Ìkálọ́wọ́kò Ha Ń Mú Ọ Rẹ̀wẹ̀sì Bí?
ÌKÁLỌ́WỌ́KÒ! Kò sí ẹni tí ó fẹ́ ẹ níti tòótọ́; síbẹ̀ gbogbo wa níláti faramọ́ ọn dé ìwọ̀n àyè kan. Ṣugbọn, a ha ń mú ọ rẹ̀wẹ̀sì nígbà mìíràn nitori pé ìgbésí-ayé rẹ dàbí èyí tí a pààlà sí jù bí? Bóyá iwọ lè nímọ̀lára tí ó sàn jù bí ó ba yí ojú-ìwòye rẹ̀ padà. Dípò dídààmú nipa ohun tí o kò lè ṣe, èéṣe tí iwọ kò fi lo àǹfààní òmìnira èyíkéyìí tí o bá ń gbádùn lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́ jùlọ?
Fún àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ awọn tí wọn kò rí jájẹ tóbẹ́ẹ̀ níti ìṣúnná-owó fẹ́ pé kí awọn jẹ́ ọlọ́rọ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, níwọ̀n bí ipò òṣì ti ń pààlà sí ohun tí a lè ṣe ninu ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan yii, awọn ohun ṣíṣe pàtàkì ninu ìgbésí-ayé wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún gbogbo wa. Awọn òtòṣì ati ọlọ́rọ̀ ń kó wọnú ìfẹ́, wọn ń gbéyàwó, wọn ń tọ́ awọn ọmọ dàgbà, wọn ń gbádùn ipò ìbádọ́rẹ̀ẹ́ rere ati bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Èyí tí ó ṣe pàtàkì jùlọ, awọn òtòṣì ati ọlọ́rọ̀ ń mọ Jehofa wọn sì ń fojúsọ́nà fún ayé titun tí a ṣèlérí naa. Awọn òtòṣì ati ọlọ́rọ̀ ń tẹ̀síwájú ninu ọgbọ́n ati ìmọ̀ Kristian, tí ó dára ju ọrọ̀ lọ. (Owe 2:1-9; Oniwasu 7:12) Gbogbo ènìyàn—ọlọ́rọ̀ ati òtòṣì—lè ṣe orúkọ títayọlọ́lá fún araawọn pẹlu Jehofa. (Oniwasu 7:1) Ní ọjọ́ Paulu awọn ènìyàn tí wọn pọ̀ jùlọ ninu ìjọ Kristian jẹ́ awọn mẹ̀kúnnù—awọn kan lára wọn tilẹ̀ jẹ́ ẹrú—tí wọn fi ọgbọ́n lo òmìnira èyíkéyìí tí àyíká ipò wọn bá yọ̀ọ̀da.—1 Korinti 1:26-29.
Ipò-Orí tí Ó Bá Ìwé Mímọ́ Mu
Ninu ìgbéyàwó Kristian, aya wà lábẹ́ ìtẹríba fún ọkọ rẹ̀—ètò kan tí a ṣe kí gbogbo ìdílé baà lè jàǹfààní lati inú rẹ̀. (Efesu 5:22-24) Aya kan ha níláti nímọ̀lára ìsọni di yẹpẹrẹ nitori èyí bí? Kí á má rí i. Alájọṣiṣẹ́pọ̀ ni ọkọ ati aya jẹ́. Ipò-orí ọkùnrin naa, nígbà tí ó bá lò ó bíi ti Kristi, ń fi aya rẹ̀ sábẹ́ ìkálọ́wọ́kò tí ó ní ààlà ó sì ń fún un ní òmìnira pupọ lati mọ agbára-ìṣe tí oun lè mú dàgbà. (Efesu 5:25, 31) Ọwọ́ “aya dídáńgájíá” ti inú Owe orí 31 (NW) dí jọjọ fún ọ̀pọ̀ ìdáwọ́lé gbígbádùnmọ́ni tí ó sì ń peniníjà. Ní kedere, ìtẹríba fún ọkọ rẹ̀ kò mú un nímọ̀lára ìjákulẹ̀.—Owe 31:10-29.
Bákan naa, kò sí ìpèsè kankan fún obìnrin kan lati mú ipò iwájú lórí awọn ọkùnrin títóótun ninu ìjọ Kristian. (1 Korinti 14:34; 1 Timoteu 2:11, 12) Awọn Kristian obìnrin ha níláti fi àìnítẹ̀ẹ́lọ́rùn hàn lábẹ́ ìkálọ́wọ́kò bí? Bẹ́ẹ̀kọ́. Awọn tí ó pọ̀ jùlọ kún fún ìmoore lati rí i pé apá-ìhà yẹn ninu iṣẹ́-ìsìn Kristian ni a bójútó ní ọ̀nà ti ìṣàkóso Ọlọrun. Wọn láyọ̀ lati jàǹfààní lati inú ìṣolùṣọ́ àgùtàn ati ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ awọn alàgbà tí a yànsípò wọn sì gbájúmọ́ iṣẹ́ ṣíṣekókó ti wíwàásù ati sísọni di ọmọ-ẹ̀yìn ni tiwọn. (Matteu 24:14; 28:19, 20) Awọn Kristian obìnrin ń ṣàṣeparí ohun pupọ ninu pápá yii, èyí sí ń mú ọlá wá fún wọn níwájú Jehofa Ọlọrun.—Orin Dafidi 68:11; Owe 3:35.
Kíká Awọn Ọ̀dọ́ Lọ́wọ́kò
Awọn ọ̀dọ́ pẹlu máa ń ráhùn nígbà mìíràn pé ìkálọ́wọ́kò ti pọ̀ jù ninu ìgbésí-ayé awọn, nitori pé lọ́pọ̀ ìgbà wọn máa ń wà lábẹ́ ọlá-àṣẹ awọn òbí wọn. Síbẹ̀ èyí pẹlu bá Ìwé Mímọ́ mú. (Efesu 6:1) Dípò tí awọn Kristian ọ̀dọ́ tí wọn jẹ́ ọlọgbọ́n ìbá fi jẹ́ kí kíká tí awọn òbí wọn ká wọn lọ́wọ́kò mú wọn bínú, wọn ń pọkànpọ̀ sórí gbígbádùn òmìnira tí wọn ní—títíkan, òmìnira kúró lọ́wọ́ awọn ẹrù-iṣẹ́ wíwúwo, gẹ́gẹ́ bí ó ti sábà máa ń rí. Nipa bayii wọn lè lo àǹfààní okun ìgbà ọ̀dọ́ ati awọn àyíká-ipò wọn lati múra araawọn sílẹ̀ fún ìgbésí-ayé jíjẹ́ àgbàlagbà.
Alábòójútó àyíká kan tẹ́lẹ̀rí ní Brazil rántí ọmọdékùnrin ẹni ọdún 12 kan dáradára, ẹni tí ohun tí ó lè ṣe mọníwọ̀n, tí ń gbé pẹlu àwùjọ àdádó kékeré kan. Iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ mú kí ọwọ́ ẹni tí ń bójútó awọn àkọsílẹ̀ dí kò sì lè fún àwùjọ naa ní àfiyèsí pupọ, ṣugbọn ó ṣètò pé kí ọ̀dọ́mọkùnrin yii ran oun lọ́wọ́. Ó mọ ibi tí gbogbo fọ́ọ̀mù wà ó sì máa ń wà lárọ̀ọ́wọ́tó nígbà gbogbo lati ṣèrànwọ́. Ọkàn-ìfẹ́ rẹ̀ fúnni níṣìírí, ó sì jẹ́ olùṣòtítọ́ alábàáṣiṣẹ́ ninu iṣẹ́-ìsìn pápá. Ọ̀dọ́mọkùnrin naa jẹ́ alàgbà kan tí a yànsípò nísinsìnyí.
Awọn ipò pupọ wà tí ó lè pààlà sí òmìnira ẹni. Àìsàn ká awọn mìíràn lọ́wọ́kò. Awọn kan ń gbé ninu agbo-ilé tí ìpínyà wà wọn sì rí i pé awọn ohun tí alábàáṣègbéyàwó kan tí ó jẹ́ aláìgbàgbọ́ n fi dandangbọ̀n béèrè ń pààlà sí òmìnira wọn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé awọn tí ń gbé pẹlu ìkálọ́wọ́kò lè fẹ́ kí awọn nǹkan yàtọ̀, wọn ṣì lè gbé ìgbésí-ayé tí ń tẹ́nilọ́rùn. Ìwé ìròyìn yii ti gbé ọ̀pọ̀ ìròyìn jáde nipa irú awọn ẹni bẹ́ẹ̀ tí wọn ti jẹ́ orísun ìṣírí jùlọ fún awọn ẹlòmíràn nitori pé wọn gbáralé Jehofa tí wọn sì lo àǹfààní ipò wọn lọ́nà dídára jùlọ.
Ní sísọ̀rọ̀ nipa ipò kan tí ó wọ́pọ̀ ní ọjọ́ tirẹ̀, aposteli Paulu wí pé: “A ha pè ọ́, nígbà tí ìwọ jẹ́ ẹrú? máṣe kà á sí: ṣugbọn bí iwọ bá lè di òmìnira, kúkú ṣe èyíinì.” (1 Korinti 7:21) Ẹ wo bí ojú-ìwòye yii ti wà déédéé tó! Awọn ipò kan ń yípadà. Awọn ọ̀dọ́ ń dàgbà. Nígbà mìíràn awọn alábàáṣègbéyàwó tí wọn ti ń ṣàtakò tẹ́lẹ̀rí ń tẹ́wọ́gba òtítọ́. A ti rí awọn ipò ìṣúnná owó tí wọn sunwọ̀n síi rí. Ara awọn tí ń ṣàìsàn lè yá. Ninu awọn ọ̀ràn mìíràn, awọn nǹkan lè má yípadà títí tí ayé titun Jehofa yóò fi dé. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, èrè wo ni a lè rígbà lati inú dídààmú nitori pé olúwarẹ̀ kò lè ṣe ohun tí awọn ẹlòmíràn lè ṣe?
O ha ti wo awọn ẹyẹ tí ń sófèérèé rí lójú òfúúrufú lókè ilẹ̀-ayé tí ẹwà ati òmìnira ìfòkiri wọn sì wọ̀ ọ́ lójú? Bóyá o ronú pé ìbá lè ṣeéṣe kí ìwọ naa lè fò bẹ́ẹ̀. Ó dára, iwọ kò lè ṣe bẹ́ẹ̀ o kò sì ní lè fò láé bí ti awọn ẹyẹ! Ṣugbọn ó ṣeéṣe kí o má ráhùn. Kàkà bẹ́ẹ̀, o láyọ̀ pẹlu awọn agbára ìṣe tí Ọlọrun fi fún ọ. O ń dọ́gbọ́n ara rẹ dáradára ní rírìn káàkiri lórí ilẹ̀-ayé. Bákan naa, ohun yòówù kí ipò wa jẹ́ ninu ìgbésí-ayé, bí a bá pọkànpọ̀ sórí ohun tí a lè ṣe dípò kí a máa dààmú nipa ohun tí a kò lè ṣe, ìgbésí-ayé yoo mú ìtẹ́lọ́rùn wá, awa yoo sì rí ayọ̀ ninu iṣẹ́-ìsìn Jehofa.—Orin Dafidi 126:5, 6.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Iwọ ha nímọ̀lára pé awọn òbí rẹ há ọ mọ́ bí?