Bí Wọ́n Tilẹ̀ Jẹ́ Olùwá-Ibi-Ìsádi, Wọ́n Láyọ̀ Láti Máa Ṣiṣẹ́sin Ọlọrun
OGUN, ìyàn, ìjábá, àti rúkèrúdò. Fún àwọn ènìyàn kan ohun àfetígbọ́ ni ìwọ̀nyí jẹ́. Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ mìíràn wọ́n jẹ́ apákan ìgbésí-ayé ojoojúmọ́. Níwọ̀n bí wọ́n ti jẹ́ ẹgbẹ́ àwọn Kristian kárí-ayé, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa mọ̀ dájú pé nígbàkígbà tí ogun bá bẹ́sílẹ̀ tàbí tí ìjábá kan bá ṣẹlẹ̀, ó ṣeéṣe kí apákan lára ẹgbẹ́ àwọn ará wọn kárí-ayé faragbá a. Nígbà tí ó bá sì ṣẹlẹ̀ pé kí àwọn ènìyàn sá àsálà fún ẹ̀mí wọn, ó ṣeéṣe pé kí àwọn ará wa náà ṣe bẹ́ẹ̀.
Fún ọ̀pọ̀ ọdún àwọn Ẹlẹ́rìí ní àwọn orílẹ̀-èdè díẹ̀ ní Africa ti níláti foríti irú àwọn ìrírí bẹ́ẹ̀. Ọ̀pọ̀ lára wọn ti níláti palẹ̀ ohunkóhun tí wọ́n bá lè gbé mọ́ kí wọ́n sì wá ibi-ìsádi sí apá ibòmíràn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé díẹ̀ nínú wọn ni ó ní ohun ìrìnnà, ò sì lè jẹ́ kẹ̀kẹ́ ológeere kan, àwọn tí ó pọ̀ jùlọ ti níláti rìn-rìn-rìn—fún ọ̀pọ̀ ọjọ́, ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀ pàápàá—lati lè dé ibi tí wọ́n ń lọ.
Ọ̀kan lára irú àwọn ibi tí wọ́n ń lọ ni ìlú kékeré kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mboki, ní Central African Republic. Láti àwọn ọdún yìí wá, tọkùnrin tobìnrin, tọmọdé tàgbà, ni wọ́n ń wọ́ wá lẹ́gbẹẹgbẹ̀rún. Díẹ̀ nínú àwọn Kristian arákùnrin àti arábìnrin wa ń bẹ lárá wọn, pẹ̀lú àwọn olùfìfẹ́hàn tí wọ́n bá wọn lọ. Àmọ́ ṣáá o, àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ wa ní ọ́fíìsì ẹ̀ka Watch Tower Society ní Bangui, olú-ìlú Central African Republic, lọ́kàn-ìfẹ́ gan-an nínú bíbá àwọn olùwá-ibi-ìsádi wọ̀nyí pàdé láti pèsè ìrànlọ́wọ́. Ìgbà márùn-ún ni a fi owó, oúnjẹ, aṣọ, àti egbòogi, tí àwọn Ẹlẹ́rìí ní Bangui, tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 1,130 kìlómítà sí ibẹ̀, fi ìwà-ọ̀làwọ́ pèsè rán aṣojú kan. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tí wọ́n ń ṣe ìrànlọ́wọ́ ọlọ́làwọ́ yìí kò fi bẹ́ẹ̀ rí jájẹ níti ìṣúnná owó, wọ́n láyọ̀ láti ṣe ohun tí wọ́n lè ṣe.
Dídé Mboki
Àwọn ará ní ọ́fíìsì ẹ̀ka fẹ́ láti mọ ohun tí a tún lè ṣe àti bí a ṣe lè ran àwọn olùwá-ibi-ìsádi naa lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí. Nítorí náà èmi àti aya mi bẹ̀rẹ̀ ìrìn-àjò náà nínú ọkọ̀ Land Cruiser ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin, Symphorien tí ó jẹ́, aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, àti aya rẹ̀ sì bá wa lọ. Symphorien mọ ọ̀nà náà dáradára, ó sì gbọ́ èdè Zande, èdè àwọn olùwá-ibi-ìsádi ní Mboki. Ó gbà wá ní ọjọ́ mẹ́rin gbáko láti lè débẹ̀.
Kìlómítà 400 tí ó kẹ́yìn jẹ́ láàárín agbègbè rírẹwà tí ó kún fún àwọn ìgbèríko onígegele àti àwọn igi àfọ̀n ràgàjì-ràgàjì. Bí a ṣe ń lọ ni a ń kọjá àwọn abúlé kéékèèké. Lójú ọ̀nà gígùn yii, aya mi ka 50 afárá ṣangiliti—ọ̀pọ̀ nínú wọn rí jẹ́gẹjẹ̀gẹ, àwọn kan kò ṣeé gbà. A fi igi àti àwọn ọ̀pá-àjà tí ó ti ń bàjẹ́ tún àwọn afárá kan ṣe, a mú kí ẹsẹ̀ táyà mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ṣiṣẹ́ papọ̀, a gbàdúrà, a sì ń lọ tìṣọ́ra-tìṣọ́ra. Níbi tí abúlé kékeré kan bá ti wà nítòsí, àwọn ọmọdé máa ń rọ́ wa láti ràn wá lọ́wọ́—a óò sì san owó táṣẹ́rẹ́ fún wọn. Ó yà wá lẹ́nu pé wọ́n sábà máa ń rí àwọn igi lílà àti pákó tí ó já lára afárá náà lábẹ́ àwọn ìràwé àti àwọn igbó ṣúúrú tí ń bẹ nítòsí. Ó mú kí a ṣe kàyéfì bóyá wọ́n ti kó wọn kúrò tí wọ́n sì tọ́jú wọn pamọ́ nítorí àwọn arìnrìn-àjò tí wọ́n lè nílò wọn.
Nígbà mẹ́ta a kọ ìrànlọ́wọ́ àwọn ọmọdé wọ̀nyẹn, nítorí tí ó jọbí ẹni pé ó ti léwu jù láti sọdá àwọn afárá náà. Nítorí naa a yà kúrò lójú ọ̀nà, ó dinú itọ́ odò, lórí àpáta, a tún padà sórí òkè lẹ́ẹ̀kan síi, a tún padà bọ́ sójú ọ̀nà. Ẹ wo bí inú wa ṣe dùn tó pé ó jẹ́ ìgbà ẹ̀rùn, bí kìí bá ṣe bẹ́ẹ̀ kì bá tí sí ọ̀nà fún wa láti rìn ìrìn-àjò náà, àyàfi bí a bá lo hẹlikopta!
Báwo ni Mboki yóò ṣe rí? Èyí sábà máa ń wá sí wa lọ́kàn bí a ṣe ń wakọ̀ lọ lójú “piste” tí kò lópin yìí, ọ̀rọ̀ èdè French kan tí a ń lò ní Central African Republic fún ojú ọ̀nà kan tàbí ipa-ọ̀nà tí ó ní yanrìn, àwọn àpáta, àti àwọn òkúta wẹ́wẹ́—àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ihò.
Ní ọjọ́ kẹrin, gẹ́rẹ́ lẹ́yìn ọjọ́-kanrí, Symphorien nawọ́ sí àwọn ahéré kan tí a fi ewéko kọ́ tí àwọn igi ìbẹ́pẹ àti oko gbágùúdá yíká. Ó lọgun pé, “Voilà! Ibí ni Mboki ti bẹ̀rẹ̀.” Ohun tí a rí yà wá lẹ́nu gidigidi. “Ṣe Mboki ọ̀hún náà nìyí? Níbo ni ibùdó náà wà?” ni a béèrè, nítorí pé ohun tí a rí kìí ṣe ibùdó, bíkòṣe àwọn ilé tí a kọ́ gátagàta. Wọ́n jẹ́ àwọn ahéré kéékèèké olórùlé ewéko ṣùgbọ́n tí ó mọ́ tónítóní. Àwọn igi àti igbó tún wà káàkiri. Àwọn ènìyàn gbin irúgbìn sẹ́bàá ilé wọn. Mboki kìí ṣe irú ibùdó tí a nírètí láti rí; abúlé ńlá kan ni, nǹkan bíi kìlómítà 35 lóòró.
Pípàdé Àwọn Ará
Àwọn ará ní Mboki ti mọ̀ pé a ń bọ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn fojú díwọ̀n rẹ̀ pé ìrìn-àjò wa yóò gbà tó ọjọ́ márùn-ún. Nígbà tí wọ́n gbọ́ ìró ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wa, wọ́n sáré jáde. Tọkùnrin, tobìnrin, àti àwọn ọmọdé tú jáde láti inú àwọn ahéré àti àgbàlá wọn wọ́n sì jáde láti inú àwọn oko wọn láti kí wa. Olúkúlùkù wọn ń rẹ́rìn-ín músẹ́, wọ́n ń rẹ́rìn-ín, wọ́n sì ń bọ̀ wá lọ́wọ́, lọ́pọ̀ ìgbà bí ó bá ṣeéṣe. Wọ́n gbé àwọn ọmọ wọn wá kí wa. Gbogbo wọn ṣáà fẹ́ kí wa, wọ́n sì gbà wá tọwọ́tẹsẹ̀.
Kò sí ohun púpọ̀ tí èmi àti aya mi lè ṣe lójú ẹsẹ̀ nítorí pé a kò gbédè wọn. A gbìyànjú sísọ èdè French díẹ̀, Sango díẹ̀, Gẹ̀ẹ́sì díẹ̀, àti Lárúbáwá. Ọ̀pọ̀ jùlọ lára àwọn ará wa lè sọ, kà, kí wọ́n sì kọ èdè Zande. Ó di dandan fún Symphorien láti máa túmọ̀ èdè, ní ṣíṣàlàyé ètò tí a bá wá.
A rin ibùsọ̀ díẹ̀ síi a gúnlẹ̀ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba. Òun ni “ṣọ́ọ̀ṣì” àkọ́kọ́ tí àwọn olùwá-ibi-ìsádi tí wọ́n jẹ́ ti ìsìn èyíkéyìí kọ́ sí Mboki. Àwọn ará púpọ̀ síi àti àwọn ọmọ wọn àti àwọn olùfìfẹ́hàn jáde wá láti bọ̀ wá lọ́wọ́. Kódà ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ tí ń gbé ládùúgbò wá pẹ̀lú àwọn ará láti bọ̀ wá lọ́wọ́.
Àwọn ará wa ti ṣètò àwọn ilé kékeré méjì fún wa, àwa tí a jẹ́ àlejò wọn. Wọ́n mọ́ tónítóní. Àwọn korobá omi mímọ́ gaara ti wà ní sẹpẹ́ tí wọ́n sì ń dúró dè wá. A ti gbé oúnjẹ àti omi mímu tiwa dání, ní ríretí pé omi àti oúnjẹ yóò wọ́n jojú àti kí a máa baà di ẹrù ru àwọn ará wa. Nígbà tí a ń já ẹrù kalẹ̀ láti inú ọkọ̀, ọ̀dọ́mọbìnrin kan wá ó sì béèrè pé báwo ni a óò ṣe fẹ́ kí wọ́n ṣe aáyan adìyẹ náà ní alẹ́ yẹn, ṣé díndín ni tàbí ní òmóòyò? A kò retí ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀ rárá a béèrè pé kí ni wọ́n wéwèé láti fi jẹ ẹ́. Ìdáhùn náà ni pé: gbágùúdá, tàbí ẹ̀gẹ́. Nítorí náà a yan adìyẹ olómòóòyò tí atá-tó tí iyọ̀ sì dùn. Ebi ajáninínújẹ tí ó ti ń pa wá bọ̀ rọlẹ̀ wọ̀ọ̀ lálẹ́ ọjọ́ yẹn. Ṣùgbọ́n wọ́n ń báa nìṣó láti máa bọ́ wa lójoojúmọ́—lọ́sàn-án àti lálẹ́. Ó ṣòro fún wa láti gbà á gbọ́—àwọn olùwá-ibi-ìsádi ń bọ́ wa wọ́n sì ń ṣètọ́jú wa, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé díẹ̀ ni àwọn fúnraawọn ní.
Ìjọ Kékeré tí Ó Láyọ̀
Níhìn-ín ni a wà, ní irú ibi àdádó bẹ́ẹ̀ ṣùgbọ́n láàárín àwọn ará wa 21. Kìkì àwọn méjì péré ni wọ́n ti ṣèrìbọmi kí wọ́n tó débí. Àwọn yòókù jẹ́ olùfìfẹ́hàn nígbà tí wọ́n dé. Wọ́n ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn nìṣó wọ́n sì ṣèrìbọmi ní àwọn ọdún méjì tí ó kọjá. A tún ṣèrìbọmi fún àwọn mẹ́rin síi nínú odò kan tí ó wà nítòsí nígbà ìbẹ̀wò wa.
Àpẹẹrẹ títayọ kan ni ti Faustino. Ṣáájú kí ó tó wá sí Mboki, ó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ìpìlẹ̀ Bibeli láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan. Faustino mọrírì ohun tí o ń kọ́. Láìpẹ́ láìjìnnà òun àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀sí wàásù fún àwọn ẹlòmíràn, ṣùgbọ́n wọ́n fojú winá àtakò a sì fi wọ́n sẹ́wọ̀n fún fífi ìsìn wọn “ru àwọn olùgbé sókè.” Nígbà tí wọ́n wà lẹ́wọ̀n, ọ̀rẹ́ Faustino juwọ́ sílẹ̀ nítorí ìbẹ̀rù wọ́n sì dá a sílẹ̀. Ní oṣù méjì lẹ́yìn náà, wọ́n gbẹ́jọ́ Faustino. Bí ó ti wù kí ó rí, ó ṣe kedere pé àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, nítorí bẹ́ẹ̀ wọ́n dá a sílẹ̀. Nígbà tí ogun dé agbègbè rẹ̀, Faustino sálọ sí Central African Republic, níbi tí ó ti ba àwọn ará pàdé tí ó sì tún bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli rẹ̀. Ó ṣèrìbọmi ní July 1991, ó sì wọnú iṣẹ́-òjíṣẹ́ alákòókò kíkún gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà déédéé ní ọdún 1992.
Ìjọ kékeré tí ó jẹ́ aláyọ̀ àti oníwà-bí-ọ̀rẹ́ náà ní Mboki ní aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe kan àti akéde 21 báyìí. Àwọn arákùnrin méjì tí wọ́n ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì ń ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà ó sì ṣeéṣe fún wọn láti máa ní ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ tí ó já geere pẹ̀lú ọ́fíìsì ẹ̀ka ní Bangui. A rò pé àwọn ara wa tí wọ́n jẹ́ olùwá-ibi-ìsádi yóò wà ní ipò bíbanilẹ́rù, tí wọn yóò sì ti sọ̀rètínù, ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n jẹ́ aláìní nípa tara, ẹnìkan nínú wọn kò ṣàròyé, ṣàníyàn, tàbí kùn. Láti ìgbà tí wọ́n ti débẹ̀ àwọn ará ti kọ́ àwọn ahéré àti ilé wọn, wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ síí ṣọ̀gbìn wọ́n sì ń sin adìyẹ. Wọn kò ní tó ti tẹ́lẹ̀ mọ́, ṣùgbọ́n wọ́n wà láàyè wọ́n sì wà pẹ̀lú àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ wọn.
Níwọ̀n bí àwọn olùwá-ibi-ìsádi tí wọ́n wà ní Mboki ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó nǹkan bíi 17,000 sí 20,000, tí púpọ̀ síi sì ń wá lóṣooṣù, àwọn ará wa ní pápá tí ó gbòòrò fún iṣẹ́-òjíṣẹ́ wọn. A lọ láti wàásù pẹ̀lú wọn, èyí sì gbádùnmọ́ni, níti gidi. Wọ́n sábà máa ń lo Bibeli ní èdè Zande, ìtumọ̀ yìí sì ní orúkọ Ọlọrun nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu àti ní àwọn ibi mélòókan nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Griki. Lójú àwọn ènìyàn wọ̀nyí, Ọlọrun kìí wulẹ̀ ṣe “Mboli” (èdè Zande fún “Ọlọrun”) ṣùgbọ́n “Yekova,” èyí tí ó jẹ́ bí wọ́n ṣe ń pe orúkọ Ọlọrun fúnraarẹ̀. “Mboli Yekova” jẹ́ gbólóhùn kan tí ó wọ́pọ̀. Àwọn olùtúmọ̀ tí wọ́n jẹ́ Protẹstanti nínú ọ̀pọ̀ àwọn èdè Africa mìíràn kìí tẹ̀lé ìtumọ̀ tí ó tọ̀nà yìí; kàkà bẹ́ẹ̀ wọ́n fi “Nzapa,” “Nzambe,” tàbí àwọn orúkọ mìíràn fún Ọlọrun lédè Africa rọ́pò “Jehofa.”
Gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ Jesu ṣe sọ, ìhìnrere Ìjọba náà ni a ti ń wàásù rẹ̀ káàkiri ayé, àní ní Mboki pàápàá. (Matteu 24:14) Ìjọ náà ń rí Bibeli, àwọn ìwé, ìwé ìròyìn, ìwé pẹlẹbẹ, àti ìwé àṣàrò kúkúrú gbà dáradára báyìí ní gbogbo èdè tí wọ́n nílò. Bóyá lọ́jọ́ iwájú, àwọn ìtẹ̀jáde púpọ̀ síi lè wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní èdè Zande.
Wọ́n Ń Dúró De Ilé tí Yóò Wàpẹ́títí
Ní ìrọ̀lẹ́ àkọ́kọ́, a fi ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwòrán ara ògiri ti Society “Awọn Olupejọpọ Alayọ Ni Ila-Oorun Europe Yin Jehofa” hàn. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ alẹ́ tí ó tẹ̀lé e ni “Yiyi Ọpọlọpọ Pada si Ododo ni Akoko Opin.” Fífi àwòrán náà hàn wáyé ní gbangba ìta, lẹ́bàá Gbọ̀ngàn Ìjọba, lábẹ́ ojú ọjọ́ mímọ́gaara àti òṣùpá tí ó mọ́lẹ̀ rokoṣo. Ẹ wo bí ipò ojú ọjọ́ náà ti tunilára tó! Ọgọ́rọ̀ọ̀rún wá láti wo àwọn àwòrán ara ògiri tí a fihàn yìí, àwọn ará wa láyọ̀ orí wọ́n sì wú pé àwọn gbé ohun tí ó ṣàrà-ọ̀tọ̀ kan kalẹ̀ fún àwọn ènìyàn.
Nígbà tí ó di ọjọ́ Monday, a múra ìrìn-àjò wa láti padà sílé. Yóò jẹ́ ìrìn-àjò ọlọ́jọ́ mẹ́rin mìíràn lójú ọ̀nà kan náà àti sísọdá àwọn 50 afárá kan náà. Arábìnrin kan tẹpẹlẹ mọ́ ṣíṣètò oúnjẹ díẹ̀ fún ìrìn-àjò náà—adìyẹ méjì síi, tí a díngbẹ tí a sì rẹ́ aáyù sí. Wọ́n ń tasánsán nínú ọkọ̀ Land Cruiser náà lọ́wọ́ àárọ̀. Nígbà tí ó di ọ̀sán a dúró lẹ́bàá igbó láti gbádùn adìyẹ díndín bí a ṣe ń ronú nípa àwọn ará wa ní Mboki. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó pọndandan fún wọn láti jẹ́ olùwá-ibi-ìsádi, wọ́n ń báa nìṣó láti máa fi ìṣòtítọ́ ṣiṣẹ́sin Jehofa, ní dídúró de ilé kan tí yóò wàpẹ́títí nínú ilẹ̀-ayé titun tí Ọlọrun ṣèlérí. (2 Peteru 3:13)—A kọ ọ́ ránṣẹ́.