Iru Àwárí Yíyàtọ̀ kan ni—Bahamas
BI ÒKÚTA-ÀTẸ̀GÙN la òkun aláwọ̀-aró rẹ́súrẹ́sú já ni agbedemeji Florida ati Cuba, Bahamas gba afiyesi ti kò sí iru rẹ̀ rí lati ọ̀dọ̀ awọn ile-iṣẹ irohin ni 1992. Eeṣe? Nitori pe ọpọ julọ awọn alaṣẹ ka Bahamas si ibi ìgúnlẹ̀sí irin-ajo oju-omi ọlọ́rọ̀-ìtàn ti Christopher Columbus ni 1492, nigba ti o ṣawari ilẹ America. Ajọdun ẹẹdẹgbẹta ọdun, tabi àyájọ́ ẹlẹẹdẹgbẹta ọdun, ti gigunlẹ Columbus ni October 12 gba afiyesi awọn orilẹ-ede jakejado aye.
Bi o tilẹ ri bẹẹ, ìtara ajọdun ẹẹdẹgbẹta ọdun naa kò ṣaini awọn ipẹgan rẹ̀. Ni sisọrọ nibi Ajọ Awọn Amofin Adulawọ Agbaye ẹlẹẹkẹtalelogun, John Carew (ọjọgbọn nipa ẹkọ jakejado awọn orilẹ-ede) ni a rohin pe o sọ pe Columbus “ni ó ṣokunfa iku fun ọpọlọpọ awọn olùgbé Erekuṣu Caribbean.”—The Nassau Guardian.
Lonii, kò sí eyikeyii ninu 250,000 iye eniyan ọmọ ibilẹ Bahamas kan ti ó lè tọpasẹ ìlà ìran rẹ̀ de ọ̀dọ̀ awọn ọmọ ibilẹ alalaafia tí Columbus bá ti ó sì ṣapejuwe gẹgẹ bi “awọn eniyan ti ara wọn le koránkorán, ti wọn ni ara ati oju lilẹwa jọjọ.” Ki ni ó ṣẹlẹ si awọn ara erekuṣu wọnni? A History of the Bahamas dahun pe: “Laaarin 1500 ati 1520 gbogbo awọn olùgbé Bahamas, ti ó ṣeeṣe ki o jẹ́ nǹkan bii 20,000 awọn ẹ̀yà Lucayan, ni a kó lọ” gẹgẹ bi ẹrú lati ṣiṣẹ ni awọn ibi ìwakùsà wura ti awọn ará Spain ni Hispaniola.
Bi wọn ti tipa bayii dinku ni iye, awọn ará Bahamas ni a “ṣẹṣẹ tún ṣawari” lakọọkọ nipasẹ awọn ará Britain ati lẹhin naa nipasẹ awọn agbajọ titobi ti awọn “olufọkansin orilẹ-ede.” Awọn olufọkansin orilẹ-ede yii jẹ́ kìkì awọn ti wọn ní oko ọ̀gbìn ti wọn wá lati awọn ilẹ ti America ń ṣakoso. Bi wọn ti jẹ́ aduroṣinṣin ti Ọba Britain, wọn sá fun ogun ominira ti ń kórajọ ni agbaala-ilẹ naa nigba naa. Awọn ará Bahamas ode-oni jẹ́ ìran-àtẹ̀lé awọn atipo wọnyi ati awọn ẹrú wọn ni ipilẹṣẹ. Tẹle idasilẹlominira wọn, ọpọlọpọ ninu awọn ẹrú naa ń baa lọ lati maa lo orukọ awọn ọ̀gá wọn tẹlẹri.
Iru Àwárí Miiran Kan
Ó fẹrẹẹ ma ni iyemeji ninu pe Columbus rí araarẹ gẹgẹ bi ojihin-iṣẹ-Ọlọrun kan. A rohin rẹ̀ pe ó sọ pe: “Ọlọrun fi mi ṣe iranṣẹ ọrun titun ati ayé titun naa. . . . Ó fi hàn mi ibi ti mo ti lè rí i.” Sibẹ, iparun ti ó jẹ́ abajade rẹ̀ jẹrii lodisi i. ‘Awọn ọrun titun ati ayé titun’ òdodo eyi ti Ọlọrun ṣeleri nilati duro de iru àwárí miiran kan.—2 Peteru 3:13.
Ni 1926, Edward McKenzie ati aya rẹ̀ gunlẹ si Bahamas. Laidabi awọn olùṣàwárí ti ó ṣaaju wọn, awọn tọkọtaya onirẹlẹ ará Jamaica yii wá lati ṣàwárí awọn eniyan alailabosi-ọkan ti wọn lè fi iṣura kan fun. Awọn ni wọn jẹ́ ẹni akọkọ lati mú ihinrere Ijọba Ọlọrun wá si Bahamas. (Matteu 13:44; 24:14) Lẹhin naa ni ọdun yẹn awọn ará Jamaica meji miiran darapọ mọ wọn, Clarence Walters ati Rachel Gregory. Nigba ti ó fi maa di 1928 a ní awọn akede Ijọba meje ni Bahamas. Fun ọdun mẹrin wọn ṣiṣẹ kára ni wiwaasu ihinrere fun awọn olugbe erekuṣu naa.
Lẹhin naa ni E. P. Roberts, sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ onitara kan lati Trinidad wá. Awọn asọye itagbangba rẹ̀ ninu awọn gbọngan ipade lilokiki ṣe pupọ lati fa awọn igbagbọ èké tu ti ó sì gbún ọkan-aya ọpọlọpọ ni kẹ́ṣẹ́ pẹlu otitọ Bibeli. Ninu ọ̀kan ninu iru awọn ipade wọnyẹn ni Donald Oscar Murray jokoo si laaarin awujọ pẹlu afiysei ti a kò pin yẹlẹyẹlẹ, oun ni a wá fi tifẹtifẹ mọ lẹhin naa si D. O. Ó gba ipo iwaju ninu iṣẹ naa lẹhin-ọ-rẹhin.
Ojihin-iṣẹ-Ọlọrun Nancy Porter ranti daradara bi D. O. Murray ṣe sọrọ nipa awọn adura rẹ̀ gbigbona janjan fun iranlọwọ ninu iṣẹ iwaasu naa. Ni 1947, Nancy ati ọkọ rẹ̀, George, papọ pẹlu awọn meji miiran, di ojihin-iṣẹ-Ọlọrun tí Watch Tower Society kọ́kọ́ rán lọ si Bahamas. Ó pada ranti pe: “Ipade akọkọ ti a lọ jẹ́ ohun kan ti emi kò rò pe a o gbagbe lae. Awọn ẹni bii mẹsan-an tabi mẹwaa ni wọn wá. Arakunrin Murray ni alaga ó sì fi adura bẹrẹ, ni didupẹ lọwọ Jehofa fun àbọ̀dé awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun naa. Iranlọwọ ni a nilo, ni oun sọ, ‘a sì ti gbadura fun iranlọwọ fun ìgbà pipẹ.’ Society ti ṣeleri lati fi iranlọwọ ranṣẹ, awa sì nìyí níhìn-ín nisinsinyi. Adura naa jẹ́ eyi ti ó gúnni ni kẹ́ṣẹ́ debi pe ó mú wa nimọlara lati duro ti a kò sì fẹ́ lae lati fi ibẹ̀ silẹ.” Nisinsinyi, ni nǹkan bii ọdun 45 lẹhin naa ati laika iku ọkọ rẹ̀ sí, Arabinrin Porter ṣì ń mú ihin-iṣẹ atunni-ninu ti Ijọba naa tọ awọn olugbe erekuṣu naa lọ.
Ni pataki lati 1947 ni iṣẹ iwaasu Ijọba naa ni Bahamas ti janfaani gidigidi lati ọ̀dọ̀ awọn ojiṣẹ alakooko kikun ati awọn miiran ti wọn ti ṣebẹwo si awọn erekuṣu naa nipasẹ ọkọ̀ oju-omi. Lọpọ ìgbà wọn ti nilati tukọ̀ la awọn etikun oniyanrin lilewu ati awọn ibi igbooro ibú omi já ti wọn yoo sì wọ́dò kọjá sí etíkun lati mu ihinrere naa dé awọn ibi ìtẹ̀dó àdádó. Awọn isapa akọkọbẹrẹ wọnyẹn ń mú eso jade àní titi di oni yii paapaa.
Kókó idagbasoke kan ni a dé ni 1950. Ni December ọdun yẹn, Nathan H. Knorr, ààrẹ Watch Tower Society nigba naa, ati akọwe rẹ̀, Milton G. Henschel, ṣebẹwo si Bahamas fun ìgbà akọkọ. Knorr bá awọn eniyan 312 ti wọn kún inu Gbọngan Mother’s Club, ile onipako kekere ni opopona Jail Alley fọ́fọ́ sọrọ. Awọn eniyan melookan ti a mọ̀ daadaa wá sibẹ, eyi ti ó ní ninu mẹmba igbimọ aṣofin ati olóòtú iwe-irohin ojoojumọ kan. Ni alẹ́ ọjọ yẹn, Arakunrin Knorr kede idasilẹ ẹ̀ka ọfiisi Society ni Bahamas.
Idahunpada Bí-Ọ̀rẹ́ Awọn Olugbe Erekuṣu Naa
Awọn eniyan ẹni bí-ọ̀rẹ́ ní Bahamas ni gbogbogboo ti fetisilẹ si ihin-iṣẹ Ijọba naa. Sibẹ, ó ṣì jẹ́ ipenija lati dé ọ̀dọ̀ gbogbo wọn. Eeṣe ti eyi fi rí bẹẹ? Ó dara, bi o tilẹ jẹ pe ọpọ julọ ninu awọn eniyan naa ń gbé ni Nassau, olu-ilu naa, ati ni Grand Bahama ti ó wà nitosi, awọn miiran wà kaakiri jakejado awọn erekuṣu ńlá 15 ati awọn nǹkan bii 700 erekuṣu kekeke ati erekuṣu-ṣonṣo ti ó parapọ di awujọ erekuṣu yii.
Ni rírí aini naa, iye awọn Ẹlẹ́rìí adugbo ti ń pọ̀ sii ati ọpọlọpọ lati ibomiran ti kó lọ si awọn awujọ erekuṣu kekeke lati ṣeranlọwọ pẹlu iṣẹ iwaasu naa. Lọna ti o yẹ fun igboriyin, wọn ti ṣe bẹẹ loju ifara-ẹni-rubọ ti ó pọ̀ ati ìnáwónára. Ṣugbọn isapa wọn ni a ti san èrè fun lọpọ yanturu.
Tọkọtaya ọ̀dọ́ kan kó lọ si erekuṣu ńlá ti Andros. Bi wọn ti ń waasu lati ile de ile ni ọjọ kan, wọn bá ajeji kan lati Haiti pade. Ẹgbẹẹgbẹrun iru awọn eniyan bawọnyi ni wọn wà ni Bahamas. Ọkunrin naa tẹwọgba ikẹkọọ Bibeli inu ile kan ni kiamọsa. Ọ̀kan ni a bẹrẹ ni alẹ́ ọjọ yẹn gan-an, ní lilo ẹ̀dà iwe Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye lede Gẹẹsi ati Faranse. Ni alẹ́ ọjọ ti o tẹle, ó wá si ipade Kristian rẹ̀ akọkọ. Laipẹ, ọkunrin naa pa siga mímu tì, ó tẹsiwaju ní kanmọkanmọ, ti ó sì bẹrẹ sii nipin-in ninu iṣẹ iwaasu naa.
Ni owurọ ọjọ ti ó yẹ ki ọkunrin yii ṣeribọmi, ó rí igbohunsilẹ téèpù kan gbà lati ọ̀dọ̀ idile rẹ̀ ni Haiti, bi o tilẹ jẹ pe oun kò tii gburo wọn fun ọdun marun-un. Ki ni ohun ti wọn ni lati sọ? Wọn ṣalaye bi wọn ṣe di Ẹlẹ́rìí Jehofa. Wọn ṣalaye pe arabinrin rẹ̀ ti di aṣaaju-ọna deedee, tabi oniwaasu alakooko kikun ṣaaju akoko naa, wọn sì gbà á nimọran lati wa awọn Ẹlẹ́rìí kan ki ó sì kẹkọọ Bibeli pẹlu wọn. Láaìdéènà pẹnu, ọkunrin naa ni a ṣeribọmi fun ni ọjọ yẹn pẹlu idaniloju kikun pe oun ń ṣe ohun ti ó tọ́.
Awọn idahunpada onitara bi iru eyi ti mú ọkàn awọn Ẹlẹ́rìí adugbo layọ. Iye ti ń pọ sii laidawọ duro ninu wọn ti nawọ́gán iṣẹ gẹgẹ bi ajihinrere alakooko kikun, eyi sì ti pakun idagbasoke naa. Bẹẹ ni o ṣe rí debi pe ni 1988 iye awọn akede Ijọba ni Bahamas de 1,000. Lonii, ninu ijọ 19, nǹkan bi 1,300 akede Ijọba ni ó wà, ni ohun ti ó fẹrẹẹ jẹ gbogbo awọn erekuṣu pataki-pataki.
A Mura Wọn Silẹ fun Ọjọ-Ọla
Nitori idagbasoke wọn niti iye, awọn Ẹlẹ́rìí naa ti ní iṣoro ni riri awọn ile lilo ti agbara wọn ká ti o tobi tó fun awọn apejọpọ ọdọọdun wọn. Apejọpọ meji ni a nilati ṣe ni awọn erekuṣu ọtọọtọ lati bojuto awujọ eniyan. Nipa bayii, iwewee ni a ṣe lati kọ́ Gbọngan Apejọ papọ pẹlu ẹ̀ka ọfiisi titun kan. Iṣẹ ni a bẹrẹ ni December 1989. Ọgọrọọrun awọn oluyọnda ara-ẹni jakejado awọn orilẹ-ede ati ti adugbo fi ‘tọkantọkan ṣiṣẹ gẹgẹ bi fun Jehofa’ lori iṣẹ́ idawọle naa.—Kolosse 3:23.
Laiṣiyemeji, ikorajọpọ awọn Ẹlẹ́rìí ti ó tii pọ̀ julọ ti ó sì jẹ́ alayọ julọ ni Bahamas titi di ọjọ oni wáyé nigba ayẹyẹ iyasimimọ ẹ̀ka ọfiisi titun ati Gbọngan Apejọ naa ni February 8 ati 9, 1992. Ifojusọna onihaaragaga ń korajọ bi awọn ará ni gbogbo agbegbe awọn erekuṣu naa ti ń ṣe imurasilẹ fun iṣẹlẹ naa. Oju-ọjọ tutù dẹ́dẹ́dẹ́, ojo sì rọ̀ ni alẹ́ ọjọ ti ó ṣaaju itolẹsẹẹsẹ iyasimimọ naa. Ṣugbọn kò si ohunkohun ti ó lè mú ayọ awujọ awọn eniyan 2,714 onidunnu naa rọlẹ̀ bi John E. Barr, mẹmba Ẹgbẹ́ Oluṣakoso Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, ti ń sọ ọ̀rọ̀ iyasimimọ, ti ó ni akọle naa “Orin Ibisi Iṣakoso.”
Ọkàn wọn kún fọ́fọ́ fun ero-imọlara, ti ojú wọn sì kún fun omije imoore si Baba ọrun, Jehofa Ọlọrun, fun iṣẹlẹ iru ayọ ati idunnu bẹẹ. Awọn ti wọn wá ni wọn tubọ gberopinnu sii lati lo ẹkunrẹrẹ agbara wọn ninu iṣẹ ikọnilẹkọọ nipa tẹmi ti o ti mú ki igbooro ti a lè fojuri naa jẹ eyi ti ó pọndandan.
Yala àwárí Columbus jẹ ikorita iyipada kan fun ire awọn erekuṣu wọnyi ni ó ṣeeṣe pe yoo maa baa lọ lati jẹ́ ọ̀ràn ariyanjiyan. Bi o tilẹ ri bẹẹ, awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni Bahamas ni a sopọṣọkan ninu imọriri wọn si Ọlọrun fun pipese awọn olupokiki Ijọba tí ẹmi ifara-ẹni-rubọ wọn sun lati forila ewu àìmọ̀ ki wọn sì mu ihinrere ologo wá sibi omi kan ti o ti jẹ eyi ti a kò ṣayẹwo rẹ̀ rí nipa tẹmi. Iṣẹ wọn ati “àwárí” ti yọrisi ọrọ̀ nipa tẹmi ju eyi ti ó lafiwe fun gbogbo awọn olùwá otitọ ni Bahamas.
[Àwòrán ilẹ̀/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24, 25]
Grand Bahama
Abaco
Andros
New Providence
Nassau
Eleuthera
Erekuṣu Cat
Great Exuma
Rum Cay
San Salvador
Erekuṣu Long
Erekuṣu Crooked
Erekuṣu Acklins
Mayaguana
Little Inagua
Great Inagua
ÒKUN CARIBBEAN
FLORIDA
CUBA
[Àwọn àwòrán]
Wiwaasu ni Ọja Ègé-koriko
Wíwọ́dò kọja si etikun lati ṣajọpin ihinrere naa
Ẹ̀ka ọfiisi ni a kọ́ sori oke kan lọkankan ibi ti Gbọngan Apejọ wà