ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 4/15 ojú ìwé 7-9
  • Ìdùnnú-Ayọ̀ Wà ní Ìpamọ́ fún Àwọn Wọnnì Tí Wọ́n Rí Òtítọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìdùnnú-Ayọ̀ Wà ní Ìpamọ́ fún Àwọn Wọnnì Tí Wọ́n Rí Òtítọ́
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ẹ̀kọ́ Tòótọ́ Bibeli Ń Mú Ìdùnnú-Ayọ̀ Wá
  • Àwọn Ìlànà Tòótọ́ Bibeli Ń Mú Ìdùnnú-Ayọ̀ Wá
  • A Gbọ́dọ̀ Mú Ìdùnnú-Ayọ̀ Dàgbà
  • Bó O Ṣe Lè Fara Dà Á bí Ọkọ Tàbí Aya Rẹ Bá Já Ẹ Jù Sílẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • ‘Ẹ Máa Rìn Nínú Òtítọ́’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • Nípìn-ín Nínú Ayọ̀ Tó Wà Nínú Fífúnni!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Ìdùnnú​—Ànímọ́ Rere Tí Ọlọ́run Ń Fúnni
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 4/15 ojú ìwé 7-9

Ìdùnnú-Ayọ̀ Wà ní Ìpamọ́ fún Àwọn Wọnnì Tí Wọ́n Rí Òtítọ́

NÍ ÒKÈ-ÀJÀ ilé rẹ̀, ọkùnrin ará Finland kan rí ìwé náà The Divine Plan of the Ages. Ó bẹ̀rẹ̀ sí kà á lójú ẹsẹ̀, kò pẹ́ kò jìnnà ó sọ nínú ara rẹ̀ pé, ‘Òtítọ́ nìyí; òtítọ́ nìyí.’ Bí ó ṣe ń sọ̀kalẹ̀ bọ̀ láti òkè-àjà náà, ó sọ fún aya rẹ̀ pé, “Mo ti rí ìsìn tòótọ́.”

Ìrírí bí ọkùnrin yìí ṣe rí òtítọ́ ṣàjèjì, ṣùgbọ́n púpọ̀ lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lè sọ irú ìhùwàpadà bẹ́ẹ̀ jáde. Gbogbo wọn lè sọ fún ọ nípa ìdùnnú-ayọ̀ tí rírí òtítọ́ ń mú wá. Àwọn ìrírí tí ó tẹ̀lé e yìí fi èyí hàn.

Àwọn Ẹ̀kọ́ Tòótọ́ Bibeli Ń Mú Ìdùnnú-Ayọ̀ Wá

Margarita Königer dàgbà ní Munich, Germany, lákòókò Ogun Àgbáyé II. Àwọn ilé tí a ju bọ́m̀bù sì tí ó sì ń jó jẹ́ ohun tí ó ń rí láti ìgbà-dégbà. Ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin kú nínú ogun náà. Bí ó ti ń lọ sí ààtò-ìsìn ṣọ́ọ̀ṣì Katoliki, ó ń gbọ́ tí a ń gbàdúrà fún àwọn sọ́jà Germany àti aṣáájú náà, Hitler. Lẹ́yìn ogun náà, ó gba ẹ̀bùn ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ láti lọ sí kọ́lẹ́ẹ̀jì ní United States gẹ́gẹ́ bí apákan ètò pípààrọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti orílẹ̀-èdè kan sí èkejì. Ó rí i pé àwọn ènìyàn hùwà bí ọ̀rẹ́ sí òun, nítorí náà ó ṣe kàyéfì nípa ohun tí ó dàbíi pé ó ń sún àwọn ènìyàn, tí ìfẹ́-ọkàn wọn lọ́nà ti ẹ̀dá jẹ́ láti máa gbé ní àlàáfíà, tí wọn kì í fi í gbẹ́kẹ̀léni tí wọ́n sì máa ń kórìíra ara wọn lẹ́nìkínní kejì lákòókò ogun. Ní Munich lọ́hùn-ún, ó bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa pàdé, nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú wọn, ó rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè rẹ̀. Ó wí pé: “A fi hàn mí láti inú Bibeli pé ó lọ́wọ́ àwọn ipá ẹ̀mí búburú nínú. . . . Bibeli pè wọ́n ní ‘awọn olùṣàkóso ayé,’ níti tòótọ́, ó sọ pé Satani ‘ń ṣi gbogbo ilẹ̀-ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà.’ . . . Ẹ wo bí ìdáhùn náà ti jẹ́ èyí tí ó lọ́gbọ́n-nínú tí ó sì tẹ́nilọ́rùn tó, bí a bá gbé e yẹ̀wò pẹ̀lú ìgbésẹ̀ abèṣù, aláìṣèfẹ́ Ọlọrun, tí àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn ènìyàn ń gbé!”—Efesu 6:12; Ìṣípayá 12:9.

Margarita ń bá a nìṣó pé: “Ó mú ìdùnnú-ayọ̀ púpọ̀ wá fún mi láti kọ́ nípa ìpèsè Ọlọrun fún yíyanjú ìṣòro ilẹ̀-ayé. Rárá, kì yóò jẹ́ nípasẹ̀ àwọn ìdábàá èrò-orí kan tàbí ìṣàkóso ẹ̀dá ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí àwọn olùdánilẹ́kọ̀ọ́ ti ayé ṣe wéwèé rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, Bibeli fi hàn pé àkóso ti ọ̀run titun kan ni yóò darí àlámọ̀rí ilẹ̀-ayé. . . . Jesu Kristi kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti gbàdúrà pé: ‘Kí ìjọba rẹ dé.’ . . . Mo bẹ̀rẹ̀ sí rí i pé ìjọba yìí jẹ́ àkóso gidi kan àti pé kìkì nípasẹ̀ rẹ̀ nìkan ni ojúlówó àlàáfíà kárí-ayé yóò fi tẹ̀ wá lọ́wọ́.” Láàárín nǹkan bíi 30 ọdún, Margarita ti ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí míṣọ́nnárì ní nǹkan bí orílẹ̀-èdè Africa márùn-ún—ó ti lo ọdún 19 tí ó gbẹ̀yìn láti polongo òtítọ́ fún àwọn ènìyàn onírẹ̀lẹ̀ ní Ouagadougou, Burkina Faso.

Ìrírí Margarita kọ́ ni àkọ́kọ́ irú rẹ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti hùwàpadà lọ́nà rere bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ nígbà tí wọ́n rí i pé àwọn àlùfáà Kristẹndọm ní ìhà méjèèjì ẹgbẹ́ tí ń jagun ń gbàdúrà sí Ọlọrun fún ìṣẹ́gun. Àwọn aláìlábòsí ọkàn rí ìlọ́gbọ́n-nínú tí ń bẹ nínú àlàyé Bibeli pé Ọlọrun kò ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú ogun ènìyàn ṣùgbọ́n pé àwọn wọ̀nyí jẹyọ nítorí pé “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú naa.” Àwọn olùwá òtítọ́ kiri wọ̀nyí kọ́ pé àwọn Kristian tòótọ́ kò níláti jẹ́ “apákan ayé” bíkòṣe kí wọ́n dúró láì dásí tọ̀tún tòsì nínú àlámọ̀rí rẹ̀. Ní mímọ̀ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti mú irú ìdúró yẹn, àwọn olùfìfẹ́hàn titun wọ̀nyí ń mọ̀ dájú pé àwọn ti rí òtítọ́. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ń dàgbà nínú ìrètí àti ìdùnnú-ayọ̀ bí wọ́n ti ń jèrè ìmọ̀ púpọ̀ síi nípa ìdí tí Ọlọrun fi fàyègba ìwà ibi àti bí yóò ṣe mú àlàáfíà àti ipò òdodo wá sórí ilẹ̀-ayé láìpẹ́ nípasẹ̀ Ìjọba rẹ̀.—1 Johannu 5:19; Johannu 17:16; Matteu 6:9, 10.

Àwọn Ìlànà Tòótọ́ Bibeli Ń Mú Ìdùnnú-Ayọ̀ Wá

Daniel Rosero ti Ecuador nímọ̀lára pé ìgbésí-ayé kò nítumọ̀, nítorí náà ó bẹ̀rẹ̀ sí mu ọtí. Ṣọ́ọ̀ṣì tí ó ń lọ kọ́ ọ pé ohun kanṣoṣo tí ó lè máa fojúsọ́nà fún ní ikú àti hẹ́ẹ̀lì oníná. Ó dáhùnpadà pé, “Inú iná ni mo ń lọ, nítorí náà jẹ́ kí ń kúkú mu ọtí!” Ó ní ìdílé ọlọ́mọ mẹ́jọ tí òun kì í gbọ́bùkátà wọn, ó sì máa ń bá aya rẹ̀, Delia, jà nígbà gbogbo. Àkókò ìyípadà dé ní òwúrọ̀ ọjọ́ Sunday kan nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa bẹ̀ wọ́n wò tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. Ìgbà àkọ́kọ́ tí Daniel lọ sí àpéjọ àyíká ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, ó mọ̀ pé òun ti rí òtítọ́. Ó sọ pé: “Ètò-àjọ náà yà mí lẹ́nu. Àwọn ènìyàn náà jùmọ̀ ń ṣe nǹkan papọ̀, ní ìrọwọ́rọsẹ̀. Bí o bá wà láàárín ogunlọ́gọ̀ yìí ìwọ yóò nímọ̀lára pé ìfẹ́ wà níbẹ̀. Kò sí ẹnì kan tí ń mu sìgá. Kò sí ọ̀rọ̀ ọ̀bùn. . . . Mo rántí ríronú pé, ‘Òtítọ́ náà nìyí!’ Kì í ṣe ìbẹ̀rù ikú tàbí ìbẹ̀rù òpin ayé ni ó ru ìmọ̀lára mi sókè. Ìmọ́tónítóní ètò-àjọ náà ni.”

Ìdílé Rosero látòkèdélẹ̀ di Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ìgbésí-ayé ìdílé wọn àti ipò ọrọ̀-ajé wọn gbé pẹ́ẹ́lí síi bí wọ́n ti ń fi àwọn ìlànà Bibeli sílò. Delia Rosero sọ pé: “Ṣe ó mọ̀ pé òtítọ́ Bibeli ni ó fa gbogbo ìtẹ̀síwájú tí ó débá ìgbésí-ayé mi. Ta ni mọ ibi tí àwọn ọmọ mi ìbá wà bí kì í bá ṣe ti Ọ̀rọ̀ Ọlọrun? Gbogbo àwọn méjèèje ti ṣe ìrìbọmi wọ́n sì wàdéédéé. Òtítọ́ náà ti túmọ̀ sí ìgbésí-ayé titun pátápátá, ayọ̀ titun, fún mi.”

Ìdílé Rosero nìkan kọ́ ni ó ní iru ìrírí yìí. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní ọjọ́ wa ni àwọn ìṣòro ń kó ìdààmú bá. Ìdí kan ni pé ọ̀pá-ìdiwọ̀n ọ̀nà ìwàhíhù tí Bibeli pèsè ni a kò bọ̀wọ̀ fún mọ́ ní gbogbogbòò, bí àwọn ìran tí ó ṣáájú ti ṣe. Àwọn ìsìn tí ó pọ̀ jùlọ ti tẹ̀lé ìtẹ̀sí yìí, yálà nítorí kí a lè sọ pé wọ́n rí ara-gba-nǹkan-sí tàbí nítorí pé wọ́n ronú pé bí àkókò ṣe ń yípadà àwọn ọ̀nà ìwàhíhù ti àtijọ́ kò bá ìgbà mu mọ́. Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹlòmíràn, a fi àwọn Rosero sílẹ̀ láti máa táràrà kiri láìsí ìdarísọ́nà Bibeli. Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí irú àwọn ènìyàn onírẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ bá lóye ojú-ìwòye Ọlọrun lórí ọ̀nà ìwàhíhù àti ìgbésí-ayé ìdílé, wọ́n tètè máa ń fi ohun tí wọ́n kọ́ sílò láì jáfara. A lè rí ìyọrísí rere tí ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ń mú wá láti inú ìtàn wọn.

A Gbọ́dọ̀ Mú Ìdùnnú-Ayọ̀ Dàgbà

Bí ó ti wù kí ó rí, èyí kò túmọ̀ sí pé, ìgbà gbogbo ṣáá ni inú Kristian kan máa ń dùn. Ní kedere, àwọn ìṣòro tí gbogbo ènìyàn ní gbogbogbòò dojúkọ, irú bí àìníṣẹ́lọ́wọ́, àìsàn, àti ikú, kan àwọn Kristian pẹ̀lú. Àwọn Kristian pẹ̀lú níláti lọ́wọ́ nínú jíja ìjàkadì láì dáwọ́dúró lòdìsí àìpé àti àìlera ti ara wọn. Àkọsílẹ̀ Bibeli sọ pé “ìkẹ́ra-ẹni-bàjẹ́ ninu ìwà-àìníjàánu awọn ènìyàn aṣàyàgbàǹgbà pe òfin níjà kó wàhálà-ọkàn bá” Loti “gidigidi” ní ìlú Sodomu. Àwọn Kristian olùṣòtítọ́ kò lè yẹra fún irú ìmọ̀lára kan náà nígbà tí wọ́n bá ń rí àwọn ipò búburú tí ń gbilẹ̀.—2 Peteru 2:7, 8.

Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn wọnnì tí wọ́n ti rí òtítọ́ ní àǹfààní kan. Fún àpẹẹrẹ, onígbàgbọ́ kan tí ń ṣọ̀fọ̀ lórí ẹnì kan tí ó kú kò níláti máa “kárísọ gan-an gẹ́gẹ́ bí awọn yòókù tí kò ní ìrètí ti ń ṣe pẹlu.” Ẹ̀dùn-ọkàn rẹ̀ kì yóò jẹ́ èyí tí kò ní ààlà. Èyí jẹ́ òtítọ́ níti àwọn ìṣòro mìíràn pẹ̀lú. Ẹni náà tí ó ti rí òtítọ́ mọ̀ pé ìnira ti lọ́ọ́lọ́ọ́ wà fún ìgbà díẹ̀. Ìrètí máa ń mú kí ó rọrùn láti lo ìforítì lábẹ́ ìṣòro. Ọ̀nà ìgbésí-ayé tí ó wàdéédéé tún ń ṣèrànlọ́wọ́.—1 Tessalonika 4:13.

Paulu fún àwọn Kristian ní ọ̀rọ̀-ìyànjú yìí: “Ẹ máa yọ̀ nígbà gbogbo ninu Oluwa. Lẹ́ẹ̀kan sí i dájúdájú emi yoo wí pé, Ẹ máa yọ̀!” (Filippi 4:4) Èyí fi hàn pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ gbogbo wa lè tó ìdùnnú-ayọ̀, ó tún lè ṣeé ṣe kí ẹnì kan má ní in. Àwọn àníyàn ètò-ìgbékalẹ̀ ògbólógbòó yìí lè jẹ́ ohun-ìdínà. Ní àfikún síi, Bibeli sọ fún wa pé ó yẹ kí a mú ìdùnnú-ayọ̀ dàgbà, ọ̀kan lára àwọn èso ẹ̀mí Ọlọrun. (Galatia 5:22) Bí o bá ń bá a nìṣó láti gba ìmọ̀ òtítọ́ tí o sì ń rán ara rẹ létí àwọn ọrọ̀ tẹ̀mí tí ó ti mú wá tí ó sì ń mú wá, ìdùnnú-ayọ̀ rẹ kì yóò dínkù. Yóò máa lágbára síi bí a ṣe ń súnmọ́ àkókò náà nígbà tí Ọlọrun ‘yoo nu omijé gbogbo nù’ kúrò ní ojú àwọn ènìyàn àti nígbà tí “ọ̀fọ̀ tabi igbe ẹkún tabi ìrora” kì yóò sí mọ́.—Ìṣípayá 21:4.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ìdùnnú-ayọ̀ àti ìṣètò dáradára ti àwọn àpéjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa máa ń wú lórí

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́