ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 3/15 ojú ìwé 21-24
  • Kò Sí Ìfẹ̀yìntì fún Wa!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kò Sí Ìfẹ̀yìntì fún Wa!
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ìsọ̀rí
  • Kí Ní Ń Fún Wọn Láyọ̀
  • Ìmúratán Láti Múra-Ẹni-Bápòmu
  • Fíforítì Í Lábẹ́ Ìṣòro Ìlera
  • Ó Ṣì Jẹ́ Ọ̀ràn Tí Ń Bá A Nìṣó
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 3/15 ojú ìwé 21-24

Kò Sí Ìfẹ̀yìntì fún Wa!

“KÒ SÍ ÌFẸ̀YÌNTÌ FÚN WA” ni ìmọ̀lára tí ìwọ yóò ní nígbà tí o bá ń ṣèbẹ̀wò sí ilé pípinminrin kan ní Tokyo, Japan. Ìdílé tí ó ní ọkùnrin àti obìnrin 22, tí ìpíndọ́gba ọjọ́-orí wọn jẹ́ 70, ni wọ́n ń gbé níbẹ̀. Kì í ṣe nítorí pé wọ́n jẹ́ ẹbí ni wọ́n ṣe wà bíkòṣe nítorí ìfẹ́-ọkàn kan náà—iṣẹ́-ìsìn míṣọ́nnárì. Wọ́n ti lo ìfaradà nínú iṣẹ́ ìwàásù alákòókò kíkún fún àròpọ̀ 1,026 ọdún! A bí àwọn mẹ́ta tí wọ́n dàgbà jù nínú wọn ní 1910. Méje lára wọn bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́-ìsìn alákòókò kíkún nígbà tí wọ́n kò tí ì pé ọmọ ogún ọdún. Mẹ́sàn-án lára wọn ti rí ìdàgbàsókè iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà ní Japan láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ rẹ̀ lẹ́yìn Ogun Àgbáyé II.—Isaiah 60:22.

Bí ó ti wù kí ó rí, ilé alájà mẹ́fà tí ó jẹ́ ti ẹ̀ka Watch Tower tẹ́lẹ̀rí yìí jẹ́ ibi tí ń fúnni ní ìṣírí, ní pàtàkì nítorí ẹ̀mí, ìtẹ̀sí èrò náà tí ó jọba lọ́kàn, àwọn míṣọ́nnárì tí ń gbé níbẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ jùlọ nínú wọn ní ibi ti agbára wọ́n mọ níti ara-ìyára èyí tí ó níí ṣe pẹ̀lú ọjọ́-orí àti àìlera, kò sí èyíkéyìí nínú àwọn jagunjagun tẹ̀mí wọ̀nyí tí ó ṣetán láti fà sẹ́yìn. Àwọn Ẹlẹ́rìí ará Japan ti tún ilé náà ṣe fún wọn pátápátá, wọ́n pèsè Gbọ̀ngàn Ìjọba ní ìsàlẹ̀ àti àtẹ̀gùn tí ń lo iná mànàmáná.

Kí Ní Ń Fún Wọn Láyọ̀

Níwọ̀n bí wọ́n ti wà lẹ́nu iṣẹ́ àyànfúnni wọn fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, àwọn míṣọ́nnárì wọ̀nyí nímọ̀lára pé ilé àwọn nìyí. Ọ̀kan lára àwọn mẹ́ḿbà tí ó dàgbà jùlọ nínú ìdílé náà sọ pé: “Nígbà tí mo padà lọ sí Australia fún àpéjọpọ̀ àgbègbè ní ìgbà ẹ̀rùn tí ó kọjá yìí, àárò ilé ti ń sọ mí lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjì!” Wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn ènìyàn tí wọ́n ń ṣiṣẹ́sìn, wọ́n sì ti mú ìfẹ́ni jíjinlẹ̀ dàgbà fún wọn. Gbogbo àwọn míṣọ́nnárì máa ń mọrírì lẹ́tà àti ìkésíni lórí fóònù tí ó máa ń pe àwọn ìgbòkègbodò ìgbà àtijọ́ wá sí ìrántí.

Ìyọrísí iṣẹ́-òjíṣẹ́ aláápọn nìyẹn. Ìfẹ́ fún Jehofa ti sún àwọn míṣọ́nnárì láti wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ní kánjúkánjú lábẹ́ onírúurú àyíká ipò. (Fiwé 2 Timoteu 4:2.) Vera MacKay, ẹni tí ó ti ṣiṣẹ́sìn ní Japan fún ọdún 37, sọ pé: “A ti kọ́ ara wa láti jẹ́ aláyọ̀ kìkì nítorí pé a ń ṣiṣẹ́sin Jehofa. Àní bí ẹnikẹ́ni kò bá tilẹ̀ wá sí ẹnu ọ̀nà, a lọ síbẹ̀ láti jẹ́rìí nípa Jehofa.”

Méjìlá nínú àwọn míṣọ́nnárì wọ̀nyí kò gbéyàwó rí, ṣùgbọ́n wọ́n ń láyọ̀ pé àwọn lè máa ṣiṣẹ́sin Oluwa láìsí ìpínyà ọkàn. (1 Korinti 7:35) Gladys Gregory, ẹni tí ó ti ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí míṣọ́nnárì fún ọdún 43, jẹ́ ọ̀kan lára wọn. Ó sọ pé: “Kí n baà lè ní òmìnira púpọ̀ síi fún iṣẹ́-ìsìn Jehofa, mo wọnú iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, lẹ́yìn náà mo lọ sí Gilead [Watchtower Bible School of Gilead], lẹ́yìn náà mo sì wọnú iṣẹ́ míṣọ́nnárì. Mo wà láìlọ́kọ, láìjẹ́ pé mo jẹ́ ẹ̀jẹ́ kankan láti ṣe bẹ́ẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí fún ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀rẹ́, n kò sì kábàámọ̀ rí pé mo ṣe bẹ́ẹ̀.”

Ìmúratán Láti Múra-Ẹni-Bápòmu

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn kan máa ń ya olóríkunkun bí wọ́n ti ń dàgbà síi, àwọn míṣọ́nnárì wọ̀nyí ti múratán láti mú ara wọn bá ipò mu. Lois Dyer, Molly Heron, pẹ̀lú Lena àti Margrit Winteler wà ní ilé kékeré ti àwọn míṣọ́nnárì ní agbègbè ilé gbígbé Tokyo. Wọ́n gbé níbẹ̀ fún ohun tí ó lé ní 20 ọdún wọ́n sì ti di ojúlùmọ̀ àwọn ènìyàn tí ń gbé ní àdúgbò yẹn. Ní agbègbè ìpínlẹ̀ wọn, àwọn ọmọ Winteler ní 40 ènìyàn tí ó jẹ́ ìpa-ọ̀nà ìwé-ìròyìn wọn, ti àwọn Molly àti Lois sì jẹ́ 74. Lẹ́yìn náà, Society ní kí wọ́n ṣí lọ sí ilé alájà mẹ́fà náà tí ó jẹ́ ti àwọn míṣọ́nnárì ní àárín gbùngbùn Tokyo. Lena jẹ́wọ́ pé: “Lákọ̀ọ́kọ́ ná mo sọ̀rètínù inú mi sì bàjẹ́.” Bí ó ti wù kí ó rí, gẹ́gẹ́ bí ó ti sábà máa ń rí, wọ́n mú ara wọn bá iṣẹ́ àyànfúnni wọn titun mu. Báwo ni ìmọ̀lára wọn ti rí báyìí? Lena fèsì pé: “A láyọ̀ gidigidi. Àwọn arákùnrin méjì wà níhìn-ín láti Beteli láti máa gbọ́únjẹ fún wa àti láti máa tọ́jú ilé. Wọ́n ń bójútó wa dáradára.” Gbogbo wọn fohùnsọ̀kan pẹ̀lú Lois, ẹni tí ó sọ pé: “Àbójútó onífẹ̀ẹ́ tí ètò-àjọ Jehofa ń fún wa ń ràn wá lọ́wọ́ láti lè máa faradà á.”

Norrine Thompson pẹ̀lú mú ara rẹ̀ bá àwọn àyíká ipò titun mu. Ó wí pé: “Fún ọdún 15 mo ní àǹfààní láti máa tẹ̀lé ọkọ mi [tí ó wá láti New Zealand] nínú iṣẹ́ àgbègbè nígbà tí gbogbo Japan jẹ́ kìkì àgbègbè kanṣoṣo.” Bí ó ti wù kí ó rí, ìlera ọkọ rẹ̀ jórẹ̀yìn, ó sì níláti borí àdánwò títóbi jùlọ nínú ìgbésí-ayé rẹ̀—ikú ọkọ rẹ̀ ní ọdún 18 sẹ́yìn. Ó sọ pé: “Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, ohun tí ó ràn mí lọ́wọ́ láti máa bá a nìṣó nínú iṣẹ́ míṣọ́nnárì ni ìfẹ́ tí àwọn ará jákèjádò Japan fi hàn, papọ̀ pẹ̀lú àdúrà àti jíjẹ́ kí ọwọ́ mi dí nínú iṣẹ́-ìsìn.”

Fíforítì Í Lábẹ́ Ìṣòro Ìlera

Albert Pastor, alábòójútó ilé àwọn míṣọ́nnárì, sọ pé: “Ọ̀pọ̀ jùlọ ní irú àwọn ìṣòro ìlera kan, ṣùgbọ́n wọ́n jẹ́ ọlọ́yàyà, ìfẹ́-ọkàn wọn láti ṣiṣẹ́sìn sì jẹ́ ànímọ́ títayọlọ́lá.” Láti bójútó àwọn míṣọ́nnárì, dókítà kan àti aya rẹ̀, tí ó jẹ́ nọ́ọ̀sì, ni a ti yàn sí ilé náà.

Ní ọjọ́ kan ní nǹkan bí ọdún mẹ́ta sẹ́yìn, Elsie Tanigawa, akẹ́kọ̀ọ́yege ní kíláàsì kọkànlá ti Gilead School, pàdánù agbára ìríran ojú rẹ̀ òsì. Ní oṣù mẹ́rin lẹ́yìn náà, àrun náà ran ojú rẹ̀ ọ̀tún. Elsie sọ pé: “Nígbà mìíràn mo máa ń sọ̀rètínù nítorí pé n kò lè ṣiṣẹ́sìn bí mo ti máa ń ṣe tẹ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú gbogbo ìpèsè onínúure ti Society àti ìtìlẹ́yìn onífẹ̀ẹ́ ti àwọn alábàáṣiṣẹ́pọ̀ mi àti àwọn mìíràn, mo ń bá a nìṣó láti máa rí ìdùnnú-ayọ̀ nínú iṣẹ́-ìsìn Jehofa.”

Shinichi Tohara àti aya rẹ̀, Masako, tí wọ́n jẹ́ ọmọ ilé-ẹkọ́ Gilead nígbà kan náà pẹ̀lú Elsie, ti dojúkọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àdánwò tí ó jẹmọ́ àìlera wọn ní àwọn ọdún díẹ̀ tí ó ti kọjá. Shinichi ní tirẹ̀, tí ó jẹ́ olùbánisọ̀rọ̀ tí ó dáńgájíá, ni ó ti jẹ́ ìpèníjà ńláǹlà fún láti má lè ríran rí àkọsílẹ̀ rẹ̀ nítorí ojú rẹ̀ tí ń ṣe bàìbàì. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti la ọ̀pọ̀ iṣẹ́-abẹ tí ó léwu àti èyí tí ó jẹ́ ráńpẹ́ kọjá lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ojú rẹ̀ ń dán nígbà tí ó bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli rẹ̀ kan tí ó jẹ ẹni 90 ọdún tí ó ń ràn lọ́wọ́ nísinsìnyí.

Láìka pé wọ́n ní ‘ẹ̀gún kan ninu ẹran-ara’ sí, àwọn míṣọ́nnárì wọ̀nyí ka àìlera wọn sí ohun tí aposteli Paulu kà á sí, ẹni tí ó wí pé: “Nitori nígbà tí emi bá jẹ́ aláìlera, nígbà naa ni mo di alágbára.” (2 Korinti 12:7-10) Alágbára sì ni wọ́n níti tòótọ́! Wọ́n ń jí fún ìjọsìn òwúrọ̀ lójoojúmọ́ ní aago méje. Lẹ́yìn oúnjẹ àárọ̀, àwọn tí wọ́n ní okun láti ṣe bẹ́ẹ̀ yóò jáde lọ fún iṣẹ́-òjíṣẹ́ pápá ní òwúrọ̀.

Richard àti Myrtle Shiroma wà lára àwọn wọnnì tí ń jáde déédéé fún iṣẹ́-ìsìn. Àrùn rọpárọsẹ̀ tí ìlegbandi iṣan agbẹ́jẹ̀ wọnú ọpọlọ ṣokùnfà rẹ̀ kọlu Myrtle ní 1978, ṣùgbọ́n ó ń tẹ̀lé ọkọ rẹ̀ nínú iṣẹ́ arìnrìn-àjò títí di November 1987. Nísinsìnyí Richard, tí òun fúnra rẹ̀ ti di ẹni 70 ọdún, ń ran Myrtle lọ́wọ́ láti ṣe ohun gbogbo. Ó ń jí ní aago 5 ìdájí, yóò gbé e kúrò lórí ibùsùn, yóò wẹ̀ ẹ́, yóò wọ aṣọ fún un, yóò ṣe ojú rẹ̀ lóge, yóò sì fi oúnjẹ nù ún. Lẹ́yìn náà ni yóò fi kẹ̀kẹ́-arọ rẹ̀ tì í jáde fún iṣẹ́-ìsìn pápá ní òròòwúrọ̀, yóò máa lọ láti ilé dé ilé fún nǹkan bíi wákàtí kan tí yóò sì lọ jẹ́rìí lẹ́yìn náà fún àwọn ènìyàn ní àwọn ibi ìdúró-de-ọkọ̀. Myrtle kò lè sọ̀rọ̀ mọ́, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ tí ó sọ kẹ́yìn ni Dendo, dendo, èdè àwọn ará Japan fún “Wíwàásù, wíwàásù.”

Sandra Sumida, ọmọbìnrin wọn, ti ṣí wá sí ilé àwọn míṣọ́nnárì láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Sandra pàdánù ọkọ rẹ̀ olùfẹ́, ẹni tí àrùn ọkàn-àyà pa láìpẹ́ yìí. Ó mọrírì ètò onínúure tí Watch Tower Society ṣe ní yíyàn án padà sí Japan láti Guam, níbi tí ó ti ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí míṣọ́nnárì pẹ̀lú ọkọ rẹ. Ó sọ pe: “Mo sábà máa ń nímọ̀lára pé n kò kó ìpa tí ó tó nínú ríran àwọn òbí mi lọ́wọ́ nítorí pé mo wà ní Guam. Arábìnrin mi, Joanne, ni ó ń bójútó wọn nínú ilé yìí. Nítorí náà nígbà tí àǹfààní náà ṣí sílẹ̀, ó dùn mọ́ mi nínú. Nínímọ̀lára pé a nílò mi níhìn-ín ti jẹ́ egbòogi mi láti ìgbà ikú òjijì ọkọ mi.”

Ó Ṣì Jẹ́ Ọ̀ràn Tí Ń Bá A Nìṣó

Àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn míṣọ́nnárì náà nímọ̀lára ohun tí ọjọ́ ogbó máa ń yọrí sí, wọ́n kọ̀ láti juwọ́sílẹ̀ nínú ẹ̀mí míṣọ́nnárì wọn. (Orin Dafidi 90:10; Romu 5:12) Jerry àti Yoshi Toma, tí wọ́n wà lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege Gilead tí wọ́n kọ́kọ́ wá sí Japan, ṣì ń jáde lọ sí agbègbè ìpínlẹ̀ iṣẹ́-ajé ní ìsàlẹ̀ ilú Shibuya. Yoshi sọ pé: “Nígbà tí a wá sí ilé alájà méjì tí ń bẹ níhìn-ín ní 1949, a ń lọ láti inú ilé àbẹ̀rẹ̀wọ̀ sí ilé àbẹ̀rẹ̀wọ̀. Nísinsìnyí Tokyo ti yípadà di ìlú-ńlá. A ti darúgbó a kò sì lè ṣe tó bí a ti ń ṣe tẹ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n nígbà tí a bá padà dé látẹnu iṣẹ́ ìwàásù, ara máa ń tù wá.”

Lillian Samson ti jẹ́ míṣọ́nnárì ní Japan fún 40 ọdún ó sì ń gbádùn iṣẹ́-òjíṣẹ́ rẹ̀ gan-an. “Mo ń ran obìnrin ẹni 80 ọdún tí alábàáṣiṣẹ́pọ̀ mi bá kẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́, Adeline Nako, tí ó padà lọ sí Hawaii láti bójútó ìyá rẹ̀ tí ara rẹ̀ kò dá. Láìpẹ́ yìí obìnrin náà di akéde Ìjọba lẹ́yìn bíborí ìṣòro ìjọsìn àwọn babańlá. Ó lọ sí tẹ́ḿpìlì ó sì sọ fún aya àlùfáà náà pé, ‘Mo ti di Kristian!’” Pẹ̀lú irú ìdùnnú-ayọ̀ bẹ́ẹ̀ nínú ìgbésí-ayé rẹ̀, Lillian kò fìgbà kan kábàámọ̀ ọjọ́ náà nígbà tí, ó jẹ́ ẹni ọdún 19, tí ó fi iṣẹ́ ajé rẹ̀ sílẹ̀ tí ó sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà.

Ruth Ulrich àti Martha Hess, àwọn míṣọ́nnárì alájùmọ̀ṣisẹ́pọ̀ fún ohun tí ó ti lé ní ọdún 45, ti ṣiṣẹ́ ní ilé àwọn míṣọ́nnárì yìí fún ọdún 35. Wọ́n ti fìdí kalẹ̀ dáradára sí agbègbè ìpínlẹ̀ náà. Alábòójútó àyíká kan béèrè lọ́wọ́ Martha nígbà kan pé: “O ha lè yá mi ní ojú rẹ láti lọ láti ẹnu-ọ̀nà sí ẹnu-ọ̀nà bí?” Àwọn ènìyàn mọ ojú Martha wọ́n sì ń gba ìwé ìròyìn, nígbà tí ó jẹ́ pé ekukáká ni alábòójútó àyíká náà fi lè bẹ̀rẹ̀ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀.

Obìnrin kan wà ní ipa-ọ̀nà ìwé ìròyìn Ruth tí kò lè kàwé nítorí ìṣòro àìlera rẹ̀. Síbẹ̀, obìnrin náà ń bá a nìṣó láti máa gba àwọn ìwé ìròyìn náà àní ó tilẹ̀ gba ìwé ẹlẹ́yìn líle náà Mankind’s Search for God. Ruth ṣe kàyéfì bóyá òun níláti máa bá a nìṣó ní mímú àwọn ìwé ìròyìn wá níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé ó dàbí ẹni pé kò sí ẹnikẹ́ni tí ń kà ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Lẹ́yìn náà lọ́jọ́ kan ọkọ obìnrin náà tọ Ruth lọ pẹ̀lú ìwé Search, ní sísọ pé: “Ìwé àgbàyanu ni èyí jẹ́! Mo ti kà á tán nígbà méjì.” Ruth bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú òun àti aya rẹ̀.

Ilé àwọn míṣọ́nnárì yìí fúnra rẹ̀ ń fa àwọn ènìyàn mọ́ra. Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, ọ̀dọ́mọkùnrin kan wá sí ilé náà ó sì sọ pé: “Mo gbọ́ pé bí mo bá wá síhìn-ín, mo lè rí ìrànlọ́wọ́ gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli.” A bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí agbọ́únjẹ ní ilé àrójẹ Chinese kan, ó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú obìnrin kan tí a ti yọlẹ́gbẹ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Àwọn ìwé ìròyìn tí akéde kan fi sóde nígbà ti ó kàn sí ilé àrójẹ náà dé ilé ìdáná. Ọ̀dọ́ agbọ́únjẹ náà fẹ́ràn wọn ó sì bẹ̀rẹ̀ sí béèrè àwọn ìbéèrè lọ́wọ́ Ẹlẹ́rìí tẹ́lẹ̀rí náà. Nígbà tí kò lè dáhùn wọn, ó sọ fún un pé kí ó ṣèbẹ̀wò sí ilé àwọn míṣọ́nnárì náà. Ó ń ṣiṣẹ́sìn nísinsìnyí gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ iṣẹ́-òjíṣẹ́ àti aṣáájú-ọ̀nà. Bí àkókò ti ń lọ, a gba obìnrin tí a ti yọlẹ́gbẹ́ náà padà, àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀ òun pẹ̀lú di aṣáájú-ọ̀nà déédéé.

Gbogbo àwọn míṣọ́nnárì inú ilé náà ni wọ́n mọrírì ohun tí Jehofa ti ṣe fún wọn. Wọ́n wá láti Australia, Canada, Hawaii, Switzerland, àti United States, tí 11 lára wọn sì wá láti kíláàsì kọkànlá ilé-ẹ̀kọ́ àwọn míṣọ́nnárì ti Gilead tàbí èyí tí ó ṣáájú rẹ̀. Wọ́n ti rí ìtẹ̀síwájú iṣẹ́ Ìjọba náà ní Japan wọ́n sì ti ṣàjọpín èrò ìmọ̀lára Ọba Dafidi, ẹni tí ó sọ pé: “Èmi ti wà ní èwe, èmi sì dàgbà; èmi kò tí ì rí i kí a kọ olódodo sílẹ̀, tàbí kí irú-ọmọ rẹ̀ kí ó máa ṣagbe oúnjẹ.” (Orin Dafidi 37:25) Nítorí ìmọrírì fún àbójútó onífẹ̀ẹ́ tí Ọlọrun ti fi hàn fún wọn, àwọn míṣọ́nnárì wọ̀nyí ti pinnu láti máṣe fẹ̀yìntì bíkòṣe kí wọ́n máa bá a nìṣó ní ṣíṣiṣẹ́sin Jehofa.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́