ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 1/1 ojú ìwé 5-10
  • Yíyọ Ayọ̀ Ìṣẹ́gun Lórí Satani àti Iṣẹ́ Rẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Yíyọ Ayọ̀ Ìṣẹ́gun Lórí Satani àti Iṣẹ́ Rẹ̀
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìwàtítọ́ Lábẹ́ Inúnibíni
  • Ní Rwanda Tí Ìjà ti Fàya Pẹ́rẹpẹ̀rẹ
  • Àwọn Ọ̀dọ́ Olùpa Ìwàtítọ́ Mọ́
  • Àwọn Ọgbọ́n Àrékérekè Mìíràn Tí Satani Ń Lò
  • Ṣé Wàá Pa Ìwà Títọ́ Ẹ Mọ́?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Máa Hùwà Tó Tọ́ Nígbà Gbogbo
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
  • Jóòbù Gbé Orúkọ Jèhófà Ga
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Gbé Ìgbé Ayé Tó Múnú Ọlọ́run Dùn
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 1/1 ojú ìwé 5-10

Yíyọ Ayọ̀ Ìṣẹ́gun Lórí Satani àti Iṣẹ́ Rẹ̀

“Nitori naa, ẹ fi ara yín sábẹ́ Ọlọrun; ṣugbọn ẹ kọ ojú ìjà sí Èṣù, oun yoo sì sá kúrò lọ́dọ̀ yín.”—JAKỌBU 4:7, NW.

1. Báwo ni “ọwọ́ ènìyàn búburú” ṣe ń nípalórí aráyé lónìí?

JOBU sọ lọ́nà tí ó tọ́ pé: “A fi ayé lé ọwọ́ ènìyàn búburú.” (Jobu 9:24) Nísinsìnyí ni a sì dojúkọ àwọn àkókò lílekoko jùlọ nínú ọ̀rọ̀-ìtàn ẹ̀dá ènìyàn. Èéṣe? Nítorí pé ìwọ̀nyí ni “awọn ọjọ́ ìkẹyìn” àkókò tí Satani ń fi ẹ̀mí-èṣù jẹgàba lé ayé lórí. Kò yanilẹ́nu pé, lábẹ́ ìsúnṣiṣẹ́ Satani, ‘awọn ènìyàn burúkú ati awọn afàwọ̀rajà ń tẹ̀síwájú lati inú búburú sínú búburú jù, wọn ń ṣinilọ́nà a sì ń ṣi awọn pẹlu lọ́nà.’ (2 Timoteu 3:1, 13, NW) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, inúnibíni, àìṣèdájọ́ òdodo, ìwà ìkà, ìwà ọ̀daràn, ipò-ìṣòro ìṣúnná-owó, àwọn àmódi ọlọ́jọ́ pípẹ́, ìroragógó ọjọ́ ogbó, ìsoríkọ́ níti èrò-ìmọ̀lára—ìwọ̀nyí àti púpọ̀ síi lè mú wa banújẹ́ gidigidi.

2. Báwo ni a ṣe lè kojú àwọn ìgbéjàko Satani lónìí?

2 Elénìní ńlá náà, Satani Eṣu, ń dojú ìgbéjàkò gidigidi kọ aráyé àti ní pàtàkì jùlọ àwọn olùjọ́sìn tòótọ́ fún Ọlọrun. Góńgó rẹ̀ ni láti dẹ̀yìn gbogbo àwọn tí ó lè ṣeé ṣe kí wọ́n di olùpa ìwàtítọ́ mọ́ kọ Ọlọrun kí ó sì mú kí wọ́n parun pọ̀ pẹ̀lú òun àti àwọn áńgẹ́lì ẹ̀mí-èṣù rẹ̀. Ṣùgbọ́n, a mú un dá wa lójú pé bí a bá lo ìfaradà nínú ìwàtítọ́, Eṣu yóò sá kúrò lọ́dọ̀ wa. Bíi ti Jesu, a lè “kọ́ ìgbọràn” sí Ọlọrun láti inú àwọn ohun tí a bá jìyà rẹ̀, kí a sì jèrè ìyè àìnípẹ̀kun, nípasẹ̀ inúrere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Rẹ̀.—Heberu 5:7, 8, NW; Jakọbu 4:7; 1 Peteru 5:8-10.

3, 4. (a) Àwọn àdánwò láti òde wá wo ni Paulu níláti bá wọ̀jà? (b) Kí ni Paulu ń ṣàníyàn nípa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Kristian alàgbà kan?

3 A dán aposteli Paulu pẹ̀lú wò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà. Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀rí ìṣeé gbáralé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Kristi, ó kọ̀wé pé: “Lọ́nà tí ó túbọ̀ yọrí-tayọ mo jẹ́ ọ̀kan: ninu òpò ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ, ninu ẹ̀wọ̀n ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ, ninu lílù dé ìwọ̀n tí ó pọ̀ lápọ̀jù, ninu bèbè-ikú ní ọ̀pọ̀ ìgbà. Ìgbà márùn-ún ni mo gba ẹgba ogójì dín ọ̀kan lati ọwọ́ awọn Júù, ìgbà mẹ́ta ni a fi ọ̀pá nà mí, lẹ́ẹ̀kan a sọ mí lókùúta, ìgbà mẹ́ta ni mo ní ìrírí ọkọ̀ rírì, òru kan ati ọ̀sán kan ni mo ti lò ninu ibú; ninu awọn ìrìn-àjò ní ọ̀pọ̀ ìgbà, ninu awọn ewu odò, ninu awọn ewu dánàdánà, ninu awọn ewu lati ọwọ́ ẹ̀yà-ìran tèmi fúnra mi, ninu awọn ewu lati ọwọ́ awọn orílẹ̀-èdè, ninu awọn ewu ninu ìlú-ńlá, ninu awọn ewu ninu aginjù, ninu awọn ewu lójú òkun, ninu awọn ewu láàárín awọn èké arákùnrin, ninu òpò ati làálàá, ninu awọn òru àìlèsùn ní ọ̀pọ̀ ìgbà, ninu ebi ati òùngbẹ, ninu ìtakété sí oúnjẹ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, ninu òtútù ati ìhòòhò.

4 “Yàtọ̀ sí awọn ohun wọnnì tí ó jẹ́ ti òde, awọn nǹkan tí ń rọ́ wọlé tọ̀ mí lati ọjọ́ dé ọjọ́ wà níbẹ̀, àníyàn fún gbogbo awọn ìjọ. Ta ní jẹ́ aláìlera, tí emi kò sì jẹ́ aláìlera? Ta ní a mú kọsẹ̀, tí ara mi kò sì gbiná?” (2 Korinti 11:23-29, NW) Nípa báyìí, Paulu pa ìwàtítọ́ mọ́ nígbà tí ó ń dojúkọ àwọn inúnibíni àti àdánwò láti òde wá, àti gẹ́gẹ́ bí Kristian alàgbà kan, ó ní àníyàn jíjinlẹ̀ fún fífún àwọn arákùnrin àti arábìnrin aláìlera nínú ìjọ lókun, ní ríràn wọ́n lọ́wọ́ láti pa ìwàtítọ́ mọ́. Ẹ wo àpẹẹrẹ rere tí ìyẹn jẹ́ fún àwọn Kristian alàgbà lónìí!

Ìwàtítọ́ Lábẹ́ Inúnibíni

5. Kí ni ìdáhùn náà sí inúnibíni ní tààràtà?

5 Àwọn ète búburú wo ni Satani ń lò láti ba ìwàtítọ́ jẹ́? Gẹ́gẹ́ bí a ti fihàn lókè, ọ̀kan lára àwọn ọgbọ́n ìwéwèé tí ó jẹ́ abèṣe jùlọ tí Satani ń lò ni inúnibíni ní tààràtà, ṣùgbọ́n ojútùú wà. Efesu 6:10, 11 (NW) gbà wá nímọ̀ràn pé: “Ẹ máa bá a lọ ní gbígba agbára ninu Oluwa ati ninu agbára ńlá okun rẹ̀. Ẹ gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun wọ̀ kí ẹ̀yin baà lè dúró gbọn-in-gbọn-in lòdì sí awọn ètekéte [tàbí, “ìwà àrékérekè,” àkíyèsí-ẹsẹ̀-ìwé] Èṣù.”

6. Báwo ni a ṣe lè fihàn pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti di “ajagunmólú pátápátá”?

6 Lọ́pọ̀ ìgbà ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti níláti wọ̀jà pẹ̀lú àwọn àdánwò. Nípa báyìí, a lè sọ pẹ̀lú Paulu pé: “Ninu gbogbo awọn nǹkan wọnyi awa ń di ajagunmólú pátápátá nípasẹ̀ ẹni naa tí ó nífẹ̀ẹ́ wa.” (Romu 8:37, NW) Ẹ̀rí èyí ni a fihàn nípasẹ̀ àkọsílẹ̀ ìwàtítọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nínú àwọn ibùdó ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ní Germany, Austria, Poland, àti Yugoslavia ní àkókò sànmánì àkóso Nazi láàárín ọdún 1933 àti 1945, lábẹ́ ìninilára ìjọba Kọministi ní Ìlà-Oòrùn Europe láàárín ọdún 1945 àti 1989, àti nígbà àwọn inúnibíni tí ó ti gbo àwọn apa ibìkan ní Africa àti Latin America jìgìjìgì ní àwọn àkókò lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí.

7. Àwọn àpẹẹrẹ ìwàtítọ́ tí ń ru ìmọ̀lára sókè wo ni a ròyìn rẹ̀ láti Etiopia?

7 Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Etiopia fúnni ní àpẹẹrẹ tí ń runisókè níti ìwàtítọ́ láàárín ọdún 1974 àti 1991. Ọ̀kan lára àwọn afinisẹ́wọ̀n tí òṣèlú jẹ lọ́kàn sọ fún arákùnrin kan tí a fi sẹ́wọ̀n pé: “Ó sàn kí a tú àwọn kìnnìún sílẹ̀ kúrò nínú ọgbà ẹranko ju kí a tún dá ẹ̀yin ènìyàn wọ̀nyí sílẹ̀ lọ!” Àwọn ìkà tí ń ṣe inúnibíni wọ̀nyí dá àwọn ìránṣẹ́ Jehofa lóró, lẹ́yìn tí ọdún díẹ̀ sì ti kọjá ilé-ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn kan pàṣẹ pé kí a pa wọ́n. Ara arákùnrin kan ni a gbé sí gbangba ní ojútáyé gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ìkìlọ̀. Àwọn arákùnrin mìíràn tí wọ́n pẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn nípa ìdájọ́ ìjìyà ikú náà ni ilé-ẹjọ́ kan tí ó túbọ̀ rọjú dá sílẹ̀, díẹ̀ lára àwọn olùṣòtítọ́ ‘aṣẹ́gun’ wọ̀nyí sì kópa nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ níbi Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ẹ̀kọ́ Àtọ̀runwá” ní Addis Ababa ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1994.a—Johannu 16:33; fiwé 1 Korinti 4:9.

8. Báwo ni Satani ti ṣe gbìyànjú láti lo “fífa àwùjọ ẹ̀yà tu tigbòǹgbò-tigbòǹgbò” fún èrè ti ara rẹ̀?

8 Satani ti kùnà láti ba ìwàtítọ́ irú àwọn arákùnrin àti arábìnrin adúróṣinṣin bẹ́ẹ̀ jẹ́ nípasẹ̀ ìgbéjàkò tààràtà lójúkorojú. Nítorí náà, àwọn ọgbọ́n àrékérekè mìíràn wo ni òun ń lò? Ìṣípayá 12:12 (NW) sọ nípa àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí pé: “Ègbé ni fún ilẹ̀-ayé ati fún òkun, nitori Èṣù ti sọ̀kalẹ̀ wá bá yín, ó ní ìbínú ńlá, ní mímọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni oun ní.” Níwọ̀n bí ó ti kùnà láti tipasẹ̀ inúnibíni pa àwọn ènìyàn Ọlọrun tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin run, nínú ìbínú rẹ̀ ó ń gbìyànjú láti pa gbogbo ènìyàn pátá run, kò sì sí iyèméjì pé èyí jẹ́ pẹ̀lú èrò náà láti pa àwọn ènìyàn Jehofa run papọ̀ pẹ̀lú àwọn yòókù. Nípa báyìí ohun tí a ń pè ní fífa àwùjọ ẹ̀yà tu tigbòǹgbò-tigbòǹgbò ti wáyé ní àwọn apá ibìkan ní Yugoslavia àtijọ́, a sì ti gbìdánwò ìparun ẹ̀yà ní Liberia, Burundi, àti Rwanda.

9. Èéṣe tí àwọn ọgbọ́n ìgbógun Satani fi sábà máa ń kùnà? Fúnni ní àwọn àpẹẹrẹ.

9 Ṣùgbọ́n, lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ọgbọ́n ìgbógun Satani ń jásí òdìkejì ohun tí ó pète, nítorí pé ìpọ́nnilójú Satani ń ta àwọn ènìyàn aláìlábòsí jí ní mímú kí wọ́n mọ̀ pé ìrètí kanṣoṣo tí wọ́n ní sinmi lórí Ìjọba Ọlọrun, tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń fi tìtara-tìtara pòkìkí rẹ̀. (Matteu 12:21) Nítòótọ́, àwọn olùfìfẹ́hàn ń rọ́ wá sínú Ìjọba náà! Fún àpẹẹrẹ, ní Bosnia àti Herzegovina tí ìjà ti fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, àwọn tí wọ́n pésẹ̀ síbi ayẹyẹ Ìṣe-Ìrántí ikú Jesu tí ó wáyé ní March 26, 1994, jẹ́ 1,307, wọ́n fi 291 pọ̀ ju ti èṣí lọ. A ròyìn góńgó iye àwọn tí ó pésẹ̀ ní Sarajevo (414), Zenica (223), Tuzla (339), Banja Luka (255), àti àwọn ìlú mìíràn. Ní orílẹ̀-èdè Croatia tí ó múlégbè é wọ́n ní góńgó titun ti 8,326 nínú iye àwọn akéde. Ìwà ipá tí ń ṣẹlẹ̀ láyìíká kò dí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tí ń bẹ ní àwọn ilẹ̀ wọnnì lọ́wọ́ láti ṣègbọràn sí àṣẹ náà láti ‘máa pòkìkí ikú Oluwa, títí tí yoo fi dé.’—1 Korinti 11:26, NW.

Ní Rwanda Tí Ìjà ti Fàya Pẹ́rẹpẹ̀rẹ

10, 11. (a) Kí ni ó ti wáyé ní ilẹ̀ Rwanda tí a fẹnu lásán pè ní ti Kristian? (b) Kí ni àwọn míṣọ́nnárì olùṣòtítọ́ sọ nípa ara wọn?

10 Ní 1993, Rwanda, tí ó ní 2,080 àwọn akéde Ìjọba, ni àwọn 4,075 pésẹ̀ sí ibi Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ẹ̀kọ́ Àtọ̀runwá” wọn, tí 230 sì ṣe ìrìbọmi. Lára àwọn wọ̀nyí, lójú-ẹsẹ̀ ni àwọn 142 béèrè fún iṣẹ́-ìsìn aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé tí a ń darí ti ga dé 7,655 ní 1994—dájúdájú èyí ti pọ̀ ju ohun tí Satani lè nífẹ̀ẹ́ sí lọ! Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé iye tí ó pọ̀ jùlọ lára àwọn ènìyàn náà ń jẹ́wọ́ jíjẹ́ Kristian, wọ́n pilẹ̀ ìpakúpa láàárín àwọn ẹ̀yà. Ìwé ìròyìn L’Osservatore Romano ti Vatican gbà pé: “Èyí jẹ́ ìparun yán-án-yán-án, tí ó ṣeniláàánú pé àwọn Katoliki ló fà á.” Iye àwọn ọkùnrin, obìnrin, àti ọmọdé tí a díwọ̀n sí ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ni wọ́n kú, nǹkan bí million méjì ni a sì sọ di aláìnílé tàbí ni ó di dandan fún láti sálọ. Ní dídi àìdásí tọ̀tún-tòsì Kristian wọn tí kò mú ìwà-ipá dání mú, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa gbìyànjú láti wà papọ̀. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa ni a pa. Ṣùgbọ́n nínú ìjọ kan tí ó ní akéde Ìjọba 65, níbi tí a ti pa ẹni 13, iye àwọn tí ń wá sí ìpàdé lọ sókè dé 170 ní August 1993. Àwọn ìpèsè ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí ní àwọn ilẹ̀ mìíràn wà lára àwọn tí ó kọ́kọ́ dé. A ń gbàdúrà fún àwọn tí wọ́n là á já.—Romu 12:12; 2 Tessalonika 3:1, 2; Heberu 10:23-25.

11 Nínú gbogbo ipò ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ náà, àwọn míṣọ́nnárì mẹ́ta tí wọ́n wà ní Rwanda sá àsálà. Wọ́n kọ̀wé pé: “A mọ̀ pé àwọn arákùnrin wa kárí-ayé ti níláti dojúkọ àwọn ipò bí irú èyí tàbí tí ó tilẹ̀ burú ju èyí lọ, a sì mọ̀ pé gbogbo rẹ̀ jẹ́ apákan àmì àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò-ìgbékalẹ̀ búburú yìí. Síbẹ̀, nígbà tí ó bá kan olúwarẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan, ó ń múni mọ bí àwọn nǹkan ṣe rí níti gidi ó sì ń múni mọrírì bí ìwàláàyè ti ṣeyebíye tó. Àwọn ẹsẹ̀ ìwé mímọ́ kan ti ní ìjẹ́pàtàkì titun fún wa, a sì ń wọ̀nà fún àkókò náà nígbà tí àwọn nǹkan àtijọ́ kì yóò wá sí àyà mọ́. Ṣùgbọ́n ní báyìí ná a fẹ́ láti mú kí ọwọ́ wa dí nínú iṣẹ́-ìsìn Jehofa.”

Àwọn Ọ̀dọ́ Olùpa Ìwàtítọ́ Mọ́

12, 13. (a) Ipa-ọ̀nà ìpàwàtítọ́mọ́ wo ni ọ̀dọ́mọdé kan tọ̀? (b) Níbo ni àwọn ọ̀dọ́ wa ti lè rí ìṣírí lónìí?

12 Jesu fihàn pé àwọn wọnnì tí àwọn mẹ́ḿbà ìdílé bá ṣátì nítorí òtítọ́ ní a óò san èrè fún ní “ìlọ́po ọgọ́rùn-ún.” (Marku 10:29, 30, NW) Èyí jẹ́ òtítọ́ nípa Entellia, ọmọdébìnrin ẹni ọdún mẹ́wàá kan ní ìhà àríwá Africa, ẹni tí ó fẹ́ràn orúkọ Ọlọrun—Jehofa—ní gbàrà tí ó gbọ́ ọ. Ó kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ó sì ń rin ìrìn 90 ìṣẹ́jú ní àlọ àti ní àbọ̀ lọ sí àwọn ìpàdé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìdílé rẹ̀ tí ń ṣàtakò máa ń sábà tì í mọ́ ìta nígbà tí ó bá padà dé. Nígbà tí ó di ọmọ ọdún 13, ó bẹ̀rẹ̀ síí wàásù láti ilé dé ilé, àtakò ìdílé náà sì gbóná janjan síi. Ní ọjọ́ kan àwọn ìbátan rẹ̀ dì í tọwọ́-tẹsẹ̀ wọ́n sì dá a dùbúlẹ̀ fún wákàtí méje nínú oòrùn tí ń mu ganrín-ganrín, wọ́n sì ń da omi dídọ̀tí lé e lórí lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Wọ́n lù ú bí ẹní má-a-kú, wọ́n sì ba ọkàn nínú ojú rẹ̀ jẹ́, àti níkẹyìn wọ́n lé e jáde kúrò nínú ilé rẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, ó rí iṣẹ́ ní ilé-ìwòsàn kan, ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀ ó tóótun gẹ́gẹ́ bí nọ́ọ̀sì. Ní ẹni 20 ọdún ó ṣe ìrìbọmi ó sì tẹ́wọ́gba iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Ìwàtítọ́ rẹ̀ wú ìdílé rẹ̀ lórí, wọ́n sì tẹ́wọ́gbà á padà sínú ilé wọn, mẹ́sàn-án nínú wọn sì ti tẹ́wọ́gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé.

13 Entellia jèrè ìṣírí púpọ̀ láti inú Orin Dafidi 116, ní pàtàkì ẹsẹ̀ 1 sí 4, èyí tí òun ti kà ní àkàtúnkà: “Èmi fẹ́ Oluwa nítorí tí ó gbọ́ ohùn mi àti ẹ̀bẹ̀ mi. Nítorí tí ó dẹ etí rẹ̀ sí mi, nítorí náà ni èmi ó máa képè é níwọ̀n ọjọ́ mi. Ìkáàánú ikú yí mi ká, àti ìrora isà-òkú dì mí mú; mo rí ìyọ́nú àti ìkáàánú. Nígbà náà ni mó képe orúkọ Oluwa; Oluwa, èmi bẹ̀ ọ́, gba ọkàn mi.” Jehofa ń dáhùn irú àdúrà bẹ́ẹ̀!

14. Báwo ni àwọn Ẹlẹ́rìí ní Poland ṣe fi ìwàtítọ́ àrà-ọ̀tọ̀ hàn?

14 Gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ní ọjọ́ Jesu, Satani ti sábà máa ń lo ìgbónára ẹhànnà ti ìsìn láti fẹ́ná inúnibíni jò—ṣùgbọ́n láìsí àṣeyọrí. Àpẹẹrẹ ti àwọn ará wa ní Poland, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàpèjúwe rẹ̀ nínú 1994 Yearbook of Jehovah’s Witnesses jẹ́ àrà-ọ̀tọ̀. Kódà àwọn ọ̀dọ́ ni a retí pé kí wọ́n fi araawọn hàn gẹ́gẹ́ bí olùpa ìwàtítọ́ mọ́. Ní 1946 irú ọ̀dọ́ bẹ́ẹ̀ ni ọmọdébìnrin ẹni ọdún 15 tí a sọ fún pé: “Ìwọ ṣáà wulẹ̀ fi ọwọ́ ṣe àmì àgbélébùú Katoliki. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ ọta ìbọn ń dúró dè ọ́!” Bí ó ti pa ìwàtítọ́ rẹ̀ mọ́, wọ́n wọ́ ọ lọ sínú igbó, wọ́n dá a lóró lọ́nà bíbanilẹ́rù, wọ́n sì yìnbọn pa á.—Fiwé Matteu 4:9, 10.

Àwọn Ọgbọ́n Àrékérekè Mìíràn Tí Satani Ń Lò

15, 16. (a) Kí ni ìlànà-ètò abèṣù tí Satani ń lò, báwo sì ni a ṣe lè gbéjàkò ó? (b) Èéṣe tí kò fi sí ìdí fún àwọn ọ̀dọ́ wa láti kọsẹ̀?

15 Ìlànà-ètò abèṣù tí Satani ń lò níti tòótọ́ ni “ṣàkóso tàbí parun-bàjẹ́”! Ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun-ìjà tí ń jẹniníyà ní ìkáwọ́ rẹ̀. Abájọ, nígbà náà, tí aposteli Paulu fi kìlọ̀ pé: “Awa ní gídígbò kan, kì í ṣe lòdì sí ẹ̀jẹ̀ ati ẹran-ara, bíkòṣe lòdì sí awọn alákòóso, lòdì sí awọn aláṣẹ, lòdì sí awọn olùṣàkóso ayé òkùnkùn yii, lòdì sí awọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú ní awọn ibi ọ̀run. Nítìtorí èyí ẹ gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun, kí ẹ baà lè dúró tiiri ní ọjọ́ burúkú naa, lẹ́yìn tí ẹ bá ti ṣe ohun gbogbo kínníkínní, kí ẹ sì lè dúró gbọn-in-gbọn-in.” (Efesu 6:12, 13, NW) Àwọn ìfẹ́-ọkàn fún ọrọ̀ àlùmọ́nì, eré ìnàjú àti ìgbékèéyíde tí ń rẹninípòwálẹ̀, àwọn orin Satani, ìkìmọ́lẹ̀ ojúgbà ní ilé-ẹ̀kọ́, ìlòkulò oògùn, àti ìmùtípara—èyíkéyìí nínú ìwọ̀nyí lè ba ìgbésí-ayé wa jẹ́. Nípa báyìí, aposteli náà ń gbaninímọ̀ràn nìṣó pé: “Lékè ohun gbogbo, ẹ gbé apata ńlá ti ìgbàgbọ́, èyí tí ẹ óò lè fi paná gbogbo awọn ohun-ọṣẹ́ oníná ti ẹni burúkú naa.”—Efesu 6:16, NW.

16 Ní pàtàkì ni èyí dàbí ohun tí ó pọndandan lónìí nítorí ti àwọn orin jágbajàgba tí Satani fi ń rin ayé yìí gbingbin. Nínú àwọn ọ̀ràn kan ìsokọ́ra tààràtà pẹ̀lú ìjọsìn Satani wà níbẹ̀. Ìròyìn kan láti ọ́fíìsì ìjòyè-òṣìṣẹ́ ìdájọ́ ti Ìjọba Ìbílẹ̀ San Diego (U.S.A.) kà pé: “Ijó jíjó kan ṣẹlẹ̀ ní apá ibi yìí níbi tí àwọn ẹgbẹ́ eléré náà ti ní 15,000 àwọn ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ tí wọ́n ń fi ‘Inatas’ kọrin—ìyẹn ni pé, Satani bí a bá sípẹ́lì rẹ̀ látẹ̀yìnwá.” Ìjọsìn Satani ni a ti ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ihò kan tí ń mú àwọn ọ̀dọ́langba kọsẹ̀ “nítorí pé wọ́n ń fi ìgbékútà rìn gbéregbère, inú ń bí wọn, wọ́n sì dá wà.” Ẹ̀yin èwe nínú ìjọ Kristian, kò sí ìdí tí ẹ fi níláti kọsẹ̀! Jehofa ń pèsè ìhámọ́ra tẹ̀mí fún yín èyí tí àwọn aṣóró Satani kò lè dálu láé.—Orin Dafidi 16:8, 9.

17. Báwo ni a ṣe lè borí ìkìmọ́lẹ̀ níti èrò ìmọ̀lára?

17 Àwọn ohun-ọṣẹ́ oníná Satani ni a ṣe láti dọ́gbọ́n darí èrò ìmọ̀lára. Nípasẹ̀ àwọn ìkìmọ́lẹ̀ ìgbésí-ayé, bí àìsàn ti ara tàbí ipò ìsoríkọ́ jíjinlẹ̀, elénìní wa lè mú kí àwọn kan nímọ̀lára àìjámọ́ nǹkankan. A lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ẹnì kan nítorí pé kò ṣeé ṣe fún un láti lo ọ̀pọ̀ wákàtí nínú iṣẹ́-ìsìn Ọlọrun tàbí nítorí pé ó ń pa díẹ̀ lára àwọn ìpàdé ìjọ jẹ. Àbójútó onífẹ̀ẹ́ nípasẹ̀ àwọn alàgbà àti àwọn arákùnrin àti arábìnrin ọlọ́kàn rere mìíràn lè ṣèrànlọ́wọ́ láti borí àwọn ìkìmọ́lẹ̀ lílekoko. Ẹ máa rántí nígbà gbogbo pé Jehofa nífẹ̀ẹ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olùṣòtítọ́. (1 Johannu 4:16, 19) Orin Dafidi 55:22 sọ pé: “Kó ẹrù rẹ lọ sí ara Oluwa, òun ni yóò sì mú ọ dúró: òun kì yóò jẹ́ kí ẹsẹ̀ olódodo kí ó yẹ̀ láé.”

18. Àwọn ètekéte Satani wo ni àwọn kan níláti bá wọ ìjàkadì, kí sì ni irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ níláti rántí?

18 Lẹ́nu lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí àwọn “ètekéte” Satani ti farahàn ní irú ọ̀nà mìíràn kan. Ní àwọn ilẹ̀ kan ọ̀pọ̀ àwọn àgbàlagbà ti ní ìrírí èrò gbígbanilọ́kàn tí ń mú kí a bò wọ́n mọ́lẹ̀ ṣíbáṣíbá pẹ̀lú ìmọ̀lára náà pé nígbà tí àwọn wà ní ọmọdé àwọn ẹgbẹ́ awo Satani kan ti fi ìwà ìkà fi ìyà jẹ wọ́n. Níbo ni irú àwọn èrò bẹ́ẹ̀ ti ń wá? Láìka àwọn ìwádìí jinlẹ̀ gbígbòòrò sí, èrò àwọn ògbóǹkángi nínú ayé yàtọ̀síra lọ́pọ̀lọpọ̀. Àwọn kan ronú pé irú àwọn èrò bẹ́ẹ̀ jẹ́ ìrántí ohun tí ó jẹ́ gidi, àwọn mìíràn kà á sí ìrònú asán—bóyá èyí tí àwọn ọ̀nà-ìgbàtọ́jú tí a lè ṣiyèméjì sí jẹ́ okùnfà fún—àwọn mìíràn pẹ̀lú sì kà á sí irú ìran ìtànjẹ kan tí àwọn ìkìmọ́lẹ̀ díẹ̀ nígbà ọmọdé jẹ́ okùnfà fún.

19. (a) Èrò wo ni Jobu níláti bá wọ̀jà? (b) Báwo ni àwọn alàgbà ṣe lè tẹ̀lé àpẹẹrẹ Elihu?

19 Ó runi lọ́kàn sókè pé Jobu ìránṣẹ́ Ọlọrun níláti wọ̀jà pẹ̀lú “àwọn èrò tí ń gbéni lọ́kàn sókè” tí Satani mú kí Elifasi àti Sofari sọ. (Jobu 4:13-18, NW; 20:2, 3) Jobu tipa báyìí jìyà “ìbìnújẹ́,” èyí tí ó jálẹ̀ sí jíjọ̀wọ́ araarẹ̀ fún ‘ọ̀rọ̀ tí ń tàsé’ nípa “ìpayà ẹ̀rù” tí ń da ọkàn rẹ̀ láàmú. (Jobu 6:2-4; 30:15, 16) Elihu tẹ́tísílẹ̀ jẹ́jẹ́ sí Jobu ó sì fi òtítọ́-inú ràn án lọ́wọ́ láti rí ojú-ìwòye ọlọ́gbọ́n gbogbo tí Jehofa ní nípa àwọn ọ̀ràn. Bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni ó rí lónìí, àwọn alàgbà tí wọ́n mòye ń fihàn pé àwọn bìkítà fún àwọn tí a ń pọ́n lójú nípa ṣíṣàì fikún “ìkìmọ́lẹ̀” irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, bíi ti Elihu, wọ́n ń fi sùúrù tẹ́tísílẹ̀ sí wọn lẹ́yìn náà ni wọ́n sì ń fi òróró Ọ̀rọ̀ Ọlọrun tí ń máratuni pa wọ́n lára. (Jobu 33:1-3, 7, NW; Jakọbu 5:13-15) Fún ìdí èyí ẹnikẹ́ni tí ìkìmọ́lẹ̀ ìdààmú bá da àwọn èrò ìmọ̀lára rẹ̀ láàmú, níti gidi tàbí nípa ìrònú asán, tàbí ‘tí àlá dáníjì tí ìran òru sì dẹ́rùbà’ gẹ́gẹ́ bíi ti Jobu, lè rí ìtùnú Ìwé Mímọ́ tí ń máratuni gbà láàárín ìjọ.—Jobu 7:14; Jakọbu 4:7.

20. Báwo ni a ṣe lè ran àwọn Kristian tí wọ́n ní ìdààmú lọ́wọ́ láti pa ìdúró déédéé wọn nípa tẹ̀mí mọ́?

20 Ní báyìí ó lè dá Kristian kan lójú pé, ní ọ̀nà kan tàbí òmíràn, Satani wà lẹ́yìn àwọn èrò tí ó burú jáì wọ̀nyí. Bí àwọn kan nínú ìjọ bá ń jìyà lọ́nà yìí, ó bọ́gbọ́nmu fún wọn láti rí irú ìmọ̀lára èrò-orí tí ń kó jìnnì-jìnnì báni bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbìdánwò tààràtà láti ọ̀dọ̀ Satani láti kó ṣìbáṣìbo bá ìdúró déédéé wọn nípa tẹ̀mí. Wọ́n nílò ìtìlẹ́yìn Ìwé Mímọ́ tí ń fi sùúrù àti ìmòye hàn. Nípa fífi tàdúrà-tàdúrà yíjú sí Jehofa àti nípa jíjèrè láti inú ṣíṣe olùṣọ́ àgùtàn nípa tẹ̀mí, àwọn wọnnì tí ìkìmọ́lẹ̀ ń bá jà yóò lo àǹfààní agbára tí ó rékọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá fún araawọn. (Isaiah 32:2; 2 Korinti 4:7, 8) Nípa báyìí yóò lè ṣeé ṣe fún wọn láti fi ìṣòtítọ́ lo ìfaradà kí wọ́n sì kọ̀ láti yọ̀ǹda fún àwọn èrò ibi tí ń kó wọni lọ́kàn láti nípa lórí àlàáfíà ìjọ. (Jakọbu 3:17, 18) Bẹ́ẹ̀ni, yóò ṣeé ṣe fún wọn láti dojú ìjà kọ Eṣu, ní fífi irú ẹ̀mí kan náà bíi ti Jesu hàn nígbà tí ó sọ pé: “Kúrò lọ́dọ̀ mi, Satani!”—Matteu 4:10, NW; Jakọbu 4:7.

21. Báwo ni Ìwé Mímọ́ ṣe kìlọ̀ fúnni nípa àwọn ọ̀nà àlùmọ̀kọ́rọ́yí Satani?

21 A mọ̀ pé góńgó Satani ni láti wá ọ̀nà kan gbà láti sọ ọkàn wa dìbàjẹ́, gẹ́gẹ́ bí aposteli Paulu ti kìlọ̀ ní 2 Korinti 11:3 (NW) pé: “Mo ń fòyà pé lọ́nà kan ṣáá, bí ejò naa ti sún Efa dẹ́ṣẹ̀ nípasẹ̀ àlùmọ̀kọ́rọ́yí rẹ̀, a lè sọ èrò inú yín di ìbàjẹ́ kúrò ninu òtítọ́-inú ati ìwàmímọ́ tí ó tọ́ sí Kristi.” Ìrunbàjẹ́ gbogbo ẹran ara, tàbí ẹgbẹ́ àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn tí a sọ dàjèjì sí Ọlọrun, rán wa létí bí àwọn àdàmọ̀dì oníwà-ipá tí a ti sọdìbàjẹ́ “Àwọn Abiniṣubú” ti ọjọ́ Noa ṣe mú ìlọsílẹ̀ débá ìwàrere. (Genesisi 6:4, 12, 13, àkíyèsí-ẹsẹ̀-ìwé; Luku 17:26) Nítorí náà, kò yanilẹ́nu pé Satani ń fàbọ̀ sórí ìwà àrékérekè àti ọ̀nà àlùmọ̀kọ́rọ́yí láti tú ìbínú rẹ̀ jáde, ní pàtàkì jùlọ sórí àwọn ènìyàn Ọlọrun.—1 Peteru 5:8; Ìṣípayá 12:17.

22. Nígbà tí Satani kò bá ṣe ìdíwọ́ mọ́, àwọn ìbùkún wo ni a lè retí?

22 A kò tilẹ̀ mẹ́nukan Satani nínú àwọn orí tí ó gbẹ̀yìn ìwé Jobu nínú Bibeli. Ìpèníjà búburú rẹ̀ pé àwọn ènìyàn kò lè pa ìwàtítọ́ mọ́ sí Ọlọrun ni a ti fi ẹ̀rí rẹ̀ hàn pé ó jẹ́ èké nípasẹ̀ ìwàtítọ́ Jobu. Bákan náà, ní ọjọ́-ọ̀la tí kò jìnnà mọ́ nígbà tí “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ti àwọn olùpa ìwàtítọ́ mọ́ bá “jáde wá lati inú ìpọ́njú ńlá,” gbígbé Satani jù sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ yóò wáyé. Àwọn ọkùnrin àti obìnrin ìgbàgbọ́, títíkan Jobu olùṣòtítọ́, yóò darapọ̀ mọ́ “ogunlọ́gọ̀ ńlá” yẹn, láti gbádùn àwọn ìbùkún paradise, àní èyí tí ó tilẹ̀ tóbilọ́lá ju ìwọ̀nyí tí a fi san èrè fún Jobu lọ!—Ìṣípayá 7:9-17, NW; 20:1-3, 11-13; Jobu 14:13.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo ìwé 1992 Yearbook of Jehovah’s Witnesses, ojú-ìwé 177.

Àwọn Ìbéèrè fún Àtúnyẹ̀wò

◻ Àwọn àpẹẹrẹ rere wo ni Jobu, Jesu àti Paulu fi lélẹ̀ níti ìwàtítọ́?

◻ Ọ̀nà wo ni àwọn olùpa ìwàtítọ́ mọ́ ti gbà dojúkọ Satani?

◻ Báwo ni àwọn ọ̀dọ́ ṣe lè dènà àwọn ọgbọ́n àrékérekè Satani?

◻ Kí ni a lè ṣe láti kojú àwọn ètekéte Satani?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ní Etiopia, Meswat àti Yoalan ń fi àkókò kíkún ṣiṣẹ́sin Jehofa ní títẹ̀lé àpẹẹrẹ bàbá wọn, tí a ṣekúpa

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Entellia, ọ̀dọ́ olùpa ìwàtítọ́ mọ́ ní ìhà àríwá Africa

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́