‘Ewé Ìwé Kanṣoṣo Lè Jáwọ Inú Òkùnkùn Lọ Bí Ìràwọ̀’
LÓNÌÍ, ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní apá ibi gbogbo lágbàáyé. Bí ó ti wù kí ó rí, ìjà tí a ń jà lé Bibeli lórí ti sábà máa ń jẹ́ ọ̀ràn ìyè àti ikú.
Nínú ìwé náà Fifteenth Century Bibles, Wendell Prime kọ̀wé pé: “Ní ọgbọ̀n ọdún lẹ́yìn ìhùmọ̀ ìwé títẹ̀, Ìwádìí Láti Gbógunti Àdámọ̀ ń bá iṣẹ́ lọ lọ́nà yíyọrísírere pátápátá ní Spain. Lára àwọn 342,000 ènìyàn tí a lò ó láti fìyàjẹ ní orílẹ̀-èdè náà 32,000 ni a sun lóòyẹ̀. Bibeli ni ó sọ wọ́n di ẹni tí ó fojúwiná ikú ajẹ́rìíkú. Èyí tí ó tún banilẹ́rù bákan náà ni aṣojú ìpanirun yìí ní Italy, ní àríwá àti gúúsù. Bí Ìwádìí Láti Gbógunti Àdámọ̀ náà ti jẹ́ àrànṣe fún wọn, àwọn bíṣọ́ọ̀bù àgbà jẹ́ ajónirun iná fún àwọn Bibeli àti àwọn tí ń kà wọ́n. Nero mú kí àwọn Kristian mélòókan tànyòò bí ìmọ́lẹ̀ nínú ayé nípa dídánásun wọ́n, rírán àpò mọ́ wọn lára, fífi ọ̀dà kùn wọ́n, lílò wọ́n gẹ́gẹ́ bí àbẹ́là láti tànmọ́lẹ̀ sí ìrísí ìran àwọn àríyá ẹhànnà rẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn iná gbangba tí a fi Bibeli dá jówòwò ní àwọn òpópónà ìlú-ńlá Europe. Àwọn Bibeli kò dàbí àwọn òǹkàwé tí a lè sọ di òtòṣì, tí a lè bọ́láṣọ, dálóró, sọ di aláàbọ̀-ara kí a sì lé sọnù. Kódà ewé ìwé kanṣoṣo tí ó bá làájá lè jáwọ inú dídúdú òkùnkùn yìí lọ bí ìràwọ̀.” (Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.)
Ohun tí òǹṣèwé Prime ṣàpèjúwe ṣẹlẹ̀ níti gidi nínú ọ̀ràn ojú-ìwé Bibeli náà tí a tún mújáde níhìn-ín yìí. Ó jẹ́ ojú-ìwé tí a ń pè ní colophon, ìyẹn ni pé, ojú-ewé ẹ̀yìn ìwé níbi tí a kọ orúkọ olùtúmọ̀ sí. Àwọn òpó-ìlà méjì tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ araawọn lókè jẹ́ àwọn ẹsẹ̀ tí ó gbẹ̀yìn nínú ìwé Ìṣípayá, tàbí ìwé Ìfihàn.
Nípa ìwé yìí, The Cambridge History of the Bible sọ pé: “Ìtumọ̀ Bibeli sí èdè Catalonia ti Bonifacio Ferrer ni a tẹ̀ ní Valencia, ní 1478; gbogbo ẹ̀dà tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó ni Ìwádìí Láti Gbógunti Àdámọ̀ ti jó dànù ṣáájú 1500, ṣùgbọ́n ewé ìwé kanṣoṣo làájá níbi àkójọ ìwé kíkà Hispanic Society ti America.” (Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.)
Wendell Prime tún ṣàlàyé pé: “Lójú àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì tí jìnnìjìnnì ti dàbò ọ̀nà kanṣoṣo tí ó ní ìtẹ́wọ́gbà tí a lè gbà lò sí Bibeli ni láti fi iná sun ún. Àwọn iná mímọ́ wọ̀nyí ìbá túbọ̀ jẹ́ lemọ́lemọ́ kí ó sì tan ìtànṣán síi lọ́pọ̀lọpọ̀ bíkòṣe ti epo tí kò tó. Ní àwọn ibi púpọ̀ kò sí àwọn iná gbangba tí a fi sun Bibeli kìkì nítorí pé àwọn aláṣẹ wà lójúfò gan-an débi pé kò sí Bibeli kankan tí a lè sun níná.” Láìka irú àwọn ìsapá gbígbónájanjan bẹ́ẹ̀ sí láti pa Bibeli tí ó yẹ kí ó wà fún àwọn ènìyàn gbáàtúù run, ọ̀pọ̀ ẹ̀dà bọ́ lọ́wọ́ ìparun. Prime fikún un pé: “Bibeli ni a pamọ́ nípa gbígbé tí àwọn ìgbèkùn ń gbé wọn lọ, tàbí nípa pípa wọ́n mọ́ bí òkúta àti metal ṣíṣeyebíye ní àwọn àkókò ìdààmú àti ewu.”
Wòlíì Ọlọrun Isaiah kọ̀wé pé: “Gbogbo ẹran-ara ni koríko . . . Koríko ń rọ, ìtànná ń rẹ̀: ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ọlọrun wa yóò dúró láéláé.” (Isaiah 40:6, 8) Láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún wá, ogunlọ́gọ̀ àwọn olùfẹ́ Bibeli àti àwọn olùtúmọ̀ onígboyà ti fi ohun púpọ̀ wewu wọ́n sì ti jẹ ìyà ńláǹlà nítorí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Síbẹ̀, ìsapá àwọn ènìyàn nìkanṣoṣo kì bá tí tó láti mú ìtọ́júpamọ́ rẹ̀ dájú. Fún ìtọ́júpamọ́ yìí, a dúpẹ́ lọ́wọ́ Òǹṣèwé Bibeli, Jehofa.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 7]
Ìyọ̀ọ̀da onínúure ti The Hispanic Society of America, New York