ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 7/15 ojú ìwé 2-4
  • Ìbẹ̀rù Gbá Aráyé Mú

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbẹ̀rù Gbá Aráyé Mú
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìbẹ̀rù Agbára Átọ́míìkì Ṣì Wà Síbẹ̀
  • Ìwà-Ipá Ń Mú Ìbẹ̀rù Pọ̀ Síi
  • Ìbẹ̀rù Àrùn AIDS
  • Àwọn Wo Ló Ń Gbára Dì fún Ogun Ọ̀gbálẹ̀gbáràwé?
    Jí!—2004
  • Ó Dájú Pé Ewu Ohun Ìjà Ọ̀gbálẹ̀gbáràwé Kò Tíì Kásẹ̀ Nílẹ̀
    Jí!—1999
  • Ìrọ̀dẹ̀dẹ̀ Ewu Agbára Átọ́míìkì Ó Ha Ti Dópin Nígbẹ̀yìngbẹ́yín Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ogun Tí Wọ́n Á Fi Bọ́ǹbù Átọ́míìkì Jà?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 7/15 ojú ìwé 2-4

Ìbẹ̀rù Gbá Aráyé Mú

BỌ́M̀BÙ títóbi fàkìà-fakia tí a gbé pamọ́ sínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan mi Ibùdó Ìṣòwò Àgbáyé alájà 110 tí ó wà ní New York City tìtì ní February 26, 1993. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn òṣìṣẹ́ ni a hámọ́ inú àwọn ẹ̀rọ agbéniròkè tí wọ́n dáwọ́ iṣẹ́ dúró tàbí tí wọ́n níláti sáré sọ̀kalẹ̀ lórí àwọn àtẹ̀gùn tí èéfín bò ṣíbáṣíbá. Wọ́n mọ ìbẹ̀rù tí ó tànkálẹ̀ nísinsìnyí nínú ayé oníwà-ipá yìí lára.

Bọ́m̀bù ti kópayà bá àwọn ènìyàn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilẹ̀, èyí tí ó ti di ohun tí ó wọ́pọ̀ ní àwọn orílẹ̀-èdè bí Ireland àti Lebanon. Họ́wù, 13 búgbàù ní ọjọ́ kanṣoṣo péré​—⁠March 12, 1993⁠—​ní Bombay, India, ní ṣíṣekúpa 200 ènìyàn! Olùṣàkíyèsí kan wí pé: “Ìpayà wà ní gbogbo ilẹ̀ Bombay.” Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Newsweek ti sọ, “ìwọ́pọ̀” bọ́m̀bù inú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ “wulẹ̀ mú kí ó túbọ̀ múni kún fún ìbẹ̀rù ni.”

Ìbẹ̀rù Agbára Átọ́míìkì Ṣì Wà Síbẹ̀

Ìbẹ̀rù wà pé àwọn bọ́m̀bù tètè máa ń mú àwọn ẹ̀rọ adíwọ̀n ìbúgbàù átọ́míìkì gbiná. Ṣíṣe àṣeyọrí láti kọlu ilé-iṣẹ́ ẹ̀rọ agbára átọ́míìkì kan lè ṣokùnfà ìpalára àti ìjìyà tí kò ṣeéfẹnusọ. Ẹ̀rí tí ó túbọ̀ fìdí ìbẹ̀rù yìí múlẹ̀ ni ti ìgbìdánwò ọkùnrin kan láti da ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ̀ bo ibodè ààbò tí ó wà ní ibùdó ilé-iṣẹ́ agbára átọ́míìkì ní Three Mile Island ní United States.

Ọ̀pọ̀ ń bẹ̀rù pé àwọn akópayàbáni àti àwọn olùṣàkóso tí agbára ń sínníwín yóò kó àwọn ohun ìjà alágbára átọ́míìkì jọ. Ẹ̀rù ń ba àwọn kan pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ agbára átọ́míìkì Soviet tí a kò gbàsíṣẹ́ yóò gbìyànjú láti ta òye-iṣẹ́ wọn. Síwájú síi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìmùlẹ̀ àdéhùn START àti àwọn àdéhùn àjùmọ̀ṣe mìíràn béèrè fún dídín àwọn ohun ìjà ọlọ́gbọ́n ẹ̀rọ tí ó jẹ́ alágbára átọ́míìkì kù lọ́nà púpọ̀, mímú irú àwọn àdéhùn bẹ́ẹ̀ ṣẹ kì yóò parí fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Ní báyìí ná, ṣíṣeéṣe náà pé kí àwọn onígbòónára ẹhànnà kan tí wọ́n ṣàdéédéé húyọ lo àwọn ohun ìjà ogun yìí gbọ́dọ̀ máa rọ̀ dirodiro lórí aráyé gẹ́gẹ́ bí ìkúukùu ẹlẹ́fùúfùù líle ti ń halẹ̀mọ́ni.

Ìwà-Ipá Ń Mú Ìbẹ̀rù Pọ̀ Síi

Ìbísí nínú ìwà ọ̀daràn oníwà-ipá tí ó tànkálẹ̀ ń mú kí àwọn ènìyàn kún fún ìbẹ̀rù nínú ilé wọn àti ní àwọn òpópónà. Àwọn ará America tí a díwọ̀n iye wọn sí 23,200 ni a ṣekúpa ní ọdún 1990. Fún àpẹẹrẹ, ní ìlú-ńlá Chicago, ìbísí nínú lílo kokéènì tí a ń fà sí agbárí dákún nǹkan bíi 700 ìṣìkàpànìyàn ní ọdún kan. Àwọn agbègbè ibìkan pàtó nínú àwọn ìlú-ńlá díẹ̀ ti di pápá ìjà níbi tí ọta ìbọn yíyìn síra ẹni ti pa àwọn tí ń kọjá lọ, títíkan àwọn ọmọdé. Ìwé ìròyìn kan sọ pé: “Ìwà-ipá ń peléke síi lọ́nà yíyárakánkán ní àwọn ìlú tí wọn kò fi bẹ́ẹ̀ tóbi. . . . Kò sí ẹni tí ọ̀ràn náà kò kàn bí oògùn àti àwọn ọ̀dọ́ ọmọ-ita ti kún inú àwọn àwùjọ àdúgbò jákèjádò [United States] dẹ́múdẹ́mú. Ní ọdọọdún 1 nínú 4 àwọn agbo ilé America ń nírìírí ìwà ọ̀daràn oníwà-ipá tàbí ìjanilólè.”​—⁠U.S.News & World Report, October 7, 1991.

Ìbẹ̀rù ìfipábánilòpọ̀ mú kí àwọn obìnrin máa kọminú. Ní France ìfipábánilòpọ̀ gasókè láti orí ìpín 62 nínú ọgọ́rùn-⁠ún láti 1985 sí 1990. Láàárín ọdún mẹ́fà ìfipákọluni nítorí ìbálòpọ̀ ròkè ní ìlọ́po méjì dé 27,000 ní Canada. Germany ròyìn pé ní ìṣẹ́jú méje-méje obìnrin kan ni a ń fipákọlù nítorí ìbálòpọ̀.

Àwọn ọmọdé pẹ̀lú ń bẹ̀rù nítorí ààbò tiwọn. Ìwé ìròyìn Newsweek ròyìn pé ní United States, “àwọn ọmọ kéékèèké, àní tí wọ́n wà ní ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ pàápàá, ń dìhámọ́ra, àyà sì ń fò àwọn olùkọ́ àti àwọn ìjòyè òṣìṣẹ́ ilé-ẹ̀kọ́.” Ipò ọ̀ràn náà léwu gan-⁠an débi pé ìdámẹ́rin lára àwọn àgbègbè ilé-ẹ̀kọ́ ìlú ńlá ń lo àwọn irin-iṣẹ́ ẹ̀rọ tí ń pèsè ìsọfúnni bí ohun tí ó ní mẹ́táàlì lára bá wà nítòsí, ṣùgbọ́n àwọn ọ̀dọ́langba tí wọ́n ti pinnu ń rí ọgbọ́n dá síi nípa títa àtaré ìbọn sí àwọn yòókù láti ojú fèrèsé.

Ìbẹ̀rù Àrùn AIDS

Àwọn ènìyàn púpọ̀ síi ń bẹ̀rù kíkó àrùn AIDS. Iye tí ó rékọjá 230,000 irú rẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ ní United States nìkanṣoṣo. Àrùn AIDS ti di okùnfà gíga jùlọ kẹfà fún ikú láàárín àwọn ọmọ ọdún 15 sí 24. Ìwé ìròyìn Newsweek sọ pé, “Ọjọ́ ọ̀la ní ìfojúsọ́nà tí ń kó jìnnìjìnnì báni nípa ti àmódi tí ń tànkálẹ̀ lọ́nà tí ó túbọ̀ pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ síi.”

Ikú láti inú àrùn AIDS ń ṣe lemọ́lemọ́ lọ́nà tí ń ga síi láàárín àwọn ènìyàn tí ń bẹ ní pápá ìmọ̀-ẹ̀kọ́ ijó-jíjó, eré-ìtàgé, àwòrán sinimá, orin, àṣà tí ó lòde, tẹlifíṣọ̀n, ọgbọ́n ọnà, àti irú mìíràn bẹ́ẹ̀. Ìròyìn kan sọ pé ìpín 60 nínú ọgọ́rùn-⁠ún ikú tí ń pa àwọn ọkùnrin tí wọ́n ń gbé ní Paris tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ìkọ̀ròyìn, ọgbọ́n ọnà, àti eré-ìnàjú tí wọ́n tó ẹni ọdún 25 sí 44 jẹ́ èyí tí AIDS ṣokùnfà rẹ̀. WHO (Ètò-Àjọ Ìlera Àgbáyé) ròyìn pé láti nǹkan bíi million 8 sí million 15 ènìyàn kárí ayé ní a ti kó èèràn HIV ràn. Dókítà Michael Merson, olùdarí ètò-àjọ WHO, sọ pé: “Ó wá ṣe kedere nísinsìnyí pé iye àdánù tí èèràn HIV ń fà káàkiri ayé ń burú síi lọ́nà yíyárakánkán, pàápàá jùlọ ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ń gòkè àgbà.”

Àmọ́ ṣáá o, àwọn ìbẹ̀rù ti àyíká àti àwọn mìíràn tún wà. Síbẹ̀, àwọn ìròyìn tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ mẹ́nukàn tán yìí mú kí ó ṣe kedere pé ìbẹ̀rù gbá aráyé mú. Ohun kan tí ó ṣe pàtàkì níti gidi ha wà nípa èyí bí? Ǹjẹ́ a lè retí láti gbádùn òmìnira kúrò lọ́wọ́ ìbẹ̀rù bí?

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]

Fọ́tò ẹ̀yìn ìwé: Òsì: Tom Haley/Sipa Press; Ìsàlẹ̀: Malanca/Sipa Press

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]

Bob Strong/Sipa Press

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́