Àyẹ̀wò Ìlera Kan fún Ọ Ha Ni Bí?
Watch Tower Society kì í ṣe àwọn ìdábàá tàbí ìpinnu fún àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan lórí àwọn àṣà ìṣègùn àti ìṣàwárí àrùn. Bí ó ti wù kí ó rí, bí àwọn àṣà kan bá ní àwọn apá tí ń kọni lóminú lójú ìwòye àwọn ìlànà Bibeli, a lè pe àfiyèsí sí ìwọ̀nyí. Lẹ́yìn náà ẹnìkọ̀ọ̀kan lè wọn ohun tí ó wémọ́ ọn wò kí ó sì pinnu ohun tí ó yẹ ní ṣíṣe.
Ẹ̀yin Ará Ọ̀wọ́n: Èmi yóò fẹ́ láti mọ èrò yín. Ó dàbí ẹni pé [ẹnì kan tí ń tọ́jú àwọn aláìsàn] ń ṣe àṣeyọrí dáradára, ṣùgbọ́n ọ̀nà tí ó ń gbà ṣe é ń mú ara fu mi. . . . Nípasẹ̀ àyẹ̀wò ni ó fi ń pinnu ohun tí ìṣòro náà jẹ́. Lẹ́yìn náà láti ṣe àwárí irú tàbí ìwọ̀n egbòogi tí ó yẹ kí ó lò, yóò fi ìgò egbòogi kan sí ìtòsí awọ-ara lẹ́bàá ẹṣẹ́ tàbí ẹ̀yà ara kan. Yóò gbìyànjú láti fa apá ti aláìsàn náà gbé sókè wálẹ̀. Bí agbára tí ó nílò láti fi fa apá náà wálẹ̀ bá ti pọ̀ tó ni yóò pinnu irú tàbí ìwọ̀n egbòogi náà. Àbá èrò-orí náà ni pé àwọn “electron,” bí i agbára iná mànàmáná, ń gba inú egbòogi náà kọjá lọ sínú ìdérí mẹ́táàlì tí a fi dé ìgò náà lọ́ sínú ẹ̀yà ara kan, ní fífún un lókun. Èyí ha dàbí fífi ọ̀pá-ìwoṣẹ́ wá omi bí?
LẸ́TÀ tí ó wá láti Oregon, U.S.A., yìí, ní í ṣe pẹ̀lú àṣà kan tí àwọn kan ń lò láti pinnu irú èròjà oúnjẹ tí ẹnì kan nílò, láti wọn àwọn ọ̀ràn ti èrò ìmọ̀lára wò, láti díwọ̀n àwọn agbára ìrántí, àti láti wá ojútùú sí àwọn ìbéèrè nípa ìgbésí-ayé ojoojúmọ́. Bí ó ti wù kí àṣà náà wọ́pọ̀ tó, ó ha dá ẹ̀mí ìfura òǹkọ̀wé náà láre bí?
Ìlera—Kí Ni Ó Ń Náni?
Láti ìgbàanì wá, àwọn ènìyàn ti ń gbìyànjú láti lóye ìdí rẹ̀ tí wọ́n fi ń ṣàìsàn àti bí ara wọn ṣe lè yá. Àwọn ọmọ Israeli ní àǹfààní kan nítorí tí wọ́n mọ̀ pé àwọn jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, wọ́n sì ní àwọn òfin láti ọwọ́ Ọlọrun tí ó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti yẹra fún kíkó tàbí títan ọ̀pọ̀ àrùn kálẹ̀. (Lefitiku 5:2; 11:39, 40; 13:1-4; 15:4-12; Deuteronomi 23:12-14) Síbẹ̀, àwọn ènìyàn Ọlọrun tún ń wá ìrànlọ́wọ́ sọ́dọ̀ àwọn oníṣègùn tí wọ́n tóótun ní ọjọ́ tiwọn.—Isaiah 1:6; 38:21; Marku 2:17; 5:25, 26; Luku 10:34; Kolosse 4:14.
Ẹ wo bí èyí ti yàtọ̀ sí ti àwọn ènìyàn ní Babiloni àti Egipti ìgbàanì tó! “Àwọn dókítà” wọn ní àwọn oògùn ojútùú kan tí a gbékarí àwọn èròjà ìṣẹ̀dá, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ lára àwọn “ìtọ́jú” wọn ní a lè ṣàpèjúwe nísinsìnyí pé ó jẹ́ arúmọjẹ. Ìwé àwọn ara Egipti kan tí a fi àwòrán kọ sọ nípa oníṣègùn kan tí ń fi àpòpọ̀ ohun olómi dídírì ti ojú ẹlẹ́dẹ̀, tìróò, èròjà ocher pupa, àti oyin wo ìfọ́jú. Àpòpọ̀ yìí ni wọ́n dà sí aláìsàn náà létí! Gbólóhùn ìjẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ kan ní ìgbàanì jẹ́wọ́ pé ìtọ́jú yìí “dára púpọ̀ níti gidi.” Ti pé ó ṣàjèjì tí ó sì jẹ́ ohun ìjìnlẹ̀ ti lè mú kí ìfanimọ́ra rẹ̀ pọ̀ sí i.
Lọ́pọ̀ ìgbà ni àwọn ará Babiloni àti Egipti máa ń fọ̀rànlọ àwọn agbára ohun ìjìnlẹ̀ awo.a Àlùfáà/oníṣègùn kan lè sọ pé kí aláìsàn kan mí sínú ihò imú àgùtàn kan, ní gbígbàgbọ́ pé ipá, tàbí agbára ìṣiṣẹ́ kan, lè ti inú aláìsàn náà jáde lọ sínú ẹ̀dá mìíràn kí ó sì mú kí ohun kan ṣẹlẹ̀. Àgùtàn náà ni a óò pa, ti a sì retí pé kí ẹ̀dọ̀ rẹ̀ ṣàfihàn àìsàn aláìsàn náà tàbí ọjọ́-ọ̀la rẹ̀.—Isaiah 47:1, 9-13; Esekieli 21:21.
Àmọ́ ṣáá o, oníṣègùn kan tí ó jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọrun ní Israeli ìgbàanì kì yóò lo àwọn àṣà ìbẹ́mìílò. Lọ́nà tí ó lọ́gbọ́n nínú, Ọlọrun pàṣẹ pé: “Kí a máṣe rí nínú yín ẹnì kan . . . tí ń fọ àfọ̀ṣẹ, tàbí alákìíyèsí ìgbà, tàbí aṣèfàyà, tàbí àjẹ́ . . . Nítorí pé gbogbo àwọn tí ń ṣe nǹkan wọ̀nyí ìríra ni sí OLUWA.” (Deuteronomi 18:10-12; Lefitiku 19:26; 20:27) Ohun kan náà ni ó kan àwọn Kristian ìránṣẹ́ Ọlọrun lónìí. Ìkíyèsára jẹ́ ohun yíyẹ.
Ní àwọn ọdún lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ti yíjú sí àwọn ọgbọ́n ìṣàwárí àti ìtọ́jú àrùn “àfidípò.” Èyí ní pàtàkì jẹ́ agbègbè kan fún ìpinnu ara-ẹni. (Matteu 7:1; fiwé Romu 14:3, 4.) Àmọ́ ṣáá o, yóò bani nínú jẹ́ bí Kristian èyíkéyìí kan bá di ẹni tí àwọn ọ̀ràn àríyànjiyàn títakora nípa ìlera gbà lọ́kàn débi pé ìwọ̀nyí síji bo iṣẹ́-òjíṣẹ́, tí ó jẹ́ ọ̀nà dídájú kanṣoṣo láti gba ìwàláàyè là. (1 Timoteu 4:16) Bibeli kò sọ pé nínú ayé titun a óò wo àìsàn sàn ti a óò sì jèrè ìlera pípé nípasẹ̀ ìtọ́jú ti ìmọ̀ ìṣègùn, tewé-tegbò, ìdíwọ̀n oúnjẹ jíjẹ, tàbí ìtọ́jú ara látòkè-délẹ̀. Níti gidi, ìwòsàn kíkún ni a óò mú wá kìkì nípasẹ̀ ìdárí ẹ̀ṣẹ̀ jinni lórí ìpìlẹ̀ ẹbọ ìràpadà Jesu.—Isaiah 33:24; Ìṣípayá 22:1, 2.
Àwọn Ipá Wo Ni Ó Ní Nínú?
Kí ni Kristian kan lè fẹ́ láti gbéyẹ̀wò nígbà tí ó bá ń ṣe ìpinnu tirẹ̀ nípa àwọn àṣà ṣíṣàyẹ̀wò iṣu-ẹran tí a mẹ́nukàn nínú lẹ́tà tí a fi bẹ̀rẹ̀?
Irú àwọn ọ̀nà kan tí a gbà ń ṣe àyẹ̀wò okun tàbí ìhùwàpadà àwọn iṣu-ẹran jẹ́ apákan ìṣègùn tí ó ṣètẹ́wọ́gbà, ìwọ̀nba díẹ̀ sì ni àwọn tí yóò gbé ìbéèrè dìde sí ìlẹ́sẹ̀nílẹ̀ rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, poliomyelitis [àrùn àkóràn tí ń mú eegun ẹ̀yìn tí ó sábà máa ń sọni di arọ] lè sọ àwọn iṣu-ẹran di aláìlera, ìtọ́jú ìṣègùn fún èyí sì lè wémọ́ ohun tí a ń pè ní kinesiology—“ẹ̀kọ́ nípa àwọn iṣu-ẹran àti ìlọsókè-sódò iṣu-ẹran.” Irú kinesiology bẹ́ẹ̀ ni a tún ń lò nínú ìtọ́jú ìṣègùn ìmúpadàbọ̀sípò fún àwọn òjìyà ìpalára àrùn tí ń rọni lọ́wọ́ rọni lẹ́sẹ̀. Ọ̀pọ̀ jùlọ àwọn ènìyàn yóò rí ìdí tí irú ìtọ́jú bẹ́ẹ̀ fi lọ́gbọ́n-nínú.
Ṣùgbọ́n kí ni nípa ti ṣíṣàyẹ̀wò iṣu-ẹran tí a ṣàpèjúwe nínú lẹ́tà tí ó wà ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ yìí? Irú “kinesiology” yìí ni a ti lò nínú ìgbìdánwò láti ṣàwárí bóyá irú àwọn oúnjẹ, ewébẹ̀, tàbí vitamin kan báyìí lè ran ẹnì kan lọ́wọ́ tàbí pa á lára. Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti sábà máa ń ṣe é, ẹni náà yóò na apá rẹ̀ sókè, olùṣètọ́jú náà yóò sì tẹ̀ ẹ́ wálẹ̀ láti dán agbára iṣu-ẹran rẹ̀ wò. Lẹ́yìn èyí ni onítọ̀hún yóò fi èròjà amẹ́mìídè tàbí ohun mìíràn sí ẹnu rẹ̀, tàbí sí ikùn rẹ̀, tàbí sí ọwọ́ rẹ̀. Nígbà náà ni yóò tún yẹ iṣu-ẹran apá rẹ̀ wò. Wọ́n jẹ́wọ́ pé bí ó bá nílò èròjà amẹ́mìídè yẹn, apá rẹ̀ yóò túbọ̀ lágbára sí i, bí kò bá dára fún un, iṣu-ẹran náà yóò túbọ̀ rọ pọ́jọ́.b
Àwọn kan tí wọ́n ti gbìyànjú èyí gbàgbọ́ pé ó ṣiṣẹ́ àti pé ìyọrísí rẹ̀ ni a gbé karí àwọn ipá tí ń bẹ nínú ara. Wọ́n ronú pé ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan wà tí àwọn ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ òde-òní kò lè ṣàlàyé ṣùgbọ́n tí wọ́n ń ṣẹlẹ̀ tàbí tí a lè kíyèsí. Nípa báyìí, wọ́n jẹ́wọ́ pé àwọn ipa ọ̀nà agbára tàbí àjọṣepọ̀ lè wà láàárín àwọn ipá àti àwọn ohun gidi, àní bí àwọn oníṣègùn kò bá tilẹ̀ tí ì ṣàwárí tàbí gbà nípa ìwọ̀nyí síbẹ̀.
Ní ọwọ́ mìíràn ẹ̀wẹ̀, ìwé náà Applied Kinesiology sọ pé: “Nígbà mìíràn [àwọn ìwé] ń kọ́ni pé àwọn èròjà kẹ́míkà, bí i àwọn ohun amẹ́mìídè, ni a ń díwọ̀n nípa mímú ohun náà dání kí a sì ṣàyẹ̀wò iṣu-ẹran. Kò sí ẹ̀rí kankan tí ó dámọ̀ràn pé irú ìṣàyẹ̀wò yìí ṣe é gbáralé lọ́nà èyíkéyìí. . . . Ẹ̀mí-ìrònú pé ohun amẹ́mìídè kan yẹ ní lílò lè lágbára débi pé èrò tí olùṣètọ́jú náà gbìn sọ́kàn nípa ìṣàyẹ̀wò náà lè forígbárí pẹ̀lú kíkó ìsọfúnni pípéye jọ nínú ọ̀nà tí a gbà ń ṣe àyẹ̀wò náà.” “Ó lè rọrùn fún olùṣàyẹ̀wò kan tí ó ní ìrírí nínú fífi ọwọ́ ṣàyẹ̀wò iṣu-ẹran láti sọ iṣu-ẹran ẹni tí ó ń tọ́jú di èyí tí kò lágbára tàbí tí ó lágbára ní ìbámu pẹ̀lú ìdánúṣe tirẹ̀ nípa wíwulẹ̀ yí . . . àyẹ̀wò náà padà fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́.”
Ṣọ́ra!
Bí ó ti wù kí ó rí, irú àwọn àyẹ̀wò iṣan ara kan a máa lọ rékọjá èyí. Ṣàyẹ̀wò ohun tí a pè ní “àyẹ̀wò ẹni àyàndípò.” Èyí ni wọ́n lè ṣe nínú ọ̀ràn ti àgbàlagbà kan tàbí ọmọ-ọwọ́ kan tí agbára rẹ̀ kò tó ti ẹni tí a lè ṣàyẹ̀wò. Nígbà tí ẹni àyàndípò kan bá fi ọwọ́ kan ọmọ-ọwọ́ náà, olùṣètọ́jú yóò wá ṣàyẹ̀wò apá ẹni àyàndípò náà. Èyí pẹ̀lú ni a ti lò fún àwọn ohun ọ̀sìn ìṣiré; a óò yẹ apá ẹni àyàndípò náà wò nígbà tí ọwọ́ rẹ̀ bá ṣì wà lórí ajá collie, ajá German shepherd, tàbí ohun ọ̀sìn ìṣiré mìíràn tí ń ṣàìsàn.
Kì í ṣe tiwa láti ṣèdájọ́ irú àwọn ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n ìwọ lè béèrè pé, ‘Àwọn ipá tí ó ṣe é fojúrí ha wà lẹ́yìn àwọn ipá ìyọrísí wọ̀nyí bí?’ Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ti fi ẹ̀rí hàn nípa wíwà àwọn ìmọ́lẹ̀ onítànṣán gíga, ìgbì afẹ́fẹ́ apèsè agbára iná, àti ọlọ́kan-ò-jọ̀kan àwọn ìtànṣán apèsè agbára iná. Síbẹ̀, ó ha lè jẹ́ pé gbogbo ẹ̀dá, àní àwọn ọmọdé jòjòló àti ohun ọ̀sìn ìṣiré pàápàá, ni ó ní àwọn ipá lára èyí tí ó lè tú jáde kí ó sì pèsè ipá ìyọrísí kan tí a lè ṣàyẹ̀wò rẹ̀ lára ẹlòmíràn kan? Àwọn ará Babiloni ronú pé àwọn ipá lè tú jáde sí ara àgùtàn kan kí wọ́n sì nípa lórí rẹ̀. Ìwọ lè bi araàrẹ pé, ‘Mo ha gbàgbọ́ pé ohun kan tí ó jọ èyí lè ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn tàbí ẹranko lónìí bí? Tàbí àwọn ipá ìyọrísí náà ha lè ní àlàyé mìíràn bí?’
Àwọn oníwòsàn kan lè jẹ́wọ́ pé àwọn ń wọn “àwọn ipá” tí ẹnì kan ní wò pẹ̀lú irú àwọn ohun ìhùmọ̀ bíi ohun lílọ́ tí a fi mẹ́táàlì ṣe tàbí ọmọ-inú agogo. Wọ́n tànmọ́ọ̀ pé wọ́n ń yí b “pápá agbára” oníwòsàn náà bá ti ń ní ìfarakanra pẹ̀lú ti aláìsàn náà. Olùṣètọ́jú àti òǹkọ̀wé kan nínú ọ̀nà ẹ̀kọ́ yìí, tí ó ti jẹ́ onímọ̀ ìjìnlẹ̀ tí ń ṣèwádìí tẹ́lẹ̀, máa ń fi ọmọ-inú agogo ṣàwárí àrùn nígbà mìíràn. Ó tún fi ìtẹnumọ́ sọ pé òun lè fí ojú inú wòye “pápá agbára ẹ̀dá-ènìyàn” tàbí ìtànṣán aláràbarà tí wọ́n sọ pé ó máa ń yí ẹnìkọ̀ọ̀kan ká. Ó jẹ́wọ́ pé òun ń lo “agbára ìríran tí ń wonú ara” láti wo inú ara láti rí àwọn kókó ọlọ́yún, sẹ́ẹ̀lì ẹ̀jẹ̀, tàbí àwọn kòkòrò akéréjojú, àti láti wo àwọn ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ kọjá.c
Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ tẹ́lẹ̀, dídán ipá wò nípasẹ̀ okun apá ni a ti lò láti dán èrò-ìmọ̀lára wò. Ìwé kan tí ó ní ìpínkiri gbígbòòrò sọ pé: “Bí o bá nífẹ̀ẹ́ ọkàn láti fi àyẹ̀wò èrò-ìmọ̀lára fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ [kún un] ní àkókò kan náà, fi igbe tantan béèrè pé ‘Ìwọ ha ni ìṣòro kan bí?’ kí o sì tún àyẹ̀wò náà ṣe. Èyí yóò máa sọ apá náà di aláìlágbára lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan bí èròjà amẹ́mìídè náà kò bá dára.” Àwọn kan ń lo irú àyẹ̀wò bẹ́ẹ̀ “láti fi mọ ọjọ́-orí náà tí ìdààmú pàtó kan nípa ti ara, èrò-ìmọ̀lára tàbí nípa tẹ̀mí” wáyé. A tún ń lò ó láti fi ṣe ìpinnu ‘bẹ́ẹ̀ni tàbí bẹ́ẹ̀kọ́’ lórí àwọn ọ̀ràn ojoojúmọ́.
Ó ṣeéṣe kí ó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn tí ń ṣe irú àyẹ̀wò iṣu-ẹran (kinesiology) bẹ́ẹ̀ yóò sọ pé ọ̀nà tí àwọn ń gbà ṣe é yàtọ̀ sí ohun tí a ṣẹ̀sẹ̀ ṣàpèjúwe tán yìí, pé kò ní ìbẹ́mìílò nínú, tàbí pé àwọn kì í ṣe àyẹ̀wò èrò-ìmọ̀lára kankan. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó ha jẹ́ pé a ṣì gbé ohun tí wọ́n ń ṣe karí ìgbàgbọ́ nínú àwọn ipá tí ń bẹ nínú ẹ̀dá ènìyàn kọ̀ọ̀kan èyí tí kìkì àwọn ènìyàn kan tí wọ́n ń jẹ́wọ́ pé àwọn ní agbára àkànṣe lè ṣàyẹ̀wò rẹ̀ tàbí rí?
Àwọn Kristian kò fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú irú àwọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀. Ọlọrun gba orílẹ̀-èdè Israeli nímọ̀ràn pé: “Oṣù titun àti sábáàtì, pípe àpéjọpọ̀—èmi kò lè fi ara da lílo agbára ti àwọn ẹ̀mí-ibi àti àpéjọ aláyẹyẹ ìsìn.” (Isaiah 1:13, NW) Nígbà tí orílẹ̀-èdè yẹn di apẹ̀yìndà, wọ́n “ń fọ àfọ̀ṣẹ, wọ́n sì ń ṣe àlúpàyídà.” (2 Awọn Ọba 17:17; 2 Kronika 33:1-6) Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ti fihàn wọ́n ń wá ìsọfúnni nípasẹ̀ àwọn àkànṣe ààtò, nígbà náà ni wọ́n sì sọ̀rọ̀ nípa “ohun tí ó jẹ́ tí àwọn ẹ̀mí-ibi.”—Sekariah 10:2, NW.
Àwọn àyẹ̀wò iṣu-ẹran kan lè jẹ́ èyí tí kò lè panilára, tí a ṣe láìsí ìpalára fún aláìsàn tàbí olùṣètọ́jú. Ṣùgbọ́n, ó ṣe kedere pé àwọn kan lè ni agbára ti àwọn ẹ̀mí-ibi tàbí apá tí ó ju ti ẹ̀dá lọ, bí i agbára ìríran tí ń wọnú ara, àwọn ìtànṣán ti ohun ìjìnlẹ̀, àti ìlò ọmọ inú agogo. Àwọn Kristian kò gbọdọ̀ lo agbára àwọn ẹ̀mí-ibi. Wọn kò sì níláti ṣe àyẹ̀wò pẹ̀lú irúfẹ́ bẹ́ẹ̀, nítorí pé wọn kì í ṣe òfíntótó nípa àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Satani. (Ìṣípayá 2:24) Kàkà bẹ́ẹ̀, ìdí rere wà láti lo ìṣọ́ra nípa ohunkóhun tí ó lè dàbí èyí tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìbẹ́mìílò, èyí tí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun dẹ́bi fún.—Galatia 5:19-21.
Ohun tí olùṣètọ́jú kan bá ṣe jẹ́ ẹrù-iṣẹ́ tirẹ̀, a kò sì ní in lọ́kàn láti gbé ohun tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn jẹ́wọ́ tàbí ọ̀nà tí wọ́n ń gbé e gbà yẹ̀wò kí a sì ṣe ìdájọ́. Kódà bí o bá ní ìmọ̀lára pé díẹ̀ lára àwọn àṣà wọ̀nyí ní agbára ti àwọn ẹ̀mí-ibi nínú, ó ṣe kedere pé ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n gbìyànjú wọn ṣe bẹ́ẹ̀ láìmọwọ́ mẹsẹ̀, láìronú pé ó lè ṣeéṣe kí wọ́n lọ́wọ́ nínú ìbẹ́mìílò. Ó kàn lè jẹ́ àmì tí ó fi ìfẹ́-ọkàn ìgbékútà tí wọ́n ní fún ìlera rere hàn. Síbẹ̀, àwọn kan tí wọ́n ti lọ́wọ́ nínú irú àwọn àṣà bẹ́ẹ̀ ti pinnu lẹ́yìn náà pé àǹfààní èyíkéyìí nípa ti ara tí ó ṣeéṣe kí ó mú wá kò tẹ̀wọ̀n tó ewu nípa tẹ̀mí tí ó wà níbẹ̀.
Lẹ́ẹ̀kan sí i, ẹnì kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ pinnu ohun tí òun yóò ṣe nípa irú àwọn ọ̀ràn ara-ẹni bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀, àwọn Kristian gbọ́dọ̀ rántí ìmọ̀ràn Ọlọrun pé: “Òpè ènìyàn gba ọ̀rọ̀ gbogbo gbọ́: ṣùgbọ́n amòye ènìyàn wo ọ̀nà ara rẹ̀ rere.” (Owe 14:15) Ìyẹn ní í ṣe pẹ̀lú àǹfààní ìlera tí ó ṣeéṣe kí ó wà nínú àwọn ọ̀nà ìgbà ṣe ìtọ́jú kan pẹ̀lú.
Satani ní ìháragàgà láti pín ọkàn àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun níyà kúrò nínú ìjọsìn tòótọ́. Inú Eṣu yóò dùn bí ó bá lè ṣe bẹ́ẹ̀ nípa mímú kí àwọn ire àǹfààní mìíràn fa àwọn Kristian mọ́ra. Inú rẹ̀ yóò túbọ̀ dùn sí í pàápàá bí a bá fà wọ́n mọ́ra nípasẹ̀ àwọn nǹkan tí ó jẹ́, tàbí dàbí èyí tí ó jẹ́, ti àwọn ẹ̀mí-ibi tí ó lè fà wọn lọ sínú ìbẹ́mìílò.—1 Peteru 5:8.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kristian kò sí lábẹ́ Òfin Mose, ìṣarasíhùwà Jehofa Ọlọrun sí àwọn àṣà ohun ìjìnlẹ̀ awo kò tí ì yípadà. Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ní ìṣáájú, Ọlọrun pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israeli pé “ẹnì kan . . . tí ń fọ àfọ̀ṣẹ, tàbí alákìíyèsí-ìgbà, tàbí aṣèfàyà, tàbí àjẹ́, tàbí atujú” ní a kò gbọdọ̀ rí láàárín wọn. “Gbogbo àwọn tí ń ṣe nǹkan wọ̀nyí ìríra ni sí OLUWA . . . Kí ìwọ kí ó pé lọ́dọ̀ OLUWA Ọlọrun rẹ.”—Deuteronomi 18:10-13.
Nígbà náà, ẹ wo bí ó ti lọ́gbọ́n-nínú tó fún àwọn Kristian lónìí láti máa bá a nìṣó ní gbígbé “ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun wọ̀ . . . nitori awa ní gídígbò kan . . . lòdì sí awọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú ní awọn ibi ọ̀run”!—Efesu 6:11, 12, NW.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọ̀pọ̀ ènìyàn ṣì ń tọ àwọn shaman, àwọn adáhunṣe, tàbí irú àwọn olùmúniláradá bẹ́ẹ̀ lọ. Shaman kan jẹ́ “àlùfáà kan tí ń lo idán fún ète wíwo aláìsàn sàn, wíwoṣẹ́ láti sọ ohun tí ó farasin, àti dídarí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀.” Adáhunṣe kan, tàbí shaman, lè da tewé-tegbò pọ̀ mọ́ àwọn àṣà ìbẹ́mìílò (ní fífọ̀rànlọ àwọn ipá ohun ìjìnlẹ̀). Kristian oníṣọ̀ọ́ra kan, tí ó jẹ́ olùṣòtítọ́ yóò takété sí lílọ́wọ́ nínú ìbẹ́mìílò, àní bí ó bá tilẹ̀ dàbí ẹni pé ó ń wonisàn.—2 Korinti 2:11; Ìṣípayá 2:24; 21:8; 22:15.
b Èyí jẹ́ àpèjúwe gbogbogbòò kan, ṣùgbọ́n ọ̀nà tí a gbà ń ṣe àyẹ̀wò náà lè yàtọ̀síra. Fún àpẹẹrẹ, wọ́n lè sọ fún onítọ̀hún láti tẹ àtàǹpàkò àti ìka ìlábẹ̀ rẹ̀ mọ́ra pinpin, olùṣètọ́jú náà yóò sì gbìyànjú láti yà wọ́n sọ́tọ̀.
c Ó kọ̀wé pé: “Báwo ni àwọn nǹkan tí ó dàbí ìṣẹ̀lẹ̀ àgbàyanu yìí ṣe ń wáyé? . . . Ọ̀nà tí mo ń gbà ṣe é ní a ń pè ní gbígbé ọwọ́ léni, ìgbàgbọ́ wò-ó-sàn tàbí ìwòsàn tẹ̀mí. Kì í ṣe ọnà ìgbà ṣe nǹkan tí ó ní ohun ìjìnlẹ̀ nínú rárá, ṣùgbọ́n ó ṣe tààràtà . . . Olúkúlùkù ni ó ní pápá agbára tàbí ìtànṣán tí ó yí ará ìyára ká tí ó sì ń wọ inú rẹ̀ ní ìhà gbogbo. Pápá agbára yìí ní ìsopọ̀ tímọ́tímọ́ mọ́ ìlera. . . . Ìwòye Alágbára Ìmòye Gíga jẹ́ irú ‘rírí’ kan nínú èyí tí ìwọ yóò ti rí àwòrán kan nínú ọkàn rẹ láìlo agbára ìríran rẹ̀ gidi. Kì í ṣe ìrònúwòye. A sábà máa ń tọ́ka sí i gẹ́gẹ́ bí agbára ìwòye tí ó rékọjá agbára ìríran.”