ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 6/15 ojú ìwé 31
  • Ibeere Lati Ọwọ́ Awọn Òǹkàwé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ibeere Lati Ọwọ́ Awọn Òǹkàwé
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ǹjẹ́ Bíbélì Lòdì Sí Tẹ́tẹ́ Títa?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Tẹ́tẹ́ Títa
    Jí!—2015
  • Yàgò Fún Ìdẹkùn Tẹ́tẹ́ Títa
    Jí!—2002
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 6/15 ojú ìwé 31

Ibeere Lati Ọwọ́ Awọn Òǹkàwé

Niwọn bi awọn Kristian kìí tií lọwọ ninu fifi owó kọ́ iyàn, wọn ha lè tẹwọgba tikẹẹti tabi kópa ninu fifa nọmba yọ, ninu eyi ti wọn ti lè jẹ awọn ẹ̀bùn bi?

Eyi jẹ ibeere kan ti a ti ń beere lati ìgbà dé ìgbà, nitori naa a ti ṣalaye nipa rẹ̀ ṣaaju akoko yii ninu awọn itẹjade wa. Ninu awọn ede kan, a ti ṣe atọ́ka fun awọn iwe-ikẹkọọ wa, bii Watch Tower Publications Index 1930-1985 (ati ọ̀kan ti o jọ ọ ti o kárí 1986 si 1990). Bi Kristian kan bá ni iru awọn atọ́ka bẹẹ ni ede rẹ̀, iwọnyi lè wulo gidigidi ni ṣiṣawari idahun ti ń tẹnilọrun ni kíákíá.

Ibeere ti a beere ni oke yii jẹ apẹẹrẹ kan. Ni wiwo Index (atọ́ka) fun 1930 si 1985 labẹ akori naa “Questions From Readers,” ẹnikan lè ri isọri-ori-ọrọ naa “‘drawings,’ may Christian accept ticket for?” (Ìfa-nọmba-yọ, Kristian kan ha lè tẹwọgba tikẹẹti fun un?) Onkawe ni a dari si apa ẹka naa “Ibeere Lati Ọwọ Awọn Onkawe” ninu Ilé-Ìṣọ́nà (Gẹẹsi) ti February 15, 1973, oju-iwe 127.a Ọpọ awọn Ẹlẹ́rìí ni wọn ni idipọ (tabi ẹyọ awọn itẹjade) Ilé-Ìsọ́nà ti 1973, tabi a sì lè lọ wò ó ninu ibi akojọ iwe kika ti ọpọ julọ awọn Gbọngan Ijọba.

Ọrọ-ẹkọ naa ti a tẹjade ni 1973 ṣalaye pe awọn Kristian ń fi ẹtọ yẹra fun èyí-jẹ-èyí-ò-jẹ eyikeyii tabi fifa awọn nọmba yọ ti o ni ninu rira anfaani ẹ̀bùn jíjẹ (iru bii tikẹẹti tẹ́tẹ́-raffle) tabi fifi owo ra anfaani naa lati jẹ ẹ̀bùn kan. Ni ṣoki, a ń yẹra fun tẹ́tẹ́ títa, eyi ti o jẹ ojukokoro dajudaju.—1 Korinti 5:11; 6:10; Efesu 4:19; 5:3, 5.

Bi o ti wu ki o ri, ile-itaja tabi iṣẹ-aje kan, lè lo fifa awọn nọmba yọ gẹgẹ bi ọ̀nà ipolowo kan. Gbogbo ohun ti ẹnikan nilati ṣe ni lati fi orukọ rẹ̀ silẹ tabi fi iru fọọmu tabi tikẹẹti kan ranṣẹ, laijẹ pe o ra ohunkohun. Fifa nọmba yọ naa wulẹ jẹ apakan ihumọ ipolowo ọja ni; a wewee rẹ̀ lati jẹ́ ọ̀nà igbaṣe kan ti kò ni ojuṣaaju ninu lati pinnu ẹni ti wọn yoo fun ni ẹ̀bùn tabi awọn ẹ̀bùn naa. Awọn Kristian kan lè nimọlara pe wọn lè tẹwọgba ẹ̀bùn ninu fifa nọmba yọ ti kò ni tita tẹ́tẹ́ ninu, gan-an gẹgẹ bi wọn ti lè tẹwọgba awọn apẹẹrẹ ọ̀fẹ́ tabi awọn ẹ̀bùn miiran ti iṣẹ-aje tabi ile-itaja kan lè lò ninu itolẹsẹẹsẹ ipolowo ọja rẹ̀.

Bi o ti wu ki o ri, awọn Kristian kan yoo takete si ohunkohun ti o jọ iru bẹẹ, laifẹ lati mú ẹnikẹni kọsẹ tabi mú ìpòrúùrù bá awọn ẹlomiran ti wọn yoo sì tún wá ọ̀nà lati jinna gédégédé si ìrélọ eyikeyii lati gbẹkẹle ohun ti a fi ẹnu lasan pe ni Iyaafin Oriire. Gẹgẹ bi Isaiah 65:11 ti fihàn, awọn iranṣẹ Ọlọrun kò so araawọn pọ̀ mọ́ ‘ọlọrun Oriire’ tabi ‘ọlọrun Kadara.’ Wọn tun lè nimọlara pe awọn kì yoo fẹ lati jẹ apakan ìfihàn-fáyé ti a lè beere pe ki awọn ti o bori nipin-in ninu rẹ̀. Awọn ti wọn nimọlara lọna yii dajudaju kò nilati fi ofintoto bá Kristian tabi awọn Kristian kan ti ẹ̀rí-ọkàn wọn yọnda fun wọn lati lọwọ ninu iru fifa nọmba yọ bẹẹ wi.—Fiwe Romu 14:1-4.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Akojọpọ ọ̀rọ̀ kan naa ni a ṣe itọka sí labẹ awọn ìsọ̀rí naa “Advertising” (Ipolowo), “Business” (Iṣẹ́-Ajé), ati “Gambling” (Tẹ́tẹ́ Títa), nitori naa ìṣeélò Index naa loniruuru ipò ń ranilọwọ lati wá isọfunni naa rí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́