ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 10/1 ojú ìwé 21
  • A Sọ Àsọtẹ́lẹ̀ Ìyàn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • A Sọ Àsọtẹ́lẹ̀ Ìyàn
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ni Ojútùú Rẹ̀?
    Jí!—1996
  • Iye Àwọn Olùwá-Ibi-Ìsádi Tí Ń Pọ̀ Sí I
    Jí!—1996
  • Wíwá Ibi Tí Wọ́n Lè Fi Ṣe Ilé
    Jí!—2002
  • Bá A Ṣe Lè Ran Àwọn Àjèjì Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Máa ‘Fayọ̀ Sin Jèhófà’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 10/1 ojú ìwé 21

A Sọ Àsọtẹ́lẹ̀ Ìyàn

NÍ ẸNU àwọn ọdún àìpẹ́ yìí ìpayà ìyàn ti di ohun tí a mọ̀ dáadáa lọ́nà tí ń ronilára nínú àwọn àkọsílẹ̀ ìròyìn àgbáyé. Láti Ethiopia àti àwọn ibòmíràn ni àwọn àwòrán ìjìyà mánigbàgbé ti ń wá. Ní 1992 àfiyèsí ayé ni a kójọ sórí àwọn òjìyà ìyàn bíbanilẹ́rù ti Somalia, èyí tí ọ̀dá àti ogun jẹ́ okùnfà fún. Ìwé-ìròyìn International Herald Tribune ròyìn ní September 1992 pé: “Kò sí ẹni tí ó mọ iye àwọn ará Somalia tí ó ti kú, ṣùgbọ́n àwọn ẹgbẹ́ Alágbèélébùú Pupa sọ pé iye náà ju ọ̀kẹ́ márùn-ún lọ. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún, bí kìí bá ṣe ẹgbẹẹgbẹ̀rún, ń kú lójoojúmọ́.”

Iye náà kò gbé ìbànújẹ́ àti ìrora tí ẹnìkọ̀ọ̀kan tí ọ̀ràn kàn ní jáde. Yvette Pierpaoli, aṣojú àwọn Olùwá-Ibi-Ìsádi Jákèjádò àwọn Orílẹ̀-Èdè ti Europe, kọ̀wé nínú ìwé-ìròyìn UN náà Refugees pé: “Ní New York tàbí Geneva, ọ̀ràn àwọn olùwá-ibi-ìsádi hàn gbangba kedere; àwọn iye ni a tọ́ka sí tí àtòpọ̀ àwọn òdo tí ó sopọ mọ́ wọn sì ṣòro láti lóye. Ṣùgbọ́n ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún kìlómítà jìnnà réré, níbi àwọn ààlà ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-édé tí wọ́n ti fẹ́rẹ̀ẹ́ di ti onírúgúdù, ìmí-ẹ̀dùn á gbà ọ mú tí ìpọ̀lápọ̀jù ìjìyà náà yóò sì mú ọ fẹ́ láti lọgun.”

Nígbà tí àwọn ẹgbẹ́ Alágbèélébùú Pupa sọ pé ìsapá àwọn láti ran Somalia lọ́wọ́ dúró fún ìgbésẹ̀ ìfẹ́dàáfẹ́re ti wíwá ìtura àlàáfíà fún ènìyàn títóbi jùlọ tí àwọn tíì ṣe rí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olùṣàkíyèsí ń ráhùn pé àwòrán gbogbogbòò jẹ́ ìrànlọ́wọ́ tí ó kéré jù, tí ó pẹ́ẹ́ dé. Pierpaoli pohùnréré pé: “Àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ń ṣètọrẹ ń lọ́ra láti máa báa lọ, ó ti rẹ̀ wọ́n láti máa ṣètìlẹ́yìn fún Africa kan tí ń yìnrìn. . . . Wọ́n dẹ́bi fún àwọn ará Africa fún àìṣàbójútó rere wọn, ìwọra àwọn aṣáájú wọn, àwọn ìforígbárí tí ó jọ bí aláìlópin.”

Bibeli sọ àsọtẹ́lẹ̀ àkókò kan nígbà tí àìtó oúnjẹ yóò wà “káàkiri.” Àìtó oúnjẹ wọ̀nyí, papọ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àwọn ohun mìíràn tí ń jẹyọ, bí ogun, ìsẹ̀lẹ̀, àti àjàkálẹ̀-àrùn, fihàn pé Ìjọba Ọlọrun kù sí dẹ̀dẹ̀. (Luku 21:11, 31) Bibeli fihàn síwájú síi pé lábẹ́ Ìjọba ẹlẹ́mìí-ìṣoore ti Ọlọrun yìí, ọ̀pọ̀ yanturu oúnjẹ fún gbogbo aráyé ni yóò wà. “Ìkúnwọ́ ọkà ni yóò máa wà lórí ilẹ̀,” ni olórin náà kọ̀wé. “Lórí àwọn òkè ńlá ni èso rẹ̀ yóò máa mì.”—Orin Dafidi 72:16.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́