Ṣíṣèrànwọ́ Fún Àwọn Ìdílé Onígbàgbọ́ Wa Ní Bosnia
ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ JEHOFA kìí kópa kankan nínú ìforígbárí ti ọ̀ràn òṣèlú. (Johannu 17:16) Bí ó ti wù kí ó rí, ní títẹ̀lé ìmọ̀ràn Paulu láti máa ṣe rere “ní pàtàkì sí awọn tí wọ́n jẹ́ ìdílé onígbàgbọ́ wa,” wọ́n ṣetán láti pèsè ìrànwọ́ fún àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ wọn ní àwọn ilẹ̀ tí ogun ti fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ. (Galatia 6:10, Beck) Bí ìgbà òtútù ti 1993 sí 1994 ṣe ń súnmọ́lé, àwọn Ẹlẹ́rìí láti Austria àti Croatia fi ìwàláàyè wọn wewu láti ṣèrànwọ́ fún àwọn ìdílé onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn ní Bosnia. Ìròyìn wọn ni ó tẹ̀lé e yìí.
Láti March sí October 1993, àyè kò sí láti fi àwọn ìpèsè ìrànlọ́wọ́ ṣọwọ́ sí Bosnia. Bí ó ti wù kí ó rí, ní ìbẹ̀rẹ̀ October, àwọn aláṣẹ fihàn pé ó lè ṣeéṣe láti fi àwọn ẹrù ránṣẹ́. Síbẹ̀ ìdáwọ́lé kan tí ó léwu ni èyí yóò jẹ́, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ọwọ́ ìjà lè ní gbogbo ibi tí àwọn ọmọ-ogun Bosnia wà.
Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ní Tuesday, October 26, 1993, ọkọ̀ akẹ́rù wa tí ó kó tọ́ọ̀nù 16 oúnjẹ àti igi ìdáná fún àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ wa ní Bosnia fi Vienna sílẹ̀. A fi káàdì àpéjọpọ̀ àgbègbè wa sí àyà gẹ́gẹ́ bí àmì ìdánimọ̀.
Bí a ti gúnlẹ̀ sí bodè Croatia àti Bosnia, a sìnwá dé ibùdó àwọn ológun níbi tí wọ́n ti yẹ gbogbo ọkọ̀ akẹ́rù wa wò fínnífínní. Wọn kò gbà kí a la agbègbè ìpínlẹ̀ Serbia kọjá. Wọ́n lè gbà pé kí a kọjá kìkì bí a bá lè gba ọ̀nà àárín gbùngbùn Bosnia—níbi ti ìjà ti ń lọ lọ́wọ́!
Ìsapá Ha Jásí Pàbó Bí?
Bí àwọn ọmọ ogun tí ń ṣamọ̀nà wa ti ń sìn wá lọ láti ibi àyẹ̀wò kan sí òmíràn, a ń gbọ́ ìró àgbọ́dití tí ń ti inú àwọn ọkọ̀ ogun àti ìbọn jáde. Láàárín òru, a rìn gba inú igbó kọjá pẹ̀lú àwọn ọkọ̀ ogún méjì àti ọkọ̀ jeep kan tí ń sìn wá lọ. Ọkọ̀ akẹ́rù wa náà ń yọ́kẹ́lẹ́ lọ ní iwájú ibi tí ìjà ti ń ṣẹlẹ̀ gan-an! Gbogbo nǹkan ń lọ déédéé títí di òwúrọ̀ nígbà tí ọta ìbọn ń fo gba orí wa kọjá tí a sì níláti farapamọ́ sí ẹ̀yìn òkè kékeré kan. Nígbà tí ó ṣe ìbọn yínyìn náà rọlẹ̀, a sì ń bá ìrìn-àjò wa lọ.
Nígbà tí a dé ibùdó kan, ọ̀gá àwọn ṣọ́jà níbẹ̀ béèrè irú ẹni tí a jẹ́ àti ohun tí a fẹ́. Lẹ́yìn tí a ti sọ ète wa fún un ó sọ pé, “Òfo ni ìdáwọ́lé yín yóò jásí. Kò sí àyè fún yín láti jáde kúrò nínú ibùdó yìí, àní láti rìn díẹ̀ síwájú. Ìyàn mú púpọ̀ ní orílẹ̀-èdè yìí débi pé àwọn ènìyàn yóò kọlù yín tí wọn yóò sì jí ẹrù yín.” Ó rọ̀ wa kí a pẹ̀yìndà kí a sì padà.
Ìsapá wa yóò ha ‘jásí òfo’ bí? Ṣe pàbó ni yóò jásí láti retí pé a lè kọjá ní àwọn agbègbè tí ogún ti fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ tí ìyàn sì ti kọlù síbẹ̀ kí a pa àwọn ẹrù wa àti ìwàláàyè wa mọ́ bí? A níláti ṣe ìpinnu kan tí ó jẹ́ kánjúkánjú. A ti gbọ́ ìró ìbọn àti ìbúgbàù àwọn bọ́m̀bù àgbọ́diti ṣáájú. Bí a ti sùn sọ́dọ̀ àwọn ṣọ́jà náà títí di òwúrọ̀, a lè rí i pé wọ́n ti gbaradì fún hílàhílo ogun náà. Wọ́n wọ àwọn àwọ̀tẹ́lẹ̀ ata-ọta-dànù wọ́n sì dira ogun háháhá. Agbóúnjẹ pàápàá gbé ìbọn arọ̀jò ọta kọ́ ẹ̀yìn rẹ̀. Àwa sì rèé tí a wọ ṣẹ́ẹ̀tì, tí a di táì, tí a sì fi káàdì sáyà! Ó ha bọ́gbọ́nmu fún wa láti máa tẹ̀síwájú bí?
A Gúnlẹ̀ sí Travnik
Ó dàbí ẹni pé, kìkì ìrètí tí a ní ni láti bá àwọn ẹgbẹ́ ogun kẹta tí ń lọ́wọ́ nínú ogún yìí sọ̀rọ̀. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì a béèrè lọ́wọ́ ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ obìnrin kan bí ó ba mọ́ ibi tí a ti lè rí àgọ́ àwọn ẹgbẹ́ ológun náà. Ó fèsì pé, “Kò jìnnà rárá. Bí ẹ bá ti ń gba inú igbó yìí lọ, ẹ óò rí ilé kan tí ó jẹ́ ilé-ìwòsàn tẹ́lẹ̀rí.” Ara wa ti wà lọ́nà. Ẹnu ya àwọn ṣọ́jà náà pé a fẹ́ fi ibùdó náà sílẹ̀ láìdira ogun.
Ilé-ìwòsàn tẹ́lẹ̀rí náà ti di àlàpà, ṣùgbọ́n ṣọ́jà kan wà níbẹ̀. Ó gbà láti ràn wá lọ́wọ́, ní fífun wa nímọ̀ràn láti kọ́kọ́ bá ọ̀gá òun sọ̀rọ̀. Ó fi ọkọ̀ rẹ̀ tí ó ti rí gbágungbàgun gbé wa lọ tí ó sì ń sáre àsápajúdé bí ó ti ń gba ojú ìjà náà kọjá. A dúró níbi ilé kan ti ọ̀gá àwọn ṣọ́jà ibẹ̀ ti gbà wá tọwọ́-tẹsẹ̀ nínú yàrá kan tí ó ṣókùnkùn.
Ó wí pé, “A fẹ́ rọ̀jò ọta ibọn lé yín lórí lálẹ́ àná. Kí ni ẹ ń fẹ́?”
“Ẹlẹ́rìí Jehofa ni wá, a sì fẹ́ láti lọ kò àwọn ẹrù ìpèsè ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ará wa.”
Ó yà á lẹ́nu—ó sì dùnmọ́ ọn nínú—níwọ̀n bí kò ti sí àwọn ọkọ̀ akẹ́rù tí wọ́n jẹ́ gbìdánwò láti kó ìpèsè ìrànlọ́wọ́ wọ Bosnia. Lẹ́yìn tí wọ́n ti yẹ araawa wò fínnífínní, wọ́n fún wa ní ìwé ẹ̀rí. Ní alẹ́ tí ó ṣáájú a rò pé kò lè sí àyè láti máa bá ìrìn-àjò wa lọ, ṣùgbọ́n a lè máa báa nìṣó wàyí láìsí pé àwọn kan ń sìn wá!
Inú igbó ni a wakọ̀ gbà, tí a sì ń kọjá láti ibi àyẹ̀wò kan sí òmíràn, a sì máa ń gba ibi tí ọwọ́ ìjá ti le kọjá nígbà mìíràn. Láìka àwọn ewu wọ̀nyí sí, a gúnlẹ̀ sí Travnik láyọ̀. Ṣọ́jà kan tí ó gbọ́ pé a ti dé sáré lọ sọ fún àwọn ará wa níbi tí wọ́n péjọ sí. Ó lọgun pé, “Àwọn ènìyàn yín ti dé pẹ̀lú àwọn ọkọ̀ akẹ́rù!” O lè fojú inú wo bí inú wọn yóò ṣe dùn tó. A gbé oúnjẹ wọnú ilé, a bá wọn sọ̀rọ̀ díẹ̀, ṣùgbọ́n a tún níláti máa bá ìrìn-àjò wa lọ. Ilẹ̀ ti ń ṣu, ìrìn-àjò kìlómítà 32 tí ó kún fún ewu ṣì wà níwájú.
Ó tún Di Zenica
Ọkọ̀ kan tí ń sìn wá lọ ṣamọ̀nà wa gba inú igbó kọjá pẹ̀lú eré àsápajúdé. Àwọn kan wí pé a kò lè dé Zenica láyọ̀, ṣùgbọ́n a débẹ̀. Ráuràu ni ilú náà rí. Kò sí iná bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí ọkọ̀ kankan lójú pópó. Wọ́n dóti Zenica ní gbogbo ìhà, tí ó sì wá yọrísí ìyàn ńlá àti àìnírètí.
Bí a ti ń wakọ̀ lọ láàárín ìgboro, a rí ohun yíyanilẹ́nu kan—àwọn Kristian arábìnrin méjì tí wọ́n ń jẹ́rìí! Bí a ṣe gbọ́, nínú ìpàdé wọn lánàá wọ́n pinnu pé àwọn arákùnrin níláti lọ sínú igbó láti lọ wá oúnjẹ, níwọ̀n bí àwọn ìpèsè tí ó wà lọ́wọ́ ti tán. A mọ̀ ọ́n rìn! A já ẹrù inú ọ̀kan lára àwọn ọkọ̀ náà ní agogo mẹ́rin ìdájí, nígbà tí òpópónà ṣì dá páro.
Ní ọjọ́ kejì a kàn sí ọ̀gágun kan, ẹni tí ẹnú yà gidigidi pé a lè dé Zenica láyọ̀. A wá béèrè nísinsìnyí nípa bí a ṣe lè rìnrìn-àjò dé ibi tí ó kàn tí a ń lọ, Sarajevo.
Ọ̀gágun náà fèsì pé, “Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó tíì gbìyànjú gbígbé ọkọ̀ akẹ́rù lọ́ síbẹ̀ láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù sẹ́yìn.” Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀ ó fún wa láṣẹ láti gba orí òkè kọjá. Ó kìlọ̀ pé, “Ṣùgbọ́n ká sọ tòótọ́, ó nira ò. Kò dá mi lójú pé ọkọ̀ akẹ́rù yín lágbára tó láti gba ibẹ̀.”
Ọ̀gágun náà kò sọ àsọdùn. Nígbà tí ó ku kìlómítà 40 péré kí a dé Sarajevo, a níláti yígba kìlómítà 140 nínú igbó! A kò lè gbàgbé ìrìn-àjò tí ó gba ọjọ́ mẹ́ta àti òru méjì láti Zenica gba Sarajevo kọjá lọ sí Jablanica, pẹ̀lú eré-sísa tí ó jẹ́ kìlómítà márùn-ún ní wákàtí kan. Àwọn ọkọ̀ ogun tí ń lọ tí ń bọ̀ ni wọ́n la “ọ̀nà” náà síbẹ̀. A wakọ̀ lórí àwọn àpáta àti ihò bíbanilẹ́rù. Lọ́pọ̀ ìgbà a níláti wakọ̀ láìtan iná, ní ìgbà méjì sì ni ọkọ̀ akẹ́rù wa fẹ́rẹ̀ẹ́ yọ̀ sísàlẹ̀ látorí àwọn òkè gíga gogoro. Ọkọ̀ akẹ́rù kan tí ó jẹ́ ti àwọn ológun tí ń tẹ̀lé wa tan iná rẹ̀ fún ìgbà díẹ̀, ní kíámọ́sá ni wọ́n rọ̀jò ìbọn síi lára. Nígbà mìíràn a níláti tún àwọn afárá tí ó ti bàjẹ́ àti táyà ṣe.
Bí a ti gúnlẹ̀ sí ẹ̀yìn-òde Sarajevo, a rọ̀ wá láti bá ọ̀gágun tí ń ṣe kòkáárí sọ̀rọ̀. Níbi tí a ti ń dúró dè é, ní a rí ọkọ̀ akẹ́rù kan lójú pópó tí ó gbé òkú ènìyàn mẹ́wàá àti orí àwọn abógunrìn tí a kó sínú àpò; àwọn ṣọ́jà ń jíròrò yíyọ̀ọ̀da àwọn òkú náà—ìran kan tí kò dùnmọ́ni láti máa wò, tí ń mú wa yánhànhàn fún ọjọ́ náà nígbà tí kì yóò sí ogun mọ́.—Isaiah 2:4.
Ní agogo 10:00 òwúrọ̀, wọ́n fún ọ̀kan nínú wa láyè láti bá ọ̀gágun àti àwọn ṣọ́jà rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ọ̀gá sọ̀rọ̀ nínú yàrá tí ó ṣókùnkùn, tí a tan kìkì àbẹ́là sí.
“Ta ni yín?” ní ọ̀gágun náà béèrè.
“Ẹlẹ́rìí Jehofa ni wá. A sí fẹ́ gbé oúnjẹ lọ fún àwọn Ẹlẹ́rìí ẹlẹgbẹ́ wa ní Sarajevo.”
“Ṣé ẹ kò mọ̀ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa pọ̀ ní Sarajevo ni?”
“A mọ̀ bẹ́ẹ̀, ìdí gan-an nìyẹn tí a fi wá.”
Nígbà náà ni ọ̀gágun náà dárúkọ Ẹlẹ́rìí kan. “Ǹjẹ́ ẹ mọ̀ ọ́n?”
“Bẹ́ẹ̀ni, ọ̀rẹ́ wa ni.”
“Ọ̀rẹ́ mi ni pẹ̀lú,” ni ọ̀gágun náà wí. “Ilé-ẹ̀kọ́ kan náà ni a jọ lọ. Mo tún wá fẹ́ràn rẹ̀ síi, nígbà tí ó di Ẹlẹ́rìí. Ó ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan fún ẹ̀yin ènìyàn yìí. Ẹ jọ̀wọ́ ẹ sọ díẹ̀ síi fún wa nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa.”
Ìjíròrò oníwákàtí kan bẹ̀rẹ̀, lẹ́yìn èyí tí a fi iye tí ó lé ní ìwé ìròyìn àti ìwé-pẹlẹbẹ méjìlá sóde. Lẹ́yìn ìpàdé kejì, ọ̀gágun náà gbà láti ṣe àkànṣe ètò kí àwọn ìpèsè ìrànlọ́wọ́ náà lè tẹ àwọn ara tí ó wà ní Sarajevo lọ́wọ́.
Èyí kìí ṣe ìdáwọ́lé kékeré. Nǹkan bíi 30 ènìyàn, títíkan àwọn kan tí kìí ṣe Ẹlẹ́rìí, ń gbé àwọn ẹrù tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn wọ̀n tó kìlógíráàmù 27. Ní alẹ́ méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wọ́n ṣiṣẹ́ láti agogo 8:00 òwúrọ̀ títí di agogo 5:00 ìrọ̀lẹ́—àròpọ̀ wákàtí 18. Alàgbà kan ròyìn pé ìsapá ìpèsè ìrànlọ́wọ́ náà mú kí ìmọ̀lára ìyàlẹ́nu bo àwọn aládùúgbò wọn ṣíbáṣíbá débi pé wọn bá àwọn ará kúnlẹ̀ papọ̀ tí wọ́n sì fi ọpẹ́ fún Jehofa! Àmọ́ ṣáá o, àwọn náà rí oúnjẹ díẹ̀ gbà.
Wo bí inú àwọn ará wa yóò ti dùn tó nígbà tí wọ́n rí àwọn ẹrù ìpèsè ìrànlọ́wọ́ tí ó wọ̀n tó 11,000 kìlógíráàmù gbà! Ipò náà kò fararọ. Ní àdúgbò, DM450 sí DM1,000 ($300 àti $660, U.S.) ni wọ́n ń ta kìlógíráàmù ìyẹfun kan. Àpò igi kan ni a ń tà ní DM400 ($260, U.S.), nígbà tí lítà epo dísù kan sì jẹ́ DM30 ($20, U.S.).
Níṣe ni ó dàbí ẹni pé a rí èrè gbà ní ìsanpadà fún ewu kọ̀ọ̀kan tí a bá pàdé lójú ọ̀nà. Ó dùn mọ́ wa láti rí ìdùnnú àwọn ará wa nígbà tí wọ́n rí àwọn ìpèsè ìrànlọ́wọ́ tí a fi ránṣẹ́ wọ̀nyí gbà. Ó jẹ́ ìrírí kan tí àwọn—àti àwa—kò jẹ́ gbàgbé láé. Ṣùgbọ́n ní báyìí a níláti máa ronú nípa ìpèníjà ti pípadà sílé.
Pípadà Sílé
A bi ọ̀gágun náà pé, “Níbo ni kí a gbà padà?”
Ó fèsì pé, “Ọ̀nà kan náà tí ẹ gbà wá ni.”
Ó ti rẹ̀ wá, epo ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tán, kò sì sí táyà tí a lè fi pààrọ̀. Òjò bẹ̀rẹ̀ síí rọ̀, a kò sì lè máa gba inú ẹrẹ̀ lọ. A béèrè lọ́wọ́ ọ̀gágun náà bí a bá lè gba apá gúúsù.
“Ìjà gbóná lápá ibẹ̀,” ni ó fèsì. “Kódà eku kò lè gba ibẹ̀ kọjá.” Ṣùgbọ́n, nígbà tí ó ṣe díẹ̀, ó tún ọ̀ràn náà gbé yẹ̀wò. Ó wí pé, “Ẹ gbìyànjú rẹ̀ wo. Ó ṣetán, ẹ débí láyọ̀.”
A níláti fi ọkọ̀ akẹ́rù kan sílẹ̀ a sì pín epo rẹ̀ sínú àwọn ọkọ̀ akẹ́rù mẹ́ta tí ó kù. A gbéra lọ́gànjọ́ òru a sì tún wakọ̀ gba inú igbó lọ.
A kò ṣaláìbá ìṣòro pàdé nígbà tí a ń padà bọ̀. A bá ọkọ̀ akẹ́rù kan tí ó jẹ́ ti àwọn ológun, tí ó fẹ̀gbẹ́ lélẹ̀, tí ó sì dábùú afárá tí a fẹ́ gbà kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ kan. A rí i pé bí a bá lè yọ ọ̀kan lára àwọn táyà ẹsẹ̀ rẹ̀, a óò rí àyè tí a lè gbà kọjá.
A rọ ọ̀kan lára àwọn ṣọ́jà tí ó dira ogun náà. “Ẹ dákun ṣe a lè yọ táyà yìí kí a sì tún gbé e si padà lẹ́yìn tí a bá kọjá afárá náà tán?”
“Bí o bá fọwọ́kan táyà náà, ìbọn mi yóò ríṣẹ́ ṣe,” ni èsì ṣọ́jà náà, tí ó sì fi ohun-ìjà rẹ̀ sun apá ibẹ̀.
A ronú pé yóò dára láti ṣètò kọfí díẹ̀ kí a sì fún ṣójà náà ní ife kan mú. Fún wákàtí díẹ̀, a sọ fún un nípa àwọn àpéjọpọ̀ àgbáyé ti 1991, irú èyí tí a ṣe ní Zagreb. Lẹ́yìn èyí, ojú rẹ̀ wálẹ̀, ó sì gbà pé kí a yọ táyà ọkọ̀ náà.
Ní Jablanica, ọ̀kan nínú wa bá ọ̀gá àwọn ṣọ́jà kan sọ̀rọ̀ nípa ọ̀nà tí a fẹ́ gbà. Ó ṣòro fún un láti gbà á gbọ́. “Ẹ fẹ́ lọ gbà ọ̀nà Àfonífojì Neretva?”
A lóye pé ó kó ìdààmú bá a. Onírúurú àwọn ọmọ ogun ni wọ́n wà ní apá òkè Àfonífojì Neretva. Léraléra ni wọ́n sì ń yìnbọn sí araawọn. Fún ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó kìlómítà 16, ọ̀nà náà léwu. Ọ̀gágun náà sọ pé, “Bí ó ṣe rí nìyẹn o, ṣe ẹ ṣì fẹ́ gba ibẹ̀ kọjá síbẹ̀síbẹ̀?”
Lẹ́yìn yíyiiri ọ̀ràn náà wò, ọ̀gágun náà wí pé a lè lọ—ṣùgbọ́n kìkì bí àwọn òṣìṣẹ́ olóyè bá lè bá wa lọ. Ṣùgbọ́n, àwọn òṣìṣẹ́ olóyè wọ̀nyí ń lọ́tìkọ̀ láti bá wa lọ! Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, a bẹ̀bẹ̀ pé kí wọ́n wulẹ̀ kàn sí àwọn tí ń bẹ níhà kejì kí wọ́n sì sọ fún wọn pé a fẹ́ kọjá. A óò kọjá láìjẹ́pé ẹni kankan sìn wá láàárọ̀ ọ̀la.
Pẹ̀lú àwọn ìwé tí a kọ gàdàgbà-gàdàgbà, a lẹ̀ ẹ́ mọ́ ara ọkọ̀ akẹ́rù wa pé àwọn ohun ìṣèrànwọ́ látọwọ́ àwọn afẹ́dàáfẹ́re ni a kó sínú ọkọ̀. Lẹ́yìn gbígba àdúrà, a kọrí sọ́nà àfonífojì náà. A fohùnsọ̀kan pé bí wọ́n bá yìnbọn, a kò ní sáré jù bẹ́ẹ̀ lọ kí a má baà jẹ́ kí wọ́n fura.
A sọdá afárá náà síhà kejì odò náà a sì ń ba ìrìn-àjò wa lọ sí àfonífojì tí ó tẹ̀lé e, ní kíkọjá lára àwọn òkú ẹran àti ọkọ̀ akẹ́rù àti ọkọ̀ àgbá ológun ńlá. Lójijì a ṣàkíyèsí àwọn bọ́m̀bù tí ó wà káàkiri ojú pópó, tí ó mú kí ó ṣòro fún wa láti kọjá. A tẹ fèrè ọkọ̀ náà títí tí àwọn ṣọ́jà méjì fi yọjú láti ẹ̀yìn àpáta kan. “Ta ni yín? Kí ni ẹ ń wá?” ni wọ́n béèrè.
Lẹ́yìn sísọ ẹni tí a jẹ́, a béèrè bí wọ́n bá lè pa ojú pópó náà mọ́, wọ́n sì gbà bẹ́ẹ̀. Nígbẹ̀yìn gbẹ́yín, a dé ìhà kejì.
Ẹnu ya àwọn ṣọ́jà tí wọ́n wà níbẹ̀ láti rí wa. Wọ́n yọ́ gọ́lọ́gọ́lọ́ jáde láti ibi tí wọ́n lúgọ sí, tí wọ́n sì kọjú ìbọn wọn sí wa bí wọ́n ṣe ń súnmọ́ ọkọ̀ akẹ́rù náà. A fí àwọn ìwé àṣẹ ìrìnnà wa àti páànù pẹlẹbẹ tí a kọ àṣẹ ìrìnnà wa sí hàn wọ́n, èyí tí a ti yọ kúrò nítorí àwọn ìdí kan tí ó jẹmọ́ ti ààbò nígbà tí a ń wakọ̀ gba ibi tí ogun ti ń jà kọjá.
Ṣọ́jà kan wí pé, “Kò sí ẹni tí ń retí yín. Báwo ni ẹ ṣe lè rọ́nà kọjá?”
Ní òdìkejì sí ohun tí a béèrè fún, kò sí ẹni kankan ní ibùdó yìí tí wọ́n sọ fún pé a ń bọ̀! Ṣọ́jà náà ń bá a lọ ní sísọ pé: “A ti fa ìrékó ìbọn wa, a sì ti fẹ́ bẹ̀rẹ̀ síí yìn ín.”
A béèrè ìdí tí wọn kò fi ṣe bẹ́ẹ̀.
Ṣọ́jà náà fèsì pé, “Èmi kò mọ̀. Mo gbàgbọ́ pé kádàrá yín ni. Ṣùgbọ́n nígbà tí a fi awò ìwọ̀nà-jínjìn wa wò yín, a rí àkọlé náà ‘ohun ìṣèrànwọ́ látọwọ́ àwọn afẹ́dàáfẹ́re,’ a kò sì mọ́ ohun tí a lè ṣe sí yín. Bí ẹ ṣe gúnlẹ̀ láyọ̀ nìyẹn.” Lẹ́yìn náà ni a gbàdúrà ọpẹ́ àtọkànwá sí Jehofa fún ààbò rẹ̀.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àyíká ipò wọn lekoko, ẹ̀mí àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa ní Bosnia tanijí. Wọ́n ṣàjọpín àwọn ohun-ìní ti ara tí wọ́n ní pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìgbàgbọ́ àti ìṣírí. Ní Zenica, wọ́n ní 40 àwọn Ẹlẹ́rìí ògbóṣáṣá, pẹ̀lú aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe 2, aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ 11, àti àwọn 14 tí wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ batisí. Àwọn Ẹlẹ́rìí 65 papọ̀ pẹ̀lú àwọn àti aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ 4 tí wọ́n ṣì wà ní ìlú-ńlá Sarajevo ń darí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli 134. Àwọn Ẹlẹ́rìí náà ń lo ìpíndọ́gba 20 wákàtí lóṣooṣù ní bíba àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa ìhìnrere Ìjọba Ọlọrun.
Nítòótọ́, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa parapọ̀ jẹ́ ìdílé onígbàgbọ́ kan tí ó kárí-ayé. Wọ́n máa ń fẹ̀mí araawọn wewu láti ṣe rere fún àwọn ìbátan wọn nínú ìgbàgbọ́—kódà àwọn tí wọn kò tilẹ̀ bá pàdé rí. Èéṣe? Nítorí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ wọn. Jesu Kristi wí pé: “Nipa èyí ni gbogbo ènìyàn yoo fi mọ̀ pé ọmọ-ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Johannu 13:35, NW) Dájúdájú bí ọ̀ràn àwọn ìdílé onígbàgbọ́ wa ní Bosnia ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyẹn.
[Àwòrán ilẹ̀/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Òkun Adriatic
AUSTRIA
SLOVENIA
HUNGARY
CROATIA
BOSNIA
Travnik
Zenica
Sarajevo
SERBIA
[Àwọn àwòrán]
Gbígbé àwọn ìpèsè ìrànlọ́wọ́ lọ sí Bosnia òun Herzegovina
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Rírọra pọ́ kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọkọ̀ akẹ́rù tí ó ti fẹ̀gbẹ́ lélẹ̀