ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 2/1 ojú ìwé 19
  • ‘Orúkọ Jehofa Ilé-Ìṣọ́ Agbára Ni’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • ‘Orúkọ Jehofa Ilé-Ìṣọ́ Agbára Ni’
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ó Ṣì Wàláàyè!
  • Agbára Àdúrà
  • Gbára Lé Ẹ̀mí Ọlọ́run Nígbà Tí Ipò Nǹkan Bá Yí Padà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • “Kọ́ Mi Láti Máa Ṣe Ìfẹ́ Rẹ”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Jèhófà Jẹ́ “Olùpèsè Àsálà” Láyé Ìgbà Tí Wọ́n Ń kọ Bíbélì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ọba Dáfídì Dẹ́ṣẹ̀
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 2/1 ojú ìwé 19

Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn

‘Orúkọ Jehofa Ilé-Ìṣọ́ Agbára Ni’

ÀWA ń gbé ní àwọn àkókò tí kò fẹsẹ̀múlẹ̀. Ìgbésí-ayé wa tí ó dàbí èyí tí ó fẹsẹ̀múlẹ̀ le yípadà lójijì, àti pé láìròtẹ́lẹ̀ àwọn kan ti bá araawọn nínú ewu ńlá ṣáájú kí wọ́n tó mọ̀. Ewu lè wá láti inú ìrugùdùsókè òṣèlú, akọluni oníwà-ipá, ìjábá ti ìṣẹ̀dá, tàbí àmódi lílekoko. Ohun yòówù kí ọ̀ràn náà jẹ́, níbo ni Kristian kan níláti yíjú sí nígbà tí ìwàláàyè rẹ̀ bá wà nínú ewu?

David, míṣọ́nnárì kan tí ń gbé ní ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ka Watch Tower Society, kẹ́kọ̀ọ́ ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn láti inú ìrírí kan tí ń da jìnnìjìnnì boni. Gẹ́gẹ́ bí awakọ̀ kan tí a yanṣẹ́ fún, ó gbọ́kọ̀ sọ́nà ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kan láti lọ́ gbé àwọn òṣìṣẹ́ Beteli tí a ń fọkọ̀ gbé (àwọn olùyọ̀ǹda ara-ẹni tí wọn ń gbé lẹ́yìn òde ẹ̀ka náà). Ilẹ̀ kò tí ì mọ́ tán. Ó ti gbé Rosalía ó sì ń gba àgọ́ ọlọ́pàá kan kọjá nígbà tí ó gbúròó ìbọn yíyìn àkọ́kọ́.

Lẹ́yìn náà àwọn nǹkan yára ṣẹlẹ̀ ní kíákíá. Ó gbọ́ ariwo kan tí ó jọ ti àkójọ iná tí ń búgbàù ó sì wá mọ̀ pé afẹ́fẹ́ ń jò jáde láti inú ọ̀kan lára àwọn táyà mọ́tò náà. Lójijì ni ó rí ṣójà kan tí ó dúró sáàárín títì tí ó sì na ìbọn ráífù kan síi. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ohun mẹ́ta ni ó ṣẹlẹ̀ lẹ́sẹ̀kan náà: Ìbọn yíyìn léraléra dá ihò sí ẹ̀gbẹ́ ọkọ̀ Jeep náà, tí ó sì fọ́ àwọn wíndò náà; David àti Rosalía forípamọ́; ṣójà náà yìnbọn gba inú gíláàsì iwájú ọkọ̀ kọjá ní déédéé ibi ojú wọn.

Bí wọ́n ti yìnbọn lu ọkọ̀ Jeep ná lára léraléra, David tẹ búréèkì bí ó ti lè ṣe é tó ní títẹríba síbẹ̀. David àti Rosalía ronú pé àwọn yóò kú. Wọ́n gbàdúrà sókè ketekete sí Jehofa, ní sísọ fún un pé kí ó fi ìṣọ́ rẹ̀ ṣọ́ àwọn. Rosalía sọ lẹ́yìn ìgbà náà pé òun ṣe kàyéfì ní àwọn àkókò wọ̀nyẹn nípa ohun tí yóò jẹ́ ìhùwàpadà ìdílé òun nígbà tí wọ́n bá gbọ́ pé òun ti kú!

Ó Ṣì Wàláàyè!

Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, ariwo ìbọn yíyìn àti gíláàsì tí ń fọ́ yángá mọ́wọ́ dúró, David sì gbójúsókè wo Rosalía. Nígbà tí ó rí ipa ẹ̀jẹ̀ kékeré kan tí ó yí ọrùn rẹ̀ ká, jìnnìjìnnì dà bò ó. Ṣùgbọ́n ègé gíláàsì kan tí ó jábọ́ ni ó wọlé síbẹ̀ kìí ṣe ọta. Ibi tí àwọn gíláàsì tí ó fọ́ náà ti gún un ní orúnkún ń ṣẹ̀jẹ̀, ṣùgbọ́n yàtọ̀ sí ìwọ̀nyẹn ó dàbí ẹni pé kò sí ohun tó ṣe é.

Àwọn ọkùnrin tí wọ́n wọ aṣọ ológun tí wọ́n sì wé aṣọ funfun mọ́ ọrùn ọwọ́ rìn wá síbi ọkọ̀ Jeep náà wọ́n sì pàṣẹ fún wọn láti bọ́ sílẹ̀ ní kíkáwọ́ sókè. Ọ̀kan, tí ó jọ pé ipò-oyè rẹ̀ ga jù nínú wọn, yíjúsí ṣójà kan tí ó sì wí pé: “A ti sọ fún yín láti máṣe yìnbọn lu ẹni tí kìí bá ṣe ológun.” Ṣójà náà wá àwọn àwáwí, ní sísọ pé òun gbúròó ìbọn yíyìn òun sì rò pé láti inú ọkọ̀ Jeep náà ni ó ti wá.

Nígbà tí David fi araarẹ̀ àti Rosalía hàn gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jehofa, wọ́n hùwàpadà lọ́nà rere. Ó ṣàlàyé ohun tí òun ti ń ṣe, ṣùgbọ́n àwọn ṣójà náà ṣì fẹ́ láti dá wọn dúró. Ó dàbí ẹni pé ní kùtùkùtù òwúrọ̀ náà, ẹgbẹ́ ológun kan ti pète ìfipágbàjọba, àwọn ṣójà wọ̀nyí sì ti wà lẹ́nu gbígba àgọ́ ọlọ́pàá náà bí David àti Rosalía ti ń kọjá lọ nínú ọkọ̀ Jeep náà.

Ọkàn Rosalía ti gbọgbẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀ ṣùgbọ́n ó fìgboyà parọ́rọ́ bí David ti ń bẹ̀bẹ̀ pé kí wọ́n dá wọn sílẹ̀. Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀ wọ́n yọ̀ǹda wọn láti fi ibẹ̀ sílẹ̀​—⁠láìgbé ọkọ̀ Jeep náà. Wọ́n níláti gba ojú-ọ̀nà kan tí ó wà nítòsí lọ wọ́n sì wọ bọ́ọ̀sì padà sí ẹ̀ka ọ́fíìsì, níbi tí ẹ̀ka-iṣẹ́ tí ń pèsè ìtọ́jú ti bójútó Rosalía.

Agbára Àdúrà

David kẹ́kọ̀ọ́ ohun kan láti inú ìrírí náà​—⁠máṣe ka agbára àdúrà ti a fi ìtara gbà sí èyí tí ó kéré ju bí ó ti yẹ lọ, má sì ṣe gbàgbé láé pé fífi àìṣojo fi ara ẹni hàn gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa máa ń fìgbà gbogbo jẹ́ ààbò. Ó lè jẹ́ òtítọ́ níti gidi pé ‘orúkọ Jehofa ilé-ìṣọ́ agbára ni: Olódodo sá wọ inú rẹ̀, ó sì là.’​—⁠Owe 15:29; 18:10; Filippi 4:⁠6.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 19]

Fotografía de Publicaciones Capriles, Caracas, Venezuela

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́