Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa Káàkiri Ayé—Colombia
COLOMBIA jẹ́ ilẹ̀ aláìlẹ́gbẹ́ kan ní South America. Àwọn òkun Atlantic àti ti Pacific súnmọ́ ilẹ̀ tí ó pààlà sí àárín omi àti ilẹ̀ tí ó wà ní orílẹ̀-èdè tí ó wà láàárín òkè ayọná-yèéfín yìí. Bí ooru ti ń mú ní àwọn ààlà-ilẹ̀ èbúté àti pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ olóoru bẹ́ẹ̀ ní òtútù ń mú ní téńté orí àwọn Òkè Ńlá Andes tí òjò-dídì bò.a
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a mọ Colombia fún wúrà àti òkúta emeraldi, àwọn ènìyàn ni wọ́n jẹ́ ọrọ̀-ìní rẹ̀ ṣíṣeyebíye jùlọ. Lónìí, Jehofa ń fi ògo kún inú ilé rẹ̀ tẹ̀mí. Àwọn olùjọ́sìn wíwuni, tí wọ́n jẹ́ ẹni yíyẹ ń rọ́ wọnú rẹ̀ ní gbogbo apá ilẹ̀-ayé, títíkan Colombia.—Haggai 2:7.
Ó Wọ Àwọn Lọ́gàálọ́gàá Iṣẹ́-Ajé Lọ́kàn
Ọjọ́ Sunday, November 1, 1992, sàmì sí ìyàsímímọ́ ọ́fíìsì ẹ̀ka titun ti Watch Tower Society àti àwọn ilé-lílò fún ìtẹ̀wé ní Facatativá, kìlómítà 42 sí àríwá ìwọ̀-oòrùn Bogotá. Ìrìn-àjò ìṣèbẹ̀wò yíká ẹ̀ka náà ní ipa ńláǹlà lórí àwọn olùbẹ̀wò náà. Nígbà tí ó padà sí ilé-iṣẹ́ ẹ̀rọ níbi tí ó ti ń ṣiṣẹ́, olùbẹ̀wò kan fi pẹ̀lú ìrusókè ìmọ̀lára rọ àwọn ọ̀gá ní ibi iṣẹ́ rẹ̀ láti lọ ṣàkíyèsí ètò-àjọ kan tí ó jẹ́ ‘àgbàyanu níti ìjáfáfá, ètò, àti àpẹẹrẹ ìwà yíyẹ àwọn ẹni tí a gbàsíṣẹ́.’ Lákòókò ìrìn-àjò ìṣèbẹ̀wò wọn tí ó tẹ̀lé e, àwọn lọ́gàálọ́gàá náà fi ọkàn-ìfẹ́ jíjinlẹ̀ hàn wọ́n sì béèrè ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìbéèrè.
Àwọn lọ́gàálọ́gàá wọ̀nyí fẹ́ láti rán àwọn ọ̀gá olùṣàbójútó, àwọn olùṣe kòkáárí, àti àwọn ọ̀gá-iṣẹ́—níti gidi, gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ wọn—lọ láti rìnrìn-àjò ìṣèbẹ̀wò. Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, wọn yóò ṣètò nǹkan bí àwọn àgbàsíṣẹ́ 15 sí 25 fún ìrìn-àjò ìṣèbẹ̀wò títí tí gbogbo òṣìṣẹ́ náà tí iye wọn jẹ́ 1,300 yóò fi lè ṣàkíyèsí irúfẹ́ ìjáfáfá nínú ìṣètò bẹ́ẹ̀.
Ọgọ́rọ̀ọ̀rún nínú àwọn òṣìṣẹ́ wọn ti rínrìn-àjò ìṣèbẹ̀wò yíká àwọn ilé-lílò ẹ̀ka náà wọ́n sì ti wo fídíò náà Jehovah’s Witnesses—The Organization Behind the Name. Bí ìtóbi ètò-àjọ náà àti ibi tí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà gbòòrò dé ti wú wọn lórí, ó yà wọ́n lẹ́nu láti rí bí ọgbọ́n iṣẹ́-ẹ̀rọ tí Society ń lò nínú iṣẹ́ wọn ti ga tó. Lẹ́yìn tí wọ́n fi ibẹ̀ sílẹ̀, a gbọ́ tí púpọ̀ nínú wọn sọ pé àwọn nímọ̀lára bí ẹni pé àwọn ‘ń fi Paradise sílẹ̀ láti padà sínú ayé rúdurùdu kan.’
Òtítọ́ Dé Ọ̀dọ̀ Onírúurú Gbogbo
Àwọn ènìyàn lónírúurú ni a ti mú ìhìnrere náà tọ̀ lọ. (1 Timoteu 2:3, 4) Fún àpẹẹrẹ, akórinjọ àti aṣáájú ẹgbẹ́ olórin rọ́ọ̀kì onílù-dídún kíkankíkan tẹ́lẹ̀rí kan gba òtítọ́ Bibeli, ó ṣe àwọn ìyípadà nínú ìgbésí-ayé rẹ̀, kò sì pẹ́ tí ó di aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Lẹ́yìn náà a yàn án sípò gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ iṣẹ́-òjíṣẹ́. Àwọn ènìyàn mélòókan tí wọ́n ti jẹ́ mẹ́ḿbà àwùjọ adojú ìjọba dé ti kẹ́kọ̀ọ́ láti fi ìgbọ́kànlé àti ìrètí wọn sínú Ìjọba Jehofa. Wọ́n ń fi taápọn taápọn lọ́wọ́ nínú wíwàásù ìhìn-iṣẹ́ nípa ayé titun alálàáfíà kan nísinsìnyí.
Àwọn àjòògùnyò àti oníṣòwò oògùn pẹ̀lú ti yíjú sí òtítọ́. Ọ̀dọ́kùnrin kan tí ó jẹ́ Ẹlẹ́rìí nísinsìnyí ti ń ṣàbójútó oko-ọ̀gbìn oògùn àti ilé-iṣẹ́ àyẹ̀wò kokéènì kan nínú ẹgàn fún ọdún márùn-ún ṣáájú kí ó tó jáwọ́ kúrò nínú irú ìgbésí-ayé bẹ́ẹ̀. Ó ti rí ayọ̀ nínú kíkẹ́kọ̀ọ́ àti fífi àwọn ìlànà Bibeli sílò. Nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n kan àwọn adìtẹ̀pànìyàn kan tí a dẹ́bi fún ni ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli rusókè tí wọ́n sì ń fi tọkàntara gbàdúrà pé kí Jehofa dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n kí ó sì tẹ́wọ́gbà wọ́n gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ rẹ̀.
Bí ó ti rí nìyẹn tí onírúurú àwọn ènìyàn fi ń dáhùnpadà sí ìhìn-iṣẹ́ Ìjọba náà. Ní Colombia, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ní àwọn ibòmíràn, Jehofa ń tipa báyìí fi ògo kún inú ilé rẹ̀.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún àfikún ìsọfúnni, wo 1994 Calendar of Jehovah’s Witnesses.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 8]
ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ NÍPA ORÍLẸ̀-ÈDÈ
Ọdún Iṣẹ́-Ìsìn 1993
GÓŃGÓ IYE ÀWỌN TÍ Ń JẸ́RÌÍ: 60,854
ÌṢIRÒ-ÌFIWÉRA: Ẹlẹ́rìí 1 sí 558
ÀWỌN TÍ Ó PÉSẸ̀ SÍBI ÌṢE-ÌRÁNTÍ: 249,271
ÌPÍNDỌ́GBA ÀWỌN AKÉDE TÍ WỌ́N JẸ́ AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ: 8,487
ÌPÍNDỌ́GBA ÀWỌN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BIBELI: 100,927
IYE TÍ Ó ṢÈRÌBỌMI: 5,183
IYE ÀWỌN ÌJỌ: 751
Ọ́FÍÌSÌ Ẹ̀KA: FACATATIVÁ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Àwọn òṣìṣẹ́ ọ́fíìsì Ẹ̀ka àti àwọn míṣọ́nnárì ní 1956
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Àwòrán àtòkèèrèyà ti ọ́fíìsì ẹ̀ka