Iwọ Ha Lè Gbẹkẹle Bibeli Bi?
BI IWỌ bá mu Bibeli kan, iwọ yoo ha reti lati ri ẹyọ-owo kan ninu rẹ̀ bi? Ki ni nipa ti ẹyọ-owo fàdákà igbaani yii?
Ọpọ wo Bibeli gẹgẹ bi iwe atijọ kan ti ń funni ni awọn ìtàn àjèjì ati awọn iwarere ti o fanilọ́kànmọ́ra. Sibẹ, wọn kò gbagbọ pe awọn akọsilẹ ọ̀rọ̀ Bibeli jẹ ìtàn ti o pé pérépéré, nipa bẹẹ, wọn sẹ́ pe Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ni. Bi o ti wu ki o ri, awọn ẹ̀rí ti o pọ̀ tó nipa ìpé pérépéré Bibeli wà. Ẹyọ-owo yii (ní irisi gàdàgbà) jẹ apẹẹrẹ didara kan. Ki ni akọsilẹ naa sọ?
Ẹyọ-owo naa ni a ṣe ni Tarsu, ilu-nla kan ni apa gusu iha ila-oorun ohun ti ń jẹ Turkey lonii. Ẹyọ-owo naa ni a ṣe nigba iṣakoso baálẹ̀ Persia naa Mazaeus ni ọrundun kẹrin B.C.E. O fi í hàn gẹgẹ bi baálẹ̀ igberiko “Ìhà-ìhín-odò,” eyiini ni Odo Eufrate.
Ṣugbọn eeṣe ti a fi lọkan ifẹ ninu àpólà ọ̀rọ̀ yẹn? Nitori pe iwọ yoo ri itọkasi kan-naa ninu Bibeli rẹ. Esra 5:6–6:13 fi ikọwe laaarin Dariusi ọba Persia ati baálẹ̀ kan ti a pe ni Tatnai hàn. Ohun ti o wà ninu ariyanjiyan ni kíkọ́ ti awọn Ju ń kọ tẹmpili wọn ni Jerusalemu. Esra jẹ ọ̀jáfáfá adawekọ ninu Ofin Ọlọrun, iwọ yoo si reti pe ki ó ṣe pàtó, ki ó pé pérépéré ninu awọn ohun ti o kọ. Iwọ yoo ri ni Esra 5:6 ati 6:13 pe ó pe Tatnai ni “baalẹ ni ìhà-ìhín-odo.”
Esra ṣe akọsilẹ eyiini ni nǹkan bi 460 B.C.E., nǹkan bi 100 ọdun ki a tó rọ owo yii jade. Óò, awọn kan lè nimọlara pe itọkasi ẹni pataki ayé atijọ kan jẹ ohun kekere. Ṣugbọn bi iwọ bá lè gbarale awọn akọwe Bibeli ninu awọn ohun kekere bẹẹ paapaa, iyẹn kò ha yẹ ki o fun igbẹkẹle rẹ lagbara sii ninu awọn ohun miiran ti wọn kọ bi?
Ninu awọn ọrọ-ẹkọ meji ti o ṣaaju ninu itẹjade yii, iwọ yoo ri awọn afikun idi fun iru igbẹkẹle bẹẹ.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]
Ìṣàkójọ Israel Dept. of Antiquities ti A Pàtẹ ati Israel Museum ti a yaworan