ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 4/1 ojú ìwé 24-27
  • “Awọn Olupokiki Ijọba” Rìn Lori Ọpọlọpọ Omi Guyana

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Awọn Olupokiki Ijọba” Rìn Lori Ọpọlọpọ Omi Guyana
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ìsọ̀rí
  • Lori Odò Demerara
  • Lati Gilead si Pomeroon
  • Wíwá “Ọkunrin Onílé-Ìṣọ́nà”
  • Awọn Irin-ajo Ijihin-iṣẹ-Ọlọrun Wọ Àárín Gbùngbùn Lọ
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 4/1 ojú ìwé 24-27

“Awọn Olupokiki Ijọba” Rìn Lori Ọpọlọpọ Omi Guyana

GUYANA.a Ọ̀rọ̀ Amerind yii tumọ si “ilẹ olomi.” Ẹ wo bi o ti ṣapejuwe irisi agbegbe ilẹ orilẹ-ede kanṣoṣo ti ń sọ èdè Gẹẹsi ni Guusu America yii lọna ti o yẹ wẹ́kú tó. Ilẹ naa ni ọpọlọpọ omi là kọja nibi ìwọdò wọn, eyi ti o ṣe lọ́kọlọ̀kọ lati Ilẹ-giga Guiana kọja gba aginju ilẹ olóoru kọja sinu Òkun Atlantic. Awọn ọ̀nà omi wọnyi di agbewalaaye ró fun ọpọlọpọ abuleko ati awọn oko ti wọn rí gátagàta lẹbẹẹba bèbè-odò wọn.

Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni Guyana mọ̀ pe nigba ti Jesu sọtẹlẹ pe “a o sì waasu ihinrere ijọba yii ni gbogbo ayé lati ṣe ẹ̀rí fun gbogbo orilẹ-ede,” iyẹn yoo ní wiwaasu ihinrere fun awọn eniyan ti wọn ń gbé ni awọn ipinlẹ ẹ̀bá-odò wọnyi ninu. (Matteu 24:14) Nipa bayii, fun ọpọ ọdun, awujọ awọn Ẹlẹ́rìí, ti ọpọlọpọ ninu wọn jẹ́ aṣaaju-ọna, ti lo ọkọ̀ oju-omi, ńlá ati kekere, lati rin lori awọn omi Guyana lati mú ihinrere tọ awọn eniyan naa lọ.

Lati ran iṣẹ naa lọwọ, Watch Tower Society ni Guyana ti ṣamulo, titi di oni, awọn ọkọ̀ onigi marun-un ti a ń pè ni Olupokiki Ijọba I titi de Olupokiki Ijọba V. Wọn jẹ́ ọkọ̀ oju-omi ti wọn gùn ni ìwọ̀n mita meje, aláìnílélórí, ti abẹ́ rẹ̀ rí palagun, ti a ń pè ni balahoo, ti idile Ẹlẹ́rìí kan ṣe ti wọn sì ń tọju. Ohun ni awọn Ẹlẹ́rìí adugbo maa ń fi tifẹtifẹ tọka si gẹgẹ bi Awọn Olupokiki, awọn meji akọkọ ni a mú ṣíwọ́ lẹnu iṣẹ lẹhin ti wọn ti ṣiṣẹ fun ọpọ ẹwadun. Nọmba III, IV, ati V, bi o ti wu ki o ri, ṣì ń gbesẹṣe lori awọn odò Pomeroon, Mahaica, ati Demerara.

Lori Odò Demerara

Ni Britain ati awọn apa ibikan ni Europe, ọ̀rọ̀ naa “demerara” lè mú èrò nipa omi ìrèké gbígbẹ, aláwọ̀ ilẹ̀ ti ó dabi wúrà wá síni lọ́kàn, eyi ti a kiyesi pe ó wá lati inu awọn oko ti o wà lẹbaa odò ẹlẹ́rẹ̀ ti ó kún fun iyanrin yii. Ni etídò ti ó wà ni apá iwọ-oorun, ọ̀nà ti o wá lati etikun pari sí ibi ti ọ̀gbìn ìrèké naa pari si. Rekọja iyẹn, awọn Ẹlẹ́rìí gbarale ọkọ̀ Olupokiki Ijọba naa lati mú ihin-iṣẹ alárinrin ti Ijọba Jehofa tọ awọn olugbe ẹ̀bá-odò naa wá—awọn Hindu, Musulumi, ati awọn Kristian ajórúkọ lasan.

Igbetaasi iwaasu lori odò Demerara lè tó irin-ajo ọjọ kan o sì lè pẹ́ tó ọsẹ melookan, ní lilọ lati ori ilẹ si ori ilẹ, lati kutukutu titi di àṣálẹ́. Nigba irin-ajo òrumọ́jú, awọn aṣaaju-ọna naa kìí seńjẹ ki wọn sì jẹun ninu ọkọ̀ oju-omi naa nikan ni ṣugbọn wọn ń sùn ninu rẹ̀ bakan naa. Nigba ti alẹ́ bá lẹ́, Olupokiki naa ni wọn yoo so mọ́ awọn igi ẹ̀bá odò tabi so ó mọ́lẹ̀ lẹbaa èbúté bi ọ̀kan bá wà larọọwọto. Ọ̀pá meji ti o gùn tó 2.5 mita, ni a gbé nàró ni iwaju ati ẹhin ọkọ̀ naa. Okùn kan ni a so pinpin ti a sì nà kọja awọn òpó gbọọrọ wọnyi loke, aṣọ tapólì fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀ kan ni a sì ta sori rẹ̀ lati di orule, tabi ibori. Awọn pákó onigi ni o rọpo bẹẹdi, ti aṣọ bulankẹẹti ati aṣọ fẹlẹfẹlẹ sì ṣiṣẹ gẹgẹ bi matírẹ́ẹ̀sì. Laika gbogbo iwọnyi si, oorun tete maa ń kun ojú lẹhin irin-ajo ọlọjọ gigun kan.

“Ǹjẹ́ ẹ maa ń fi omi ẹlẹ́rọ̀fọ̀ naa wẹ̀ bi?” ni a beere lọwọ awọn aṣaaju-ọna naa.

“Bẹẹkọ bi a bá rí ọgbọn miiran dá!” ni idahun naa. “Nigbakigba ti a bá kọja iṣàn omi mímọ́gaara, a o rọ omi kun inu awọn ohun-eelo ipọnmisi fun didana, mimu, ati wíwẹ̀.”

Ifarada wọn ni a san èrè fun pẹlu ọpọ awọn iriri alarinrin. Ni akoko kan, ọkunrin kan wá si ilẹ naa, ó duro yàkàtà, fọwọ́gándìí, ó sì ń wò wá pẹlu ọkàn-ìfẹ́ mimuna. “Olupokiki Ijọba V”! Ó ka orukọ ti ó wà niwaju ọkọ̀ oju-omi naa jade ketekete. “Ẹ gbọdọ jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ẹyin eniyan yii nikan ni ẹ ń lo ọ̀rọ̀ naa ‘ijọba’ ni ọ̀nà yii. Ẹ ni Gbọngan Ijọba yin ati nisinsinyi Olupokiki Ijọba.”

Lati Gilead si Pomeroon

Iṣẹ loju Odò Pomeroon ní animọ ọ̀tọ̀ lọna kan ṣá, gẹgẹ bi Frederick McAlman ṣe pada ranti. Ni ọdun kan lẹhin ikẹkọọyege rẹ̀ jade kuro ni Watchtower Bible School of Gilead ni 1970, ó wá si Charity, abúlé olódò kan ti o fi kilomita 34 jinna si òkun lápá ila-oorun Pomeroon, nibi ti awujọ awọn akede Ijọba marun-un wà.

“Fun odidi ọdun gigun marun-un, a ‘gbadun’ wíwa ọkọ̀ Olupokiki II lọ soke sodo Pomeroon ki a tó rí àlòkù ọkọ̀ ti a ń so mọ́ ẹhin ọkọ̀ oju-omi oniwọn-agbara-ẹṣin mẹfa,” ni Arakunrin McAlman rohin. “Ni títukọ̀ kọja ìgbì omi òkun naa, awa yoo waasu lọ si apá isalẹ etikun apa ila-oorun titi ti a o fi de Hackney, kilomita 11 lati ibi ti odò yẹn ti wọnu òkun. Nibẹ, awa yoo sun orun alẹ́ ti o tunilara ni ile Arabinrin DeCambra, agbẹ̀bí ti ń ṣiṣẹ ni agbegbe naa ni akoko yẹn. Ni kutukutu owurọ ọjọ keji, awa yoo maa ba irin-ajo lọ titi de ibi ti omi naa ti wọnu òkun ki a tó sọda si iha etídò apa iwọ-oorun. Nigba naa ni awa yoo dari wálé ni ririn kilomita 34 pada wa si Charity.”

Ọkọ̀ oniwọn-agbara-ẹṣin mẹfa naa ṣiṣẹsin wọn daradara fun ọdun mẹwaa. Lẹhin naa, ni 1986, a fi titun kan ti o jẹ́ oniwọn-agbara-ẹṣin 15, rọpo rẹ̀. Lẹhin ti o ti fi iṣotitọ ṣiṣẹ lori odò Pomeroon fun ohun ti o ju ọdun 21 lọ, Arakunrin McAlman lè fi imọlara aṣeyọri wo Gbọngan Ijọba titun ti a ṣẹṣẹ kọ́ ni Charity, tí ijọ ti o ni akede 43, ti wọn wá lati oke ati isalẹ odò naa ń lò nisinsinyi. Ipindọgba iye awọn eniyan ti ń wá si ipade kọja 60, ati ni Iṣe-iranti iku Jesu Kristi ti 1992, wọn ni awujọ ero 190!

Wíwá “Ọkunrin Onílé-Ìṣọ́nà”

Monday jẹ ọjọ ọja ni Charity. Nitori naa o jẹ akoko ti o dara fun wiwaasu ihinrere naa, awọn Ẹlẹ́rìí sì wà nibẹ pẹlu iwe-irohin Ilé-Ìṣọ́nà ati Ji! Ni ọjọ kan ni ibẹrẹ awọn ọdun 1970, Monica Fitzallen lati Warimuri loju odò Moruka wá si ọjà naa ó sì gba awọn iwe-irohin meji lati ọwọ Arakunrin McAlman. Ṣugbọn nigba ti o de ile, ó ti awọn iwe-irohin naa bọ abẹ́ apoti aṣọ rẹ̀.

“Wọn wà nibẹ fun ọdun meji laijẹ pe mo kà wọn,” ni Monica pada ranti. “Lẹhin naa mo ṣaisan emi kò sì lè kuro lori ibusun fun awọn akoko kan. Bi mo ti jere ilera pada, mo bẹrẹ sii ṣayẹwo gbogbo ọrọ-ẹkọ akojọpọ iwe kíkà ti o wà ninu ile lati mú ọwọ araami dí. Nikẹhin, mo ranti awọn iwe-irohin meji naa ti ń bẹ ninu apoti aṣọ mo sì bẹrẹ sii ṣayẹwo wọn.” Ó kiyesi i pe otitọ ni lọgan.

Nigba ti Monica jere ilera pada, ó beere lọwọ ọkọ rẹ, Eugene, lati wá iṣẹ ni oju odò Pomeroon ki o baa lè wá ọgbẹni ti o fun un ni awọn iwe-irohin naa rí. Eugene gbà ṣugbọn ó ṣeeṣe fun un lati rí iṣẹ ninu oko kan ni agbegbe Pomeroon fun ọsẹ kan, lati Monday si ọ̀sán Saturday.

Ni ọjọ Saturday yẹn gan-an, Monica kò tii rí ọkunrin naa ti o fun un ni awọn iwe-irohin naa sibẹ. Ni nǹkan bii ọjọ́kanrí, ó beere lọwọ ọkọ rẹ̀ bi ìgbì òkun bá lè yọnda fun wọn lati tukọ̀ lọ si Charity lati wá “ọkunrin Onílé-Ìṣọ́nà.” Gẹ́lẹ́ bi o ti pari ọ̀rọ̀ sisọ, wọn gbúròó ẹsẹ bata loju ọ̀nà wọn sì rí oju ẹlẹrin-in músẹ́ ti arabinrin kan ti ó ń bọ̀ lati fi awọn ẹ̀dà ti o ṣẹṣẹ dé kẹhin ninu awọn iwe-irohin lọ̀ wọn. “Ṣe ọ̀kan lara awọn Onílé-Ìṣọ́nà ni ọ?” ni Monica beere. Ọpọlọpọ ibeere tẹle debi pe arabinrin naa nilati pada lọ sinu ọkọ̀ oju-omi lati lọ wá ẹni kúnra. Ta ni o wá jẹ́? Ta ni ìbá tun ṣe bikoṣe Arakunrin McAlman!

Ikẹkọọ Bibeli kan nipasẹ ikọweranṣẹ ni a ṣeto. Ni akoko kukuru lẹhin naa, Monica fi lẹta ìfiṣọ́ọ̀ṣìsílẹ̀ rẹ̀ ranṣẹ si Ṣọọṣi Anglica. Ni ifesipada ó gba iwe pelebe kan lati ọ̀dọ̀ alufaa pe: “Maṣe fetisilẹ si awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Òye wọn nipa Bibeli kò jinlẹ. Emi yoo wá lati bá ọ jiroro ọ̀ràn naa.” Titi fi di òní yii, alufaa naa kò tíì wá. Ni akoko yi ná, Monica ni a baptisi ni 1975. Ni ọdun kan lẹhin naa, ọkọ rẹ̀, ti awọn ara ń fi tifẹtifẹ pe ni Uncle Eugene ni bayii, ni a tun ti baptisi lẹhin ti o ti fi tiṣọratiṣọra wá inu Iwe Mimọ. (Iṣe 17:10, 11) Bi o tilẹ jẹ pe wọn ń gbé ibi ti wọn ń fi ọkọ̀ ọlọ́pọ́n rin fun wakati 12 si ijọ ti o sunmọ wọn julọ ni Charity, wọn ń baa lọ gẹgẹ bi akede Ijọba ti o gbéṣẹ́ titi fi di òní yii.

Awọn Irin-ajo Ijihin-iṣẹ-Ọlọrun Wọ Àárín Gbùngbùn Lọ

Ni ẹnu awọn ọdun aipẹ yii Watch Tower Society ti ń ṣonigbọwọ awọn irin-ajo ijihin-iṣẹ-Ọlọrun deedee wọ àárín gbùngbùn lọ. Nipasẹ awọn ọkọ̀ oju-omi ti a ń fi awọn ẹ̀rọ atukọ wà, awọn oluyọnda ara-ẹni ti wọn muratan ti jẹgbadun mímú ihinrere tọ awọn eniyan ti ń gbé nibi awọn ile ti a pamọ fun lilo ni Amerind ati nibi awọn ẹgbẹ́ awujọ agégẹdú ati ẹgbẹ́ ti wọn wà ni adado lọ ni awọn ọ̀nà omi ti wọn wà ni àárín gbùngbùn jijinnarere. Awọn aṣaaju-ọna ní èrò itumọ ọ̀rọ̀ naa gan-an, wọn ní anfaani mímú ‘orukọ Jehofa’ ti ń gba iwalaaye là lọ si awọn agbegbe jijinnarere wọnyi fun ìgbà akọkọ rí. (Romu 10:13-15) Awọn ará nilati farada ọpọlọpọ inira, nigba miiran wọn yoo tukọ loju odò naa fun odidi ọjọ mẹta gbáko lati dé diẹ ninu awọn ibi wọnyi. Ṣugbọn èrè naa tobẹẹ ó jù bẹẹ lọ.

Ọdọkunrin kan, ti o jẹ́ onisin Pentikosta ti ń gbé lẹbaa ẹgbẹ́ awujọ agégẹdú ti Kwebanna loju Odò Waini, ni a bá pade ni ìgbà irin-ajo ijihin-iṣẹ-Ọlọrun akọkọ si agbegbe yẹn ni July 1991. Nigba ibẹwo ti o tẹle ni October, ikẹkọọ Bibeli kan ni a bẹrẹ. Fun ìgbà akọkọ, ó rí i lati inu Bibeli tirẹ̀ pe Jehofa ni orukọ Ọlọrun, pe Jesu kìí ṣe Olodumare, ati pe ẹkọ-igbagbọ Mẹtalọkan kò bá Iwe Mimọ mu. (Orin Dafidi 83:18; 1 Korinti 11:3) Ìtara rẹ̀ pọ̀ tobẹẹ debi pe, lẹhin ti awọn ará naa lọ, ó kó awọn onisin Pentikosta ẹlẹgbẹ rẹ̀ jọ ó sì bẹrẹ sii fi otitọ Bibeli nipa Jehofa Ọlọrun ati Jesu Kristi hàn wọn lati inu Bibeli tiwọn funraawọn. Nigba ti ọpọ julọ kọ ẹhin wọn si otitọ, ó pinnu pe akoko tó fun oun lati kọwe ki oun sì jade kuro ninu “Babiloni Ńlá.” (Ìfihàn 18:2, 4) Nigba ti awọn ará pada wá lati wò ó ni February 1992, ó sọ ohun ti o ti ṣẹlẹ fun wọn ó sì fikun un pe: “Mo fẹ lati darapọ mọ yin. Mo fẹ lati di ọ̀kan lara awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Mo fẹ lati kọ́ awọn eniyan ni otitọ!”

Awọn iriri bi iyẹn ṣeranwọ lati jẹ ki awọn ará maa baa lọ ninu iṣẹ ti ń peninija yii. Awọn wọnni ti wọn lọ si irin-ajo ijihin-iṣẹ-Ọlọrun gbọdọ fi fàájì ile rubọ, wọn di ẹni ti a ṣí kalẹ si awọn aisan bi ibà, ki wọn sì farada awọn ewu igbesi-aye oko. Ṣugbọn awọn wọnni ti wọn wà ni ile bakan naa ń ṣe irubọ pẹlu. Awọn idile ń ṣalairi awọn ololufẹ wọn, nigba miiran fun ọpọ ọsẹ lẹẹkan. Awọn ijọ nilati wà laisi awọn alagba wọn ati awọn ọdọkunrin miiran gẹgẹ bi o ti jẹ pe, ninu awọn ọ̀ràn kan, kìkì arakunrin kan ni a fi silẹ nile lati bojuto awọn aini ijọ. Sibẹ, ayọ ati iṣiri wo ni ó wà nibẹ nigba ti ijọ bá gbọ́ awọn iriri arunisoke wọn nigba ti wọn bá pada dé! Ti a bá fiwera pẹlu ayọ naa, awọn ohun ti wọn fi rubọ dabi ohun ti kò jamọ nǹkankan.

Awọn olupokiki Ijọba ti wọn rìn lori ọpọlọpọ omi Guyana pẹlu ihinrere ń gbadun iriri ti o tayọ nitootọ. Papọ pẹlu awọn oṣiṣẹ ẹlẹgbẹ wọn yika-aye, wọn ń fi igboya ati imuratan “rú ẹbọ iyin si Ọlọrun nigba gbogbo, eyiini ni eso ètè wa, ti ń jẹwọ orukọ rẹ̀.”—Heberu 13:15.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Oun ni a mọ̀ si British Guiana tẹlẹri, orukọ naa ni a yipada si Guyana lẹhin ti orilẹ-ede naa gba ominira kuro lọwọ Britain ni 1966.

[Àwọn àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 24]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

HONDURAS

NICARAGUA

COSTA RICA

PANAMA

VENEZUELA

COLOMBIA

GUYANA

SURINAME

FRENCH GUIANA

BRAZIL

BOLIVIA

ÒKUN ATLANTIC

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26, 27]

Apá òsì: Jijẹrii ni ọjọ ọjà

Lókè: Jijiroro ihinrere lori Odò Demerara

Apá ọ̀tún lókè: Awujọ ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ti wọn ń tukọ pada si àgọ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́