Rírí Ọrọ̀ Tootọ Ni Hong Kong
HONG KONG jẹ́ ibikan ti owó pupọ ti ṣeérí ni akoko kukuru—bi gbogbo awọn nǹkan bá ṣẹnuure fun ọ. Ní ẹnu 40 ọdun ti o kọja tabi ti o fẹrẹẹ tobẹẹ, orilẹ-ede ti a ń ti ọwọ́ awọn ara Britain ṣakoso yẹn ti dagbasoke lati ori etikun ti kò ni igbokegbodo pupọ si ti ọlọ́rọ̀-ajé ti o ṣe pataki gidi kan kìí ṣe kìkì ni Southeast Asia nìkan ṣugbọn ninu ipo ọ̀ràn iṣẹ-aje kari-aye pẹlu.
Iye owo-ori ti o mọniwọn fa awọn olùdókòwò orilẹ-ede miiran mọra ó sì pese iṣiri fun awujọ oṣiṣẹ alakitiyan ti a rí laaarin awọn million mẹfa olugbe Hong Kong. Eyi ti o tun dara, pẹlu, ni ibi ti ó wà gẹgẹ bi ẹnu-ọna laaarin iha guusu China ati ẹkun Asia-oun-Pacific ati rekọja rẹ̀. Pẹlu eto irinna ati ijumọsọrọpọ ode-oni ati ètò ọjà àtàpọ̀ ati alátùn-ún-tà ti o sokọ́ra, Hong Kong ni a ti mú gbaradi lati dahun ní kánmọ́ si awọn ibeere iṣowo jakejado awọn orilẹ-ede.
Ikẹsẹjari ọrọ̀-ajé ti fun Hong Kong ni ọ̀kan lara awọn ọpa-idiwọn giga julọ ni ayé. Bi o ti wu ki o ri, gbogbo awọn aasiki ohun ti ara naa ha ti mú itẹlọrun ati ayọ pipẹtiti wá fun awọn olugbe Hong Kong bi? Bẹẹkọ, ṣugbọn awọn kan ti wá ọrọ̀ iru eyi ti o sàn jù kan ní àwárí.
Wọn Rí Ọrọ̀ Tẹmi
Lara awọn wọnni ti wọn ti rí ọrọ̀ tẹmi ti kò ṣeediyele ni Alfred ọmọ ibilẹ Hong Kong. Ó ní iṣẹ igbesi-aye kan ti o kẹ́sẹjárí gẹgẹ bi alaboojuto iparapọ iṣẹ-aje ńlá jakejado awọn orilẹ-ede ti o ni orile-iṣẹ ni Britain. Bi ọpọ awọn miiran ni Hong Kong, gongo rẹ̀ ninu igbesi-aye ni lati ṣiṣẹ kó owó rẹpẹtẹ jọ, lati ní ile tirẹ̀ funraarẹ, lati jẹun daadaa, ati lati gbé igbesi-aye ti ó rọ̀sọ̀mù. Pẹlu ipo rẹ̀ ati owó tí ń wọle fun un, ó jọbi ẹni ti ọwọ́ rẹ̀ ti tẹ gbogbo iyẹn. Ṣugbọn ó ha layọ bi? “Mo kẹkọọ nipasẹ iriri pe owó niti gidi ní ààlà tirẹ̀,” ni Alfred kédàárò. Oun maa ń ṣaniyan lemọlemọ nipa bi owó ti oun ti ń tùjọ yoo ti tọ́jọ́ tó bi oun bá padanu iṣẹ oun. Nigba ti o tubọ ya akoko pupọ sii sọtọ fun iṣẹ rẹ̀, awọn iṣoro idile bẹrẹ sii dide. Aya rẹ̀, Emily, ni ọkàn rẹ̀ bajẹ nigba ti ọmọkunrin wọn déédé fò ṣánlẹ̀kú. “Mo fẹ́ lati mọ ibi ti ó wà kí ń baa lè ṣe ohun kan lati ràn án lọwọ,” ni obinrin naa sọ. Niwọn bi kò ti lè ṣe ohunkohun, ó di ẹni ti inu rẹ̀ bajẹ gidigidi.
Justina padanu baba rẹ̀ nigba ti ó ṣì wà ni ọmọ kekere. Ṣugbọn nipa ṣiṣiṣẹ kára ó kẹkọọyege kuro ni Yunifasiti Hong Kong ti o gbayì. Eyi ni o jẹ́ ki o rí iṣẹ ijọba kan. Ní èdè Cantonese eyi ni a ń pè ni gum fan woon, abọ́ irẹsi oniwura kan—aabo iṣẹ ati owó ti o jọjú. Sibẹ, Justina kò layọ bẹẹ ni kò nitẹẹlọrun. Ó sábà maa ń ṣe kayefi nipa ohun ti ète igbesi-aye jẹ́ ati ohun ti ọjọ-ọla yoo mú dani. Ọkọ rẹ̀, Francis, tun nimọlara pe igbesi-aye kò ni ète. Ó dabi apá ti kò jámọ́ nǹkankan ninu ẹ̀rọ ńlá kan, eniyan lásán kan, ti a gbámú ninu ọ̀nà iṣiṣẹ deedee ti kò lopin kan.
Lẹhin naa ni ti Ricky, oluṣaboojuto iṣẹaje kan. Bi o tilẹ jẹ pe oun ń rí owó ti o pọ rẹpẹtẹ, ó bẹrẹ sii ri apa keji igbesi-aye—ibaradije aláìláàánú laaarin awọn oṣiṣẹ ẹlẹgbẹ rẹ̀ ati awọn iṣoro ninu idile rẹ̀. Owó kò lè ràn án lọwọ lati yanju awọn iṣoro wọnyi. Gẹgẹ bi ironu iyawo rẹ̀, Wendy, iṣẹ igbesi-aye ti o lọ́wọ̀, owó jaburata, ati gbigbe ninu ẹgbẹ́ awujọ ti o duro deedee niti iṣelu tumọsi aabo. Ṣugbọn bawo ni igbesi-aye rẹ̀ ti o jẹ eyi ti o laabo yoo ti pẹ́ tó? Iyẹn dà á laamu nitori ijotiitọ gidi iku mú un ki o maa nimọlara pe igbesi-aye oun kò ni itumọ ó sì jẹ́ eyi ti kò ní ète ninu.
David ní ìtàn tirẹ̀ lati sọ. Imọ-ẹkọ yunifasiti rẹ̀ jẹ ki ó rí iṣẹ daradara ati aabo iṣunna-owo, ṣugbọn kò rí itẹlọrun kankan. Eeṣe? Oun ni a rì wọnu ẹfoluṣọn ati ọgbọn-imọ-ọran, ó sì gbagbọ pe igbesi-aye kò lọ rekọja iwalaaye isinsinyi. David ronu pe oun kò ní ohunkohun lati wọna fun, gbogbo awọn ọrọ̀ ohun ti ara rẹ̀ kò sì dí i lọwọ lati maṣe nimọlara ainiranlọwọ.
Bi o tilẹ jẹ pe awọn ẹnikọọkan wọnyi ní ohun ti o jẹ́ ipo atilẹwa yiyatọsira, ohun kan wọ́pọ̀ fun wọn. Gbogbo wọn ni ọwọ́ wọn ti tẹ ohun ti wọn rò pe yoo mú igbesi-aye alayọ ati itẹlọrun wá. Bi o ti wu ki o ri, nigba ti wọn dori koko naa nibi ti wọn ti rò pe àlá wọn yoo ní imuṣẹ, igbesi-aye wọn ṣófo.
Níní Ọrọ̀ Lọdọ Ọlọrun
Ipo Alfred, Justina, ati awọn miiran ti a ṣẹṣẹ mẹnukan tán yii fi pupọpupọ dabi ti ọkunrin ọlọ́rọ̀ inu owe-akawe Jesu. Ó “to iṣura jọ fun araarẹ̀, ti kò si ni ọrọ̀ lọdọ Ọlọrun.” (Luku 12:21) Lọna ti o muni layọ, bi o ti wu ki o ri, wọn rí ohun kan ti ó sàn jù—igbesi-aye kan ti ó kún fun ọrọ̀ gidi. Awọn wọnni ti wọn fọkanfẹ ayọ ati itẹlọrun tootọ kò gbọdọ “gbẹkẹle ọrọ̀ aidaniloju, bikoṣe lé Ọlọrun alaaye, ti ń fi ohun gbogbo fun wa lọpọlọpọ lati lò.” (1 Timoteu 6:17) Bẹẹni, wíwá lati mọ Ọlọrun tootọ naa, Jehofa, ati fifi igbẹkẹle wọn sinu rẹ̀ mú iyatọ wá ninu igbesi-aye ọkọọkan awọn eniyan wọnyi. Ẹ jẹ ki a wo bi gbogbo eyi ti ṣe wáyé.
Alfred ati Emily ni a sọ di alainiranlọwọ nigba ti ọmọkunrin wọn déédé fò ṣánlẹ̀kú, ti gbogbo awọn ohun-ìní ti ara wọn kò sì lè pẹ̀tù sí ìrora wọn. Wọn lọ si ṣọọṣi ṣugbọn wọn nimọlara òfo ati àìnítẹ̀ẹ́lọ́rùn sibẹ. Lẹhin naa ni ọ̀kan lara awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa wá sẹnu ọ̀nà wọn ti ó sì beere pe: “Ki ni ireti eniyan fun ọjọ-ọla?” Alfred fesipada ni ibamu pẹlu ohun ti a ti sọ fun un ni ṣọọṣi nipa ọrun ati ọrun-apaadi. Bi o ti wu ki o ri, lati inu Bibeli a fi hàn án pe awọn oku “kò mọ ohun kan” awọn wọnni ti wọn sì wà ninu iranti Ọlọrun wà ninu iboji gbogbo araye lapapọ ti wọn ń duro de ajinde. (Oniwasu 9:5, 10; Johannu 5:28, 29) Eyi dun bi ohun ti o bá ọgbọ́n mu ti o sì bá ironu rere mú fun Alfred. Nisinsinyi ó wá mọ̀ pe kìí ṣe pe ọmọkunrin oun ń jiya nibikan ṣugbọn pe ó ń sun ninu oorun iku, pẹlu ireti pe boya a jẹ́ di ẹni ti a tun mu ṣọkan pẹlu idile rẹ̀ nipasẹ ajinde kan. Ẹ wo iru itunu ati itura ti eyi jẹ́! Bi akoko ti ń lọ Alfred ati aya rẹ̀ tẹwọgba ikẹkọọ Bibeli inu ile kan wọn sì mú ọ̀nà ti wọn lè gbà di ọrọ̀ gidi tí Bibeli pese mú gírígírí pọ̀n.
Justina ni a dà lójúrú nigba ti o kuna lati rí ẹmi imuratan ti o le rannilọwọ lati bikita fun awọn eniyan laaarin awọn oṣiṣẹ ẹlẹgbẹ rẹ̀. Onisin Katoliki paraku kan ni, oun ni a mú jakulẹ nigba ti ó ṣakiyesi pe alufaa yoo mu siga yoo sì lọ sibi ijó, gan-an gẹgẹ bi awọn ọkunrin miiran. Lẹhin naa ni ó ṣe alabaapade awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti ó sì bẹrẹ sii rí awọn idahun Iwe Mimọ ti ń tẹnilọrun si ọpọlọpọ ibeere. Alufaa kò rí nǹkankan fun un bikoṣe èrò àdáni tirẹ̀, kò sì tíì ṣí Bibeli fun ọdun 16, àní bi o tilẹ jẹ pe oun jẹ́ olùre ṣọọṣi deedee ti ó sì ti maa ń ṣiṣẹ gẹgẹ bi mẹmba kan ninu ṣọọṣi fun ọdun mẹwaa.
Bi awọn Ẹlẹ́rìí naa ti ń ba Justina ati ọkọ rẹ̀, Francis kẹkọọ Bibeli, iṣọkan wọn kari-aye ninu igbagbọ ati iṣesi wú ọkọ naa lori. Francis di ẹni ti a mú ọ̀rọ̀ dálójú pe Ọlọrun jẹ́ gidi. Ó ṣetan, kìkì Ọlọrun alaaye tootọ, ni ó lè lo iru agbara-idari bẹẹ lori awujọ awọn eniyan jakejado awọn orilẹ-ede. Awọn tọkọtaya meji yii ti layọ tó pe awọn ti rí ọrọ̀ gidi!
Ricky ati Wendy mọ̀ pe awọn nilati ṣe ohun kan nigba ti wọn rí i pe awọn iṣoro ara-ẹni wiwuwo ń yi awọn po. Niwọn bi awọn mejeeji ti ni ifarakanra pẹlu awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni ìgbà atijọ, wọn lo idanuṣe lọtọọtọ lati wá wọn lẹẹkan sii. Nipasẹ isapa onifọkansi, kìí ṣe kìkì ojutuu ti o ṣeemulo si awọn iṣoro wọn nikan ni Ricky ati Wendy rí ṣugbọn wọn tun rí ọrọ̀ tootọ ninu ipo-ibatan ara-ẹni pẹlu “Ọlọrun alayọ naa,” Jehofa.—1 Timoteu 1:11, NW.
Igbesi-aye David pẹlu yipada nigba ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ké sí i. Pẹlu èrò ọkàn naa lati tudii aṣiiri aṣiṣe wọn, ó gbà pe ki wọn pada tọ oun wá. Bi akoko ti ń lọ, bi o ti wu ki o ri, oju rẹ̀ ni a là, nitori pe ó bẹrẹ sii rí i pe Bibeli péye niti imọ-ijinlẹ, niti ọ̀rọ̀-ìtàn, ati lọna miiran. Gbogbo eyi ran David lọwọ lati wo Bibeli gẹgẹ bi iwe otitọ kan ti o fun un ni ète tootọ ninu igbesi-aye. Ẹ wo iru iyipada alayọ ati asọnidọlọrọ ti eyi jẹ́ fun un!
Ríran Ọpọ Awọn Miiran Lọwọ Lati Rí Ọrọ̀ Tootọ
Ninu iye awọn olùgbé Hong Kong tí o pọ̀-bíi-rẹ́rẹ, Alfred, Emily, Justina, Francis, ati awọn miiran ti a mẹnukan nihin-in wulẹ jẹ́ diẹ lara awọn wọnni ti wọn ti rí ọrọ̀ tootọ ti otitọ Bibeli ati igbagbọ ninu Jehofa Ọlọrun ni. Ní 1992 iye ti o sunmọ 2,600 awọn Ẹlẹ́rìí ti Jehofa lo aropọ iye wakati ti o fẹrẹẹ tó 900,000 ni kíkésí awọn eniyan Hong Kong ati didari awọn ikẹkọọ Bibeli inu ile ti ó lé ni 3,800 pẹlu wọn. Bi o ti wu ki o ri, iṣisẹrin igbesi-aye ni Hong Kong yára, ọwọ́ awọn eniyan sì dí. Ní afikun si lilọ lati ile de ile, nitori naa, awọn olupokiki Ijọba ń ní aṣeyọri gidigidi ninu ijẹrii opopona. Wọn tun lọ sọdọ awọn eniyan ni ibi iṣẹ wọn nipa kíkésí awọn oṣiṣẹ ọfiisi, oluṣabojuto ṣọọbu, awọn àgbẹ̀, ati awọn ọkunrin ti ń bọ̀ lati odò ẹja pipa ni Òkun South China.
A lè sọ nitootọ pe “ikore pọ̀, ṣugbọn awọn alagbaṣe kò tó nǹkan” ni Hong Kong. (Matteu 9:37) Ní lọ́ọ́lọ́ọ́, ipin awọn Ẹlẹ́rìí si iye awọn eniyan olugbe jẹ́ 1 si 2,300. Ní mimọriri ijẹkanjukanju iṣẹ ikore naa, iye ti o fẹrẹẹ tó 600 ninu 2,600 awọn akede Ijọba nibẹ ni wọn jẹ́ aṣaaju-ọna, tabi oniwaasu ihinrere alakooko kikun. Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni Hong Kong, bi awọn wọnni ti wọn wà ní ibomiran, mọ daju pe “ibukun Oluwa ní múniílà.” (Owe 10:22) Fun idi yii, wọn ń ṣiṣẹ kára lati ran ọpọlọpọ awọn eniyan sii lọwọ ninu ẹgbẹ́-àwùjọ alaasiki yẹn lati rí ọrọ̀ tootọ.
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 23]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
ÒKUN SOUTH CHINA
CHINA
Hong Kong
Kilomita
Ibusọ
15
15