A Fi Tìfẹ́tìfẹ́ Késí Ọ
Ikú ọkùnrin náà Jesu Kristi ní ohun tí ó ju 1,900 ọdún sẹ́yìn ni ó jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣe pàtàkì jùlọ nínú ìtàn ẹ̀dá ènìyàn. Ó ṣí ìrètí jíjèrè ìyè àìnípẹ̀kun nínú paradise lórí ilẹ̀-ayé sílẹ̀. Lákòókò ayẹyẹ ráńpẹ́ kan, Jesu lo ìṣù búrẹ́dì aláìwú àti wáìnì gẹ́gẹ́ bí ohun ìṣàpẹẹrẹ ìrúbọ onífẹ̀ẹ́ ti ẹ̀dá ènìyàn rẹ̀. Lẹ́yìn náà ó sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” (luku 22:19) Ìwọ yóò ha rántí ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì yìí bí? Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fi tọ̀yàyà tọ̀yàyà késí ọ láti darapọ̀ mọ́ wọn nínú ṣíṣe ayẹyẹ ìṣe-ìrántí yìí. Yóò jẹ́ lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀ ní ọjọ́ tí ó ṣe rẹ́gí pẹ̀lú nisan 14 lórí kalẹnda òṣùpá ti Bibeli. Ìwọ lè lọ sí gbọ̀ngàn ìjọba tí ó bá súnmọ́ ilé rẹ jùlọ. Wádìí lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní àdúgbò rẹ fún àkókò náà gan-an àti ibi tí a óò ti ṣe é. Ọjọ́ ayẹyẹ náà ní 1995 yóò jẹ́ Friday, April 14.