ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 2/15 ojú ìwé 23-26
  • Dominican Republic Ṣì Ṣísílẹ̀ fún Ìṣàwárí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Dominican Republic Ṣì Ṣísílẹ̀ fún Ìṣàwárí
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ìsọ̀rí
  • Irú Ìṣàwárí Mìíràn Kan
  • Ìbùkún fún Nínawọ́ Ìrànlọ́wọ́ Jáde
  • Ìdáhùnpadà Rere Láti Ọ̀dọ̀ Àwọn Ọ̀dọ́
  • “Àwọn Olùṣèwákiri” Láti Ilẹ̀ Mìíràn
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 2/15 ojú ìwé 23-26

Dominican Republic Ṣì Ṣísílẹ̀ fún Ìṣàwárí

GẸ́GẸ́ bí ọ̀dọ́mọkùnrin kan, Christopher Columbus dágbálé ìgbésí-ayé orí òkun èyí tí ó sún un ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀ láti ṣàwárí erékùṣù tí a wá mọ̀ sí West Indies lónìí. Ní December 1492, ọkọ̀ òkun ńlá rẹ̀, Santa María, gúnlẹ̀ sí ọ̀kánkán àríwá bèbè-etíkun erékùṣù Española, tí a wá mọ̀ sí erékùṣù Hispaniola lónìí, nínú rẹ̀ ni Haiti àti Dominican Republic jọ múlé sí. Níbẹ̀ ni Columbus fìdí ibi ìtẹ̀dó àwọn ará Europe àkọ́kọ́, tí ó jẹ́ odi-ìgbèjà kan tí a fi ìkánjú kọ́, sọlẹ̀ sí, ó sì pè é ní La Navidad. Erékùṣù yìí di ibùdó ìwádìíkiri rẹ̀ síwájú síi.

Columbus ṣàwárí pé àwọn ènìyàn tí wọ́n dára bí egbin, tí wọ́n ṣeé gbáralé, tí wọ́n sì jẹ́ olùfẹ́ àlejò, tí a mọ̀ sí àwọn ará Taino India, ni ń gbé erékùṣù náà. A díwọ̀n iye àwọn tí ń bẹ nígbà náà sí 100,000. Bí ó ti wù kí ó rí, nítorí ìbálò lílekoko láti ọwọ́ àwọn tí wọ́n wọlé gbógun tì wọ́n, àwọn ẹni tí olórí ète wọn jẹ́ láti wá wúrà, iye àwọn ọmọ-ìbílẹ̀ tí ń gbé níbẹ̀ joro lọ́nà tí ó yára kánkán. Nígbà tí ó fi máa di ọdún 1570 a ròyìn pé kìkì ìwọ̀nba 500 àwọn ará Taino India ni wọ́n ṣẹ́kù.

Lónìí, ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn tí ẹ̀yà-ìran àti àwọ̀ wọn yàtọ̀síra, tí àwọn babańlá wọn ṣí wá síbẹ̀, ni wọ́n ń gbé ní Dominican Republic. Síbẹ̀ náà, ó dàbí ẹni pé wọ́n ní ọ̀pọ̀ lára ìwà àtàtà tí àwọn Taino ní, níti gidi ìyẹn ni ti jíjẹ́ ẹni-pẹ̀lẹ́ àti oníwà-bí-ọ̀rẹ́. Èyí, papọ̀ pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àtọkànwá nínú Ọlọrun àti ọ̀wọ̀ fún Bibeli, ti mú kí iṣẹ́ ìwàásù àti ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa yọrísírere lọ́nà pípẹtẹrí ní ilẹ̀ yìí.

Irú Ìṣàwárí Mìíràn Kan

Àwọn míṣọ́nnárì Watch Tower àkọ́kọ́, Lennart àti Virginia Johnson, dé sí Dominican Republic lákòókò sànmánì Trujillo aláṣẹ bóofẹ́-bóokọ̀. Sí ìdùnnú wọn, wọ́n ṣàwárí pé ọ̀pọ̀ yára dáhùnpadà lọ́nà rere sí ìhìn-iṣẹ́ Bibeli wọn. Bí ó ti wù kí ó rí, èyí kò dùn mọ́ àwọn aláṣẹ àti àwọn onísìn tí ń gbà wọ́n nímọ̀ràn nínú. Kò pẹ́ púpọ̀ tí inúnibíni kíkan kíkan fi bẹ́ sílẹ̀, a sì mú ìgbàgbọ́ àwọn wọnnì tí wọ́n kọ́kọ́ di Ẹlẹ́rìí ní ilẹ̀ Dominican yẹn wá sábẹ́ ìdánwò lílekoko. Títí di òní yìí, ìdúróṣinṣin àti ìgbàgbọ́ wọn—títí dójú ikú pàápàá—ni a ṣì ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nígbà gbogbo.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, tí wọ́n ti to 16,000 ní ilẹ̀ náà nísinsìnyí, ni a mọ̀-bí-ẹní-mowó. Ní àkókò díẹ̀ sẹ́yìn, àwọn ibùdó ilé-iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n márùn-ún jákèjádò orílẹ̀-èdè náà gbé fídíò Jehovah’s Witnesses—The Organization Behind the Name sáfẹ́fẹ́.a

Èyí gbé iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí jáde sí gbangba kì í ṣe ní àwọn ìlú títóbi nìkan ni ṣùgbọ́n ní àwọn ìlú kéékèèké àti àwọn àrọ́ko kan pẹ̀lú. Gẹ́gẹ́ bí ìgbésẹ̀ tí ó tẹ̀lé e, wọ́n ṣètò àkànṣe ìgbétásì láti nawọ́ ìrànlọ́wọ́ jáde kí wọ́n sì mú ìhìnrere Ìjọba náà lọ sí àwọn agbègbè jíjìnnà lẹ́yìn-odi wọ̀nyí.

Ìbùkún fún Nínawọ́ Ìrànlọ́wọ́ Jáde

Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí, tí wọ́n jẹ́ abarapá, tí wọ́n sì jẹ́ onítara yọ̀ǹda ara wọn láti lo àkókò tí ó tó oṣù méjì láti wàásù ní àwọn agbègbè ìpínlẹ̀ jíjìnnà wọ̀nyí. Ìsapá wọn ni a san èrè-ẹ̀san fún. Àwọn Ẹlẹ́rìí méjì rí ibi tí a ti fi ọkàn-ìfẹ́ àrà-ọ̀tọ̀ hàn ní agbègbè kan. Níwọ̀n bí àkókò ti tó fún ṣíṣayẹyẹ Ìṣe-Ìrántí ikú Jesu, wọ́n ṣètò wọ́n sì késí àwọn ènìyàn láti wá. Gbọ̀ngàn náà kún dẹ́múdẹ́mú, wọ́n sì ṣe ìpàdé náà. Sí ìyàlẹ́nu wọn, nígbà tí ó parí, wọn rí i pé àwùjọ àwọn ènìyàn púpọ̀ mìíràn ti wà lẹ́yìn òde gbọ̀ngàn náà tí wọ́n ń dúró láti wọlé. Nítorí náà wọ́n késí wọn wọlé wọ́n sì tún ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ṣe lẹ́ẹ̀kan síi. Ìjọ kan ti wà ní agbègbè náà nísinsìnyí.

Ìwà ọ̀làwọ́ àti ìkónimọ́ra àwọn ènìyàn náà sábà máa ń sún wọn láti ṣàjọpín òtítọ́ Bibeli tí wọ́n ń kọ́ pẹ̀lú àwọn mẹ́ḿbà ìdílé wọn àti àwọn ẹlòmíràn. Inú akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli kan ń dùn ṣìnkìn nígbà tí ó tóótun lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn láti kópa nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ ilé-dé-ilé. Ó ti ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli márùn-ún tẹ́lẹ̀ ní agbègbè àdúgbò rẹ̀, ṣùgbọ́n ó láyọ̀ láti ní ìpín tí ó túbọ̀ pọ̀ síi nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ náà.

Bí ọ̀pọ̀ agbègbè ìpínlẹ̀ ti wà tí àwọn akéde Ìjọba kì í bẹ̀wò déédéé, wọ́n sapá láti wàásù fún àwọn ènìyàn tí ń bẹ nínú bọ́ọ̀sì àti àwọn wọnnì tí wọ́n wá sínú ìlú-ńlá láti ṣòwò tàbí láti rajà. Èyí ti yọrísí àwọn àbájáde tí ń múniláyọ̀, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàkàwé rẹ̀ nínú ìrírí tí ó níí ṣe pẹ̀lú lẹ́tà kan tí ọ́fíìsì ẹ̀ka rígbà. Ó wá láti ọ̀dọ̀ àwọn ọkùnrin méjì tí wọ́n béèrè fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, ní agbègbè àrọ́ko kan. Nígbà tí Ẹlẹ́rìí kan bẹ̀ wọ́n wò, ó rí i pé ẹni ọdún 10 àti 11 ni “àwọn ọkùnrin” náà. Ṣùgbọ́n báwo ni wọ́n ṣe kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìṣètò ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli? Ó dára, ọkùnrin kan láti abúlé náà wá sí olú-ìlú náà láti ṣòwò. Ó bá Ẹlẹ́rìí kan pàdé ní òpópónà, ẹni tí ó fún un ní ìwé-àṣàrò kúkúrú tí ó sì fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́ lọ̀ ọ́. Nígbà tí ó padà sí abúlé rẹ̀, ọkùnrin náà fún ọmọdébìnrin ẹni ọdún 12 kan ní àdúgbò ní ìwé-àṣàrò-kúkúrú náà ó sì sọ fún un nípa ìṣètò ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. Ní ìdà kejì ẹ̀wẹ̀, ọmọdébìnrin náà ta àtaré ìsọfúnni náà sí àwọn ọmọdékùnrin méjì tí wọ́n yára kọ lẹ́tà. A bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú àwọn ọmọdékùnrin náà, ọmọdébìnrin náà, ọkùnrin náà, àti àwọn ọmọ rẹ̀ méjì.

Ìdáhùnpadà Rere Láti Ọ̀dọ̀ Àwọn Ọ̀dọ́

Nítòótọ́, àwọn ọ̀dọ́, àwọn tí a tọ́ dàgbà nínú òtítọ́ àti àwọn mìíràn, ni ó dàbí ẹni pé wọ́n fi ọwọ́ tí ó ṣe pàtàkì mú ìjọsìn wọn sí Ọlọrun. Fún àpẹẹrẹ, Tamar àti àbúrò rẹ̀ obìnrin Keila jọ ṣèrìbọmi ní ẹni ọdún 10 wọ́n sì wọnú iṣẹ́-òjíṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà alákòókò kíkún ní ẹni ọdún 11. Wendy Carolina jẹ́ ẹni ọdún 12 nígbà tí ó fi àpẹẹrẹ ìyàsímímọ́ rẹ̀ hàn nípasẹ̀ ìrìbọmi nínú omi, ní ọdún méjì lẹ́yìn náà, ní 1985, ó bẹ̀rẹ̀ síí ṣe aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Lónìí ó jẹ́ olùkọ́ tí ó gbéṣẹ́, tí ó sì ń gbádùn iṣẹ́-òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Jovanny ọ̀dọ́mọdé, tí ó ṣèrìbọmi ní ẹni ọdún 10 tí ó sì jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé ní ẹni ọdún 11, ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé mẹ́rin. Nígbà tí Rey ọmọ ọdún mẹ́wàá rí i pé òǹtàwé àlòkù kan ní ìwé kékeré tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tẹ̀ jáde, Rey bẹ ìyà rẹ̀ láti rà á fún òun. Ó kà á láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé ìparí. Wíwá tí ó ń wá ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli púpọ̀ síi kiri ni ó mú un dé ọ́fíìsì ẹ̀ka nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín. Lónìí ó ń gbádùn iṣẹ́-ìsìn alákòókò kíkún, ìyá rẹ̀ pẹ̀lú sì ń sin Ọlọrun.

Kí ni ó ti ran àwọn wọ̀nyí àti àwọn ọ̀dọ́ mìíràn lọ́wọ́ láti mọrírì ìníyelórí àwọn nǹkan tẹ̀mí? Ní ọ̀pọ̀ ìgbà ọ̀ràn ìtọ́sọ́nà yíyẹ láti ọ̀dọ̀ àwọn òbí kó ipa pàtàkì. Bí ọ̀ràn ti rí nìyí pẹ̀lú Josué tí àwọn òbí rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ Kristian ń ṣiṣẹ́ olùkọ́. Nígbà tí alábòójútó arìnrìn-àjò kan dámọ̀ràn pé kí àwọn òbí gbìyànjú láti ran ó kérétán ọ̀kan lára àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́-òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, wọ́n fún Josué ní àfiyèsí. Níwọ̀n bí Josué ti jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ tí ó tayọ, a fún un ní àǹfààní ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ ti ìjọba láti kọ́ nípa ìmọ̀-iṣẹ́-ẹ̀rọ. Lẹ́yìn ọdún kan àti ààbọ̀ ní yunifásitì, ó tẹ́wọ́gba ìkésíni láti darapọ̀ nínú ìwéwèédáwọ́lé ilé-kíkọ́ níbi ilé-lílò fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Dominican Republic. Àwọn òbí rẹ̀ fi ìtẹ́lọ́rùn jíjinlẹ̀ hàn pé àwọn yọ̀ǹda ọmọkùnrin àwọn fún iṣẹ́-ìsìn Jehofa.

“Àwọn Olùṣèwákiri” Láti Ilẹ̀ Mìíràn

Ọ̀rọ̀ Jesu pé “ìkórè pọ̀, ṣugbọn ìwọ̀nba díẹ̀ ni awọn òṣìṣẹ́” ni a lè sọ nítòótọ́ pé ó bá pápá tí ó wà níhìn-ín mu. (Matteu 9:37) Àìní tí ó pọ̀ àti ìdáhùnpadà tí ó dára ti sún àwọn Ẹlẹ́rìí láti ilẹ̀ mìíràn láti wá nípìn-ín nínú ṣíṣe ìwákiri àwọn ìṣúra òde-òní tòótọ́ ní agbègbè ìpínlẹ̀ náà—àwọn olùfòtítọ́-inú wá òtítọ́ kiri.

Láti erékùṣù Puerto Rico tí ó múlégbè é ni àwọn ìdílé tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí tí wọ́n ń rí ìtẹ́lọ́rùn nínú ṣíṣiṣẹ́sìn ní apá ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní Dominican Republic ti wá. Olórí ìdílé kan sọ pé: “Wíwà ní ipò láti sọ nípa ìgbàgbọ́ àti ìrètí rẹ fún àwọn ènìyàn tí wọ́n múratán láti gbọ́ ń mú kí òtítọ́ wàláàyè níti gidi!” Bí wọ́n ti mọ̀ nípa àìní tí ó wà níhìn-ín, Cecilia láti Sweden àti Nia láti United States wá láti ṣiṣẹ́ papọ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ mélòókan mìíràn tí wọ́n jẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Wọ́n ń ṣiṣẹ́sìn ní eréko níbi tí wọ́n ti rí ilẹ̀ gíga àti ipò ojú-ọjọ́ tí ó tutù gbẹ̀dẹ̀. Bákan náà, lókè lọ́hùn-ún níbi òkè-ńlá títutù nini tí ó kún fún igi pine, àwọn ìdílé ara Canada méjì darapọ̀ pẹ̀lú ìdílé ara Dominican kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ darí dé láti United States. Wọ́n jẹ́ apákan ìjọ kékeré kan ó sì ṣeé ṣe fún wọn láti nawọ́ ìrànlọ́wọ́ sí àwọn ènìyàn tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kò tí ì bẹ̀wò fún nǹkan bí ọdún mẹ́wàá.

Alfredo àti Lourdes àti àwọn ọmọ wọn márùn-ún ti New York City dé wọ́n sì darapọ̀ pẹ̀lú ìjọ kékeré kan tí ó wà ní ọ̀kan lára àwọn ìlú rírẹwà létí òkun tí àwọn arìnrìn-àjò ìgbafẹ́ ń ṣèbẹ̀wò sí. Inú wọn dùn pé ó ṣeé ṣe láti ṣàjọpín nínú wíwá àwọn ọlọ́kàn-àyà títọ́ rí àti ríran ìjọ náà lọ́wọ́ láti dàgbàsókè. Roland, tí ń fi ẹ̀rọ kọ̀m̀pútà ṣiṣẹ́ tí ó wá láti Austria, àti aya rẹ̀, Yuta, ti fìdíkalẹ̀ sí apá ibi lílọ́wọ́ọ́wọ́, gbígbẹ fúrúfúrú, ní ìhà gúúsù orílẹ̀-èdè náà. Wọ́n ti láyọ̀ láti rí ìjọ titun kan tí a dá sílẹ̀ láti ìgbà tí wọ́n ti débẹ̀. Ní ìlú kan tí ó múlégbè é, àwùjọ àwọn arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà mẹ́ta àti tọkọtaya kan láti California ròyìn pé àwọn rí ọ̀pọ̀ ìbéèrè fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli gbà débi pé àwọn kò lè darí gbogbo wọn pátá. Nítorí náà wọ́n fún àwọn olùfìfẹ́hàn náà ní ìṣírí láti máa pésẹ̀ sí àwọn ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba àdúgbò kí a sì to orúkọ wọn sínú ìwé ìdúró-dìgbà-tí-àkókò-bá-yọ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. Stefan àbúrò Yuta ń fi ìṣòtítọ́ ṣiṣẹ́sin pẹ̀lú ìjọ kékeré kan ní ìlú Samaná kékeré tí ó rẹwà, ní apá ìhà àríwá ìlà-oòrùn. Ní ìwọ̀nba ọdún méjì péré, iye àwọn akéde Ìjọba tí ń bẹ níbẹ̀ ti di ìlọ́po méjì.

Ìfẹ́ àti ìtara tí àwọn wọ̀nyí àti àwọn mìíràn tí wọ́n wá láti ṣèrànlọ́wọ́ fihàn yẹ fún ìgbóríyìn níti tòótọ́. Kì í wulẹ̀ ṣe ìpèníjà ti ṣíṣí lọ sí ilẹ̀ titun tí àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àti àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ rẹ̀ yàtọ̀ síra nìkan ni wọ́n tẹ́wọ́gbà, ṣùgbọ́n nínú ọ̀ràn tí ó pọ̀ jùlọ, ti kíkọ́ èdè titun kí wọ́n baà lè bójútó àìní tẹ̀mí tí àwọn ẹni-bí-àgùtàn ní pẹ̀lú. Ìsapá wọn ti yọrísí ìdáhùnpadà gbígbéṣẹ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn ará àdúgbò.

Àwọn ìdílé ara Dominican kan ti yááfì ìgbádùn tí ń bẹ ní àwọn ìlú ńláńlá wọ́n sì ti jáde lọ sí àwọn àrọ́ko. Gbogbo wọn ni a ń fi ìdùnnú-ayọ̀ ṣíṣàwárí ìṣúra tòótọ́ tí ó jẹ́ ti àwọn olùfòtítọ́-inú wá òtítọ́ kiri san èrè-ẹ̀san fún lọ́nà dídọ́ṣọ̀.

Kì í se àlàáfíà ni àwọn olùwá ìṣúra kiri ti ọ̀rúndún kẹẹ̀ẹ́dógún mú wá fún àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ Taino, bíkòṣe ìsìnrú àti ìjìyà tí ó kọ sísọ. Columbus fúnra rẹ̀ pàápàá kò jàǹfààní láti inú ìṣúra Ayé Titun. Wọ́n fi àṣẹ ọba mú un nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín wọ́n sì mú un kúrò ní erékùṣù náà tí ó ṣàwárí padà lọ sí Spania pẹ̀lú ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ lọ́wọ́.

Lónìí irú ìwákiri kan tí ó yàtọ̀ ń lọ lọ́wọ́, ìṣúra tí ó sì ṣeyebíye jù ni a ń rí. Ọwọ́ àwọn ènìyàn Jehofa dí fún wíwá àwọn ènìyàn tí kò lábòsí ọkàn tí wọ́n ń dáhùnpadà sí ìhìnrere Ìjọba náà kiri. Ohun tí ó ti jẹ́ ìyọrísí rẹ̀ ni pé ogunlọ́gọ̀ tí ó túbọ̀ ń pọ̀ sí i ṣáá ń gbádùn òmìnira tí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun nìkan lè mú wá. (Johannu 8:32) Wọ́n ń fojúsọ́nà fún àkókò náà nígbà tí ilẹ̀ tí ó kún fún àpáta, ìyalulẹ̀ omi rírẹwà, etíkun rírẹwà, àti ihò àpáta fífanimọ́ra yìí yóò di, kì í wulẹ̀ ṣe erékùṣù paradise kan, bíkòṣe apákan ayé titun tí yóò yí gbogbo ayé ká.—2 Peteru 3:13.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A tẹ̀ ẹ́ jáde láti ọwọ́ Watch Tower Bible and Tract Society.

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 24]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Dominican Republic

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24, 25]

Àwọn ọ̀dọ́ ṣàwárí ìníyelórí àwọn nǹkan tẹ̀mí nípa lílépa iṣẹ́-ìsìn alákòókò kíkún

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́