Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn
A Ó Ṣe Inúnibíni sí Àwọn Kristian Tòótọ́
LÁTI ọjọ́ Abeli wá, ọ̀pọ̀ lára àwọn ìránṣẹ́ Jehofa ti fara da inúnibíni ti ìsìn. (Luku 11:49-51) Kò sì yani lẹ́nu, nítorí Bibeli kìlọ̀ pé “gbogbo awọn wọnnì tí wọ́n ń ní ìfẹ́-ọkàn lati gbé pẹlu ìfọkànsin Ọlọrun ní ìbákẹ́gbẹ́ pẹlu Kristi Jesu ni a óò ṣe inúnibíni sí pẹlu”! (2 Timoteu 3:12) Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, lónìí, ní èyí tí ó ju orílẹ̀-èdè 25 lọ, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa wà lábẹ́ ìfòfindè, wọ́n sì ń fara da inúnibíni.
Ní orílẹ̀-èdè kan níbi tí kì í ti í ṣe pé a fòfin de àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nìkan ni ṣùgbọ́n tí a tún ń ṣe inúnibíni sí wọn láti ọwọ́ àwọn onísìn, iye tí ó lé ní 12,000 akéde ìhìnrere ń bá a nìṣó láti máa ṣiṣẹ́ tìtaratìtara, ní kíkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú iye tí ó ju 15,000 àwọn ènìyàn lọ. Àmọ́ ṣáá o, iṣẹ́ ìwàásù wọn ni wọ́n ń fọgbọ́n ṣe. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, wọ́n ń ṣe àwọn ìpàdé Kristian wọn nínú àwọn ilé àdáni, wọ́n sì máa ń ṣọ́ra nígbà tí wọ́n bá ń ké sí àwọn olùfìfẹ́hàn wá sí irú àwọn ìpàdé bẹ́ẹ̀.
Ní àìpẹ́ yìí, ìjọba ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ìṣarasíhùwà tí ó túbọ̀ fàánú hàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí, àwọn tí ń ṣe èyí tí ó pọ̀ jù nínú iṣẹ́ wọn nísinsìnyí láìsí ìdílọ́wọ́ oníjàgídíjàgan. Bí ó ti wù kí ó rí, onírúurú àwọn àwùjọ onísìn ti lo agbára ìdarí wọn láti ru ìjàngbọ̀n sókè.
Ní ìlú-ńlá kan àwọn awọ́jọ-kọluni tí inú ń bí tí wọ́n ní nǹkan bí 200 àwọn agbawèrèmẹ́sìn nínú, tò lọ sí ilé kan níbi tí nǹkan bí 50 àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tí ń ṣe ìpàdé ìjọ wọn. Àwọn kan lára àwọn awọ́jọ-kọluni náà gbé òkúta lọ́wọ́ wọ́n sì ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ amóríwú ti ìsìn sókè fatafata. Ó hàn gbangba pé èrò inú wọn ni láti kọlu àwọn Ẹlẹ́rìí kí wọ́n sì ba ilé náà jẹ́. Ó dájú gbangba pé àwọn aṣáájú ìsìn ti ń ṣọ́ ìgbòkègbodò ìpàdé náà fún sáà kan wọ́n sì ti ń dúró de àkókò tí ó tọ́ láti kọ lù wọ́n. Ó kù díẹ̀ kí àwọn awọ́jọ-kọluni náà wọ ilé náà nígbà tí àwọn ọlọ́pàá 15 dé tí wọ́n sì pàṣẹ fún àwọn àwùjọ náà láti túká. Èyí jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu fún àwọn Ẹlẹ́rìí náà, níwọ̀n bí kò ti sí ọ̀kankan nínú wọn tí ó tilẹ̀ rí àyè láti pe àwọn ọlọ́pàá.
Bí ó ti wù kí ó rí, ní àwọn àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn, àwọn alátakò máa ń túbọ̀ ṣe àṣeyọrí. Ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí ni a ti pè lẹ́jọ́ tí a sì ti rán lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n. Ọ̀ràn kan ní ilé-ẹjọ́ ni a ti ń sún síwájú fún ọdún mélòó kan, ó sì dájú gbangba pé àwọn olùpẹ̀jọ́ kò ní ọkàn-ìfẹ́ nínú rẹ̀ mọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí àwùjọ àlùfáà àdúgbò súnná sí i, ọ̀ràn náà ni a tún mú wá sí ilé-ẹjọ́ padà, tí a sì fi àwọn Ẹlẹ́rìí náà sí ọgbà ẹ̀wọ̀n.
Ní ibòmíràn àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí pàdé ní ilé àdáni kan láti ṣèrántí Oúnjẹ Alẹ́ Oluwa. Lálẹ́ ọjọ́ náà àwọn ọlọ́pàá mélòó kan fàṣẹ ọba mú onílé náà àti alàgbà tí ó darí ìpàdé náà. Ní àgọ́ ọlọ́pàá, wọ́n lù wọ́n yíiyìi. Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò oníkà bá a lọ fún wákàtí mélòó kan. Ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí náà tún fara da ìdálóró ti fífi í sínú kànga tí ó ní omi tútù nínú.
Èé ṣe tí àwọn ọlọ́pàá fi ń gbé irú ìkọlù báyìí dìde? Lẹ́ẹ̀kan sí i, àwùjọ àwọn agbawèrèmẹ́sìn, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn àwùjọ àlùfáà àdúgbò, wà lẹ́yìn ìwà àwọn ọlọ́pàá náà. Níkẹyìn ọ̀gá ọlọ́pàá ṣí i payá pé àwọn ìfàṣẹ-ọba-múni náà ni a ṣe láìgbàṣẹ lọwọ́ òun. Wọ́n tọrọ àforíjì, àwọn ẹnì tí ó lù wọ́n ni a fìyà jẹ.
Jákèjádò ayé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń bá a lọ láti máa wàásù ìhìnrere Ìjọba Ọlọrun, àní ní ojú àtakò líle koko pàápàá. Wọ́n tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jesu pé: “Wò ó! Mo ń rán yín jáde gẹ́gẹ́ bí àgùntàn sáàárín awọn ìkookò; nitori naa ẹ jẹ́ oníṣọ̀ọ́ra gẹ́gẹ́ bí ejò síbẹ̀ kí ẹ jẹ́ ọlọ́rùnmímọ́ gẹ́gẹ́ bí àdàbà.”—Matteu 10:16.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Abeli ni ẹni àkọ́kọ́ tí a ṣe inúnibíni sí