ati irẹsi, ati awọn paali ikẹrusi bakan naa, ni a fi ṣetọrẹ lati ọwọ́ awọn onpese ayé. Sibẹ awọn miiran ṣetọrẹ taya ti a ń lò lori yinyin fun awọn ọkọ̀ akẹ́rù naa tabi yọnda lati dá owó.
“Awọn arakunrin ni Italy mọriri anfaani yii lati ṣeranlọwọ. Awọn ọmọde ń fẹ lati ṣetọrẹ. Ọmọdekunrin ọlọdun marun-un kan fi ọrẹ kekere kan ranṣẹ eyi ti oun lero pe yoo ra ‘agolo ẹja tuna kan ti o ga dé ofuurufu fun awọn ara ni Russia.’ Fun gbígba ipò ti o dara ni ile-ẹkọ ọmọdebinrin kan ri owó gbà lati ọ̀dọ̀ awọn òbí rẹ̀ àgbà lati fi ra ẹ̀bùn kan fun awọn òbí rẹ̀. ‘Ṣugbọn,’ ó kọwe pe, ‘nigba ti mo mọ̀ pe pupọ ninu awọn arakunrin mi kò ni gbogbo awọn ohun daradara eyi ti emi ní lati jẹ, mo ronu pe ẹbun ti o dara julọ ti emi lè rà fun awọn òbí mi ni lati ran awọn ará wọnni lọwọ.’ Oun fi iye owó ti o jọju kan sinu apoti ọrẹ. ‘Mo nireti lati maa baa lọ ni gbigba awọn ipo ti o dara ni ile-ẹkọ, ki o baa lè ṣeeṣe fun mi lati fi owó pupọ sii ranṣẹ,’ ni oun wi.” Irohin ẹ̀ka naa pari nipa sisọ pe awọn lẹta imoore ọlọyaya lati ọ̀dọ̀ awọn ará ni Ukraine, ọpọ awọn ọ̀rọ̀ imọriri awọn ará Italy, ati awọn iriri daradara ni ṣiṣeto ati jíjá awọn ipese naa ń runisoke, ń ṣinilori, wọn si ń sonipọṣọkan.
Ounjẹ fun Ẹgbẹẹgbẹrun Awọn Ayanṣaṣoju
Apejọpọ agbegbe akọkọ ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni Soviet Union tẹlẹri ni a ṣe ni Gbọngan Iṣere Kirov ni St. Petersburg ni Russia, ni June 26 si 28, 1992. Apejọpọ ti o jẹ koko idagbasoke yii, pẹlu ẹṣin-ọrọ naa “Awọn Olùtan Ìmọ́lẹ̀,” ni awọn ayanṣaṣoju ti wọn pọ̀ ju 46,200 pesẹ si lati orilẹ-ede 28. O pese anfaani miiran fun wọn lati fi ifẹ Kristian hàn fun “awọn ara.”—1 Peteru 2:17.
Awọn tọọnu ounjẹ lati Denmark, Finland, Sweden, ati awọn ilẹ miiran ni iha Iwọ-oorun Europe ni a pín lọfẹẹ fun ẹgbẹẹgbẹrun awọn ayanṣaṣoju apejọpọ lati U.S.S.R. tẹlẹri naa, lati jẹ nigba apejọpọ naa. Bi wọn ti ń fi apejọpọ naa silẹ lẹhin akoko ijokoo ti o gbẹhin, a tun fun wọn ni ìdì ẹrù ounjẹ kan pẹlu ipese fun irin-ajo wọn pada si ile.
Awọn irohin ti a mẹnukan nihin-in fihàn pe fifunni naa kò tíì maa lọ si iha ọ̀nà kan—ila-oorun—nikan. Iṣepaṣipaarọ fifunni ni o ti wà. Ounjẹ ati ohun-eelo aṣọ siha ila-oorun, bẹẹni, ṣugbọn siha iwọ-oorun awọn ọ̀rọ̀ onifẹẹ arunilọkansoke ti kò lóǹkà ati awọn iriri afungbagbọlokun ti o fi idurogangan ati iṣotitọ ẹgbẹẹgbẹrun awọn olujọsin Jehofa ni awọn ẹwadun ti ikimọlẹ ati inira hàn. Nipa bayii, iha mejeeji ti ni iriri otitọ ọ̀rọ̀ Jesu naa: “Ati funni o ni ibukun ju ati gba lọ.”—Iṣe 20:35.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
1. Lati Finland: St. Petersburg, Russia; Tallinn ati Tartu, Estonia; Riga, Latvia; Vilnius ati Kaunas, Lithuania; Kaliningrad, Russia; Petrozavodsk, Karelia
2. Netherlands: Lviv, Ukraine
3. Lati Sweden: St. Petersburg, Russia; Lviv, Ukraine; Nevinnomyssk, Russia
4. Lati Denmark: St. Petersburg, Russia; Lviv, Ukraine
5. Lati Austria: Lviv, Ukraine; Belgrade, Mostar, Osijek, Sarajevo, Zagreb (ni Yugoslavia tẹlẹri)
6. Lati Switzerland: Lviv, Ukraine
7. Lati Italy: Lviv, Ukraine
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Awọn paali aṣọ ni ẹ̀ka Sweden
Didi awọn ẹrù ipese iranlọwọ
Awọn ohun-eelo ounjẹ ninu ìdì ẹrù kan
Ẹran ìhà ati itan ẹlẹdẹ ti a fi iyọ pa lati Denmark
Awọn ọ̀wọ́ ọkọ̀ arinrin-ajo akẹ́rù 11 ti wọn wá papọ ati ọkọ̀ ayọkẹlẹ kan
Awọn ìdì ẹrù ati apoti ikaṣọsi ni ẹka Austria
Jíjá ẹrù ni Lviv, Ukraine