Ní Ojú-Ìwòye Títọ̀nà Nípa Àánú Ọlọrun
DÓKÍTÀ náà jẹ́ onínúure àti alánìíyàn gidigidi. Ní ìbámu pẹ̀lú ìṣèdíyelé rẹ̀ dídára jùlọ, olùgbàtọ́jú rẹ̀ fi ìgbékútà nílò iṣẹ́-abẹ kan kí ó baà lè gba ìwàláàyè rẹ̀ là. Nígbà tí obìnrin náà lọ́tìkọ̀ tí ó sì gbé ọ̀ràn ìfàjẹ̀sínilára dìde, ẹnu yà dókítà náà. Nígbà tí obìnrin náà ṣàlàyé pé fún àwọn ìdí tí ó jẹ mọ́ ti ìsìn òun kò ní fọwọ́sí iṣẹ́-abẹ kan tí ó wémọ́ ìfàjẹ̀sínilára, kàyééfì ni ó jẹ́ fún un. Dókítà náà gbìyànjú láti ronú gidigidi nípa ọ̀nà láti ràn án lọ́wọ́. Níkẹyìn, ó ronú pé òun ti rí ọ̀kan. Ó sọ pé: “Ṣé o mọ̀, bí ìwọ kò bá gba ìfàjẹ̀sínilára, ìwọ yóò kú. Ìwọ kò fẹ́ ìyẹn, àbí o fẹ́ bẹ́ẹ̀?”
“Dájúdájú bẹ́ẹ̀kọ́,” ni olùgbàtọ́jú rẹ̀ sọ.
“Ṣùgbọ́n, ó fẹ́ dàbí ẹni pé, bí o bá tẹ́wọ́gba ọ̀kan, ìwọ yóò hùwà lòdìsí ìgbàgbọ́ ìsìn rẹ, èyí tí ó tún ṣe pàtàkì fún ọ pẹ̀lú. Ó dára, ìdámọ̀ràn mi nìyí. Èéṣe tí o kò fi tẹ́wọ́gba ìfàjẹ̀sínilára kí o sì tipa bẹ́ẹ̀ gba ìwàláàyè rẹ là. Lẹ́yìn náà kí o jẹ́wọ́ fún Ọlọrun pé o ti ṣẹ̀, kí o sì ronúpìwàdà. Ní ọ̀nà yẹn, ìwọ ni a óò mú padàbọ̀sípò sínú ìsìn rẹ pẹ̀lú.”
Dókítà ọlọ́kàn rere náà rò pé òun ti rí ìdáhùn pípé. Ó mọ̀ pé olùgbàtọ́jú òun gbàgbọ́ nínú Ọlọrun aláàánú. Dájúdájú, àkókò yíyẹ ní èyí jẹ́ láti lo àǹfààní àánú Ọlọrun! Ṣùgbọ́n ìdámọ̀ràn rẹ̀ ha bọ́gbọ́nmu tó bí ó ti dún létí bí?
Àwa Ha Tíì Ronú Báyìí Rí Bí?
Nígbà mìíràn a lè ríi tí àwa fúnraawa ń ronú lọ́nà tí dókítà yẹn gbà ronú. Bóyá ìbújáde àtakò tí a kò retí tẹ́lẹ̀ ní ilé-ẹ̀kọ́ tàbí lẹ́nu iṣẹ́ dáyàfò wá. Tàbí a lè bá araawa nínú ipò kan tí ń kótìjú báni níbi tí a ti wà lábẹ́ ìkìmọ́lẹ̀ láti ṣe ohun kan tí kò bá ẹ̀rí-ọkàn wa mu. Bí ó bá bá wa láìròtẹ́lẹ̀, a lè ní ìtẹ̀sí láti yan ipa-ọ̀nà tí ó rọrùn jùlọ kí á sì ṣe ohun tí a mọ̀ pé kò tọ́, ní lílérò láti tọrọ àforíjì nígbà tí ó bá yá.
Ẹnìkọ̀ọ̀kan ni a sì lè dánwò nípa àwọn ìtẹ̀sí aláìtọ̀nà tiwọn fúnraawọn. Fún àpẹẹrẹ, ọ̀dọ́mọkùnrin kan lè bá araarẹ̀ nínú ipò kan níbi tí a ti fi tagbára-tagbára dán an wò láti hu ìwà-pálapàla. Dípò bíbá ìfẹ́-ọkàn tí kò tọ́ náà jà, ó lè juwọ́sílẹ̀, ní níní i lọ́kàn láti mú àwọn ọ̀ràn tọ́ pẹ̀lú Ọlọrun nígbà tí ó bá yá. Àwọn kan tilẹ̀ ti lọ jìnnà débi dídá ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo nígbà tí wọ́n mọ̀ pé àwọn ni ó ṣeéṣe kí á yọ lẹ́gbẹ́ kúrò nínú ìjọ Kristian. Ó ṣeéṣe kí wọn ti ronú pé, ‘Èmi yóò jẹ́ kí ìgbà díẹ̀ kọjá lọ. Lẹ́yìn náà èmi yóò ronúpìwàdà a ó sì gbà mí padà.’
Gbogbo àwọn ipò wọ̀nyí ní ohun méjì tí wọ́n fi jọra. Èkínní, àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan juwọ́sílẹ̀ dípò sísapá láti ṣe ohun tí ó tọ́. Èkejì, wọ́n nímọ̀lára pé lẹ́yìn tí àwọn tí ṣe ohun tí kò tọ́, Ọlọrun yóò ṣàdédé dáríjì bí wọ́n bá wulẹ̀ ti béèrè.
Kí ni Ojú-Ìwòye Títọ́nà?
Èyí ha fi ìmọrírì yíyẹ fún àánú Ọlọrun hàn bí? Ó dára, ronú nípa àánú yẹn fún ìgbà díẹ̀. Jesu sọ pé: “Ọlọrun fẹ́ aráyé tóbẹ́ẹ̀ gẹ́, tí ó fi Ọmọ-bíbí rẹ̀ kanṣoṣo fúnni, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́ má baà ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Johannu 3:16) Aposteli Johannu ṣàlàyé bí àánú yẹn ti ń ṣiṣẹ́ nígbà tí ó sọ pé: “Ìwé nǹkan wọ̀nyí ni mo kọ sí yín, kí ẹ má baà dẹ́ṣẹ̀. Bi ẹnikẹ́ni bá sì dẹ́ṣẹ̀, àwa ní alágbàwí lọ́dọ̀ Baba, Jesu Kristi olódodo.” (1 Johannu 2:1) Fún ìdí yìí, bí a bá ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀ nítorí àìpé, a lè tọ Ọlọrun wá nínú àdúrà kí á sì bẹ̀bẹ̀ fún ìdáríjì lórí ìpìlẹ̀ ìrúbọ Jesu.
Bí ó ti wù kí ó rí, èyí ha túmọ̀sí pé kò jámọ́ nǹkan yálà a dẹ́ṣẹ̀ tàbí a kò dẹ́ṣẹ̀, níwọ̀n ìgbà tí a bá ti béèrè fún ìdáríjì lẹ́yìnwá ìgbà náà? Kí á má ríi. Rántí àwọn ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ nínú àyọlò yẹn: “Ìwé nǹkan wọ̀nyí ni mo kọ sí yín, kí ẹ má baà dẹ́ṣẹ̀.” Àwọn ọ̀rọ̀ Johannu síwájú síi nínú ẹsẹ yẹn fi ìṣètò onífẹ̀ẹ́ Jehofa fún bíbójútó àìpé wa hàn. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, a níláti gbìyànjú kárakára bí a bá ti lè ṣe tó láti yẹra fún dídẹ́ṣẹ̀. Bí bẹ́ẹ̀ kọ̀ a ó fi àìbọ̀wọ̀ tí ó burújáì hàn fún ìfẹ́ Ọlọrun, bíi ti àwọn tí Juda tọ́ka sí tí wọ́n lo ìnúrere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí àwáwí fún ìwà-àìníjàánu.—Juda 4.
Wíwo àánú Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí irú àwọ̀n adáàbòboni kan tí yóò máa gbà wá dúró nígbà gbogbo láìka ohun yòówù tí a ṣe sí a máa sọ àánú Ọlọrun di ohun kékeré tí yóò sì mú kí ó dàbí ẹni pé ẹ̀ṣẹ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ burú. Èyí kìí ṣe òtítọ́ rárá. Aposteli Paulu sọ fún Titu pé: “Oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun tí ń mú ìgbàlà fún gbogbo ènìyàn wá ti farahàn, ó ń kọ́ wa pé, kí á sẹ́ àìwà-bí-Ọlọ́run àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ayé, kí á sì máa wà ní àìrékọjá, ni òdodo, àti ní ìwà-bí-Ọlọ́run ní ayé ìsinsìnyí.”—Titu 2:11, 12.
Paulu fi ìmọrírì rẹ̀ fún àánú Ọlọrun hàn ní ọ̀nà tí ó gbà wọ̀jàkadì lòdìsí àìpé tirẹ̀ fúnraarẹ̀. Ó sọ pé: “Èmi ń pọ́n ara mi lójú, mo sì ń mú un wá sábẹ́ ìtẹríba: pé lẹ́yìn tí mo ti wàásù fún àwọn ẹlòmíràn, nítorí ohunkóhun, kí èmi tìkáaràmi máṣe di ẹni ìtanù.” (1 Korinti 9:27) Paulu kò wulẹ̀ fọwọ́ yẹpẹrẹ mú un lọ́nà gbẹndẹ́kẹ pé òun ni ó di dandan fún láti dẹ́ṣẹ̀ láti ìgbà dé ìgbà. Ó ha yẹ kí àwa ṣe bẹ́ẹ̀ bí?
Kókó Ojú-Ìwòye Jesu
Lákòókò kan, Jesu fihàn bí òun ṣe wo èrò fífi ohun tí ó tọ́ bánidọ́rẹ̀ẹ́ àti gbígba ipa-ọ̀nà tí ó rọrùn jù kí ó baà lè yẹra fún ìjìyà hàn. Nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ síi sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ nípa ikú ìrúbọ̀ rẹ̀ tí ń bọ̀, Peteru gbìyànjú láti pàrọwà fún un, ní wíwí pé: “Ṣàánú araàrẹ, Oluwa; ìwọ kò ní ní kádàrá yí rárá.” Kí ni ìdáhùnpadà Jesu? “Bọ́ sẹ́yìn mi, Satani! Òkúta ìkọ̀sẹ̀ ni ìwọ jẹ́ fún mi, nítorí ìwọ ń rò, kìí ṣe àwọn ìrònú Ọlọrun, bíkòṣe ti àwọn ènìyàn.”—Matteu 16:22, 23, NW.
Bíbá tí Jesu bá Peteru wí kíkan-kíkan fihàn lọ́nà amúnijígìrì pé Jesu kọ̀ láti gba ipa-ọ̀nà rírọrùn tí ó wémọ́ lílòdì sí ìfẹ́-inú Ọlọrun. Àkọsílẹ̀ náà fihàn pé òun tẹ̀lé ipa-ọ̀nà títọ́ láìyẹsẹ̀, ní fífarada ìyọlẹ́nu lemọ́lemọ́ láti ọwọ́ Satani. Ní òpin rẹ̀ òun ni a fi ṣẹlẹ́yà, nà bíi-kíkú-bíi-yíyè, tí ó sì jìyà ijú olóró. Síbẹ̀, òun kò juwọ́sílẹ̀, àti nítorí èyí ó ṣeéṣe fún un láti fi ẹ̀mi rẹ̀ lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìràpadà fún wa. Dájúdájú òun kò farada gbogbo èyí kí á baà lè ‘ṣàánú araawa’ nígbà tí àwọn ìṣòro tàbí àdánwò bá dìde!
Nípa Jesu ni a sọ pé: “Ìwọ fẹ́ òdodo, ìwọ sì kórìíra ẹ̀ṣẹ̀.” (Heberu 1:9) Gbígba ọ̀nà rírọrùn sábà máa ń wémọ́ ẹ̀ṣẹ̀. Fún ìdí yìí, bí a bá kórìíra èyí nítòótọ́—gẹ́gẹ́ bí Jesu ti ṣe—àwa yóò máa fìgbà gbogbo kọ̀ láti juwọ́sílẹ̀. Nínú ìwé Owe, Jehofa sọ pé: “Ọmọ mi, kí ìwọ kí ó gbọ́n, kí o sì mú inú mi dùn; kí èmi kí ó lè dá ẹni tí ń gàn mi lóhùn.” (Owe 27:11) Òdodo Jesu tí ó wà déédéé ṣùgbọ́n tí a kò fi bánidọ́rẹ̀ẹ́ mú ayọ̀ ńláǹlà wá fún ọkàn-àyà Jehofa. A lè fún Jehofa ní irú ìgbádùn kan-náà bí a bá tẹ̀lé ipa-ọ̀nà ìwàtítọ́ Jesu.—1 Peteru 2:23.
Ìfaradà Kọ́ Wa Lẹ́kọ̀ọ́
Aposteli Peteru kọ̀wé pé: “Nínú èyí tí ẹ̀yin ń yọ̀ púpọ̀, bí ó tilẹ̀ ṣe pé nísinsìnyí fún ìgbà díẹ̀, níwọ̀n bí ó ti yẹ, a ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdánwò bà yín nínú jẹ́: Kí ìdánwò ìgbàgbọ́ yín, tí ó ní iye lórí ju wúrà tíí ṣègbé lọ, bí ó tilẹ̀ ṣe pé iná ni a fi ń dán an wò, kí á lè rí i fún ìyìn, àti ọlá, àti nínú ògo ní ìgbà ìfarahàn Jesu Kristi.” (1 Peteru 1:6, 7) Nítorí pé a jẹ́ aláìpé tí a sì ń gbé nínú ayé Satani, àwa yóò máa dojúkọ àwọn ìdánwò àti ìdẹwò lémọ́lemọ́. Gẹ́gẹ́ bí Peteru ti fihàn, ìwọ̀nyí lè siṣẹ́ fún ète rere. Wọ́n ń dán ìgbàgbọ́ wa wò, wọ́n ń fihàn yálà ó jẹ́ aláìlágbára tàbí alágbára.
Wọ́n tún ń ṣiṣẹ́ láti dá wa lẹ́kọ̀ọ́. Jesu “kọ́ ìgbọràn nípa ohun tí ó jìyà.” (Heberu 5:8) Àwa pẹ̀lú lè kọ́ ìgbọràn, àti ìgbáralé Jehofa bákan náà, bí a bá faradà lábẹ́ ìdánwò. Ọ̀nà ìgbà kẹ́kọ̀ọ́ yìí yóò sì máa báa lọ títí tí yóò fi parí, gẹ́gẹ́ bí Peteru ti sọ: “Ọlọrun . . . yóò sì ṣe yín ní àṣepé, yóò fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀, yóò fun yín ní agbára, yóò fi ìdí yín kalẹ́.”—1 Peteru 5:10.
Bí ó ti wù kí ó rí, bí a bá juwọ́sílẹ̀ lábẹ́ ìdánwò, a fi araawa hàn bí ojo tàbí aláìlera, tí kò ní ìfẹ́ lílágbára fún Jehofa àti òdodo tàbí tí kò ní ìkóra-ẹni-níjàánu. Irú àìlera èyíkéyìí bẹ́ẹ̀ fi ipò-ìbátan wa pẹ̀lú Ọlọrun sínú ewu gidigidi. Nítòótọ́, ìkìlọ̀ Paulu lè jásí òtítọ́ nínú ọ̀ràn wa pé: “Bí àwa bá mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀ lẹ́yìn ìgbà tí àwa bá ti gba ìmọ̀ òtítọ́ kò tún sí ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́.” (Heberu 10:26) Ó ti sàn jù tó láti máṣe dẹ́ṣẹ̀ ní ipò àkọ́kọ́ ju láti juwọ́sílẹ̀ fún àìlera kí á sì fa ewu ti pípàdánù gbogbo ìfojúsọ́nà fún ìyè wá sórí araawa!
Ìwàtítọ́ tí Kò Ní Ipò Àfilélẹ̀
Ní àwọn ọjọ́ wòlíì Danieli, àwọn Heberu mẹ́ta ni a fi ikú oníná halẹ̀ mọ́ bí wọn kò bá ní jọ́sìn ère kan. Kí ni èsì wọn? “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, Ọlọrun wa tí àwa ń sìn, lè gbà wá lọ́wọ́ iná ìléru náà tí ń jó, òun ó sì gbà wá lọ́wọ́ rẹ, ọba. Ṣùgbọ́n bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kí ó yé ọ, ọba pé, àwa kì yóò sin òrìṣà rẹ, bẹẹ ni àwa kì yóò sì tẹríba fún ère wúrà tí ìwọ gbé kalẹ̀.”—Danieli 3:17, 18.
Wọ́n mú ìdúró yẹn nítorí pé wọ́n fẹ́ láti ṣe ohun tí ó tọ́. Bí ó bá ṣamọ̀nà sí ikú wọn, déédéé ló ṣe. Ìgbọ́kànlé wọn wà nínú àjíǹde. Bí ó ti wù kí ó rí, bí Ọlọrun bá dá wọn nídè, dáadáa náà ni. Ṣùgbọ́n ìdúróṣinṣin wọn kìí ṣe èyí tí ó ní ipò àfilélẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ó níláti máa fìgbà gbogbo rí pẹ̀lú àwọn ìráńṣẹ́ Ọlọrun.
Ní ọjọ́ wa àwọn kan tí wọ́n ti kọ̀ láti juwọ́sílẹ̀ ni a ti fi sẹ́wọ̀n, dá lóró, tí a tilẹ̀ pa pàápàá. Àwọn mìíràn ti ṣe ìrúbọ ohun-ìní ti ara, ní yíyàn láti wà ní òtòṣì dípò dídi ọlọ́rọ̀ lórí ìpìlẹ̀ fífi àwọn ìlànà títọ́ rúbọ. Kí ni ó ṣẹlẹ̀ sí Kristian obìnrin tí a mẹ́nukàn ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ yìí? Ó mọrírì ìsúnniṣe onínúure bí ó tilẹ̀ jẹ́ èyí tí a gbégbòdì ti dókítà náà, ṣùgbọ́n òun kò juwọ́ ìgbàgbọ́ rẹ̀ sílẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọ̀wọ̀ rẹ̀ fún òfin Jehofa sún un láti kọ iṣẹ́-abẹ náà. Lọ́nà tí ó múni láyọ̀, ara rẹ̀ yá ṣáá ó sì ń báa lọ láti fi ìjáfáfá ṣiṣẹ́sin Jehofa. Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí ó mú ìdúró rẹ̀, òun kò mọ ohun tí àbájáde náà yóò jẹ́, ṣùgbọ́n ó múratán láti fi gbogbo ọ̀ràn náà lé Jehofa lọ́wọ́.
Kí ni ó ràn án lọ́wọ́ láti dúró gbọnyingbọnyin tóbẹ́ẹ̀ lábẹ́ ìkìmọ́lẹ̀? Òun kò gbìyànjú láti gbáralé okun araarẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni ìráńṣẹ́ Ọlọrun èyíkéyìí kò níláti ṣe bẹ́ẹ̀. Rántí pé, “Ọlọrun ni ààbò wa àti agbára, lọ́wọ́lọ́wọ́ ìrànlọ́wọ́ ní ìgbà ìpọ́njú.” (Orin Dafidi 46:1) Ó ti sàn jù tó láti yíjú sí Ọlọrun fún ìrànlọ́wọ́ nígbà tí a bá wà lábẹ́ àdánwò jù láti dẹ́ṣẹ̀ kí á tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá yíjú sí i fún àánú!
Bẹ́ẹ̀ni, ẹ máṣe jẹ́ kí á fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú àánú ńlá Ọlọrun. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ kí á mú ojúlówó ìfẹ́-ọkàn láti ṣe ohun tí ó tọ́ dàgbà, àní ní ojú àwọn ìṣòro pàápàá. Èyí yóò mú kí ipò-ìbátan wa pẹ̀lú Jehofa jinlẹ̀ síi, yóò fún wa ní ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí a nílò fún ìyè àìnípẹ̀kun, yóò sì fi ọ̀wọ̀ yíyẹ fún àánú Ọlọrun hàn. Irú ìwà ọlọ́gbọ́n bẹ́ẹ̀ yóò mú ayọ̀ wá sínú ọkàn-àyà Baba wa ọ̀run.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Ìgbọ́kànlé pátápátá nínú àjíǹde ran àwọn Heberu mẹ́ta náà lọ́wọ́ láti pa ìwàtítọ́ mọ́