Wọ́n Darapọ̀ Mọ́ Ẹgbẹ́ Àwọn Ará tí Wọ́n Sopọ̀ṣọ̀kan
Ójẹ́ August 7, 1993, ní Pápá Eré Ìdárayá Republican ní Kiev, Ukraine. Àwọn olùpésẹ̀ tí iye wọn rékọjá 64,000 ń fojúsọ́nà pẹ̀lú ìrètí bí àkókò náà ti tó. Lẹ́yìn náà, ní ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè méjì tí ó nítumọ̀, ẹgbẹẹgbẹ̀rún gbé ohùn wọn sókè pé “Da!” (“Bẹ́ẹ̀ni!”) Ní ọ̀nà yìí, wọ́n ṣe ìjẹ́wọ́ ìgbàgbọ́ wọn ní gbangba tí wọ́n sì lọ lẹ́yìn náà láti fàmìṣàpẹẹrẹ ìyàsímímọ́ wọn sí Jehofa Ọlọrun nípa ìrìbọmi nínú ọ̀kan lára àwọn ìkùdu mẹ́fà tí ń bẹ ní pápá ìṣeré náà.—Matteu 28:19.
Nípa báyìí, ní ọjọ́ kẹta Àpéjọpọ̀ Àgbègbè àgbáyé “Ẹ̀kọ́ Àtọ̀runwá” ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa yìí, àwùjọ náà ṣẹlẹ́rìí ìṣẹ̀lẹ̀ títayọ kan: 7,402 ní a rìbọmi tí wọn sì di, kìí ṣe apákan ṣọ́ọ̀ṣì kan tí ìyapa wà, bíkòṣe ti ìjọ Kristian tí a sopọ̀ṣọ̀kan kárí-ayé.
Bí ìwọ yóò bá fẹ́ láti mọ púpọ̀ síi nípa ìṣọ̀kan Kristian tòótọ́, jọ̀wọ́ kọ̀wé sí Watch Tower, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State, tàbí sí àdírẹ́sì tí ó ṣe wẹ́kú tí a tò sí ojú-ìwé 2.