Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Irú ìṣarasíhùwà wo ni ó yẹ kí a fi hàn nígbà ìbatisí Kristian?
Ìbéèrè tí ń ru ọkàn-ìfẹ́ sókè nìyẹn, nítorí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nínú àwọn òǹkàwé wa ni ó ti ṣe batisí, ó kàn wọ́n, bí ó ti kan àwọn tí ń ṣe ìbatisí. Ẹ jẹ́ kí a kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ lórí àwọn wọnnì tí ń ṣe batisí gan-an, tí a rìbọmi pátápátá. Kí ni ó yẹ kí ó jẹ́ ìṣarasíhùwà wọn?
Ní Matteu 28:19, 20, Jesu sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n lọ láti sọ àwọn ènìyàn di ọmọ-ẹ̀yìn, kí wọ́n kọ́ wọn kí wọ́n sì batisí wọn. Òun kò fi ìbatisí hàn gẹ́gẹ́ bí ìrírí elérò-ìmọ̀lára gíga, ìgbésẹ̀ kan tí ń wá láti inú ìrusókè ìmọ̀lára ojú-ẹsẹ̀. Ó jẹ́ ìgbésẹ̀ pàtàkì kan, gẹ́gẹ́ bí a ti rí i nínú àpẹẹrẹ Jesu. Luku 3:21 sọ pé: “A batisí Jesu pẹlu, bí ó sì ti ń gbàdúrà, ọ̀run ṣí sílẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ni, Àwòkọ́ṣe wa fi ọwọ́ pàtàkì mú ìbatisí, tàdúrà tàdúrà. A kò lè finúwòye rẹ̀ pé, lẹ́yìn ìbatisí, kí ó máa faraṣàpèjúwe lọ́nà tí ń fi ìṣẹ́gun hàn, ní kíkọ lálá fún ayọ̀ ìṣẹ́gun, tàbí kí ó bẹ̀rẹ̀ sí kápá sókè, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan láìpẹ́ yìí ti ṣe àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀. Bẹ́ẹ̀kọ́, pẹ̀lú Johannu Oníbatisí nìkanṣoṣo níbẹ̀, Jesu yíjú sí Bàbá rẹ̀ nínú àdúrà.
Bí ó ti wù kí ó rí, Bibeli kò dábàá pé ìbatisí gbọ́dọ̀ jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ amúnifajúro tàbí ìṣẹ̀lẹ̀ abaninínújẹ́ kan, tí ń béèrè fún ipò ìdúró tàbí àkọ́sórí àkànṣe, gẹ́gẹ́ bí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kristẹndọm kan ti béèrè lónìí. Èéṣe, ronú nípa ọjọ́ Pentekosti, nígbà tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Júù àti àwọn aláwọ̀ṣe ṣe ìbatisí Kristian. Wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́ Òfin Ọlọrun wọ́n sì ti wá sínú ipò-ìbátan pẹ̀lú rẹ̀. Kìkì pé kí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ nípa Messia náà, Jesu, kí wọ́n sì tẹ́wọ́gbà á. Bí wọ́n bá ti ṣe èyí, wọ́n lè ṣe batisí.
Ìṣe 2:41 ròyìn pé: “Awọn wọnnì tí wọ́n fi tọkàntọkàn gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni a batisí.” Ẹ̀dà Bibeli ti Weymouth kà pé: “Nítorí náà, àwọn wọnnì tí wọ́n fi ìdùnnú-ayọ̀ gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni a sì baptisí.” Wọ́n rí ìdùnnú-ayọ̀ nínú ìròyìn amúnilóríyá nípa Messia, dájúdájú ìdùnnú-ayọ̀ àtọ̀runwá yẹn tàn dé ìgbà ìbatisí náà fúnra rẹ̀, batisí kan tí wọ́n ṣe lójú ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn òǹwòran tí wọ́n láyọ̀. Kódà àwọn áńgẹ́lì ní ọ̀run ń wò ó wọ́n sì ń yọ̀. Rántí àwọn ọ̀rọ̀ Jesu pé: “Mo sọ fún yín, bayii ni ìdùnnú-ayọ̀ ṣe máa ń sọ láàárín awọn áńgẹ́lì Ọlọrun lórí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí ó ronúpìwàdà.”—Luku 15:10.
Oríṣiríṣi ọ̀nà ni ó wà tí ẹnìkọ̀ọ̀kan wa lè gbà fi ìjẹ́pàtàkì àti ìdùnnú-ayọ̀ ìbatisí hàn. Ní àwọn ṣọ́ọ̀ṣì kan àwọn wọnnì tí ń ṣe ìbatisí ń wọ aṣọ àwọ̀kanlẹ̀ funfun tàbí dúdú. Kò sí ìtìlẹyìn Ìwé Mímọ́ kankan fún irú àwọn ohun àbéèrèfún bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀, aṣọ ìwẹ̀ tí ó fò tàbí tí ń fi ara hàn kì yóò bójúmu fún àwọn ọkùnrin tàbí obìnrin. Gẹ́gẹ́ bí a sì ti ṣàkíyèsí, lẹ́yìn jíjáde kúrò nínú omi, Kristian titun náà kò níláti ṣe ìfaraṣàpèjúwe àrà-ọ̀tọ̀ tàbí ṣe bí ẹni pé ó ti jagunmólú. Àwọn Kristian ẹgbẹ́-ará yòókù kárí ayé láyọ̀ pé àwọn ẹni titun ṣè batisí. Ó níláti mọ̀ pé ìṣàfihàn ìgbàgbọ́ yìí wulẹ̀ jẹ́ ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ nínú ipa-ọ̀nà gígùn ti ìwàtítọ́ láti jèrè ìtẹ́wọ́gbà Ọlọrun.—Matteu 16:24.
Àwa, gẹ́gẹ́ bí òǹwòran níbi ìbatisí ní gbangba, ṣàjọpín nínú ìdùnnú-ayọ̀ àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ náà, pàápàá bí ẹni tí ń ṣe batisí bá jẹ́ mọ̀lẹ́bí wa tàbí ẹni tí a bá kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. Bí ó ti wù kí ó rí, láti ṣàjọpín lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, ó yẹ kí a fetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ àwíyé náà látòkèdélẹ̀ pẹ̀lú àwọn olùnàgà fún àǹfààní ìrìbọmi, kí a gbọ́ kí wọ́n dáhùn àwọn ìbéèrè tí a bi wọ́n náà ní gbangba, kí a sì darapọ̀ mọ́ wọn nínú àdúrà. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ní ojú-ìwòye tí ó tọ́ nípa batisí náà; a óò ní ojú-ìwòye Ọlọrun nípa rẹ̀. Lẹ́yìn ìrìbọmi náà gan-an, ìdùnnú-ayọ̀ wa kò béèrè ìyanlọ-yanbọ̀ ti jíjagunmólú, gbígbé ìdìpọ̀ òdòdó lọ́wọ́, tàbí àpèjẹ kan fún dídá ẹni náà tí ó ṣè batisí lọ́lá. Ṣùgbọ́n a lè tọ arákùnrin tàbí arábìnrin wa titun lọ láti fi ìdùnnú wa hàn lórí ìgbésẹ̀ àgbàyanu tí ó gbé kí a sì fi tọ̀yàyà tọ̀yàyà kí i káàbọ̀ sínú ẹgbẹ́ ará Kristian wa.
Nígbà náà, ní àkópọ̀, gbogbo wa, títíkan àwọn wọnnì tí a rìbọmi, níláti fi ọwọ́ pàtàkì tí ó yẹ mú ìbatisí. Kì í ṣe àkókò fún ariwo gèè, fún pípe àpèjẹ, tàbí fún ẹ̀rín aláriwo. Ṣùgbọ́n kì í tún ṣe àkókò amúnifajúro tàbí abaninínújẹ́. Lọ́nà tí ó tọ́ a lè láyọ̀ pé àwọn ẹni titun ti darapọ̀ mọ́ wa lójú ọ̀nà sí ìyè àìnípẹ̀kun. A sì lè fi pẹ̀lú ìdùnnú-ayọ̀ kí àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa titun káàbọ̀.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]