ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 7/15 ojú ìwé 9-12
  • Jehofa Ń Daabobo Awọn Eniyan Rẹ̀ ní Hungary

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jehofa Ń Daabobo Awọn Eniyan Rẹ̀ ní Hungary
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ìsọ̀rí
  • Ìbẹ̀rẹ̀ Mímọníwọ̀n Kan
  • Awọn Igboguntini naa Ń Pọ̀ Sii
  • Ọpọlọpọ Ọdun Labẹ Ikaleewọ
  • Iyipada kan ti O Báradé Wulẹ Jẹ́ fun Ìgbà Diẹ Ni
  • Ìpayà Bẹrẹ
  • Awọn Ifojusọna Dídán
  • Wọn Dominira Nikẹhin!
  • Ohun ti N Ṣẹlẹ Lonii
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 7/15 ojú ìwé 9-12

Jehofa Ń Daabobo Awọn Eniyan Rẹ̀ ní Hungary

HUNGARY, ti ó wà ni aarin Europe, ti sábà maa ń niriiri awọn ọ̀rọ̀-ìtàn onirukerudo. Awọn eniyan rẹ̀ ti jiya pupọ, laika pe a ti yà wọn si mímọ́ fun Maria Wundia ti a sì ti fipá mu wọn lati di Kristian ajórúkọ lasan ní ọdun 1001 nipasẹ Stephen, ọba wọn akọkọ.

La ọpọ ọrundun kọja Hungary ni a ti sọ di alailagbara nipasẹ oniruuru rogbodiyan abẹle ti o faayegba awọn orilẹ-ede miiran lati jẹgaba lé e lori leralera. Ọpọ awọn olugbe gbogbo abule ni a parun lakooko awọn rogbodiyan wọnyi, ti a sì nilati fi awọn ajeji rọ́pò wọn lẹhin naa. Nipa bayii, awọn olugbe rẹ̀ wa di ìlúpọ̀mọ́ra ọpọlọpọ orilẹ-ede. Niti isin, ki a sọ pe ìdáméjì ninu mẹta iye awọn olugbe ilẹ naa tẹramọ isin Katoliki, bi o tilẹ jẹ pe ajọ-isin Alatun-unṣe wa tàn kalẹ ni awọn agbegbe miiran.

Ìbẹ̀rẹ̀ Mímọníwọ̀n Kan

Ọdun 1908 ni a kọkọ gbin awọn èso otitọ Bibeli ni Hungary. Obinrin kan ti o ti kẹkọọ otitọ lati ọ̀dọ́ awọn Akẹkọọ Bibeli, gẹgẹ bi a ti mọ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nigba naa, ni ó ṣe eyi. Nitori iwaasu rẹ̀, pupọ eniyan di ọlọkan-ifẹ ninu ihinrere naa. Laipẹ si akoko naa awọn ọkunrin meji ti wọn ń pada si Hungary lati United States lo akoko kikun lati tan ihinrere naa ká gẹgẹ bi awọn olùpín-ìwé-ìsìn-kiri. Otitọ naa tankalẹ diẹdiẹ ṣugbọn pẹlu idaniloju, ile-iṣẹ itẹwe kan ni a sì dá silẹ ni Kolozsvár.

Irohin akọkọ ti o ṣee gbẹkẹle ni a ri gba ní 1922, nigba ti awọn Akẹkọọ Bibeli 67 lati ilu mẹwaa lọ sibi Iṣe-iranti iku Kristi. Iṣẹ ijẹrii wọn ní ipa ojú-ẹsẹ̀ kan, ti ń yọrisi atako bi awọn alufaa ti lo ipa lori ijọba ati awọn ile-iṣẹ iwe-irohin lati ṣediwọ fun iṣẹ iwaasu naa.

Awọn Igboguntini naa Ń Pọ̀ Sii

Ní 1928, alufaa Katoliki naa Zoltán Nyisztor tẹ iwe pẹlẹbẹ kan jade ti a fun ní akọle naa Millennialist Bible Students. Ninu rẹ̀ ó fi itẹnumọ sọ nipa awọn Akẹkọọ Bibeli pe: “Wọn buru ju awọn oṣelu kọmunist ti wọn ń gboguntini pẹlu awọn nǹkan ija ogun lọ, nitori pe awọn wọnyi ń ṣi awọn alaimọkan lọna nipa lilo Bibeli lati fi awọn isunniṣe wọn niti gidi pamọ́. Royal State Police ti ilẹ Hungary ń ṣọ́ igbokegbodo wọn pẹlu ìháragàgà.”

Ní akoko yẹn, arakunrin onitara kan ti orukọ rẹ̀ ń jẹ Josef Kiss bẹ awọn ijọ naa wò. Awọn ọlọpaa France yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ tẹlee lẹhin. Ní 1931 ó wà ninu ile arakunrin kan nigba ti awọn ọlọpaa yà á lẹnu ti wọn si paṣẹ fun un lati fi ibẹ silẹ lẹsẹkẹsẹ. Bí Arakunrin Kiss ti bẹrẹ sii kó awọn ẹrù rẹ̀, ọlọpaa France kan fi ìdí ibọn rẹ̀ gbá a ti o si halẹ mọ́ ọn pe: “Ṣe kia, bi bẹẹ kọ a o gún ọ yánnayànna!” Arakunrin Kiss rẹ́rìn-ín musẹ o sì wi pe: “Nigba naa emi yoo lọ sile ní kiakia,” ni titọka si ireti rẹ̀ ti ọ̀run gẹgẹ bi Kristian ẹni-amiororo.

Awọn ṣọja naa tẹle Arakunrin Kiss dé ìdíkọ̀. A reti pe ki o dé ijọ ti o wà ni Debrecen ni June 20, 1931, ṣugbọn oun kò farahan titi. Awọn ará pari ero si pe awọn ọ̀tá rẹ̀ ti pa á, pe o ti “lọ si ile” sibi èrè rẹ̀ ti ọ̀run nitootọ. Bi o tilẹ jẹ pe a da iṣẹ rẹ̀ duro, awọn alaṣẹ kò lè pa iná otitọ naa lae.

Ọgbọ́n ni a sábà maa ń lò ki a baà lè jẹrii funni. Fun apẹẹrẹ, ní aarin awọn ọdun 1930, arakunrin kan kú ní Tiszakarád. Isinku ni a lè ṣe nigba naa kiki pẹlu iyọọda awọn oṣiṣẹ ijọba. A gba awọn ará laaye lati gba kiki adura iṣẹju kan ati orin iṣẹju kan. Awọn ọlọpaa France, ti wọn wá si ibi isinku naa pẹlu awọn ibọn ti wọn ní idà lẹnu, ni wọn nilati rii pe a mu eyi ṣẹ. Pupọ awọn eniyan ilu wá nitori pe wọn fẹ́ lati ṣofintoto nipa bi a o ti ṣe dari isinku naa.

Arakunrin kan dide ni ẹgbẹ pósí naa o sì gbadura fun ọgbọ̀n iṣẹju ṣugbọn ni iru ọ̀nà kan ti awọn eniyan naa fi wi pe awọn kò tii gbọ́ ohunkohun bi iru rẹ̀ rí. “Àní bi o bá jẹ pe awọn alufaa mẹfa ni wọn ti dari isinku naa,” ni wọn wi, “kò ni wuni lori tobẹẹ.” Arakunrin kan ti o ni ohùn daradara wá bẹrẹ sii ṣaaju ninu orin, ṣugbọn ọlọpaa kan paṣẹ fun un pe ki o dakẹ. Awọn ọlọpaa naa wá jẹwọ lẹhin naa pe, bi o tilẹ jẹ pe kò tẹ́ awọn lọrun, awọn kò lè dá adura naa duro.

Bí igboguntini naa ti ń baa lọ, Lajos Szabó, alufaa Ṣọọṣi Alatun-unṣe, kọ awọn ohun ti o tẹlee yii ninu iwe pẹlẹbẹ rẹ̀ ti 1935 naa Antichrist by the River Tisza: “O jẹ́ èrò ọlọgbọ́n lati fi iṣelu kọmunisti bọ́ awọn eniyan ni orukọ isin . . . Marx gbe irisi Kristi wọ̀ . . . Aṣodi sí Kristi naa wa níhìn-ín ninu aṣọ rẹ̀ pupa pẹlu awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa.”

Ọpọlọpọ Ọdun Labẹ Ikaleewọ

Ní 1939 iṣẹ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni a kàléèwọ̀ ni gbangba. A sami ẹ̀gàn sii lara gẹgẹ bi igbokegbodo kan ti o “lodisi isin ati awujọ.” Awọn onisin Adventist, Baptist, Evangelical, ati Presbyterian gbe awọn iwe pẹlẹbẹ lodisi awọn Ẹlẹ́rìí jade. Ṣugbọn Jehofa kò fi awọn iranṣẹ rẹ̀ silẹ, awọn Ẹlẹ́rìí ní awọn orilẹ-ede miiran sì bojuto wọn. Ní afikun sii, awọn eniyan Ọlọrun ní Hungary ní ọpọ iriri afungbagbọ-lokun.

Fun apẹẹrẹ, nigba ti arakunrin kan ra àpò ìgbékẹ́yìn kan ti o kun fun awọn iwe-irohin wa lati Czechoslovakia, oṣiṣẹ aṣọ́bodè beere lọwọ rẹ̀ pe: “Ki ni o wà ninu àpò ìgbékẹ́yìn rẹ?” Arakunrin naa fi ailabosi dahun pe: “awọn Ilé-Ìṣọ́nà.” Oṣiṣẹ ijọba naa wá ṣe àmì kan pẹlu ọwọ́ rẹ̀ bi ẹni pe lati tọka pe ori arakunrin naa daru, o sì jẹ ki o maa bá ọ̀nà rẹ̀ lọ. Nipa bayii, ounjẹ tẹmi dé si Hungary laisewu.

Sibẹ, ihalẹmọni naa kò dawọduro. Pupọ pupọ sii awọn ará ni a fi aṣẹ-ọba mú ti a sì mú ni igbekun fun awọn akoko ti o yatọsira. Lẹhin naa ẹgbẹ́ aṣewadii akanṣe kan ni a fun ni iṣẹ-ayanfunni ti igbesẹ ifiyajẹni lori awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ní 1942, awọn ọkunrin, obinrin, ati awọn ọmọde ni a kojọ ti a sì fi wọn sinu awọn ibùjẹ ẹran ati awọn ile-ẹkọ awọn Ju ti o ṣófo. Lẹhin oṣu meji idaloro, a gbẹ́jọ́ wọn a sì ṣedajọ wọn. A fi awọn diẹ si ẹ̀wọ̀n gbére; awọn miiran gba lati ọdun 2 si 15 ni ọgbà-ẹ̀wọ̀n-amúnipàwàdà. Awọn arakunrin mẹta—Dénes Faluvégi, András Bartha, ati János Konrád—ni a dajọ iku ìsonikọ fun, ṣugbọn idajọ naa ni a wá yipada si ẹ̀wọ̀n gbére. Lẹhin naa, awọn 160 arakunrin ni a mu lọ si àgọ́ iku ní Bor. Lẹhin sisọda odi ilu, a wi fun wọn pe wọn kò ni pada láàyè lae. Lara awọn 6,000 Ju ti a mu lọ si àgọ́ yii, awọn 83 pere ni wọn walaaye. Bi o ti wu ki o ri, gbogbo awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni wọn dari pada ayafi awọn mẹrin ninu wọn.

Awọn kan ninu awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa jẹ́ ajẹ́rìíkú. Ní apa ipari Ogun Agbaye II, awọn Nazi pa ọpọlọpọ awọn ará. Bertalan Szabó, János Zsondor, ati Antal Hónis ni a yin ibọn pa, ti a si so Lajos Deli kọ́.—Matteu 24:9.

Iyipada kan ti O Báradé Wulẹ Jẹ́ fun Ìgbà Diẹ Ni

Lẹhin ogun agbaye keji, ipo awọn nǹkan yipada lẹẹkan sii. Ijọba iṣọkan ṣeleri ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn. Awọn ará ti wọn ń padabọ lati awọn àgọ́ naa bẹrẹ sii waasu lẹsẹkẹsẹ ati lati ṣeto awọn ijọ. Wọn nimọlara pe Jehofa ti fun wọn ni ominira ki wọn baà lè yin orukọ rẹ̀, kìí ṣe pe ki o lè ṣeeṣe fun wọn lati gbiyanju lati kó awọn nǹkan ti ara jọ. Nigba ti o di opin ọdun 1945, awọn 590 ogboṣaṣa akede Ijọba naa ni a ní. Ní 1947, a ra ile kan nitosi odi ilu fun lílò gẹgẹ bi ẹ̀ka ọfiisi Watch Tower Society, apejọpọ agbegbe jakejado awọn orilẹ-ede iru rẹ̀ akọkọ ni a sì ṣe, ni gbọngan iṣere kan. Iye awọn ti wọn pejọ sibẹ jẹ́ 1,200, ajọ rélùwéè orilẹ-ede Hungary si tilẹ fi ẹdinwo ipin 50 ninu ọgọrun-un fun awọn ti wọn ń rinrin-ajo lọ si apejọpọ agbegbe naa.

Bi o ti wu ki o ri, ominira kò wà lọ fun akoko pipẹ. Laipẹ Ẹgbẹ́ Kọmunist gba agbara, ijọba si yipada. Ibisi awọn eniyan Jehofa gba afiyesi ijọba titun naa, nitori pe wọn ti gberu lati ori 1,253 akede ni 1947 de 2,307 ni 1950. Ní ọdun yẹn, awọn oṣiṣẹ ijọba bẹrẹ sii gbe awọn ohun ìdènà si ọ̀nà iṣẹ iwaasu naa. Iyọọda lati waasu ni a beere fun, ṣugbọn ijọba kọ̀ lati gbe wọn jade, awọn ti wọn sì beere fun iyọọda ni awọn Ẹ̀ṣọ́ Ijọba lù. Lati ìgbà de ìgbà ni ọrọ inu awọn iwe-irohin ń kilọ nipa awọn Ẹlẹ́rìí gẹgẹ bi ‘aṣoju awọn ijọba agbókèèrè-jẹgàba.’ Ó le wuni lati gbọ́, pe ki ijọba Kọmunist tó bọ si ori aleefa, a ti fi awọn Ẹlẹ́rìí si àgọ́ itimọle loju ẹsun ‘iṣalatilẹhin fun ijọba Kọmunist ti ilẹ Ju.’

Ìpayà Bẹrẹ

Ní November 13, 1950, alaboojuto ẹ̀ka ati olutumọ-ede (awọn meji ninu awọn ti a dajọ iku fun tẹlẹri) ni a fi àṣẹ ọba mú, papọ pẹlu alaboojuto ti ayika kìn-ín-ní. A mu wọn lọ si ọgbà ẹ̀wọ̀n abẹlẹ ti o lorukọ buburu naa ní 60, Opopona Andrássy ní Budapest, lati lè “mú wọn rọ̀.” Igbẹjọ wọn waye ní February 2 ọdun ti o tẹlee. Alaboojuto ẹ̀ka ni a dajọ ẹ̀wọ̀n ọdun mẹwaa ninu itimọle fun, olutumọ-ede naa ni a fi si ẹ̀wọ̀n ọdun mẹsan-an, ati alaboojuto ayika naa si ẹ̀wọ̀n ọdun mẹjọ. Ẹrù awọn mẹtẹẹta ni a sọ di ti ijọba. Lakooko igbẹjọ naa, awọn alaboojuto ijọ mẹrin miiran ni a dajọ ẹ̀wọ̀n fun eyi ti o bẹrẹ lati ori ọdun marun-un si mẹfa lori ẹ̀sùn gbigbiyanju lati gba ijọba.

A fi awọn arakunrin naa si ọgbà ẹ̀wọ̀n ti aabo rẹ̀ ga, nibi ti wọn kò ti lè gba lẹta, ẹrù, tabi alejo. Awọn idile wọn kò gbọ irohin kankan nipa wọn. Awọn ẹ̀ṣọ́ naa kò tilẹ lè pe orukọ wọn. Fun idanimọ, ẹnikọọkan wọ àsokọ́ onípátákó ti o gbékọ́ si ọrùn rẹ̀ pẹlu nọmba kan lara rẹ̀. Ami kan tilẹ wa ni ara ogiri ti o kà pe: “Maṣe wulẹ ṣọ́ awọn ẹlẹwọn naa; koriira wọn.”

Awọn Ẹlẹ́rìí naa ni a pa lẹnu mọ́, ṣugbọn iṣẹ iwaasu naa kò duro. Awọn Ẹlẹ́rìí miiran ń baa lọ ni ipo awọn ti a ti fi sẹwọn naa. Bi akoko ti ń lọ awọn afirọpo naa ni a gbamu pẹlu. Ní ọdun 1953, eyi tí ó ju 500 lọ lara awọn ará naa ni a ti ṣedajọ wọn ti a sì fi si ẹ̀wọ̀n, ṣugbọn ihinrere naa ni a kò lè fi ṣẹkẹṣẹkẹ dè. Kiki diẹ ninu awọn ará naa ni wọn gba awọn ileri atannijẹ ti awọn ẹ̀sọ́ ń ṣe gbọ́ ti wọn sì juwọsilẹ.

Awọn Ifojusọna Dídán

Ní ìgbà ikore ọdun 1956, awọn eniyan naa bẹrẹ sii ṣọtẹ lodisi ijọba. Ẹgbẹ́ Ọmọ-ogun ilẹ Soviet pana iṣọtẹ naa, Ẹgbẹ́ Komunist sì gba agbara pada.

Gbogbo awọn Ẹlẹ́rìí ti a fi sẹwọn ni a ti tu silẹ, ṣugbọn ṣa awọn arakunrin diẹ ti a mọ dunju ni a dá pada si ẹ̀wọ̀n lati maa bá ifisẹwọn wọn lọ, bi o tilẹ jẹ pe awọn ẹni titun ni a kò dalẹjọ ẹ̀bi. Nikẹhin, ní 1964, awọn nǹkan bẹrẹ sii rọjú. Awọn alaṣẹ kò ṣe nǹkankan mọ lati dá awọn isinku ati àsè igbeyawo duro. Awọn ipade ayika ni a ṣe ninu ẹgàn. Nigba ti o sì jẹ pe diẹ ninu awọn wọnyi ni a da duro, a kò tun fi awọn Ẹlẹ́rìí miiran sẹwọn.

Ní 1979 awọn arakunrin ti wọn wà ni ipo abojuto ni a gbà láàyè lati lọ si apejọpọ ni Vienna. Ninu ọdun yẹn pẹlu, awọn alaṣẹ pinnu lati fun awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni àṣẹ idanimọ, ṣugbọn ọdun mẹwaa sii kọja ki eyi tó ṣẹlẹ niti gidi. Ní 1986 apejọpọ agbegbe akọkọ ni a ṣe, ni Youth Park ti Kamara Forest, pẹlu ifọwọsi awọn alaṣẹ. Ami kan ni a tilẹ lẹ̀, ti o sọ pe eyi ni Apejọpọ Agbegbe “Alaafia Atọrunwa” ti Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ní ọdun ti o tẹlee, Apejọpọ “Ni Igbẹkẹle Ninu Jehofa” ni a ṣe, ati ní 1988 awọn ará gbadun Apejọpọ “Idajọ Ododo Atọrunwa.”

Wọn Dominira Nikẹhin!

June 27, 1989, jẹ́ ọjọ yiyanilẹnu kan, nitori pe nigba naa ni awọn ará gba iwe-akọsilẹ kan ti o fi idanimọ labẹ ofin fun Eto-Ajọ Isin Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni Hungary. Ní July Gbọngan Iṣere Budapest gbàràmù naa gba 9,477 awọn eniyan ti wọn pejọ nibi Apejọpọ Agbegbe “Ifọkansin Oniwa-bi-Ọlọrun.” Gbọngan kan-naa ni a lò fun Apejọpọ Agbegbe “Ede Mimọgaara” ní 1990, awọn apejọpọ agbegbe ni a sì tun ṣe ní awọn ilu-nla titobi mẹta miiran ní Hungary.

Nisinsinyi ti a ti gbé ikalọwọko naa kuro patapata, o ṣeeṣe lati ṣeto apejọpọ akọkọ jakejado awọn orilẹ-ede. Laika ojú-ọjọ́ ti kò dara si, a ṣe é ní Népstadion ní Budapest, nibi ti 40,601 eniyan ti pade lati gbadun ọyàyà ìfẹ́ ará. Awọn mẹmba Ẹgbẹ́ Oluṣakoso wá wọn sì fun igbagbọ awọn ará lókun pẹlu awọn ọ̀rọ̀-asọye wọn, awọn iwe titun ati awọn iwe-pẹlẹbẹ tí wọn ní awọn aworan àkàwé mèremère ni a sì mu jade ní apejọpọ yii.

Ohun ti N Ṣẹlẹ Lonii

Ẹ̀dà Ilé-Ìṣọ́nà ati Ji! ni ede Hungary ni a ń tẹjade nisinsinyi lẹẹmeji loṣu pẹlu ẹ̀dà wọn ni ede Gẹẹsi ó sì jẹ́ pẹlu ìṣètòlẹ́sẹẹsẹ lilẹwa kan-naa. Ní 1992 ni a bẹrẹ sii tẹ Yearbook jade ni ede Hungary. Iye awọn akede ihinrere naa ga soke lati 6,352 ní 1971 si 13,136 ní January 1993.

Lonii, awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni Hungary gbadun ominira isin wọ́n sì ń waasu falala lati ile de ile. Nǹkan bii 205 ijọ ni ó wà, ti 27,844 sì wá si ibi Iṣe-iranti ni April 17, 1992. Titi di ìgbà ti awọn Gbọngan Ijọba ti o pọ̀ tó yoo fi wà, awọn ijọ naa ń baa lọ lati pade ni awọn ile-ẹkọ, ibi apejọ iṣẹmbaye, awọn àgọ́ ọlọpaa ti wọn ṣófo, ati paapaa ní awọn ọfiisi Ẹgbẹ́ Kọmunist ti wọn kò lò mọ́. Ní 1992, ijọ mẹwaa ni o ti ya Gbọngan Ijọba tiwọn si mímọ́, ti a sì ń kọ́ awọn gbọngan miiran lọwọ.

La gbogbo awọn iyipada ati iṣọtẹ naa kọja, awọn ará naa ti fi iṣotitọ duro ni iha ọ̀dọ̀ Jehofa Ọlọrun ati Ọmọkunrin rẹ̀, Jesu Kristi, wọn sì ti ń bá wiwaasu niṣo. Awọn ìjì akoko naa kò tii pa wọn run, nitori pe Jehofa ti daabobo awọn eniyan rẹ̀ ni Hungary.—Owe 18:10.

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 9]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Vienna

AUSTRIA

Budapest

Debrecen

HUNGARY

ROMANIA

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Awọn eniyan Jehofa pejọpọ ní Budapest

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́