ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 6/15 ojú ìwé 23-27
  • Jehofa Yí Akoko ati Ìgbà Pada ní Romania

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jehofa Yí Akoko ati Ìgbà Pada ní Romania
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ìsọ̀rí
  • Ìtàn Gígùn Kan
  • Awọn Ìnira Ń Baa Lọ
  • Wiwaasu Ní Gbangba Lẹẹkan Sii
  • Awọn Ohun Nla Ń Ṣẹlẹ Ní Awọn Ibi Kekere
  • Awọn Aṣaaju-Ọna Akanṣe La Ọ̀nà Silẹ
  • Awọn Ifojusọna Agbayanu Níwájú
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 6/15 ojú ìwé 23-27

Jehofa Yí Akoko ati Ìgbà Pada ní Romania

AFẸ́FẸ́ iyipada fẹ́ la iha Ila-oorun Europe kọja ni 1989. Ní nǹkan bi oṣu diẹ, awọn ijọba ti wọn ti figbakan ri dabi odi agbára alaiṣeeṣẹgun wá ń ṣubu lulẹ tẹlera. Awọn iyipada ẹgbẹ-oun-ọgba, iṣunna-owo, ati, eyi ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lọkan-ifẹ sí julọ, awọn iyipada isin waye pẹlu iyipada oṣelu. Ní orile-ede kan si omiran, ni a ti ka iṣẹ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa sí labẹ ofin, ominira lati maa bá igbokegbodo onisin wọn lọ ni a dá pada fun wọn.

Ṣugbọn o farahan bi ẹni pe awọn nǹkan yoo yatọ ni Romania. Ijọba naa ní iru ipá alagbára ti o ṣe gírígírí tobẹẹ lori awọn eniyan naa ti o fi dabi ẹni pe awọn afẹ́fẹ́ iyipada naa yoo ni ipa ti kò tó nǹkan. Bi awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti wọn wà nibẹ ti gbọ́ nipa ohun ti ń ṣẹlẹ ni awọn orilẹ-ede iha Ila-oorun Europe, wọn bi araawọn leere pe, ‘Awa yoo ha lè gbadun ominira ijọsin rara ṣaaju Armageddoni bi?’ Ọkàn-àyà wọn ń yánhànhàn fun akoko naa nígba ti wọn yoo lè pejọpọ ni awọn ipade Kristian pẹlu awọn arakunrin ati arabinrin wọn nipa tẹmi, ki wọn waasu ihinrere naa ni gbangba, ki wọn sì kẹkọọ awọn itẹjade Bibeli wọn ni gbangba, laini maa fi wọn pamọ ni gbogbo ìgbà. Gbogbo iwọnyẹn dabi àlá kan lasan.

Àlá naa sì wá ṣẹ! O ṣẹlẹ ni December 1989. Si iyalẹnu gbogbo eniyan, iṣakoso Ceauşescu ni a tì lulẹ̀ lojiji. Lojiji, awọn Kristian wọnyẹn rí ìtura alaafia. Ní April 9, 1990, a ka iṣẹ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa sí labẹ ofin gẹgẹ bi eto-ajọ isin kan ni Romania. Jehofa ti yí akoko ati ìgbà pada fun awọn 17,000 Ẹlẹ́rìí alaapọn ti wọn wà.—Fiwe Danieli 2:21.

Ìtàn Gígùn Kan

Ní 1911, Carol Szabo ati Josif Kiss pada si Romania lati United States, nibi ti wọn ti kẹkọọ otitọ Bibeli ti wọn sì ti ya igbesi-aye wọn si mímọ́ si Jehofa lati ṣe ifẹ-inu rẹ̀. Wọn fẹ́ lati ṣajọpin ihinrere naa pẹlu awọn eniyan orilẹ-ede wọn. Nígbà ti wọn wà ni Romania, lẹsẹkẹsẹ ni wọn bẹrẹ sii waasu. Nígbà ti Ogun Agbaye I bẹ́ silẹ, a faṣẹ ọba mu wọn nitori ohun ti wọn ń ṣe. Sibẹ, awọn eso Ijọba naa ti wọn ti gbìn bẹrẹ sii mu iyọrisi wá. Ní 1920, nígba ti a ṣatunto iṣẹ naa, nǹkan bii 1,800 awọn akede Ijọba ni wọn wà ni Romania.

Ní akoko yẹn ẹmi iṣọtẹ ti o ru jade ni awọn ilẹ Balkan ni a ń nimọlara rẹ̀ siwaju ati siwaju sii ni Romania, ti awọn idiwọ sì wọ́pọ̀. Laika awọn akoko lilekoko naa si, awọn ara wa nipa tẹmi ń ba iṣẹ naa lọ. Ní 1924 Watch Tower Society ṣí ọfiisi kan si nọmba 26 Opopona Regina Maria ni Cluj-Napoca lati bojuto iṣẹ naa ni Romania, Hungary, Bulgaria, Yugoslavia, ati Albania.

Àmọ́ ṣáá ipo oṣelu ibẹ di eyi ti o lekoko, ati pe ni afikun si awọn iṣoro lati ọ̀dọ̀ awọn alaṣẹ, iṣoro wà ninu eto-ajọ naa. Iwe 1930 Year Book rohin pe: “Nitori aiṣotitọ ẹni ti Society rán si ibẹ, awọn ọ̀rẹ́ naa ni a ti fọ́nká ti a sì gbo igbẹkẹle wọn jìgìjìgì. Society ti ń woye fun awọn anfaani lati tun mú iṣẹ naa sọji lẹẹkan sii ni ilẹ yẹn, ṣugbọn awọn alaṣẹ adugbo ka ohun gbogbo leewọ, gbogbo wa sì gbọdọ duro titi di ìgbà ti Oluwa bá ṣí ọ̀nà ti o tubọ wọ̀ silẹ.” Lẹhin naa, ni 1930, Martin Magyarosi, Ẹlẹ́rìí ọmọ ilẹ Romania kan ti o ṣeribọmi ni 1922, ni a yansipo gẹgẹ bi iranṣẹ ẹ̀kà titun, ọfiisi naa ni a wá gbé lọ si nọmba 33 Opopona Crişana, Bucharest lẹhin naa. Lẹhin ọpọlọpọ igbiyanju, nigbẹhin-gbẹhin a fun Society ni aṣẹ idanimọ gẹgẹ bi àjọ-ẹgbẹ́ kan labẹ ofin ni Romania ni 1933.

Awọn Ìnira Ń Baa Lọ

Awọn idanwo likekoko ń baa lọ lati wá sori awọn Ẹlẹ́rìí ni Romania. Iwe 1936 Year Book rohin pe: “Laisi àníàní kò si apa ilẹ̀-ayé ti awọn ará ti ń ṣiṣẹ pẹlu iṣoro giga ju Romania lọ.” Laika gbogbo ipọnju naa si, irohin iṣẹ-isin 1937 mẹnukan awọn ijọ 75 ti wọn ni akede 856 ni Romania. Nibi Iṣe-iranti, awọn 2,608 ni wọn pésẹ̀.

Bi Ogun Agbaye II ti ń bọ̀, kò ṣaikan Romania. Ní September 1940, Ọgagun Ion Antonescu gba agbára iṣakoso ti o sì bẹrẹ iṣakoso kan ti o farajọ ti Hitler. Awọn ohun ìpayà wọ́pọ̀. Ọgọrọọrun awọn ara wa ni a fi àṣẹ ọba mú, ti a nà, ti a sì daloro. A fi àṣẹ ọba mú Arakunrin Magyarosi ni September 1942, ṣugbọn o ṣì ṣeeṣe fun un lati ṣabojuto iṣẹ fun Transylvania lati inu ọgbà ẹ̀wọ̀n.

Inunibini ń baa lọ nígbà ti awọn ikọ̀ Hitler la orilẹ-ede naa kọja ni 1944. Irohin kan lati Bucharest ṣapejuwe ipo awọn nǹkan labẹ iṣakoso Nazi: “Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni orilẹ-ede yii ni a ń ṣẹ́ níṣẹ̀ẹ́ lọna lilekoko. A fi wọn sẹwọn pẹlu awọn oṣelu Kọmunist, awọn alufaa ti wọn kọwọti Hitler fẹsun kàn wọn pe wọn buru ju awọn oṣelu Kọmunist lọ, pupọ ninu wa ni a dájọ ẹ̀wọ̀n ọdun 25, tabi ẹ̀wọ̀n gbére fun, tabi dá lẹ́bi iku.”

Nikẹhin ogun naa dopin, nígbà ti o si di June 1, 1945, ọfiisi Society ti o wà ni Bucharest pada ṣẹnu igbokegbodo. Laika iṣoro riri bébà si, awọn oṣiṣẹ onifọkansin tẹ ẹ̀dà iwe-pẹlẹbẹ ti o ju 860,000 lọ ati 85,000 ẹ̀dà Ilé-Ìṣọ́nà èdè Romania ati Hungary. Jehofa bukun iṣẹ aṣekara wọn ni jingbinni. Nigba ti o fi maa di 1946 iye ti o sunmọ 1,630 awọn ẹni titun ni a ti baptisi. Koko itẹnumọ ọdun yẹn ni apejọpọ ti orilẹ-ede naa ti a ṣe ni Bucharest ni September 28 ati 29. Awọn alufaa sa gbogbo agbára wọn lati ṣayọnusi ki wọn sì dá apejọpọ naa duro, ṣugbọn wọn kò ṣaṣeyọri, awọn eniyan ti wọn sì fẹrẹẹ tó 15,000 ni wọn wá sí asọye itagbangba naa. O jẹ́ ìgbà akọkọ ti awọn ará ni Romania ti lè ṣe iru apejọpọ bẹẹ.

Society rán Arakunrin Alfred Rütimann lati ẹka ti Swiss si Romania. Ní August 1947 o ni anfaani lati bá awọn Ẹlẹ́rìí ti iye wọn pọ̀ tó 4,500 ni awọn ibi 16 sọrọ, ni gbigbe wọn ró fun ohun ti o wà niwaju. Laipẹ awọn ikimọlẹ yoo tun pada wá sori awọn ará, ni ọ̀tẹ̀ yii lati ọ̀dọ̀ iṣakoso oṣelu Kọmunist. Ní February 1948 awọn alaṣẹ ka iwe títẹ̀ ati igbokegbodo iwaasu wa leewọ. Lẹhin naa, ni August 1949, ọfiisi ti o wà ni nọmba 38 Opopona Alion ni awọn onísùnmọ̀mí kó. Tẹle eyi, ọpọ awọn ará, titi kan Arakunrin Magyarosi, ni a fi àṣẹ ọba mú. Lọ́tẹ̀ yii, a fẹsun kíkó awọn eniyan jọ fun anfaani ara-ẹni kàn wọn, a rán wọn lọ si ẹ̀wọ̀n tabi awọn àgọ́ iṣẹ́. Fun 40 ọdun ti o tẹlee, a ka iṣẹ naa leewọ, awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa sì jiya gan-an. Awọn iṣoro ti ọ̀tá sún awọn eniyan si ninu eto-ajọ naa dakun idaamu naa. Nikẹhin, a bi iṣakoso Ceauşescu ṣubu ni 1989, wọn sì dominira! Ki ni wọn yoo ṣe nisinsinyi pẹlu ominira wọn?

Wiwaasu Ní Gbangba Lẹẹkan Sii

Awọn Ẹlẹ́rìí kò fi akoko kankan ṣofo. Lẹsẹkẹsẹ ni wọn bẹrẹ sii waasu lati ile de ile. Ṣugbọn eyi kò rọrun fun awọn ti wọn ti fi igboya ṣe iṣẹ naa fun ọpọlọpọ ọdun labẹlẹ nipa ijẹrii alaijẹ-bi-aṣa. Ojora mú wọn nisinsinyi ti wọn lè waasu ni gbangba. Pupọ ninu wọn kò tii ṣe eyi rí, ìgbà ti o si kẹhin ti eyikeyii ninu wọn ti waasu lati ile de ile jẹ ni opin awọn ọdun 1940. Iru iyọrisi wo ni wọn ń ní? Ẹ jẹ ki a wò ó.

Ibi ti o yẹ lati bẹrẹ ni olu-ilu naa, Bucharest, eyi ti o ní 2.5 million awọn olùgbé. Ní ọdun meji sẹhin, ìjọ mẹrin péré ni o wà ni ilu-nla naa. Nisinsinyi ìjọ mẹwaa ni o wà, ti awọn 2,100 si wá si ibi ajọdun Iṣe-iranti ti ọdun 1992. Pẹlu ọpọlọpọ awọn ikẹkọọ Bibeli inu ile ti ń tẹsiwaju ti a ń ṣe, awọn ijọ titun diẹ sii ni a lè dasilẹ.

Craiova jẹ́ ilu-nla kan ti o ni iye ti o tó 300,000 awọn olùgbé, ni apa iha guusu iwọ-oorun orilẹ-ede naa. Titi ti o fi di 1990, kiki 80 awọn Ẹlẹ́rìí ni wọn wà ni odindi ilu-nla naa. Ẹmi aṣaaju-ọna wá lokiki, iṣẹ naa si ń gbèrú siwaju sii. Ní 1992 nikan, eniyan 74 ni a baptisi, awọn ikẹkọọ Bibeli ti o ju 150 lọ ni a sì ń ṣe. Pẹlu iye awọn akede ti o ju 200 lọ, wọn ń wọna pẹlu iharagaga fun ibikan ti o bojumu fun Gbọngan Ijọba.

Ní Tirgu-Mures, arabinrin Ẹlẹ́rìí kan ati awọn arakunrin meji lọ sọdọ alufaa ṣọọṣi Orthodox lati jẹ́ ki a yọ orukọ rẹ̀ kuro ninu iwe orukọ ijọ naa. Ní mímọ idi fun ibẹwo wọn, alufaa naa pè wọn wọle, wọn sì ní ijiroro daradara kan. Alufaa naa sọ lẹhin naa pe: “Mo jowu yin ṣugbọn kìí ṣe ni ọ̀nà ti kò dara. O yẹ ki awa maa ṣe iṣẹ ti ẹ ń ṣe. O buru jai pe Ṣọọṣi Orthodox jẹ́ òmìrán olóorun”! O gba iwe pẹlẹbẹ naa Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí? ati ẹ̀dà kan Ilé-Ìṣọ́nà. Arabinrin naa layọ pe oun kò jẹ́ apakan “òmìrán olóorun” naa mọ́.—Ìfihàn 18:4.

O ṣe pataki pe eyi ti o pọ julọ lara awọn ti wọn ń kẹkọọ otitọ lonii jẹ́ ọ̀dọ́. Eeṣe? O hàn gbangba pe wọn rétí pupọ ninu iyipada ijọba, ṣugbọn a ti kó ṣìbáṣìbo bá wọn. Wọn layọ lati kẹkọọ pe kiki Ijọba Jehofa ni o lè mú abajade pipẹtiti wá fun awọn iṣoro wa.—Orin Dafidi 146:3-5.

Awọn Ohun Nla Ń Ṣẹlẹ Ní Awọn Ibi Kekere

Abule kekere kan ni Ocoliş jẹ́ ní iha ariwa Romania. Ní 1920 ọkunrin kan ti orukọ rẹ̀ ń jẹ́ Pintea Moise pada lati ọ̀gbagadè Russia, nibi ti a ti mu un gẹgẹ bi ẹlẹ́wọ̀n ogun. Ó ti figba kan rí jẹ́ Katoliki, ṣugbọn ki ó tó pada ó ti di Baptist. Ní ọsẹ mẹta lẹhin naa, awọn Akẹkọọ Bibeli, gẹgẹ bi a ti mọ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa sí nígbà naa, ṣebẹwo sọdọ rẹ̀. Lẹhin ibẹwo yẹn, o polongo pe: “Ní bayii mo ti rí otitọ nipa Ọlọrun!” Nígbà ti o di 1924 awujọ awọn 35 ni wọn wà ni Ocoliş.

Lonii, lara iye awọn eniyan adugbo ti wọn jẹ́ 473, awọn 170 akede Ijọba ni wọn wà nibẹ. Akede kọọkan ní eyi ti o tó ile meji ti a yàn fun un gẹgẹ bi ipinlẹ iṣiṣẹ rẹ̀, wọn si tun ń ṣiṣẹ ni awọn abule ti o wà layiika. Sibẹ, wọn ni ifojusọna fun rere. Wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ Gbọngan Ijọba daradara kan ti ó gba 400 eniyan ni ijokoo ẹ̀ẹ̀kan ni. Awọn Ẹlẹ́rìí ni adugbo ni wọn ṣe gbogbo iṣẹ naa.

Valea Largă ni ibi ti Arakunrin Szabo ati Kiss fi ìkàlẹ̀ sí ni 1914. Ní 1991, lara awọn 3,700 olùgbé rẹ̀, ni ìjọ mẹjọ ati 582 awọn akede Ijọba naa wà. Ní ibi Iṣe-iranti ti 1992, eniyan 1,082 ni wọn pesẹ—eyi ti o fẹrẹ jẹ́ eniyan 1 ninu awọn 3 ni àfonífojì yii.

Awọn Aṣaaju-Ọna Akanṣe La Ọ̀nà Silẹ

Awọn aṣaaju-ọna akanṣe kó ipa titobi ni mímú ihinrere naa tọ awọn eniyan lọ ni awọn agbegbe ti o tubọ wọnú. Gbàrà ti a ti fun wọn ni ominira lati waasu, Ionel Alban bẹrẹ si ṣiṣẹ ni awọn ilu-nla meji, ni lilo ọjọ meji ni ọ̀sẹ̀ kọọkan ni Orşova ati ọjọ marun-un ní Turnu-Severin.

Kò si awọn Ẹlẹ́rìí kankan ni Orşova nigba ti Ionel dé ibẹ. Ní ọ̀sẹ̀ akọkọ, ó bẹrẹ ikẹkọọ Bibeli kan pẹlu ọmọdekunrin ọlọdun 14 kan. Ọmọdẹkunrin naa ṣe awọn iyipada pupọ gan-an ni oṣu meji debi pe ọ̀rẹ́ kan ati aladuugbo kan bẹrẹ sii kẹkọọ. Aladuugbo naa, Roland, ẹni ti o jẹ́ Katoliki tẹlẹ, tẹsiwaju lọna yiyanilẹnu. Lẹhin kiki oṣu kan ati ààbọ̀, ó tẹle Ionel lọ sẹnu iṣẹ iwaasu, ati ni oṣu marun-un a baptisi rẹ̀. Lẹsẹkẹsẹ ni ó wọnu iṣẹ-isin alakooko kikun. Iya rẹ̀ pẹlu bẹrẹ sii kẹkọọ a sì baptisi rẹ̀ ní Apejọpọ Agbegbe “Awọn Olùtan Ìmọ́lẹ̀” ti 1992. Ní bayii awọn akede mẹwaa ni wọn wà ni Orşova, wọn sì ń darí 30 awọn ikẹkọọ Bibeli inu ile.

Ẹni ti o kọ́kọ́ gba otitọ ní Turnu-Severin ni olùgbàlejowọlé ní hotẹẹli tí Ionel ń gbé. Lẹhin oṣu meji ọkunrin naa di akede ti a kò tii baptisi, ati ni oṣu mẹta a baptisi rẹ̀. Ni bayii oun jẹ́ ọ̀kan lara awọn akede 32 nibẹ ti gbogbo wọn ń ṣe ikẹkọọ Bibeli inu ile 84.

Aṣaaju-ọna akanṣe miiran, Gabriela Geica, ṣiṣẹsin gẹgẹ bi aṣaaju-ọna deedee koda nigba ti iṣẹ wa wà labẹ ìfòfindè paapaa. Ìfẹ́-ọkàn rẹ̀ jẹ́ lati ṣiṣẹ ni ibi ti aini gbe pọju. A yan ipinlẹ iṣiṣẹ gbigbooro kan fun un. Ní awọn ìgbà miiran ó maa ń rìnrìn-àjò lati 100 si 160 kilomita lati kesi awọn olufifẹhan. Ilu-nla kan ti o ti ṣiṣẹ ni Motru, nibi ti awọn Ẹlẹ́rìí mẹrin pere wà. “Nitori igbokegbodo ti a mu gbooro sii ni Motru, awọn alufaa ati awọn ẹgbẹ́ onisin miiran bẹrẹ sii ṣatako si wa,” ni oun sọ. “Wọn lo agbara idari lori olori ilu-nla naa ati awọn ọlọpaa lati yọ awọn idile ti wọn fi mi wọ̀ sile lẹnu. Wọn lé mi jade, nitori naa ni nǹkan bii oṣooṣu, ni mo nilati wá ibikan lati gbé.”

Gabriela bẹrẹ ikẹkọọ kan pẹlu ẹnikan ti kò gbagbọ pe Ọlọrun wà ní Orşova, ẹni ti o sọ pe oun kò ní ìfẹ́-ọkàn ninu isin tabi Bibeli. Ṣugbọn lẹhin kiki oṣu mẹrin ikẹkọọ, obinrin naa bẹrẹ sii gbèjà Bibeli. Bi o tilẹ jẹ pe ọkọ rẹ̀ tì í mọ́ ìta ni òru ti o sì halẹ ati kọ̀ ọ́ silẹ tabi ki ó pa á paapaa, ó di iwatitọ rẹ̀ mú. Àní ki ó tó ṣe iribọmi, o dari ikẹkọọ Bibeli mẹwaa.

Awọn Ifojusọna Agbayanu Níwájú

Ni August 1992, Romania dé ori gongo 24,752 akede ni 286 ìjọ. Iye awọn ti wọn pesẹ sibi Iṣe-iranti ju 66,000 lọ. Ní ẹ̀ka ọfiisi kekere ti o wà ni Bucharest, awọn oṣiṣẹ 17 ń ṣe gbogbo ohun ti wọn lè ṣe lati bojuto aini tẹmi awọn ará wọn. Wọn ń wọna laipẹ fun bibẹrẹ iṣẹ ile kíkọ́ ni ẹ̀ka ti o tubọ tobi.

Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni Romania kò lè ṣai kún fun iyalẹnu nipa gbogbo awọn iyipada yiyara kankan ni awọn ọdun bii melookan ti o kọja. Wọn ṣọpẹ́ fun Jehofa Ọlọrun pe wọn jẹ́ apakan ìjọ jakejado awọn orilẹ-ede ti ń jẹ́ orukọ rẹ̀ ti wọn si ń ṣamọna awọn eniyan si ìmọ̀ pipeye nipa oun ati ète rẹ̀ alaileṣeeyipada. Lẹhin ọpọlọpọ ọdun inira ati inunibini, ẹ wo bi wọn ti kun fun ọpẹ́ si Jehofa tó pe ó ti yí akoko ati ìgbà pada niti gidi ní Romania!

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 23]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

HUNGARY

ROMANIA

Bucharest

Cluj-Napoca

Craiova

Tirgu-Mures

Orşova

Turnu -Severin

Motru

Turda

BULGARIA

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24, 25]

1. Awọn Ẹlẹ́rìí ti iye wọn tó 700 pejọpọ ninu igbó ni 1947

2. Ìwé-ìléwọ́ fun ọ̀rọ̀ asọye itagbangba kan ní 1946

3. Apejọ ẹnu aipẹ yii kan ni Romania

4. Jíjẹ́rìí ni Cluj-Napoca lonii

5. Gbọngan Ijọba nitosi Turda

6. Idile Beteli ní Bucharest

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́