ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 3/15 ojú ìwé 32
  • Báwo Ni Bibeli kan Ti Níyelórí Tó?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Ni Bibeli kan Ti Níyelórí Tó?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 3/15 ojú ìwé 32

Báwo Ni Bibeli kan Ti Níyelórí Tó?

ILÉ Àkójọ-Ìwé-Kíkà ilẹ̀ Britain láìpẹ́ yìí gbà láti san iye tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó $1,600,000 fún ẹ̀dà kan ìtumọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì ti Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ti William Tyndale. A tẹ̀ ẹ́ jáde ní 468 ọdún sẹ́yìn, òhun nìkanṣoṣo ni odindi ẹ̀dà Bibeli Tyndale tí a kọ́kọ́ tẹ̀ jáde tí ó la ìsapá àfìpinnuṣe láti pa á run já. Bibeli yìí ni a ti fi sí ibi tí gbogbo ènìyàn ti lè rí i ní London.

Bibeli Tyndale ni a rà lọ́wọ́ Bristol Baptist College ní England, níbi tí a tọ́jú rẹ̀ sí láti 1784. Ọ̀mọ̀wé Roger Hayden, tí ó jẹ́ igbákejì alága ìgbìmọ̀ kọ́lẹ́ẹ̀jì náà, sọ pé: “Èyí jẹ́ ìwé àkọsílẹ̀ ti àpapọ̀ orílẹ̀-èdè, ti ìṣẹ̀dálẹ̀ àti ti Kristian tí ó ní ìjẹ́pàtàkì gidigidi a sì fẹ́ kí ó túbọ̀ wà lárọ̀ọ́wọ́tó lọ́nà tí ó gbòòrò, níwọ̀n bí a ti fi í pamọ́ sí ihò abẹ́ ilẹ̀.”

Fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún Bibeli ti wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní pàtàkì ní èdè Latin kìkì àwọn àlùfáà àti àwọn ọ̀tọ̀kùlú tí wọ́n jẹ́ ọ̀mọ̀wé ni wọ́n sì lè kà á. Gẹ́gẹ́ bíi ti John Wycliffe tí ó ṣáájú rẹ̀, Tyndale fẹ́ kí Bibeli tí gbogbo ènìyàn yóò lè kà kí wọ́n sì lóye rẹ̀ wà lárọ̀ọ́wọ́tó. Ó sọ nígbà kan fún àlùfáà kan tí ó takò ó pé: ‘Bí Ọlọrun bá dá ẹ̀mí mi sí ṣáájú kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún tó kọjá lọ, èmi yóò mú kí ọ̀dọ́mọkùnrin tí ń wa ohun-èlò ìtúlẹ̀ mọ apá tí ó pọ̀ jùlọ lára Ìwé Mímọ́ ju bí ìwọ ti mọ̀ ọn lọ.’

Èyí jẹ́ ìdáwọ́lé kan tí ó léwu, níwọ̀n bí àwọn àlùfáà ti tako ìsapá èyíkéyìí láti mú kí Ìwé Mímọ́ wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún àwọn gbáàtúù ènìyàn. Nítorí èyí, Tyndale sá láti England lọ sí Germany. Níbẹ̀ ni ó ti túmọ̀ “Májẹ̀mú Titun” láti inú èdè Griki ìpilẹ̀ṣẹ̀. Nǹkan bí ẹ̀dà 3,000 ni a tẹ̀ jáde tí a sì ṣe fàyàwọ́ rẹ̀ wọ England. Bíṣọ́ọ̀bù London ra gbogbo ẹ̀dà tí ó rí ó sì sun wọ́n ní gbangba ní àgbàlá ṣọ́ọ̀ṣì St. Paul. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, wọ́n gbá Tyndale mú, ó jẹ́jọ́, wọ́n sì dá a lẹ́bi ṣíṣe àdámọ̀. Ní 1536 wọ́n lọ́ ọ lọ́rùn pa, wọ́n sì dáná sun ún lórí òpó igi. Ẹ wo bí ó ti dùnmọ́ni nínú tó pé Bibeli tí àwọn àlùfáà kórìíra tóbẹ́ẹ̀ ni ó wá níyelórí tó báyìí!

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń fi pẹ̀lú ìtara làkàkà láti fi ìmọ̀ pípéye Bibeli fún àwọn wọnnì tí ń wá a. Yàtọ̀ sí títẹ̀ àti pípín àwọn ẹ̀dà mìíràn kiri, wọ́n ti ṣe ìmújáde ìtumọ̀ odindi Bibeli tí ó péye tí ó sì tún rọrùn láti kà láti inú àwọn èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀. Ní 1995 iye tí ó ju 74,000,000 ẹ̀dà New World Translation of the Holy Scriptures yìí ni a ti tẹ̀ jáde ní èdè 12. Àmọ́ ṣa o, ìníyelórí tòótọ́ tí Bibeli èyíkéyìí lè ní ni ìhìn-iṣẹ́ rẹ̀ tí ń fúnni ní ìyè.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]

William Tyndale

[Credit Line]

Láti ará iṣẹ́-ọnà fínfín ní Bibliothèque Nationale

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́