Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn
Àwọn Ọmọ Kéékèèké Polongo Ìhìnrere ní Africa
KÉTÉ lẹ́yìn àjíǹde Jesu, ọkùnrin ọmọ Africa kan ṣèbẹ̀wò sí Jerusalemu. Bibeli kò sọ orúkọ rẹ̀. A mọ̀ ọ́ kìkì gẹ́gẹ́ bí “ọkùnrin kan tí ó wà ní ipò agbára lábẹ́ Kandake ọbabìnrin awọn ará Etiopia, ẹni tí ó sì ń bójútó gbogbo ìṣúra rẹ̀.” Èéṣe tí a fi mẹ́nukàn-án nínú Bibeli? Nítorí pé áńgẹ́lì kan darí Kristian ajíhìnrere náà Filipi láti polongo “ìhìnrere nípa Jesu” fún un. Ọkùnrin ará Etiopia yìí ni ọmọ Africa àkọ́kọ́ tí a ṣàkọsílẹ̀ pé ó di mẹ́ḿbà ìjọ Kristian.—Ìṣe 8:26-39.
Lónìí, ọgọ́rọ̀ọ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni ó wà ní Africa. Wọ́n ń lo gbogbo àǹfààní tí ó wà láti ṣàjọpín ìhìnrere nípa Jesu pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Àwọn ìrírí tí ó tẹ̀lé e yìí fi hàn pé àwọn ọmọ kéékèèké pàápàá ní Africa ní ipa láti sà nínú èyí.
◻ Sandy àti Priya, àwọn ọmọbìnrin méjì ọlọ́dún 11 ní Nairobi, Kenya, jẹ́ aládùúgbò. Wọ́n gbádùn ṣíṣeré papọ̀ àti ṣíṣe pàṣípààrọ̀ àwọn ìwé ìtàn. Àwọn òbí Priya bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Nísinsìnyí Priya ní àṣàyàn àwọn ìwé titun láti fi kún àkójọpọ̀ ìwé rẹ̀, èyí ní nínú ọ̀kan ní pàtàkì tí ó di ààyò rẹ̀, Fifetisilẹ si Olukọ Nla na, tí a tẹ̀jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society. Ó ṣàjọpín ìwé Olukọ Nla rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀rẹ́ rẹ̀ Sandy, àwọn ọmọbìnrin méjèèjì sì bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ déédéé.
Bí ó ti wù kí ó rí, màmá Sandy, Una, ń darapọ̀ mọ́ Ṣọ́ọ̀ṣì Anglikan kò sì fẹ́ kí ọmọbìnrin òun ka ìwé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Láìka àtakò ìyá náà sí, ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ń bá a nìṣó. Ní ọjọ́ kan Sandy bẹ màmá rẹ̀ láti tẹ́tí sí ìjíròrò wọn lẹ́ẹ̀kan péré. Àkórí tí àwọn ọmọbìnrin náà kà lọ́jọ́ náà ní àkọlé náà “Ọkunrin Meji Ti O Ṣe Ajọdun Ọjọ-ibi.” Una fetísílẹ̀ orí rẹ̀ sì wú. Ó tọ ìyá Priya lọ ní kíákíá pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìbéèrè láti inú Bibeli.
Ìyá Priya ṣètò kí Ẹlẹ́rìí kan kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú Una. Láìpẹ́ Una fúnra rẹ̀ ń ṣàjọpín ohun tí ó ń kọ́ pẹ̀lú òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ Dolly. Láàárín àkókò yìí, Priya ọmọ ọdún 11 ń tẹ̀síwájú nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ó sì pinnu láti fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ rẹ̀ sí Jehofa Ọlọrun hàn nípa ìrìbọmi ní àpéjọpọ̀ àgbègbè ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ní àpéjọpọ̀ kan náà yẹn, ẹ wo bí ó ti dùnmọ́ Priya nínú to, Una àti Dolly náà ṣe ìrìbọmi!
◻ Àwọn orílẹ̀-èdè Africa kan wà tí a kò ti fi orúkọ iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa sílẹ̀ lábẹ́ òfin. Ní ọ̀kan lára irú àwọn ilẹ̀ bẹ́ẹ̀, a fàyègba ìgbòkègbodò àti ìgbàgbọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí níbi gbogbo. Ní ilé-ẹ̀kọ́ kan ní ilẹ̀ náà, ọmọkùnrin ọlọ́dún méje kan àti ọmọkùnrin ọlọ́dún mẹ́fà àbúrò rẹ̀—àwọn ọmọ Ẹlẹ́rìí—ni a yọ̀ọ̀da fún láti kúrò ní yàrá ìkàwé nígbà tí wọ́n bá ń gba àdúrà ìsìn.
Ní ọjọ́ kan olùkọ́ titun kan fi dandan béèrè pé kí àwọn ọmọkùnrin náà darapọ̀ mọ́ àwọn ọmọ yòókù nínú àdúrà gbígbà. Ọmọkùnrin àgbà kọ̀ jálẹ̀ tíṣà náà sì nà án. Àbúrò rẹ̀ ọkùnrin, Shadrack ọmọ ọdún mẹ́fà, fi dandan lé e pé òun gbọ́dọ̀ rí olùkọ́ àgbà ní ọ́fíìsì rẹ̀. Olùkọ́ àgbà àti tíṣà titun náà bi í léèrè ìdí tí kò fi fẹ́ láti darapọ̀ mọ́ àwọn yòókù. Wọ́n bi í léèrè bóyá ó ń bẹ̀rù kí àwọn òbí rẹ̀ máṣe nà án. Ó dáhùn padà ní èdè Arabic tí ó gbámúṣé pé: “Bẹ́ẹ̀kọ́, Ọlọrun tí èmi ń sìn kì í ṣe Ọlọrun ohun rúdurùdu ṣùgbọ́n ti àlàáfíà. Èmi kò lè jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní ilé kí n sì jẹ́ ti ìsìn mìíràn ní ilé-ẹ̀kọ́!” Nítorí ìdí èyí, a yọ̀ọ̀da fún un.
Lẹ́yìn tí ó ti ṣèrìbọmi, ọkùnrin ará Etiopia tí a mẹ́nukàn nínú ìwé Ìṣe “ń bá ọ̀nà rẹ̀ lọ ó ń yọ̀.” (Ìṣe 8:39) Bákan náà lónìí, àwọn olùpòkìkí Ìjọba ní àgbáálá-ilẹ̀ Africa tí ó gbòòrò ń yọ̀ nínú àǹfààní wọn ti ‘wíwàásù ìhìnrere nípa Jesu.’—Ìṣe 8:35.