ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 3/15 ojú ìwé 31
  • Jehofa Yóò Gba Ilẹ̀-Ayé Là

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jehofa Yóò Gba Ilẹ̀-Ayé Là
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 3/15 ojú ìwé 31

Jehofa Yóò Gba Ilẹ̀-Ayé Là

PÁPÁ ọkọ̀ òfuurufú tí ó wà ní àwọn erékùṣù Maldives ni a ń tìpa fún wákàtí mélòókan lójoojúmọ́. Èéṣe? Nítorí omi tí ìrugùdù rẹ̀ pọ̀ kún ibi tí ọkọ̀ òfuurufú ti máa ń gbéra fọ́fọ́, ó sì mú kí ó léwu fún àwọn ọkọ̀ òfuurufú láti balẹ̀. Àwọn onímọ̀-ìjìnlẹ̀ kan ń bẹ̀rù pé ìwọ̀n ìtẹ́jú òkun ní àwọn erékùṣù Maldives lè ga sókè ó kérétán dé mítà kan ní ọ̀rúndún tí ń bọ̀. Nígbà tí èyí jọ bí iye kan tí kò tó nǹkan, irú ìlọsókè bẹ́ẹ̀ lè gbá orílẹ̀-èdè méje tí ó jẹ́ erékùṣù lọ pátápátá. Níti tòótọ́, gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn UN Chronicle ti sọ, ìlọsókè ní mítà méjì lè bo àgbájọ gbogbo erékùṣù náà pátápátá, nǹkan bí 1,200 àwọn erékùṣù!

Kí ló fa ìlọsókè ìwọ̀n ìtẹ́jú òkun náà? Gẹ́gẹ́ bí Ètò Ìgbáyìíkámọ́ ti àjọ UN ti sọ, bíba afẹ́fẹ́ àyíká ilẹ̀-ayé jẹ́ nípasẹ̀ “ìmóoru ilẹ̀-ayé” ń mú kí òkun fẹ̀ síi ní àwọn ilẹ̀ tí ó lọ́ wọ́ọ́rọ́, kí àwọn ìdìpọ̀ yìnyín àti òkìtì yìnyín di yíyọ́, àti nípa bẹ́ẹ̀, kí ìwọn ìtẹ́jú òkun ga sókè. Ilé-Iṣẹ́ Panos tí a fìdí rẹ̀ kalẹ̀ sí London sọ pé ìbàyíkájẹ́ “lè ti tannáran àjálù-ibi kárí-ayé tí ń yọ́kẹ́lẹ́ yí àwọn ààlà ilẹ̀ àti òkun padà.”

Pé ilẹ̀-ayé ń lọ́ wọ́ọ́rọ́ ṣì jẹ́ ohun tí àwọn onímọ̀-ìjìnlẹ̀ ń jiyàn lé lórí láàárín ara wọn. Bí ó ti wù kí ó rí, a lè ní ìdánilójú pé àwọn ìṣòro àyíká kí yóò dabarú ète Ọlọrun. Bibeli sọ pé: “Ayé pẹ̀lú sì fi ìdí múlẹ̀ tí kì óò fi lè yí.” (1 Kronika 16:30) Jehofa ní agbára lórí àyíká ilẹ̀-ayé, a sì láyọ̀ pé láìpẹ́ òun yóò gba ilẹ̀-ayé àti aráyé là lọ́wọ́ ìparun.—Orin Dafidi 24:1, 2; 135:6; 2 Peteru 3:13.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 31]

Àwòrán ni a gbéka fọ́tò NASA

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́