Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Ojoojúmọ́ Fún Ọdún 1994
JANUARY
1. Ẹ lọ ki ẹ sì sọ awọn eniyan gbogbo orilẹ-ede di ọmọ-ẹ̀yìn, ki ẹ maa batisí wọn ni orukọ Baba ati ti Ọmọkunrin, ati ti ẹmi mímọ́, ki ẹ maa kọ́ wọn lẹkọọ lati fiṣọra kiyesi ohun gbogbo ti mo ti paṣẹ fun yin.—Matt. 28:19, 20, NW. w-YR 9/1/92 1, 2
2. Dragoni naa si binu gidigidi si obinrin naa, o si lọ ba awọn iru-ọmọ rẹ̀ iyoku jagun, ti wọn ń pa ofin Ọlọrun mọ́, ti wọn si di ẹri Jesu mu.—Ìfi. 12:17. w-YR 9/15/92 19-21a
3. A ṣá a ni ọgbẹ nitori irekọja wa, a pa a ni ara nitori aiṣedeedee wa.—Isa. 53:5. w-YR 10/1/92 18, 19
4. Ẹyin baba, ẹ maṣe mu awọn ọmọ yin binu: ṣugbọn ẹ maa tọ́ wọn ninu ẹkọ ati ikilọ Oluwa.—Efe. 6:4. w-YR 10/15/92 11
5. O si sọ ofin kan ni Israeli, tí ó ti pa ni aṣẹ fun awọn baba wa pe, ki wọn ki o le sọ wọn di mímọ̀ fun awọn ọmọ wọn.—Orin Da. 78:5. w-YR 11/1/92 9
6. Ibukun Oluwa ní múniílà, kìí sìí fi làálàá pẹlu rẹ̀.—Owe 10:22. w-YR 12/1/92 4, 5
7. Kò si idanwo kan tí ó tii ba yin, bikoṣe iru eyi tí ó mọ ni iwọn fun eniyan: ṣugbọn olododo ni Ọlọrun, ẹni ti ki yoo jẹ ki a dan yin wò ju bi ẹyin ti le gbà; ṣugbọn ti yoo si ṣe ọ̀nà atiyọ pẹlu ninu idanwo naa, ki ẹyin ki o ba le gbà á.—1 Kor. 10:13. w-YR 2/15/92 10
8. Ǹjẹ́ nisinsinyi, Ọlọrun wa, awa dupẹ lọwọ rẹ, a si yin orukọ ògo rẹ.—1 Kron. 29:13. w-YR 11/15/92 20-22
9. A o si waasu ihinrere ijọba yii ni gbogbo aye lati ṣe ẹri fun gbogbo orilẹ-ede.—Matt. 24:14. w-YR 1/1/93 19, 20
10. Ẹ wá Oluwa nigba ti ẹ le ri i, ẹ pè é, nigba tí ó wà nitosi. Jẹ ki eniyan buburu kọ ọ̀nà rẹ̀ silẹ, ki ẹlẹṣẹ sì kọ̀ ironu rẹ̀ silẹ: sì jẹ ki o yipada sí Oluwa, oun o sì saanu fun un, ati sí Ọlọrun wa, yoo sì fi ji ni ọpọlọpọ.—Isa. 55:6, 7. w-YR 9/15/92 1-3
11. Kò si panṣaga, tabi alaimọ eniyan, tabi olojukokoro, tii ṣe olubọriṣa, ti yoo ni ìní kan ni ijọba Kristi ati ti Ọlọrun.—Efe. 5:5. w-YR 1/15/93 15-17b
12. Emi kò le ṣe ohun kan funraami: bi mo ti ń gbọ, mo ń dajọ: ododo si ni idajọ mi; nitori emi kò wá ifẹ ti emi tikaraami, bikoṣe ifẹ ti ẹni tí ó rán mi.—Joh. 5:30. w-YR 2/1/93 12, 13
13. Oluwa, kọ́ mi ni ọ̀nà rẹ; emi ó sì maa pa á mọ́ de opin.—Orin Da. 119:33. w-YR 2/15/93 9, 10a
14. Ọmọ mi, gbọ́ ẹ̀kọ́ baba rẹ, ki iwọ ki o má si kọ ofin iya rẹ silẹ.—Owe 1:8. w-YR 10/15/92 4
15. Kiyesi i, òkùnkùn bo ayé mọ́lẹ̀, ati òkùnkùn biribiri bo awọn eniyan: ṣugbọn Oluwa yoo yọ lara rẹ, a o sì rí ògo rẹ̀ lara rẹ.—Isa. 60:2. w-YR 3/1/93 1, 2a
16. Nigba ti wọn ba si fi yin le wọn lọwọ, ẹ maṣe ṣàníyàn pe, bawo tabi ki ni ẹyin o wi? nitori a o fi ohun ti ẹyin o wi fun yin ni wakati kan-naa.—Matt. 10:19. w-YR 9/15/92 10a
17. Ẹbọ Ọlọrun ni irobinujẹ ọkàn: ìròbínújẹ́ ati irora àyà, Ọlọrun, oun ni iwọ kì yoo gàn.—Orin Da. 51:17. w-YR 3/15/93 15, 16a
18. Ẹ maa wa ni airekọja, ẹ maa ṣọra; nitori Eṣu, ọ̀tá yin, bi kinniun tí ń ké ramúramù, ó ń rìn kaakiri, ó ń wá ẹni tí yoo pajẹ kiri: Ẹni tí kí ẹyin kí ó kọ oju ìjà sí pẹlu iduroṣinṣin ninu igbagbọ.—1 Pet. 5:8, 9. w-YR 11/15/92 18, 19b
19. Wo iranṣẹ mi, ẹni ti mo yàn; ayanfẹ mi, ẹni ti inu mi dùn si gidigidi: emi o fi ẹmi mi fun un, yoo sì fi idajọ hàn fun awọn [orilẹ-ede, NW].—Isa. 42:1. w-YR 1/15/93 7, 8
20. Ki ẹyin ki o si maa fi wọn kọ́ awọn ọmọ yin, ki ẹyin maa fi wọn ṣe ọ̀rọ̀ sọ nigba ti iwọ ba jokoo ninu ile rẹ, ati nigba ti iwọ ba ń rin ni ọ̀nà, nigba ti iwọ ba dubulẹ, ati nigba ti iwọ ba dide.—Deut. 11:19. w-YR 11/1/92 1
21. Ẹ mu gbogbo idamẹwaa wa si ile iṣura, ki ounjẹ baa lè wà ni ile mi, ẹ sì fi eyi dán mi wò nisinsinyi, bi emi ki yoo bá ṣi awọn ferese ọ̀run fun yin, kí ń si tú ibukun jade fun yin, tobẹẹ ti kì yoo sí àyè tó lati gbà á.—Mal. 3:10. w-YR 12/1/92 6, 7
22. Emi kò dá ohunkohun ṣe fun ara mi; ṣugbọn bi Baba ti kọ́ mi, emi ń sọ nǹkan wọnyi.—Joh. 8:28. w-YR 12/15/92 3, 4a
23. O ń gbé . . . ẹni rirẹlẹ dide lati inu erupẹ; o ń gbe òtòṣì ga lati kòtò eérú funraarẹ, lati mu ki o jokoo pẹlu awọn ọ̀tọ̀kùlú . . . O n mu ki àgàn obinrin gbe inu ile gẹgẹ bi iya alayọ awọn ọmọkunrin.—Orin Da. 113:6-9, NW. w-YR 11/15/92 10, 11
24. Peteru si ranti ọ̀rọ̀ ti Jesu wi fun un pe, Ki akukọ to kọ, iwọ o sẹ mi lẹẹmẹta. O si bọ si ode, o sọkun kikoro.—Matt. 26:75. w-YR 9/15/92 9-11
25. Ki iwọ ki o fi gbogbo aya rẹ, ati gbogbo ọkan rẹ, ati gbogbo inu rẹ fẹ Ọlọrun Oluwa rẹ. . . . Iwọ fẹ ọmọnikeji rẹ bi araarẹ.—Matt. 22:37, 39. w-YR 2/1/93 3, 4a
26. Ẹni tí ó bá rò pe oun duro, ki o kiyesara, ki o má baà ṣubu.—1 Kor. 10:12. w-YR 2/15/93 8-10
27. Nitori naa, emi òǹdè ninu Oluwa, ń bẹ yin pe, ki ẹyin ki o maa rin bi o ti yẹ fun ìpè yin.—Efe. 4:1. w-YR 3/1/93 5, 6
28. Ó ń mú oòrùn rẹ̀ ràn sára eniyan buburu ati sára eniyan rere, o sì ń rọ̀jò fun awọn oloootọ ati fun awọn alaiṣootọ.—Matt. 5:45. w-YR 11/15/92 7, 8a
29. Emi ó sì gbé oluṣọ-agutan kan soke lori wọn, oun ó sì bọ́ wọn, àní Dafidi iranṣe mi.—Esek. 34:23. w-YR 1/1/93 4, 5a
30. Oluwa Jehofa ti fi ahọn akẹkọọ fun mi, ki emi ki o le mọ̀ bi a ti i sọrọ ni akoko fun alaarẹ, o ń ji ni orowurọ, o ṣi mi ni eti lati gbọ́ bi akẹkọọ.—Isa. 50:4. w-YR 11/1/92 20, 21a
31. Bi baba ti i ṣe ìyọ́nú si awọn ọmọ, bẹẹ ni Oluwa ń ṣe ìyọ́nú si awọn tí ó bẹru rẹ̀. Nitori tí ó mọ ẹda wa; o ranti pe erupẹ ni wá.—Orin Da. 103:13, 14. w-YR 9/15/92 15, 16