“Ẹja Pípa” Nínú Àwọn Omi Fiji
FIJI—orúkọ náà gbé àwòrán paradise àwọn Òkun Gúúsù yọ síni lọ́kàn. Àwọn omi dúdú bí aró, àwọn òkúta iyùn, àwọn imọ̀ àgbọn tí ń jù riyẹriyẹ, àwọn òkè-ńlá oníkoríko, ẹja ilẹ̀ olóoru, àwọn èso àti òdòdó àmútòkèèrèwá. Ìwọ lè rí gbogbo ìwọ̀nyí ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ níbi àwọn àgbájọ 300 erékùṣù wọ̀nyí tí wọ́n fẹ̀ tó 1,800 kìlómítà ní ìhà àríwá New Zealand ní Gúúsù Pacific. Fún ìdí yìí, ìwọ lè gbà pé Fiji lè jẹ́ paradise ilẹ̀ olóoru kan tí olúkúlùkù ènìyàn fi ń láàlá.
Bí ó ti wù kí ó rí, ohun tí Fiji fi fanimọ́ra ju ẹwà àdánidá rẹ̀ lọ. Bẹ́ẹ̀ni, bí ìyàtọ̀ ńláǹlà ti wà lára àwọn ẹja àárín òkúta iyùn inú omi, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni a tún rí ìyàtọ̀ ńláǹlà lórí ilẹ̀. Ìyàtọ̀ tí ó wà nínú àwùjọ àwọn ẹ̀yà tí wọ́n dàpọ̀mọ́ra ní Fiji, fẹ́rẹ̀ jẹ́ èyí tí kò ní alábàádọ́gba ní Gúúsù Pacific. Àwọn àwùjọ méjì tí wọ́n tóbi jùlọ lára àwọn olùgbé tí ó fẹ́rẹ̀ tó 750,000 tí wọ́n ń gbé níbẹ̀ jẹ́ àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Fiji, tí wọ́n ṣẹ̀ wá láti Melanesia, àti àwọn India tí a bí ní Fiji, àtọmọdọ́mọ àwọn òṣìṣẹ́ tí a mú wọlé wá láti India ní ìgbà tí àwọn ará Britain ń gbókèèrè ṣàkóso. Àwọn ará Banaba, China, Europe, Gilbert, Rotuma, Tuvalu, àti àwọn mìíràn tún wà níbẹ̀ pẹ̀lú.
Nínú ẹgbẹ́ àwùjọ ọlọ́pọ̀ àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ yìí, ọwọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa dí fún iṣẹ́ “ẹja pípa.” (Marku 1:17) Ó jẹ́ ìpèníjà láti wàásù ìhìnrere Ìjọba Ọlọrun nínú irú àwùjọ ọlọ́kan-kò-jọ̀kan bẹ́ẹ̀. Lákọ̀ọ́kọ́, àwọn ìdínà ti èdè àti àṣà-ìṣẹ̀dálẹ̀ wà láti ṣẹ́pá. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Gẹ̀ẹ́sì ni èdè àjọsọ wọn, lọ́pọ̀ ìgbà ni a gbọ́dọ̀ lo èdè Fijian, Hindi, Rotuman, tàbí àwọn èdè mìíràn.
Ọ̀nà ìgbàyọsíni ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní a tún gbọ́dọ̀ lò láti jùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ pẹ̀lú àwọn wọnnì tí ipò àtilẹ̀wá ìsìn wọn yàtọ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Fiji àti àwọn olùgbé erékùṣù mìíràn jẹ́ mẹ́ḿbà onírúurú ẹ̀ka-ìsìn Kristian. Àwọn olùgbé ìlú tí wọ́n jẹ́ ará India ní àwọn Hindu, Mùsùlùmí, àti Sikh nínú, àwọn Hindu ni wọ́n sì pọ̀ jùlọ. Àwọn ṣọ́ọ̀ṣì pọ̀ rẹpẹtẹ ní àwọn ìlú àti abúlé, ṣùgbọ́n ní àwọn erékùṣù méjì tí wọ́n tóbi jùlọ ní Fiji, ọ̀pọ̀ àwọn tẹ́ḿpìlì Hindu àti mọ́ṣáláṣí àwọn Mùsùlùmí náà mú ìyàtọ̀ wá ní ìfiwéra.
Ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí àdúgbò ti kọ́ láti máa sọ àwọn èdè pàtàkì mẹ́tà náà—Gẹ̀ẹ́sì, Fijian, àti Hindi. Níní òye yìí jẹ́ àǹfààní ńlá nínú iṣẹ́ “ẹja pípa” náà. Nígbà mìíràn ó máa ń ya àwọn ènìyàn lẹ́nu láti gbọ́ tí ará Fiji ń sọ èdè Hindi jíjágaara tí ará India sì ń sọ èdè Fiji jíjágaara. Pẹ̀lú àwọn ìyàtọ̀ ti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀, ìsìn, àti èdè tí wọ́n níláti kojú rẹ̀, ó béèrè fún mímọwọ́ọ́yípadà nínú ọ̀nà ìgbàyọsíni láti lè jẹ́ “alájọpín ninu [ìhìnrere] pẹlu awọn ẹlòmíràn.”—1 Korinti 9:23, NW.
“Ẹja Pípa” ní Abúlé Fiji Kan
Àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Fiji jẹ́ àwọn ènìyàn oníwà-bí-ọ̀rẹ́, olùfẹ́ àlejò-ṣíṣe. Ó ṣòro láti ronú pé ní ohun tí ó fi díẹ̀ ju ọ̀rúndún kan sẹ́yìn, ogun láàárín ẹ̀yà wọ́pọ̀. Níti tòótọ́, nígbà tí àwọn ará Europe ṣe ìbẹ̀wò wọn àkọ́kọ́, Fiji ní a mọ̀ sí Erékùṣù Ajẹ̀nìyàn. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, lẹ́yìn tí olóyè pàtàkì kan gorí oyè tí ó sì tẹ́wọ́gba ìsìn Kristian, ìjà jíjà àti ìjẹ̀nìyàn kásẹ̀nílẹ̀. Nínú ọ̀pọ̀ àwọn èdè àdúgbò tí a ń sọ ní onírúurú àwọn ẹkùn ìpínlẹ̀ náà nìkan ni àwọn ìyàtọ̀ láàárín ẹ̀yà ṣẹ́kù sí, bí ó tílẹ̀ jẹ́ pé èdè àdúgbò náà Bauan ní a ṣì lóye nibi púpọ̀.
Ní àfikún sí Suva, olú-ìlú, ọ̀pọ̀ àwọn ìlú ni wọ́n wà jákèjádò Fiji. Ọ̀pọ̀ jùlọ lára àwọn ará Fiji ń gbé ní àwọn àwùjọ abúlé tí ó wà lábẹ́ ìdarí turaga ni koro, tàbí baálé. Nígbà tí a bá ń wọlé lọ láti kópa nínú “ẹ̀ja pípa,” ó jẹ́ àṣà láti tọ ọkùnrin yìí lọ láti gba ìyọ̀ọ̀da láti ṣèbẹ̀wò sí onírúurú àwọn bure, tàbí ilé àdúgbò. Kìkì lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan ni a kìí rí ìyọ̀ọ̀da gbà, èyí sì sábà máa ń jẹ́ nítorí àtakò tí àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì díẹ̀ ní abúlé ń ṣe sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Báwo ni ṣíṣe ìbẹ̀wò sí ilé ara Fiji kan ti máa ń rí?
Ní wíwọnú bure kan, a óò jókòó sílẹ̀ ní gbígbé ẹsẹ̀ lé orí araawọn. Níhìn-ín, a kò nílò ìnasẹ̀-ọ̀rọ̀ kan tí a fi tìṣọ́ratìṣọ́ra sọ, irú èyí tí a ń lò láti fa ọkàn-ìfẹ́ mọ́ra ní àwọn ilẹ̀ Ìwọ̀-Oòrùn. Wọ́n ń gba ẹnikẹ́ni tí ó bá wá láti sọ̀rọ̀ nípa Ọlọrun tọwọ́tẹsẹ̀. Nígbà tí a bá rọ̀ ọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀, onílé náà á fi pẹ̀lú ìmúratán dìde nílẹ̀, ní sísọ gbólóhùn náà “tulou” (mo tọrọ gáfárà), a lọ síbi pẹpẹ ìkówèésí rẹ̀ láti mú ẹ̀dà Bibeli kan ní èdè Fiji yóò sì fi ìháragàgà ka onírúurú àwọn ẹsẹ̀ Ìwé Mímọ́ tí òjíṣẹ́ tí ó bẹ̀ ẹ́ wò náà bá mẹ́nukàn. Bí ó ti wù kí ó rí, ìṣesí àwọn ará Fiji ti jíjẹ́ olùfẹ́ àlejò-ṣíṣe àti ẹni tí ó bọ̀wọ̀ fúnni gbé ìpèníjà dìde ní ọ̀nà kan tí ó yàtọ̀. Ìfòyemọ̀ àti ọgbọ́n-ẹ̀wẹ́ púpọ̀ ni a nílò láti fa àwọn onílé wọnú ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀, láti fún wọn ní ìṣírí láti máa fí ọkàn bá ọ̀nà ìgbàronú tí a ń bá bọ̀ nìṣó, tàbí láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí àìní náà láti fi ìgbàgbọ́ tiwọn wéra pẹ̀lú ẹ̀kọ́ Bibeli.
Àwọn onílé tí wọ́n jẹ́ ará Fiji sábà máa ń lọ́kàn-ìfẹ́ jù nínú jíjíròrò àwọn àkòrí tí ó dálórí ẹ̀kọ́-ìsìn ju sísọ̀rọ̀ nípa àwọn ipò tàbí ọ̀ràn ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà. Níti tòótọ́, ọ̀pọ̀ lára iye tí ó ju 1,400 àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tí ń ṣe déédéé ní Fiji di ẹni tí ó fìfẹ́hàn nínú òtítọ́ Bibeli nítorí ìjíròrò kan lórí irú àwọn ìbéèrè bíi, Irú ibo ni hẹ́ẹ̀lì jẹ́? Àwọn wo ni ó ń lọ sí ọ̀run? àti A ó ha pa ilẹ̀-ayé run bí? Bí ó ti wù kí ó rí, pípadà ṣiṣẹ́ lórí ọkàn-ìfẹ́ tí a fihàn béèrè fún ìmọwọ́ọ́yípadà àti ìforítì. Ní pípadà lọ ní àkókò tí a fohùnṣọ̀kan lé lórí, ẹnìkan sábà máa ń rí i pé onílé náà ti lọ sí teitei (oko) tàbí ibòmíràn. Bẹ́ẹ̀kọ́, kìí ṣe pé wọn kò ní ìmọrírì fún ìbẹ̀wò náà ṣùgbọ́n ó wulẹ̀ jẹ́ pé ojú-ìwòye wọn nípa àkókò yàtọ̀. Àmọ́ ṣáá, èyí kò dàbí ohun tí kò wọ́pọ̀ lójú àwọn Ẹlẹ́rìí àdúgbò. Wọ́n tẹramọ́ ọn nípa bíbẹ̀ wọ́n wò ní ìgbà mìíràn. Kò sí àwọn orúkọ àdúgbò tàbí nọ́ḿbà ilé tí a lè kọ sílẹ̀, nítorí náà ẹnìkan nílò agbára ìrántí tí ó dára nígbà tí ó bá ń padà ṣèbẹ̀wò.
“Ẹja Pípa” Lọ́nà tí Àwọn Ará Polynesia
Nísinsìnyí, ẹ jẹ́ kí a lọ sẹ́nu iṣẹ́ “ẹja pípa” pẹ̀lú òjíṣẹ́ arìnrìn-àjò, tàbí alábòójútó àyíká kan, bí ó ti ń ṣèbẹ̀wò sí ìjọ kékeré náà tí ó wà ní Rotuma. Àwùjọ tí ń bẹ ní erékùṣù òkè-ayọnáyèéfín yìí wà ní 500 kìlómítà sí ìhà àríwá Fiji. Láti débẹ̀, a rìnrìn-àjò nínú ọkọ̀ òfuurufú tí ó ní ìjókòó fún ènìyàn 19. Erékùṣù gbígbòòrò jùlọ náà jẹ́ 50 kìlómítà níbùú-lóòró yíká, pẹ̀lú àpapọ̀ nǹkan bíi 3,000 àwọn olùgbé. Ọ̀nà oníyanrìn kan gba ibi ilẹ̀ bèbè-etikún kọjá, ní síso nǹkan bíi 20 abúlé mọ́ra. Fiji ni ó ń ṣàkóso Rotuma ṣùgbọ́n ó ní àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àti èdè tí ó yàtọ̀. Nítorí pé Polynesia ni wọ́n ti ṣẹ̀ wá, ìrísí àwọn ènìyàn náà yàtọ̀ sí ti àwọn ará Fiji tí wọ́n ṣẹ̀ láti Melanesia. Níti ìsìn, ọ̀pọ̀ jùlọ nínú wọn jẹ́ yálà onísìn Roman Katoliki tàbí Mẹ́tọ́díìsì.
Bí ọkọ̀ òfuurufú náà ti ń balẹ̀ tí ó sì ń ràbàbà láti wá ibi dúró sí, a rí ọ̀pọ̀ ewéko tútù minimini tí ń bẹ ní erékùṣù náà. Àwọn màrìwò yẹbẹyẹbẹ ti igi àgbọn ni a lè rí ní ibi gbogbo. Àgbájọ àwọn ènìyàn púpọ̀ ti wà níbẹ̀ láti kí ọkọ̀ òfuurufú tí ń dé lẹ́ẹ̀kan lọ́sẹ̀ náà káàbọ̀. Lára wọn ni àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí wà. Wọ́n fi tọ̀yàyàtọ̀yàyà kí wa káàbọ̀, wọ́n sì fi àwọn àgbọn títobi mélòókan tí wọ́n ti já “lójú” lé wa lọ́wọ́ láti fi pòùngbẹ.
Lẹ́yìn ìrìn-àjò ráńpẹ́ kan, a dé sí ibùgbé wa. Wọ́n ti pèsè ohun jíjẹ kan tí a yan lórí ààrò tí a gbẹ́lẹ̀ fún. Àyangbẹ ẹlẹ́dẹ̀, adìẹ, ẹja díndín, edé, àti irè-oko àdúgbò, taro, ni wọ́n gbékalẹ̀ fún wa. Àsè náà mà dùnyùngbà o, ẹ sì wo bí ìrísí àyíká náà ti dàbí paradise lábẹ́ àwọn igi àgbọn kékeré náà!
Ní ọjọ́ kejì a ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn inú abúlé náà, ho’aga ní èdè Rotuma. Bí a ti yọ sí ilé àkọ́kọ́, ọmọ ẹlẹ́dẹ̀ kan tí ó yọ́pọ́rọ́ jáde láti inú ọ̀kan lára àwọn ilé ẹlẹ́dẹ̀ náà sáré kọjá wa, ó sì ń pariwo bí ó ti ń lọ. Onílé náà ti rí wa bí a ti ń bọ̀ ó sì ṣílẹ̀kùn pẹ̀lú ẹ̀rín músẹ́, ní kíkí wa pé “Noya!” ní èdè Rotuma, lẹ́yìn náà ni ó késí wa láti jókòó. Àwo ọ̀gẹ̀dẹ̀ pípọ́n ní a gbékalẹ̀ níwájú wa, a sì tún késí wa láti mu omi àgbọn tí kò tíì gbó. Àlejò ṣíṣe ni ohun àkọ́kọ́ ní Rotuma.
Kò sí àwọn onígbàgbọ́ Ọlọrun kòṣeémọ̀ tàbí àwọn onígbàgbọ́ ẹfolúṣọ̀n níhìn-ín. Olúkúlùkù ènìyàn ní ìgbàgbọ́ nínú Bibeli. Àwọn kókó-ẹ̀kọ́ bí ète Ọlọrun fún orí ilẹ̀-ayé máa ń tètè fa àfiyèsí wọn mọ́ra lọ́nà rírọrùn. Ó ya onílé náà lẹ́nu láti mọ̀ pé a kì yóò pa ilẹ̀-ayé run ṣùgbọ́n pé àwọn olódodo tí yóò gbé nínú rẹ̀ títíláé ni yóò wà níbẹ̀. (Orin Dafidi 37:29) Ó ń fi ọkàn báa lọ tímọ́tímọ́ nígbà tí a ka àwọn ẹsẹ̀ Ìwé Mímọ́ tí ó fìdí kókó yìí múlẹ̀, ó sì fi ìháragàgà tẹ́wọ́gba àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli tí a fi lọ̀ ọ́. Bí a ti gbéra láti máa lọ, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ wa fún wíwá sọ́dọ̀ rẹ̀ ó sì fún wa ní ọ̀rá kan tí ó kún fún ọ̀gẹ̀dẹ̀ pípọ́n tí a lè jẹ lójú ọ̀nà. Wíwàásù níhìn-ín mà lè tètè mú ènìyàn sanra o!
Mímú Ara Bá Ipò Àwùjọ India Mu
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn tí wọ́n jẹ́ erékùṣù ní Gúúsù Pacific pẹ̀lú jẹ́ ọlọ́pọ̀ ẹ̀yà, ti Fiji yàtọ̀ gedegbe. Àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àwọn ará Melanesia, Micronesia, àti Polynesia wà ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú èyí tí a mú wọlé wá láti Asia. Láàárín ọdún 1879 àti 1916, àwọn òṣìṣẹ́ láti India tí ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ àdéhùn ní a kó wá láti ṣiṣẹ́ nínú àwọn pápá ìrèké. Ìṣètò yìí, tí a pè ní girmit (àdéhùn), yọrísí wíwá tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ará India wá sí Fiji. Àtọmọdọ́mọ àwọn òṣìṣẹ́ wọ̀nyí parapọ̀ jẹ́ apá títóbi kan nínú àwọn olùgbé orílẹ̀-èdè náà. Àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀, èdè, àti ìsìn wọn kò tíì yípadà.
Ní ìhà òdìkejì ibi tí afẹ́fẹ́ okun ń darí sí ní erékùṣù gbígbòòrò jùlọ ti ilẹ̀ Fiji ni ìlú-ńlá Lautoka wà. Èyí ni àárín gbùngbùn ilé-iṣẹ́ ìrèké Fiji ó sì jẹ́ ilé fún apá tí ó pọ̀ nínú àwọn ará India tí ń gbé nínú orílẹ̀-èdè náà. Àwọn mẹ́ḿbà ìjọ mẹ́ta ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tí wọ́n wà níhìn-ín gbọ́dọ̀ mọwọ́ọ́yípadà nínú iṣẹ́ “ẹja pípa” wọn. Nígbà tí ẹnìkan bá ń ṣèbẹ̀wò láti ilé-dé-ilé, ó níláti wà ní ìmúrasílẹ̀ láti yí àwọn àkòrí ọ̀rọ̀ padà ní sísinmilórí ẹ̀yà àti ìsìn onílé náà. Ẹ jẹ́ kí a darapọ̀ mọ́ àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí àdúgbò bí wọ́n ti ń ṣèbẹ̀wò sí àwọn ilé tí ó wà káàkiri ní àwọn pápá ìrèké ní ẹ̀yìn-òde Lautoka gan-an.
Bí a tí yọ sí ilé àkọ́kọ́, a ṣàkíyèsí àwọn igi ọparun gígùn kan tí a so ìrépé aṣọ pupa mọ́ lókè ní ẹ̀gbẹ́ kan ní apá iwájú àgbàlá náà. Èyí fihàn pé onísìn Hindu ni ìdílé náà. Ọ̀pọ̀ jùlọ lára ilé àwọn India ní a fi àwòrán àwọn ọlọrun wọn ṣe ní ọ̀ṣọ́. Ọ̀pọ̀ ní àwọn ọlọrun àyànláàyò, bíi Krishna, wọ́n sì máa ń sábà ní ojúbọ kékeré kan.a
Ọ̀pọ̀ jùlọ lára àwọn India gbàgbọ́ pé gbogbo ìsìn ni ó dára ṣùgbọ́n pé wọ́n jẹ́ ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láti gbà jọ́sìn. Nípa báyìí, onílé kan lè fetísílẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, kí ó gba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ díẹ̀, kí ó fúnni ní ìpanu, kí ó sì ronú pé òun ti ṣe ojúṣe òun. Láti gbé ìbéèrè yíyẹ dìde láti fa àwọn onílé wọnú àwọn ìjíròrò tí ó túbọ̀ nítumọ̀, ó sábà máa ń ṣèrànlọ́wọ́ láti mọ díẹ̀ lára àwọn ìtàn tí ó jẹ́ apákan ìgbàgbọ́ wọn. Fún àpẹẹrẹ, bí a ti mọ̀ pé díẹ̀ lára àwọn ìtàn wọn sọ nípa àwọn ọlọrun tí wọ́n fi àwọn ìwà tí ọ̀pọ̀ ènìyàn yóò gbé ìbéèrè dìde sí kẹ́rabàjẹ́, a lè béèrè pé: “Ìwọ yóò ha gba aya (ọkọ) rẹ láyè láti hu irú ìwà bẹ́ẹ̀ bí?” Ìdáhùn náà sábà máa ń jẹ́: “Bẹ́ẹ̀kọ́, kí a má ríi!” Lẹ́yìn náà, a lè ti ìbéèrè náà sí ẹni náà pé: “Ó dára, ó ha yẹ kí ọlọrun kan hùwà lọ́nà bẹ́ẹ̀ bí?” Irú àwọn ìjíròrò bẹ́ẹ̀ sábà máa ń ṣí àǹfààní sílẹ̀ fún fífi ìníyelórí Bibeli hàn.
Ìgbàgbọ́ nínú àtúnwáyé, tí ó jẹ́ apá ẹ̀ka mìíràn nínú ìsìn Hindu, jẹ́ kókó-ẹ̀kọ́ amésojáde kan láti jíròrò lélórí. Obìnrin ọ̀mọ̀wé kan tí ó jẹ́ onísìn Hindu tí baba rẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ kú ní a béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ìwọ yóò ha fẹ́ láti tún rí baba rẹ gẹ́gẹ́ bí ó ti wà rí bí?” Ó dáhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ni, ohun àgbàyanu ni ìyẹn yóò jẹ́.” Láti inú ìdáhùn rẹ̀ àti ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ tí ó tẹ̀lé e, ó ṣe kedere pé ìgbàgbọ́ náà pé baba rẹ̀ wàláàyè ní irú ọ̀nà mìíràn kan nísinsìnyí àti pé kò tún ní mọ̀ ọ́n mọ́ ko tẹ́ ẹ lọ́rùn. Ṣùgbọ́n ẹ̀kọ́ àgbàyanu ti Bibeli nípa àjínde wọ̀ ọ́ lọ́kàn ṣinṣin.
Àwọn India díẹ̀ máa ń ní ìbéèrè wọ́n sì ń wá àwọn ìdáhùn tí ó tẹ́nilọ́rùn kiri. Nígbà tí Ẹlẹ́rìí kan ṣèbẹ̀wò sí ilé onísìn Hindu kan, ọkùnrin náà bi í pé: “Kí ni orúkọ ọlọrun rẹ?” Ẹlẹ́rìí náà ka Orin Dafidi 83:18 fún un ó sì sàlàyé pé Jehofa ni orúkọ Ọlọrun àti pé Romu 10:13 sọ pé láti jèrè ìgbàlà a gbọ́dọ̀ képe orúkọ yẹn. Ó wọ ọkùnrin náà lọ́kàn ó sì fẹ́ láti mọ púpọ̀ síi. Níti tòótọ́, ó fi pẹ̀lú ìgbékútà fẹ́ láti mọ̀ síi. Ó ṣàlàyé pé baba òun, tí ó ní ìfọkànsìn fún òrìṣà ìdílé àwọn, dùbúlẹ̀ àìsàn lẹ́yìn jíjọ́sìn níwájú rẹ̀ ó sì kú láìpẹ́ lẹ́yìn náà. Ohun kan-náà ni ó ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin. Lẹ́yìn náà ni ó fikún un pé: “Ikú ni ère yẹn ń mú wá sórí wa, kìí ṣe ìyè. Nítorí náà ohun kan níláti lòdì nípa jíjọ́sìn rẹ̀. Bóyá Ọlọrun tí ń jẹ́ Jehofa yìí lè ràn wá lọ́wọ́ láti rí ọ̀nà sí ìyè.” Nítorí náà a bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli kan pẹ̀lú rẹ̀, aya rẹ̀, àti àwọn ọmọ rẹ̀ méjì. Wọ́n tẹ̀síwájú lọ́nà yíyára kánkán kò sì pẹ́ tí wọ́n fi ṣèrìbọmi. Wọ́n ti fi àwọn òrìṣà wọn sílẹ̀ wọ́n sì ń rìn ní ọ̀nà Jehofa, Ọlọrun ìyè nísinsìnyí.
Lẹ́yìn náà ni a dé ilé ìdílé Mùsùlùmí kan. Aájò àlejò-ṣíṣe kan-náà farahàn gbangba, kò sì pẹ́ tí a fi jókòó pẹ̀lú ohun-mímu tí ó tutù ní ọwọ́ wa. A kò rí àwòrán ìsìn kankan lára ògiri yàtọ̀ sí ẹsẹ kékeré kan tí a kọ lédè Lárúbááwá nínú férémù tí a gbékọ́ sára ògiri. A mẹ́nukàn án pé ìsopọ̀ kan tí ó wọ́pọ̀ wà láàárín Bibeli àti Kùránì, ìyẹn ni ti baba ńlá náà Abrahamu, àti pé Ọlọrun ṣèlérí fún Abrahamu pé nípa irú-ọmọ rẹ̀ ní a óò ti bùkún fún gbogbo orílẹ̀-èdè. Ìlérí yìí ní a níláti múṣẹ nínú Ọmọkùnrin Rẹ̀, Jesu Kristi. Àwọn Mùsùlùmí kan kò jẹ́ gbà pé Ọlọrun ní ọmọkùnrin kan. Fún ìdí yìí, a ṣàlàyé pé gẹ́gẹ́ bí a ti pe ọkùnrin àkọ́kọ́, Adamu, ní ọmọkùnrin Ọlọrun nítorí pé Ọlọrun ni ó dá a, ní ọ̀nà kan-náà, Jesu jẹ́ Ọmọkùnrin Ọlọrun. Kò di dandan pé kí Ọlọrun ní ìyàwó gidi kan láti mú irú àwọn ọmọkùnrin bẹ́ẹ̀ jáde. Nítorí pé àwọn Mùsùlùmí kò gbàgbọ́ nínú ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan, a lo èyí gẹ́gẹ́ bíi kókó àjọfohùnṣọ̀kan lélórí láti fihàn pé Jehofa Ọlọrun ni ẹni gíga jùlọ.
Ní báyìí àkókò ti tó fún oúnjẹ ọ̀sán, àwọn mẹ́ḿbà àwùjọ wa sì ti ń padà bọ̀ wá sójú ọ̀nà, láti inú àwọn oko ìrèké, láti dúró de bọ́ọ̀sì tí yóò gbé wa padà lọ sínú ìlú. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti rẹ̀ wá díẹ̀, ìgbòkègbodò “ẹja pípa” ti òwúrọ̀ náà mú ara gbogbo wa yá gágá. Ìsapá tí a ṣe láti mú araawa bá àwọn ipò yíyàtọ̀síra àti àwọn ìgbàgbọ́ tí a bá pàdé náà mu yẹ fún un.
Àwọn omi àti òkúta abẹ́ òkun Fiji kún fún ọ̀pọ̀ oríṣiríṣi ẹja. Láti ṣàṣeyọrísírere, gonedau (apẹja) ilẹ̀ Fiji kan gbọ́dọ̀ jẹ́ ọ̀jáfáfá lẹ́nu iṣẹ́. Ohun kan náà ni ó jẹ́ òtítọ́ nípa iṣẹ́ “ẹja pípa” tí Jesu Kristi yàn fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Àwọn Kristian “apẹja ènìyàn” gbọ́dọ̀ jẹ́ ọ̀jáfáfá, tí wọ́n ń yí ọwọ́ ìgbékalẹ̀ àti àlàyé ọ̀rọ̀ wọn padà láti bá ìgbàgbọ́ yíyàtọ̀síra tí àwọn ará ìlú mu. (Matteu 4:19) Dájúdájú a nílò èyí ní Fiji. Àwọn ìyọrísí náà sì ṣe kedere níbi àpéjọpọ̀ ọdọọdún ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, níbi tí àwọn ará Fiji, India, Rotuma, àti àwọn ènìyàn tí ipò àtilẹ̀wá àwùjọ ẹ̀yà wọn jẹ́ onírúurú ti ń sin Jehofa Ọlọrun ní ìṣọ̀kan. Bẹ́ẹ̀ni, ìbùkún rẹ̀ wà lórí iṣẹ́ “ẹja pípa” nínú àwọn omi Fiji náà.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo ìwé náà Mankind’s Search for God, tí a tẹ̀jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ojú-ìwé 115 sí 117.
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 23]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Viti Levu
Vanua Levu
Suva
Lautoka
Nandi
0 100 km
0 100 mi
18°
180°
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Bure, tàbí ilé àdúgbò
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Tẹ́ḿpìlì Hindu kan ní Fiji
[Àwọ̀n àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Iṣẹ́ ‘apẹja’ ènìyàn tí ó yọrísírere ní Fiji
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 24]
Fiji Visitors Bureau