Gígun Òkè-Ńlá Tí Ó Ga Ju Ti Àwọn Himalaya Lọ
ÀWỌN Himalaya! Kí ni àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn gbé wá sí ọ lọ́kàn? Ó ha jẹ́ àwọn òkè oníyìnyín pẹ̀lú ẹ̀fúùfù líle, tí ń múni kún fún ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ bí? Ó ha jẹ́ ìmóríyá ti jíjàjàyè, ní dídúró sórí òkè tí ó ga jùlọ lórí ilẹ̀-ayé bí? Lójú èyí tí ó pọ̀ jùlọ lára wa, láti gun Òkè-Ńlá Everest, ní àwọn Himalaya ní Nepal, kì yóò ṣeé ṣe. Síbẹ̀, lónìí ọ̀pọ̀ ènìyàn ní Nepal ń gun òkè-ńlá kan tí ó ga ju àwọn òkè-ńlá ti Himalaya lọ! Ṣáájú ṣíṣe ìwádìí nípa ìrìn-àjò sí òkè-ńlá kàbìtì-kabiti yìí, ẹ jẹ́ kí a bojúwo Ìjọba Nepal tí ó kéré ṣùgbọ́n tí ó rẹwà náà.
Nepal—Ìjọba Olókè-Ńlá
Ìjọba Nepal tayọlọ́lá nítorí pé ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ilẹ̀ díẹ̀ tí ó ṣẹ́kù tí ọba ń ṣàkóso ní ayé àti pẹ̀lú nítorí pé kì í ṣe, ìjọba olóṣèlú, ṣùgbọ́n ti onísìn. Nepal ni orílẹ̀-èdè Hindu kanṣoṣo tí ó wà ní gbogbo ayé. Iye tí ó pọ̀ jùlọ lára àwọn 20 million olùgbé rẹ̀ jẹ́ Hindu. Bí ó ti wù kí ó rí, ìpilẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀yà-ìbílẹ̀ ti àwọn ènìyàn rẹ̀ jẹ́ ọlọ́kan-ò-jọ̀kan lọ́nà tí ó gadabú. Kìkì àwọn ará Tibeto-Burman ni wọ́n ń gbé ní ìhà àríwá tí ó jẹ́ ẹkùn olókè-ńlá, nígbà tí ó sì jẹ́ pé ní ìhà gúúsù onípẹ̀tẹ́lẹ̀, gbogbo àwọn ènìyàn náà fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ àwọn ará Indo-Aryan. Nepali ni èdè tí a fàṣẹ sí ní orílẹ̀-èdè náà ó sì jẹ́ èdè àbínibí nǹkan bí ìpín 60 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ènìyàn náà. Àwọn yòókù ń sọ èdè ẹ̀yà-ìbílẹ̀ tí ó lé ní 18.
Ìrísí Nepal dàbí igun mẹ́rin, kìlómítà 880 láti ìlà-oòrùn sí ìwọ̀-oòrùn àti kìlómítà 200 láti àríwá sí gúúsù. Àwọn Himalaya tí ń múni kún fún ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀, èyí tí ó pààlà sí ìhà àríwá, ní nínú Òkè-Ńlá Everest, òkè tí ó ga jùlọ ní ayé ní mítà 8,848, àti àwọn òkè mẹ́jọ mìíràn tí ó ju 8,000 mítà lọ. Ní àárín gbùngbùn Nepal ni àwọn òkè-ńlá tí kò ga púpọ̀ àti àwọn adágún àti erékùṣù wà. Ní ìsàlẹ̀ ìhà gúúsù, tí ó bá India pààlà, ni ilẹ̀ Tarai tí ó lọ́ràá wà, ẹkùn tí a ń lò jùlọ fún iṣẹ́ àgbẹ̀.
Kathmandu, olú-ìlú náà, tí ó wà ní ẹkùn àárín gbùngbùn, jẹ́ ibi tí ó ń gbádùnmọ́ àwọn arìnrìn-àjò nítòótọ́. Ọkọ̀ òfúúrufú lè gbéra láti ibẹ̀ lọ sórí àwọn òkè-ńlá àwòyanu náà, kí ó rin ìrìn-àjò lọ sí àwọn ọgbà ẹranko, àti ọ̀pọ̀ àwọn ibi tí a ti lè fójú lóúnjẹ ní àdúgbò. Nígbà mìíràn Nepal ni a ń pè ní erékùṣù àwọn ọlọrun nítorí pé ìsìn ń kó ipa pàtàkì nínú ìgbésí-ayé àwọn ènìyàn rẹ̀. Nítorí ìsìn ni àràádọ́ta ọ̀kẹ́ káàkiri ayé fi ń rìn lọ sí orí “òkè-ńlá” tí ó ga ju ti àwọn Himalaya lọ.
Ní nǹkan bíi 2,700 ọdún sẹ́yìn, wòlíì Heberu náà Isaiah ni a mí sí láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé “ní ọjọ́ ìkẹyìn, a óò fi òkè ilé Oluwa kalẹ̀ lórí àwọn òkè ńlá . . . Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni yóò sì lọ, wọn óò sì wí pé, Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a lọ sí òkè Oluwa . . . Òun óò sì kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀, àwa óò sì máa rìn ní ipa rẹ̀.” (Isaiah 2:2, 3) Níhìn-ín ìjọsìn mímọ́ gaara ti Jehofa, Ẹlẹ́dàá àti Olùṣàkóso Ọba-Aláṣẹ àgbáyé, tí a gbéga ni a fi wé òkè-ńlá, tí a gbéga sókè ju gbogbo àwọn ọ̀nà ìjọsìn yòókù tí ó dàbí òkè. Ó jẹ́ kókó-ọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ àgbáyé tí ń ran àwọn ènìyàn tí ebi òtítọ́ ń pa lọ́wọ́ láti mọ̀ nípa àwọn ọ̀nà Jehofa. Báwo ni iṣẹ́ yìí ṣe bẹ̀rẹ̀ ní Nepal?
Ìbẹ̀rẹ̀ Ráńpẹ́
Sójà kan nínú Ẹgbẹ́ Ọmọ Ogun Britain nígbà Ogun Àgbáyé II ń wá ìsìn tòótọ́ kiri. Àwọn òbí rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ará Nepal onísìn Hindu tí di onísìn Katoliki. Bí ó ti ń dàgbà, ó rí ìwà òmùgọ̀ tí ó wà nídìí ìbọ̀rìṣà, ó kọ àwọn ẹ̀kọ́ bí ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ hẹ́ẹ̀lì oníná, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣàyẹ̀wò àwọn ìgbàgbọ́ ṣọ́ọ̀ṣì Protẹstanti. Ṣùgbọ́n kò tẹ́ ẹ lọ́rùn.
Nígbà tí àwọn ará Japan mú un gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́wọ̀n ní ibi tí a ń pè ní Rangoon ní Burma, nígbà náà, sójà yìí gbàdúrà pé kí òun lè la hílàhílo ibùdó ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ já láti lè máa bá ìwákiri òun fún ìjọsìn tòótọ́ lọ. Lẹ́yìn náà, ó gbìyànjú láti ja àjàbọ́ kúrò lọ́wọ́ àwọn tí ó mú un, olùkọ́ ilé-ẹ̀kọ́ kan sì ràn án lọ́wọ́ ẹni tí òun rí ìwé pẹlẹbẹ náà Where Are the Dead?, tí J. F. Rutherford kọ, nínú ilé rẹ̀. Ní lílóye òkodoro òtítọ́, ó fi pẹ̀lú ìháragàgà gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kàn sí i ní Rangoon ní 1947. Láàárín oṣù díẹ̀, ó ṣe ìrìbọmi, aya rẹ̀ kékeré sì ṣe ìrìbọmi láìpẹ́ lẹ́yìn náà. Wọ́n pinnu láti padà sí India, wọ́n sì fìdí kalẹ̀ sí ìlú wọn ní Kalimpong, ní ìhà àríwá ìlà-oòrùn àwọn òkè-ńlá. Níhìn-ín ni wọ́n bí àwọn ọmọ wọn méjèèjì sí tí wọ́n sì ti lọ sí ilé-ẹ̀kọ́. Ní March 1970, wọ́n ṣí lọ sí Kathmandu.
Òfin Nepal ka sísọni di aláwọ̀ṣe léèwọ̀. Ẹnikẹ́ni tí ọwọ́ bá tẹ̀ pé ó ń tan ìsìn tí a fẹnu lásán pè ní ti òkèèrè kálẹ̀ yóò fi ẹ̀wọ̀n ọdún méje jura, ẹni tí ó bá sì darapọ̀ mọ́ irú ìsìn bẹ́ẹ̀ ni wọ́n lè jù sí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́ta pẹ̀lú owó ìtanràn tí kò mọníwọ̀n. Nítorí ìdí èyí ìjẹ́rìí jẹ́ èyí tí a níláti fi ìṣọ́ra ṣe. Iṣẹ́-òjíṣẹ́ ilé-dé-ilé túmọ̀ sí kíkàn sí ilé kan, lẹ́yìn náà kí a gbéra lọ sí agbègbè mìíràn kí a sì ṣe ìkésíni níbẹ̀. Lọ́nà tí ó yéni, ìjẹ́rìí aláìjẹ́-bí-àṣà kó ipa pàtàkì nínú títan ìhìnrere náà kálẹ̀.
Ìtẹ̀síwájú náà kò tètè dé. Pẹ̀lú iye àwọn olùgbé bí àádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà mẹ́wàá, pápá náà dàbí èyí tí ó kó ìrẹ̀wẹ̀sì báni. Irúgbìn òtítọ́ náà ni a ń fún bí kìkì ìdílé ẹlẹ́rìí yìí ṣe ń jẹ́rìí fún àwọn ọ̀rẹ́, ojúlùmọ̀, agbanisíṣẹ́, àti alájùmọ̀ṣiṣẹ́pọ̀ wọn. Wọ́n ń ṣe ìpàdé déédéé nínú ilé wọn wọ́n sì ń késí àwọn olùfìfẹ́hàn láti darapọ̀ mọ́ wọn. Nígbẹ̀yìn gbẹ́yín, ní March 1974, lẹ́yìn ọdún mẹ́rin ti gbígbìn àti bíbomirin láìdábọ̀, àmújáde-èso àkọ́kọ́ láti Nepal wá—ìyẹn sì wá láti orísun kan tí a kò retí!
Nígbà tí ó ń ṣe ìbẹ̀wò sí ilé kan, akéde náà bá ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan sọ̀rọ̀ ẹni tí ó jẹ́ akọ̀wé fún mẹ́ḿbà ìdílé ọba. Ọkùnrin náà wí pé: “Bá ọmọkùnrin mi sọ̀rọ̀.” Ọmọkùnrin náà gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. Lẹ́yìn àkókò díẹ̀ ó yí iṣẹ́ rẹ̀ padà, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ilé tẹ́tẹ́ ni ó ti ń ṣiṣẹ́. Bàbá rẹ̀, tí ó jẹ́ olùfọkànsìn Hindu, takò ó. Síbẹ̀, ọ̀dọ́mọkùnrin náà mú ìdúró rẹ̀ síhà ọ̀dọ̀ Jehofa. Kí ni ìyọrísí rẹ̀? Nígbà tí ó ṣe bàbá rẹ̀ dẹ́kun títakò ó, àwùjọ àwọn ìbátan rẹ̀ tímọ́tímọ́ sì tẹ́wọ́gba òtítọ́ Bibeli. Ó ń ṣiṣẹ́sìn nísinsìnyí gẹ́gẹ́ bí alàgbà nínú ìjọ Kristian.
Láti dúró gẹ́gẹ́ bí alágbára nípa tẹ̀mí kí a sì kọbiara sí àṣẹ Ìwé Mímọ́ láti máṣe kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀, àwùjọ kékeré náà ní Kathmandu ń ṣe ìpàdé déédéé nínú ilé àdáni kan. Ṣùgbọ́n dé àyè gíga, kò ṣeé ṣe fún àwọn ará náà láti lọ sí àwọn àpéjọ tí ó tóbi. Àwọn wọnnì tí ó lè ṣe bẹ́ẹ̀ rin ìrìn-àjò lọ sí India fún àwọn àpéjọ—ìrìn-àjò jíjìnnà tí ó sì ń náni lówó la ọ̀wọ́ àwọn òkè-ńlá já.
Ẹ wo àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ onídùnnú-ayọ̀ tí ó jẹ́ nígbà tí a ṣe ìgbékalẹ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọpọ̀ àgbègbè náà látòkèdélẹ̀ nínú ilé náà tí wọ́n ti ń ṣe ìpàdé wọn! Fojúwòye arákùnrin mẹ́rin, títíkan mẹ́ḿbà kan láti ẹ̀ka India, tí ń bójútó ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà látòkèdélẹ̀! Àní a ṣe ìgbékalẹ̀ àwòkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pàápàá. Báwo? A ti ya fọ́tò àwòrán ara ògiri nígbà ìmúrasílẹ̀ tí a ṣe bí a óò ṣe gbé e kalẹ̀ gan-an ní India. Ní Nepal, a gbé àwòrán ara ògiri wọ̀nyí jáde lára aṣọ títa, pẹ̀lú ohùn tí a ti gbà sínú téèpù. Àwùjọ náà nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Báwo ni àwùjọ náà ṣe tóbi tó? Ènìyàn 18!
Ìrànlọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù láti òkèèrè kéré. Iṣẹ́ míṣọ́nnárì kò ṣeé ṣe rárá, kò sì rọrùn fún àwọn àjòjì láti rí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn Ẹlẹ́rìí méjì tí wọ́n jẹ́ ará India rí iṣẹ́ ní Nepal ní àwọn àkókò tí ó yàtọ̀ síra, ní lílo ọdún mélòókan ní Kathmandu tí wọ́n sì ṣèrànlọ́wọ́ láti gbé ìjọ tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ ró. Nígbà tí yóò fi di 1976 àwọn akéde Ìjọba 17 ti wà ní Kathmandu. Ní 1985 àwọn ará kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tiwọn. Nígbà tí wọ́n parí rẹ̀, a bẹ̀rẹ̀ síí ṣe, àpéjọpọ̀ àgbègbè ọdọọdún, àti àwọn àpéjọ mìíràn, níbẹ̀ déédéé. Gbọ̀ngàn náà nítòótọ́ ni ibi ìkóríjọ fún ìjọsìn mímọ́ gaara ní àdádó, agbègbè ìpínlẹ̀ olókè-ńlá yẹn.
Ìmúgbòòrò Láìka Ìṣòro Sí
Ní àwọn ọdún ìbẹ̀rẹ̀ yẹn, iṣẹ́ ìwàásù náà, tí a ń fi tìṣọ́ra tìṣọ́ra ṣe, kò tí ì pe àfiyèsí púpọ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn aláṣẹ. Ṣùgbọ́n, ní apá ìparí 1984, a bẹ̀rẹ̀ sí gbé ìkálọ́wọ́kò kalẹ̀. A fàṣẹ ọba mú arákùnrin kan àti arábìnrin mẹ́ta a sì fi wọ́n pamọ̀ sí àhámọ́ fún ọjọ́ mẹ́rin ṣáájú kí a tó dá wọn sílẹ̀ pẹ̀lú ìkìlọ̀ pé kí wọ́n máṣe máa bá ìgbòkègbodò wọn nìṣó mọ́. Ní abúlé kan, a fàṣẹ ọba mú ẹni mẹ́sàn-án nígbà tí wọ́n ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli nínú ilé wọn. A fi àwọn mẹ́fà sí ọgbà ẹ̀wọ̀n fún ọjọ́ 43. Ìfàṣẹ ọba mú àwọn mélòókan mìíràn wáyé, ṣùgbọ́n a kò gbé ìgbésẹ̀ kankan tí ó bófinmu.
Láìpẹ́ yìí ní 1989, gbogbo àwọn arákùnrin àti arábìnrin ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ kan ni a fàṣẹ ọba mú, a há wọn mọ́ fún ọjọ́ mẹ́ta, a sì dá wọn sílẹ̀. Nígbà mìíràn, a ní kí wọ́n fọwọ́ sí àkọsílẹ̀ tí ó sọ pé àwọn kì yóò wàásù mọ́. Wọ́n kọ̀. A dá àwọn kan sílẹ̀ kìkì lẹ́yìn tí wọ́n bá ti fọwọ́ sí àkọsílẹ̀ náà pé wọ́n yóò múratán láti dojúkọ àbájáde náà bí a bá tún mú wọn pé wọ́n ń wàásù.
Láìka irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀ sí, àwọn arákùnrin ń bá a nìṣó ní wíwàásù ìhìnrere Ìjọba náà pẹ̀lú ìtara. Fún àpẹẹrẹ, ní 1985, ọdún náà lẹ́yìn tí ìjọba bẹ̀rẹ̀ sí dásí i, ìbísí ìpín 21 lórí ọgọ́rùn-ún wà nínú iye àwọn tí ń wàásù. Akéde 35 náà lo ìpíndọ́gba 20 wákàtí ní oṣù kan ní bíbá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa ìjọsìn mímọ́ gaara.
Bí àkókò ti ń lọ, ìyípadà nínú ètò òṣèlú bẹ̀rẹ̀ sí wáyé ní Nepal. Àwọn òṣìṣẹ́ olóyè ìjọba bẹ̀rẹ̀ sí mọ̀ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kò léwu. Níti tòótọ́, iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bibeli wọn ní ìyọrísí tí ó ṣàǹfààní, tí ó sì gbé àwọn ènìyàn náà ró, ní sísọ wọn di ọlọ̀tọ̀ tí ó dára síi. Àwọn òṣìṣẹ́ olóyè rí i pé àìlábòsí, ìṣiṣẹ́ kára, àti ìwàrere adúróṣinṣin ni a ń tẹnumọ́ gẹ́gẹ́ bí ohun pàtàkì tí a ń béèrè fún lọ́wọ́ àwọn olùjọsìn Jehofa.
A fúnni ni ìjẹ́rìí tí ó jíire nígbà tí obìnrin kan tí ó jẹ́ olùfọkànsìn Hindu tẹ́lẹ̀rí di Ẹlẹ́rìí tí ó sì kọ̀ láti gba ẹ̀jẹ̀ sára. Ẹnu ya àwọn dókítà náà fún ìpinnu, àti ìdúró rẹ̀ bí ẹni tí òye yé. A ran obìnrin yìí lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ pẹ̀lú ìrànwọ́ ìwé pẹlẹbẹ náà Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae! Láìka àtakò àti ìfiniṣẹlẹ́yà sí láti ọ̀dọ̀ ìdílé rẹ̀, ó ṣe ìrìbọmi ní 1990 bí ó ti ń súnmọ́ 70 ọdún. Lẹ́yìn náà ó fi ẹsẹ̀ dá, tí ó sì ń jìyà lọ́wọ́ àwọn ìṣòro mìíràn, wọ́n níláti ṣe iṣẹ́ abẹ tí ó le fún un. Fún ọ̀sẹ̀ méjì ó takú mọ́ àwọn dókítà àti ìbátan rẹ̀ lọ́wọ́ pé òun kò ní gba ẹ̀jẹ̀. Níkẹyìn, àwùjọ àwọn oníṣẹ́ abẹ ṣe iṣẹ́ abẹ́ náà láṣeyọrí láìlo ẹ̀jẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ̀nba ni ó lè rìn mọ báyìí, arábìnrin olùṣòtítọ́ yìí ń jókòó ní ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ láràárọ̀ ó sì ń késí àwọn tí ń lọ tí ń bọ̀ láti jókòó pẹ̀lú òun kí wọ́n sì gbọ́ àwọn ìhìnrere adùnyùngbà díẹ̀.
Nepal Lónìí
Báwo ni nǹkan ṣe rí ní Nepal lónìí? Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń gbádùn òmìnira ìjọsìn dé àyè tí ó dára bíi ti àwọn ará wọn kárí-ayé. Láti ìgbà tí àwọn olùgòkè ìṣàpẹẹrẹ kan tàbí méjì ti bẹ̀rẹ̀ sí darapọ̀ mọ́ àwọn wọnnì tí ń gun òkè-ńlá ti ìjọsìn tòótọ́, iye àwọn ènìyàn tí ń pọ̀ síi ti wí pé, ‘Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a lọ sí òkè-ńlá ti Jehofa.’ Nígbà tí yóò fi di 1989 àwọn tí ìpíndọ́gba wọn tó 43 ni ó ti wà tí ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù náà, 204 sì pésẹ̀ síbi Ìṣe-Ìrántí ikú Kristi ní ọdún yẹn.
Nígbà náà, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣèlérí, Jehofa bẹ̀rẹ̀ sí mú kí ìkójọpọ̀ àwọn olùwá òtítọ́ kiri náà sínú ilé rẹ̀ yára kánkán. (Isaiah 60:22) Láìpẹ́ yìí a dá ìjọ kejì sílẹ̀ ní Kathmandu, àwọn àwùjọ àdádó méjì sì wà ní ẹ̀yìn-òde olú-ìlú náà nísinsìnyí. Ní April 1994, 153 àwọn Kristian ni ó ròyìn ìgbòkègbodò ìwàásù—ìbísí ìpín 350 lórí ọgọ́rùn-ún ní ohun tí kò tí ì tó ọdún márùn-ún! Wọ́n darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé 386 pẹ̀lú àwọn olùfìfẹ́hàn. Nígbà Ìṣe-Ìrántí ní 1994, iye àwọn 580 tí ó wá múnilóríyá. Fún ọjọ́ àpéjọ àkànṣe, àwọn 635 kún inú gbọ̀ngàn náà fọ́fọ́, 20 sì ṣe ìrìbọmi. Nítorí náà ìbísí ńláǹlà tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń gbádùn káàkiri-ayé ń ṣẹlẹ̀ ní Nepal kékeré pẹ̀lú.
Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí iye ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a mú jáde ní èdè Nepali ti pọ̀ síi lọ́nà tí ó gadabú, ní ríran àwọn onírẹ̀lẹ̀ lọ́wọ́ láti di òtítọ́ náà mú gírígírí. Àwọn olùtúmọ̀ tí a dálẹ́kọ̀ọ́ ní ọ́fíìsì ẹ̀ka India láti lo àwọn ọgbọ́n ìtúmọ̀ àti kọ̀m̀pútà ń ṣiṣẹ́sìn nísinsìnyí ní àkókò kíkún ní Kathmandu. Bí a ti mú wọn gbaradì fún ìmúgbòòrò síi, àwọn olùgòkè-ńlá atẹ̀lé ìlànà ìṣàkóso Ọlọrun tí wọ́n jẹ́ olùgbé Nepal ń tẹ̀síwájú!
Gun Òkè Tí Ó Ga Ju Ti Àwọn Himalaya Lọ
Ìwọ pẹ̀lú lè gbádùn gígun òkè-ńlá tí ó ga ju ti àwọn Himalaya lọ. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, kì í ṣe àwọn ará Nepal nìkan ni ìwọ yóò darapọ̀ mọ́ bíkòṣe àràádọ́ta ọ̀kẹ́ “lati inú gbogbo awọn orílẹ̀-èdè ati ẹ̀yà ati ènìyàn ati ahọ́n.” (Ìṣípayá 7:9) Pẹ̀lú wọn, ìwọ yóò gbádùn gbígba ìtọ́ni láti ọ̀dọ̀ Ẹlẹ́dàá àwọn òkè-ńlá kàbìtì-kabiti irú àwọn èyí ti ó wà ní Nepal. Ìwọ yóò rí i bí Ẹlẹ́dàá náà “ṣe ń mú àwọn ọ̀ràn tọ́,” ìwọ yóò sì lè máa fojúsọ́nà fún wíwàláàyè títíláé lórí ilẹ̀-ayé tí a fọ̀ mọ́ tí a sì sọ di ẹlẹ́wà.—Isaiah 2:4, NW.
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 24]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Kathmandu
Òkè-Ńlá Everest
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Lóde Gbọ̀ngàn Ìjọba ní Kathmandu
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Ọ̀pọ̀ àwọn ará Nepal ń jàǹfààní láti inú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli